ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/22 ojú ìwé 13-15
  • Àwọn Ìwé Kíkéréjù Tí Ó Wuni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìwé Kíkéréjù Tí Ó Wuni
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apá Kan Iṣẹ́ Ọnà
  • Bíbélì Thumb
  • Àwọn Ìdìpọ̀ Ìwé Mímọ́ Tí Kò Wọ́pọ̀
  • Èwo Ló Kéré Jù Lọ?
  • Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ẹni Tó Kọ Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Iṣẹ́ Tí Jèhófà Rán Sí Àwọn Èèyàn Ayé Ọjọ́un Ṣì Wà Fún Wa Lónìí
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ohun Tí Ó Wà Nínú Ìwé Náà
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/22 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ìwé Kíkéréjù Tí Ó Wuni

LÁTI ỌWỌ́ ASOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ NÍ BRITAIN

ÀWỌN ohun tí ìwọ̀n wọn kọjá ààlà máa ń ru ìfẹ́ ìtọpinpin ẹni sókè—òkè tí ó ga jù lọ, òkun tí ó jindò jù lọ, ilé gígajùlọ, ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ó gùn jù lọ—nítorí náà, ìwé tí ó kéré jù lọ ńkọ́? Àwọn ìwé kíkéréjù máa ń wuni! Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn tí ń sọ nípa gbogbo kókó ọ̀rọ̀ tí a lè finú wòye ní 20 èdè, ó kéré tán, ni a ti tẹ̀ jáde. Bí o kò bá tíì ṣàyẹ̀wò wọn rí, wò wọ́n nísinsìnyí.

Báwo ni a ṣe lè ṣàlàyé ìwé kíkéréjù kan? Ohun tí gbogbo ènìyàn fara mọ́ ni ìwé kan tí kò gùn ju mìlímítà 76 lọ, tí kò sì fẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n wọn páálí ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́ ọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣàkójọ kan tí wọ́n ní ìṣọ́ra gidigidi fẹ́ láti wọn àwọn abala ìwé náà nìkan. Èé ṣe tí a fi ń tẹ àwọn ìwé kíkéréjù wọ̀nyí?

Apá Kan Iṣẹ́ Ọnà

Yàtọ̀ sí ohun tí ẹnì kan lè retí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé kíkéréjù ló ṣeé rí kà kedere. A lè tipa bẹ́ẹ̀ máa gbé àwọn ìsọfúnni nípa ojú ọjọ́ nínú ọdún, ìwé ìtàn àkànṣe, ìwé ìtàn àròsọ, ìwé eré onítàn, ìwé atúmọ̀ èdè, àti àwọn ìwé mímọ́ ìsìn kiri, kí a sì máa lò wọ́n láìsí iṣẹ́ ńlá kan níbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ì bá ti jẹ́ ìdí pàtàkì tí a fi ní láti ní irú àwọn ìwé kéékèèké bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọdún kan sẹ́yìn, àníyàn aṣàkójọ kan lóde òní túbọ̀ dá lórí apá mìíràn nínú àwọn ìwé kíkéréju: òye iṣẹ́ tí àwọn tí wọ́n tẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì ṣe ìdìpọ̀ wọ́n ní.

Àwọn òǹtẹ̀wé ní láti borí ọ̀pọ̀ ìṣòro tí ó jẹ mọ́ òye iṣẹ́ kí wọ́n tó lè ṣe ọnà rẹ̀, kí wọ́n sì lo ìkọ̀wé tí yóò ṣeé kà, ní lílo awò amúǹkantóbi tàbí láìlò ó. Wọ́n ti tipa èyí ṣe àwọn ìwé tí ó lẹ́wà gan-an. Àwọn tí ń ṣe bébà àti tàdáwà pẹ̀lú lo òye iṣẹ́ wọn láfikún láti rí i pé àwọn ojú ìwé tí a tẹ̀ jáde rí nigínnigín.

