Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìjẹ́pàtàkì Dídáwà
NÍGBÀ kan, Jésù “gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti lọ, ó wà níbẹ̀ ní òun nìkan ṣoṣo.” (Mátíù 14:23) Nígbà mìíràn, “nígbà tí ó di ojúmọ́, ó jáde lọ, ó sì rìn síwájú sí ibì kan tí ó dá.” (Lúùkù 4:42) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí jẹ́rìí sí i pé Jésù Kristi wá àwọn àkókò láti dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì mọyì irú àkókò bẹ́ẹ̀.
Bíbélì fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ mìíràn nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n mọyì dídáwà bí ti Jésù. Nígbà ìdáwà ìṣọ́ òru ni onísáàmù ṣàṣàrò lórí bí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ṣe kàmàmà tó. Nínú ọ̀ràn ti Jésù Kristi, ní kété tó gbọ́ ikú Jòhánù Olùbatisí, ó “lọ sí ibi tí ó dá, láti dá nìkan wà.”—Mátíù 14:13; Sáàmù 63:6.
Lónìí, lójú gbogbo sísá síhìn-ín sá sọ́hùn-ún ìgbésí ayé òde òní, àwọn ènìyàn kò ka dídáwà sí ohun pàtàkì kan, bóyá nítorí ipò tí wọ́n bá ara wọn tàbí nítorí pé ó wù wọ́n bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o lè rántí ìgbà tí o dá wà kẹ́yìn? Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ adélébọ̀ kan sọ pé: “Kò sí ìgbà tí mo dá wà rí láyé mi.”
Àmọ́, ṣé a nílò ìdáwà ní gidi ni? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè lo àwọn àkókò ìparọ́rọ́ lọ́nà tó pé, tó sì ṣàǹfààní? Ipa wo sì ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ń kó nínú dídáwà?
Dídáwà—Èé Ṣe Tó Fi Ṣe Pàtàkì?
Bíbélì sọ fún wa pé ẹni Ọlọ́run kan látijọ́, Ísákì, lọ dá wà “nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́.” Èé ṣe? Ó sọ pé, “kí ó lè ṣe àṣàrò.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:63) Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣe sọ, láti ṣàṣàrò túmọ̀ sí “láti ronú lọ́nà jíjinlẹ̀ tàbí lọ́nà tó fara balẹ̀.” Ó “ní àkókò ìpọkànpọ̀ tọkàntara, tó sì pọ̀ nínú.” Ní ti Ísákì, tí ń múra láti tẹ́rí gba àwọn bùkátà wíwúwo, irú àṣàrò láìsí ìdílọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ó lè ronú dáadáa, kí ó ṣètò ìrònú rẹ̀ bó ṣe yẹ, kí ó sì díye lé àwọn ohun àkọ́múṣe rẹ̀.
Ògbógi kan nípa ìlera ọpọlọ sọ pé, níwọ̀n bí ‘ìdáwà bá ti ń mọ sáyè tó yẹ ẹ́, àìsí ẹlòmíràn nítòsí ń mú kí ó ṣeé ṣe láti tún èrò ẹni pa, kí a sì pọkàn pọ̀ dáradára.’ Ọ̀pọ̀ ènìyàn lè jẹ́rìí sí i pé èyí ń tuni lára, ó ń fúnni lókun, ó sì ń mára le.
Lára àwọn àǹfààní tí àṣàrò ń mú wá ni ìṣọ́ra kíkún, tó sì fàyà balẹ̀, àwọn ànímọ́ tí ń mú kí a sọ̀rọ̀, kí a sì hùwà pẹ̀lú òye, èyí tí yóò yọrí sí ìṣọ̀kan nínú àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó kọ́ láti ṣàṣàrò yóò kọ́ láti mọ ìgbà tí ó yẹ ká dákẹ́. Kàkà kí ó máa sọ̀rọ̀ láìronú, yóò kọ́kọ́ ronú ṣáájú lórí ipa tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè ní. Òǹkọ̀wé Bíbélì tí a mí sí náà béèrè pé: “Ìwọ ha ti rí ènìyàn tí ń fi ìkánjú sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀?” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Ìrètí ń bẹ fún arìndìn jù fún un lọ.” (Òwe 29:20) Ọ̀nà àtúnṣe wo ló wà fún lílo ahọ́n láìronú bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”—Òwe 15:28; fi wé Sáàmù 49:3.
Fún Kristẹni kan, àṣàrò ìparọ́rọ́ ní ipò ìdáwà jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ìdàgbàdénú tẹ̀mí. Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fara pẹ́ èyí pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tímótì 4:15.
Lo Ìdáwà Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
Òǹkọ̀wé Gẹ̀ẹ́sì kan wí pé: “Ibi àdádó ni iyàrá ìkọ̀kọ̀ tí a ti í bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Jésù ń rí i pé ó yẹ kí òun yẹra fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ òun, kí òun sì gbàdúrà sí Ọlọ́run lóun nìkan. Àpẹẹrẹ kan ni a fúnni nínú Bíbélì pé: “Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́, ó sì dìde, ó sì jáde lọ sí ibi tí ó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà níbẹ̀.”—Máàkù 1:35.
Nínú Sáàmù, a mẹ́nu ba àṣàrò sípa ti Ọlọ́run léraléra. Nígbà tí Dáfídì Ọba ń darí ọ̀rọ̀ sí Jèhófà, ó wí pé: “Mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ.” Ásáfù pẹ̀lú sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sáàmù 63:6; 77:12) Nítorí náà, ríronú lórí àwọn ànímọ́ àti ìbálò Ọlọ́run ń mú èrè púpọ̀ wá. Ó ń mú kí ìmọrírì wa fún Ọlọ́run pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí a lè sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́.—Jákọ́bù 4:8.
Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Pọndandan
Bí ó ti wù kí ó rí, ó yẹ kí a lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìdáwà. A lè ṣàpèjúwe ibi àdádó kan bí ibi tó ṣàǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí, ṣùgbọ́n tó léwu láti máa gbé lọ títí. Yíya ara ẹni sọ́tọ̀ jù lòdì sí ọ̀nà ìṣẹ̀dá ènìyàn nípìlẹ̀ láti báni kẹ́gbẹ́, láti máa báni sọ̀rọ̀ pọ̀, àti láti fi ìfẹ́ hàn. Síwájú sí i, dídáwà ṣeé fi wé ilẹ̀ tí àwọn èpò ìwà òmùgọ̀ àti ìmọtara-ẹni-nìkan ti ń hù. Òwe kan nínú Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Láti ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìdáwà, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ewu ìdáwà.
Bí ti Jésù àti àwọn ẹni tẹ̀mí ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn Kristẹni lónìí ń ṣìkẹ́ àwọn àkókò ìdáwà wọn. Lóòótọ́, nítorí àwọn àìgbọ́dọ̀máṣe àti àníyàn púpọ̀ tí wọ́n ní, ó lè ṣòro gan-an láti rí àkókò àti àǹfààní fún àṣàrò níbi àdádó. Síbẹ̀, bí ó ti máa ń rí nípa gbogbo ohun tó bá ṣe pàtàkì ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ra “àkókò tí ó rọgbọ padà.” (Éfésù 5:15, 16) Nígbà náà ni a lè sọ bí onísáàmù náà pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.”—Sáàmù 19:14.