O Ha Máa Ń Jẹ Eyín Rẹ Bí?
ÀTAYÉBÁYÉ ni àwọn ènìyàn ti ń jẹ eyín wọn tí wọ́n bá ní àìfararọ. Bíbélì sábà ń lo jíjẹ eyín, tàbí pípa eyín keke láti tọ́ka sí ìrunú tàbí làásìgbò. (Jóòbù 16:9; Mátíù 13:42, 50) Nínú ayé òde òní tí ó kún fún ìbínú àti àìfararọ, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ni a ń rí tí wọ́n ń jẹ eyín, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò sì mọ̀ pé àwọn ń ṣe bẹ́ẹ̀. Eyín wọn lè máa jẹ.
Kí ló ń fà á tí àwọn ènìyàn kan máa ń jẹ eyín wọn? Àwọn ohun tí ń fà á díjú, a kò sì tí ì lóye wọn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ọ̀ràn kan, àìfararọ tí ìṣòro ìmọ̀lára ń fà hàn gbangba bí ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó máa fà á. Lẹ́tà ìròyìn UC Berkeley Wellness Letter tọ́ka pé: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń jẹ eyín wọn sábà máa ń ròyìn pé àwọn ń ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó tàbí ètò ìnáwó, ṣíṣe ìdánwò àṣekágbá, ìbẹ̀rù pípàdánù iṣẹ́ àwọn, tàbí bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn wà nínú pákáǹleke.” Àwọn okùnfà àti ohun mìíràn tí ń dá kún un ni ìfarakanra eyín òkè àti ti ìsàlẹ̀ lọ́nà tí ó lábùkù, ìdíwọ́ lójú oorun, tàbí mímu ọtí líle. Nítorí náà, lẹ́tà ìròyìn náà, Wellness Letter, dámọ̀ràn pé kí àwọn tó ń ṣe gbìyànjú láti dín ìwọ̀n ọtí lílé; tí wọ́n ń mu kù, kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ rírọrùn láti sinmẹ̀dọ̀ kí wọ́n tó sùn, bíi fífi omi lílọ́wọ́ọ́wọ́ wẹ̀; tàbí sísọ àwọn ìṣòro tí ń dà wọ́n láàmú fún ọ̀rẹ́ kan tàbí olùgbaninímọ̀ràn kan tí ó ṣeé finú tán.
Lọ́sàn-án, o lè ṣàkíyèsí pé o ń jẹ eyín rẹ tàbí pé o ń fi wọ́n gbo ara wọn. Ṣùgbọ́n báwo ni o ṣe lè mọ̀ bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójú oorun? Nígbà mìíràn, jíjẹ ẹ́ lọ́nà tí ó ti di bárakú, tí a mọ̀ sí àṣà ìjeyín, máa ń mú ìró kan tí dídún rẹ̀ lọ sókè gan-an tí yóò fi lè jí ẹlòmíràn tí ń sùn nínú iyàrá kan náà sílẹ̀ wá. Ẹ̀bátí lè máa sán ọ bí o bá jí, páárì rẹ sì lè máa pariwo pẹkẹpẹkẹ.a Olùtọ́jú eyín rẹ tilẹ̀ lè kíyè sí i pé eyín rẹ ń jẹ jù. Ó lè dámọ̀ràn àwọn ohun díẹ̀ tí o lè ṣe láti dín in kù, bí ìhùmọ̀ kan tí ìwọ yóò gbé sórí eyín rẹ ní alẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ṣe irú ohun adáàbòbo ẹnu yìí láti máà jẹ́ kí o máa jẹ eyín, ó lè dáàbò bo eyín rẹ kí ó má baà bàjẹ́ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, má fòyà! Bí ìdààmú rẹ bá ṣe dín kù tó ni jíjẹ eyín rẹ yóò ṣe dín kù tó.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ wo Jí!, ìtẹ̀jáde November 22, 1991, ojú ìwé 20 sí 22.