Lẹ́yìn títẹ̀wé kan, wọn óò ṣe ìdìpọ̀ rẹ̀; ṣíṣe ìdìpọ̀ àwọn ìwé kíkéréjù sì lè ṣẹlẹgẹ́. Òye iṣẹ́ àwọn oníṣẹ́ ọnà hàn gbangba nínú ìmújáde àwọn èèpo ẹ̀yìn ìwé kéékèèké tí a fi awọ, iṣẹ́ ọnà oníwúrà tàbí fàdákà, ìkarawun ìjàpá, tàbí ohun dídán tí a fi irin iṣẹ́ ọwọ́ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ṣe. A fi sílíkì tàbí àrán ṣe àwọn èèpo ẹ̀yìn ìwé mìíràn tàbí kí a fi abẹ́rẹ́ ṣe ọnà sí wọn lára tàbí kí a tilẹ̀ fi àwọn péálì àti ohun dídángbinrin ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn ìwé kan sì ní àwọn àpò-ìfìwésí láti dáàbò bò wọ́n.

Àwọn oníṣọ̀nà tí wọ́n ya àwọn àwòrán inú ìwé náà ṣẹ̀dá àwọn àwòrán oníkúlẹ̀kúlẹ̀ lọ́nà tí ó yani lẹ́nu, tí ó sábà máa ń gba àyè tí kò tó sẹ̀ǹtímítà méje níbùú lóròó lórí bébà! Àpẹẹrẹ kan ni ti fọ́tò Ọ̀mọ̀wé Samuel Johnson, òǹṣèwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì kan, tí ó wà nínú ìwé atúmọ̀ èdè olójú ìwé 368 náà, Bryce’s Thumb English Dictionary, tí a tẹ̀ jáde ní àwọn ọdún 1890; òmíràn sì ni àwòrán tí ó dojú kọ ojú ewé àkọlé ìwé tí Shakespeare ṣe náà, King Richard III, tí ó fi yẹ́ obìnrin òṣèré orí ìtàgé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Ellen Terry, sí ní 1909.

Ìwé Bibliothèque Portative du Voyageur, tí wọ́n ṣe ní Paris, jẹ́ ìwé kíkéréjù tí a rò pé Napoléon Bonaparte ń gbé kiri nígbà ìgbétáásì ológun rẹ̀. Ìdìpọ̀ 49 rẹ̀ tí ó jẹ́ àkànṣe ti èdè Faransé ni a fi pamọ́ sínú àpótí kan tí a fi awọ bò, tí a bá sì tì í pa, ó rí bí ìwé tí ó tóbi tó fáìlì ńlá kan.

Bíbélì Thumb

Kò di dandan pé kí àwọn Bíbélì Thumb jẹ́ odindi Bíbélì. Àwọn kan jẹ́ kìkì “Májẹ̀mú Tuntun.” Àwọn mìíràn jẹ́ àpẹẹrẹ irú àwọn ìtàn Bíbélì kékeré tàbí kí wọ́n ní odindi ìtàn Bíbélì tí a sọ di ìwọ̀n kékeré tí ó ní nǹkan bí 7,000 ọ̀rọ̀ nínú, a sì ṣe wọn ní pàtàkì fún kíkà àwọn ọmọdé. Wọ́n ní àwọn àkọlé bí The Bible in Miniature, The History of the Holy Bible, àti The Child’s Bible.

Báwo ni Bíbélì thumb ṣe gba orúkọ rẹ̀? Àlàyé tí a tètè ń gbọ́ ni pé, irú Bíbélì bẹ́ẹ̀ tóbi díẹ̀ ju apá òkè àtàǹpàkò [thumb] ènìyàn lọ. Síbẹ̀ ìwé Three Centuries of Thumb Bibles dámọ̀ràn pé, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé lẹ́yìn tí gbajúmọ̀ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ó nírìísí kíkéréjọjọ náà, Charles Stratton, tí a mọ̀ dáradára bí Ọ̀gágun Tom Thumb, ṣèbẹ̀wò sí England ni wọ́n ṣàgbélẹ̀rọ ọ̀rọ̀ náà. Òtítọ́ náà pé Tom Thumb bẹ England wò ní 1844 ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, ó sì jọ pé 1849 ni wọ́n kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “Bíbélì thumb” ní London.

