ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 5/15 ojú ìwé 12-13
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́
  • Jí!—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ló Fà Á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Dá Wà?
    Jí!—2004
  • Kí Ló Dé Tí Ẹnikẹ́ni Kì Í Dá Sí Mi?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 5/15 ojú ìwé 12-13

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Mo ní àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí wọ́n jọ máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀, àmọ́ wọn kì í pè mí sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń gbọ́ pé wọ́n jọ lọ ṣeré níbì kan. Lọ́jọ́ kan, mo tẹ ọkàn nínú wọn laago nílé, àṣé àwọn méjèèjì ló jọ wà níbẹ̀. Ẹlòmíì ló gbé ìpè mi, mo sì ń gbóhùn àwọn méjèèjì lábẹ́lẹ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín. Bí mo ṣe gbọ́ tí wọ́n ń ṣeré mú kó túbọ̀ máa ṣe mí bí i pé mi ò ní ọ̀rẹ́!”—Maria.a

Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bí i pé àwọn èèyàn pa ẹ́ tì tàbí pé o kò ní ọ̀rẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa níní ọ̀rẹ́.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní ìṣòro yìí. Ó máa ń ṣe àwọn tó gbajúmọ̀ pàápàá bí i pé wọn ò ní ọ̀rẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé èèyàn lè ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ àmọ́ kí wọ́n máà jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi. Téèyàn ò bá sì ní ọ̀rẹ́ gidi, bí ẹni tí kò lọ́rẹ̀ẹ́ rárá ni. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé téèyàn bá mọ èèyàn tó pọ̀, kò túmọ̀ sí pé gbogbo wọn ni ọ̀rẹ́ gidi, ó ṣì lè máa ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ bíi pé kò lọ́rẹ̀ẹ́ kankan.

Tí o kò bá ní ọ̀rẹ́, ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ. Àwọn kan ṣe ìwádìí nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́jọ [148]. Ìwádìí náà fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn èèyàn ṣeré kú ní rèwerèwe, ìyẹn sì léwu gan-an. Kódà, “ìlọ́po méjì ni ewu yìí fi burú ju kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀,” jàǹbá tó sì máa ń ṣe dà bí ìgbà “téèyàn ń mu sìgá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lójoojúmọ́.”

Tí o kò bá ní ọ̀rẹ́, o lè mú kó o ṣìwà hù. Ó lè mú kó o gbà láti bá ẹnikẹ́ni tó o bá ṣáà ti rí ṣọ̀rẹ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alan sọ pé: “Tí o kò bá ní ọ̀rẹ́, ó lè mú kó máa ṣe ẹ́ bí i pé kó o ṣá ti rí ẹnì kan yàn lọ́rẹ̀ẹ́. O lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé kéèyàn yan ẹnì kan ṣá lọ́rẹ̀ẹ́ sàn ju kéèyàn máà ní ọ̀rẹ́ rárá. Ìyẹn sì lè kó ẹ sí wàhálà.”

Níní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kò lè yanjú ìṣòro náà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Natalie sọ pé: “Mo lè fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ èèyàn lóòjọ́, síbẹ̀ á ṣì máa ṣe mí bí i pé mi ò lọ́rẹ̀ẹ́ kankan.” Ọ̀dọ́ míì tó ń jẹ́ Tyler sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Fífi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ dà bí ìgbà téèyàn ń jẹ ìpápánu, àmọ́ ká rẹ́ni bá sọ̀rọ̀ lójúkojú dà bí ìgbà téèyàn jẹ oúnjẹ gidi. Ìpápánu máa ń dùn, àmọ́ kéèyàn tó lè yó dáadáa, ó gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ gidi.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Má ṣe ronú pé ńṣe ni wọ́n dìídì pa ẹ́ tì. Ká sọ pé o rí fọ́tò kan táwọn ọ̀rẹ́ rẹ yà níbi àpèjẹ kan tí wọ́n kò pè ẹ́ sí. Lákòókò yẹn, ìwọ lo máa pinnu bóyá kó o gbà pé wọ́n dìídì pa ẹ́ tì tàbí bóyá ọkàn wọn fò ẹ́ ni. Nígbà tí o kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, kò yẹ kó o ronú pé wọ́n dìídì pa ẹ́ tì ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ko ronú nípa ohun tó fà á tí ọkàn wọ́n fi fò ẹ́, tí wọn ò sì rántí pè ẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó wà lọ́kàn èèyàn ló ń mú kó máa ronú pé òun kò ní ọ̀rẹ́.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 15:15.