Àwọn Ìdìpọ̀ Ìwé Mímọ́ Tí Kò Wọ́pọ̀

Àfikún mìíràn sí àwọn Bíbélì kéékèèké tí ó gba àfiyèsí ẹni ni The Finger New Testament, tí a tẹ̀ ní nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí. Ó fẹ̀ ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́ta péré, ó sì gùn ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́sàn-án—ìwọ̀n ìka—ibi tí orúkọ rẹ̀ ti wá nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ó ti gùn ju mìlímítà 76 lọ, kí a sọ ní pàtó, kì í ṣe ìwé kíkéréjù kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń kà á mọ́ irú àwọn Bíbélì bẹ́ẹ̀ níbi gbogbo. Lẹ́tà ìtẹ̀wé tí ó jẹ́ nǹkan bí sẹ̀ǹtímítà 0.14 tí a fi kọ ìwé yìí hàn kedere gan-an, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lè kà á tìrọ̀rùntìrọ̀rùn láìlo awò amúǹkantóbi.

Àpẹẹrẹ ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ kan ló ní àkọlé náà, The Illustrated Bible, tí ó ní àwọn ewì tí ó ní àkọlé náà, Railway to Heaven. Wọn fi 50 ọdún tẹ̀ ẹ́ ní àwọn ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin ní ilẹ̀ Britain. Òǹṣèwé náà lo àǹfààní iṣẹ́ ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin, pẹ̀lú ewì olójú-ewé méjì kan tí ó ní àkọlé náà, “Láti Darí Rẹ sí Ọ̀nà Mìíràn.” Ọ̀nà mìíràn yẹn ni a mọ̀ sí “Jésù Kristi, Ọmọkùnrin Jèhófà.” Ewì náà parí báyìí pé: “Ọlọ́run wí pé, ọmọkùnrin mi, yí ọkàn rẹ síhà ọ̀dọ̀ mi. Ṣe wéré—bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óò ṣíkọ̀.”

Ìwé mìíràn tí ó tún ṣàrà-ọ̀tọ̀ ni My Morning Counsellor, tí a ṣe ní ọdún 1900. Ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́ kan, a sì fi ẹ̀dà orúkọ àtọ̀runwá náà sí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀dà tí ó wà fún oṣù February ni “Jèhófà-Ṣàlómì.” Ìwé yìí àti The Illustrated Bible, tí a mẹ́nu kan níṣàájú, fi òtítọ́ náà hàn pé àwọn ènìyàn ń lo Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run, ní gbogbogbòò ní Britain ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.

Èwo Ló Kéré Jù Lọ?

Láàárín ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti kọjá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni a ti sọ nípa wọn pé àwọn ló kéré jù lọ. Èyí tí a kọ́kọ́ fìdí ìkéréjùlọ rẹ̀ múlẹ̀ jẹ́ ní 1674 nígbà tí wọ́n tẹ̀ ìwé náà, Bloem-Hofje, tí C. van Lange ṣe, jáde ní lẹ́tà ìtẹ̀wé kíkéréjọjọ. Ìwé Miniature Books ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “ìwọ̀n èékánná,” ó sì ní àkọsílẹ̀ kan tí ó wà fún 200 ọdún.

Ẹ̀dà kan tí ó lókìkí nínú La Divina Commedia ti Dante ni a fi lẹ́tà ìtẹ̀wé tí ó jẹ́ nǹkan bí sẹ̀ǹtímítà 0.07 tẹ̀, tí a ronú pé òun ni lẹ́tà ìtẹ̀wé kíkéréjùlọ tí a tí ì lò rí—tí a kò lè fi ojú lásán kà. Wọ́n ṣe ìwé náà ní Padua, Ítálì, ní 1878. Ó gba oṣù kan láti tẹ 30 ojú ìwé, lẹ́tà ìtẹ̀wé tuntun sì pọn dandan fún gbogbo ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ tuntun. Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, 1,000 ẹ̀dà ni wọ́n tẹ̀ jáde.

Dídín ìwọ̀n ìtóbi kù ń bá a lọ. Ní 1978, ewì àwọn ọmọdé náà, Three Blind Mice, láti Ilé Ìtẹ̀wé Gleniffer ní Paisley, Scotland, di “ìwé kíkéréjùlọ lágbàáyé.” Nígbà tí àwọn kan náà tí wọ́n ṣe ìwé yìí ṣe ẹ̀dá 85 ìwé ewì àwọn ọmọdé mìíràn, Old King Cole!, ní 1985, ó gbẹyẹ lọ́wọ́ ẹ̀dà tí iye rẹ̀ mọ níwọ̀n yìí. Ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan wulẹ̀ jẹ́ mìlílítà kan lóròó, ó sì jẹ́ mìlílítà kan níbùú. Abẹ́rẹ́ ni a lè fi ṣí abala ìwé náà!

Irú àwọn ìwé tí ó kéré gan-an bẹ́ẹ̀, tí Louis Bondy ṣàpèjúwe bí “èyí tí ó fi agbára káká ju erukuru lọ,” fúnni ní ẹ̀rí arabaríbí sùúrù àti òye iṣẹ́ ọnà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìwé kéékèèké wọ̀nyí ju èròǹgbà àtètèkọ́ṣe ti jíjẹ́ ìwé kíkéréjù, tí ó yẹ kí ó gbé àwọn ìwé tí ó ṣeé kà, tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lò jáde lọ.

A lè rí àwọn àkójọ dáradára ti àwọn ìwé kíkéréjù tí ń gbádùn mọ́ni wọ̀nyí ní àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn sì wà ní ọwọ́ àwọn tó ní wọn. Bí ìgbà kankan bá wà tí o ní àǹfààní láti rí àwọn ìwé kéékèèké wíwuni wọ̀nyí, rántí pé o ní láti ṣe wọ́n jẹ́jẹ́. Iṣẹ́ ọnà gbáà ni wọ́n!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìlànà Adín-Ǹkankù Onífọ́tò

David Bryce, láti Glasgow, Scotland, ló ṣe “Májẹ̀mú Tuntun” kíkéréjùlọ tí a tí ì ṣe jáde rí ní 1895. Ó jẹ́ 1.9 sẹ̀ǹtímítà lóròó àti 1.6 sẹ̀ǹtímítà níbùú, ó sì nípọn ní 0.8 sẹ̀ǹtímítà péré! Báwo ló ṣe rọrùn láti tẹ èyí? Louis Bondy ṣàlàyé nínú ìwé Miniature Books pé: “A tẹ̀ ẹ́ nigínnigín àti ní kedere sínú ìhùmọ̀ adín-ǹkankù onífọ́tò.” Níwọ̀n bí iṣẹ́ fọ́tò yíyà ti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, èyí kì í ṣe àṣeyọrí tí ó kéré.

David Bryce pẹ̀lú tẹ Bíbélì Thumb bí mélòó kan jáde ní lílo ìlànà kan náà. Fún àwọn tí wọ́n ní ìṣòro kíka ohun tí a tẹ̀ wẹẹrẹ náà, Bíbélì kọ̀ọ̀kan ní awò amúǹkantóbi kékeré kan tí a tẹ̀ bọ àárín èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Pẹ̀lú àrànṣe yìí, àwọn tí wọ́n forí tì í rí i kà.

Ó gbàfiyèsí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo títẹ àwọn ìwé pẹ̀lú ìlànà adín-ǹkankù onífọ́tò lọ́nà tí ó dára nígbà tí ìjọba Nazi ń ṣenúnibíni sí wọn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àti nígbà tí àwọn Kọ́múníìsì ṣenúnibíni sí wọn lẹ́yìn náà. Àwòrán tí ó wà níhìn-ín ni àrànṣe kan fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a fi ìlànà yìí tẹ̀ jáde. Wọ́n tọ́jú rẹ̀ sínú ilé ìṣáná, wọ́n sì yọ́ ọ mú lọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi kan.

Èyí wọ inú ilé ìṣáná kan, wọ́n sì yọ́ ọ mú wọnú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré, àwọn ìwé kíkéréjù ṣeé kà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àkójọ àwọn ìwé kíkéréjù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́