Má ṣe máa sọ àsọrégèé. Tí o kò bá lọ́rẹ̀ẹ́, o lè máa ronú pé, ‘Kò sẹ́ni tó ní kí n wá kí òun nílé rí’ tàbí ‘Gbogbo èèyàn ló ń sá fún mi.’ Téèyàn bá ń sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ àsọrégèé bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa mú kó túbọ̀ máa ṣèèyàn bíi pé òun dá wà, ìṣòro náà kò sì ní yanjú. Á máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò, ìwọ náà á wá pa gbogbo èèyàn tì. Ìyẹn á sì mú kó túbọ̀ máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò ní ọ̀rẹ́ kankan.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 18:1.

Múra tán láti yan àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ lọ́rẹ̀ẹ́. Bíbélì sọ ìtàn ìgbésí ayé Dáfídì. Ó ṣeé ṣe kó máà tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó pàdé Jónátánì, tó fi ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún ju Dáfídì lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì ju Dáfídì lọ dáadáa, síbẹ̀ àwọn méjèèjì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (1 Sámúẹ́lì 18:1) Ìwọ náà lè yan irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiara, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21], sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ti wá gbádùn kí n máa bá àwọn tó jù mí lọ ṣọ̀rẹ́. Mo ní àwọn ọ̀rẹ́ kan tá a jọ mọ́wọ́ ara wa gan-an tí wọ́n fi ohun tó lé ní ogún ọdún jù mí lọ, mo sì mọyì bí wọ́n ṣe máa ń fi ojú àgbà wo nǹkan àti bí wọ́n ṣe máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ wọn.”—Ìlànà Bíbélì: Jóòbù 12:12.

Àǹfààní wà nínú kéèyàn dá wà. Ó máa ń ṣe àwọn kan bí i pé ńṣe ni wọ́n dá wà bí kó bà sí ẹnì kankan pẹ̀lú wọn. Àmọ́ ti pé èèyàn kankan kò sí lọ́dọ̀ rẹ kò sọ pé o kò lọ́rẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Jésù máa ń bá àwọn èèyàn ṣeré, àmọ́ ó tún gbádùn kó máa dá wà. (Mátíù 14:23; Máàkù 1:35) Ìwọ náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò tí wàá fi máa kárísọ torí pé o kò lọ́rẹ̀ẹ́, ńṣe ni kó o lo àkókò náà láti ronú lórí àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ. Ìyẹn lè wá mú kó o ní ìwà tó dá a táá mú kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi fáwọn èèyàn.—Òwe 13:20.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” —Òwe 15:15.

  • “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ . . . gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.

  • “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?”—Job 12:12.

BO

“Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò ní ọ̀rẹ́, àmọ́ wọn kì í fẹ́ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kí wọ́n máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, àmọ́ wọn ò lè fojú rí irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, èyí sì máa ń mú kò dà bíi pé èèyàn kò ní ọ̀rẹ́ kankan.”

ABIGAIL

“Gbogbo wa la máa ń ní ọ̀rẹ́ tó ti kúrò ní àdúgbò tá a jọ ń gbé tàbí kó máà ní nọ́ńbà fóònù wa lọ́wọ́ mọ́. Mo fẹ́ràn kí n máa kàn sí irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, kódà bí ibi tí wọ́n ń gbé bá tiẹ̀ jìnnà. Tí mo bá kàn bá wọn sọ̀rọ̀, inú mi máa ń dùn gan-an.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́