ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/15 ojú ìwé 21-24
  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni O Lè Ṣe?
  • Jẹ́ Kí Awọn Ọ̀rẹ́ Ṣèrànlọ́wọ́
  • Jehofa Bìkítà
  • Máṣe Dá Ọlọrun Lẹ́bi
  • Bíborí Ìṣòro Dídá Wà
    Jí!—2004
  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Fà Á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Dá Wà?
    Jí!—2004
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/15 ojú ìwé 21-24

Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa

TÀGBÀ-TÈWE ni ìdánìkanwà lè ṣe ìgbésí-ayé wọn báṣabàṣa. Judith Viorst ninu ìwé ìròyìn Redbook sọ pé: “Ìdánìkanwà dàbí orísun ìkìmọ́lẹ̀ ninu ọkàn-àyà. . . . Ìdánìkanwà máa ń raniníyè ó sì ń sọni di aláìnírètí. Ìdánìkanwà ń mú kí a dàbí ọmọ aláìníyàá, bí ọ̀dọ́-àgùtàn kan tí ń ṣáko lọ, tí ó kéré jọjọ tí ó sì sọnù sínú ayé kan tí ó lọ salalu tí ó sì jẹ́ aláìbìkítà.”​—⁠September 1991.

Ìyapa kúrò lọ́dọ̀ awọn ọ̀rẹ́, awọn àyíká tí a kò gbé rí, ìkọ̀sílẹ̀, ṣíṣọ̀fọ̀, tabi ìwólulẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀​—⁠onírúurú awọn nǹkan yii lè mú kí o nímọ̀lára ìdánìkanwà. Àní nígbà tí awọn kan bá tilẹ̀ wà ní àyíká awọn ènìyàn mìíràn, wọn máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà jíjinlẹ̀.

Kí Ni O Lè Ṣe?

Bí o bá nímọ̀lára ìdánìkanwà, o ha wulẹ̀ níláti dàbí òjìyà tí kò ní olùrànlọ́wọ́ bí? Ohunkóhun ha wà tí o lè ṣe lati máṣe fàyègba ìdánìkanwà lati run ọ́ díẹ̀-díẹ̀ tabi kí ó gba ìfẹ́-inú rẹ lati wàláàyè mọ́ ọ lọ́wọ́ bí? Níti gidi ohun kan wà tí o lè ṣe. Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí ó lè ṣèrànlọ́wọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí, Bibeli, sì pèsè ọ̀pọ̀ àmọ̀ràn rere pẹlu. Ó lè jẹ́ pé irú awọn ìṣírí bẹ́ẹ̀ ni kìkì ohun tí o nílò lati ṣẹ́pá ìdánìkanwà.​—⁠Matteu 11:​28, 29.

Fún àpẹẹrẹ, o lè rí i pé kíkà nipa Rutu, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí ó gbé ní Middle East ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn ń fúnni níṣìírí. Ó dájú pé oun jìyà ìdánìkanwà. Nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ kú, ó bá ìyakọ rẹ̀ lọ lati gbé ní awọn àyíká tí oun kò gbé rí ní Israeli. (Rutu 2:11) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi awọn ìdílé ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí dù ú tí oun sì jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, kò sí ìtọ́kasí kankan ninu Bibeli pé ó jẹ́ kí ìdánìkanwà bo oun mọ́lẹ̀. O lè ka ìtàn rẹ̀ ninu ìwé Rutu ninu Bibeli.

Gẹ́gẹ́ bíi Rutu, o níláti mú ojú-ìwòye ìfojúsọ́nà-fun-rere dàgbà. Ọ̀nà tí o ń gbà ronú lórí awọn nǹkan ati ìṣẹ̀lẹ̀ lè mú kí ìdánìkanwà gbèrú. Ann, ẹni tí ó tọ́jú baba rẹ̀ jálẹ̀ àkókò àmódi atánnilókun fún ọdún mẹ́rin, jẹ́rìí sí èyí. Nígbà tí baba rẹ̀ kú ó nímọ̀lára ìdánìkanwà lọ́nà jíjinlẹ̀ gan-⁠an. Ó sọ pé, “Mo nímọ̀lára bí ẹni pé mo wà ninu ahoro, tí n kò sì jámọ́ nǹkankan​—⁠bí ẹni pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó tún nílò mi mọ́. Ṣugbọn mo dojúkọ òtítọ́ naa pé ìgbésí-ayé mi ti yípadà bayii, mo sì wá mọ̀ pé láti lè kojú ìdánìkanwà mi mo níláti lo àǹfààní àyíká ipò mi lọ́nà dídára jùlọ.” Nígbà mìíràn o kò lè yí awọn àyíká ipò rẹ padà, ṣugbọn ó ṣeéṣe pé o lè yí ìwà rẹ sí wọn padà.

Jíjẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí fún awọn ìgbòkègbodò tí ń mérè wá kìí ṣe ìdáhùn pátápátá sí kíkojú ìdánìkanwà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣèrànwọ́. Irene, ẹni tí ó di opó lẹ́yìn oṣù mẹ́fà péré tí a gbé e níyàwó, rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́ ninu ọ̀ràn tirẹ̀. Ó sọ pé, “Mo rí i pé ìgbà tí mo máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà jùlọ ni nígbà tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀, nitori naa mo tẹramọ́ fífi ara rora pẹlu awọn ẹlòmíràn tí mo sì ń ràn wọn lọ́wọ́ lati kojú awọn ìṣòro wọn.” Ṣíṣèrànlọ́wọ́ fún awọn ẹlòmíràn ń mú ayọ̀ wá, awọn Kristian tí wọn n nímọ̀lára ìdánìkanwà sì lè ní pupọ lati ṣe ninu iṣẹ́ Oluwa.​—⁠Iṣe 20:35; 1 Korinti 15:58.

Jẹ́ Kí Awọn Ọ̀rẹ́ Ṣèrànlọ́wọ́

Ìwé The New York Times Magazine ṣàpèjúwe awọn ọmọdé ti wọn ń nímọ̀lára ìdánìkanwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí “ọgbẹ́ àìrẹ́nibáṣọ̀rẹ́” ti bà lọ́kàn jẹ́. (April 28, 1991) Ọ̀pọ̀ awọn ènìyàn tí wọn nímọ̀lára ìdánìkanwà, lọ́mọdé ati lágbà, ń nímọ̀lára àìrẹ́nibáṣọ̀rẹ́. Nitori naa, àǹfààní gidi ni ó jẹ́, lati ní ojúlówó ìbáṣọ̀rẹ́ tí ìjọ Kristian tí ó bìkítà ń pèsè. Ṣiṣẹ́ kára lati túbọ̀ ní ọ̀rẹ́ pupọ síi láàárín ìjọ, kí o sì jẹ́ kí wọn ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọ̀nà èyíkéyìí tí wọn bá lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun kan tí awọn ọ̀rẹ́ wà fún nìyẹn​—⁠lati tinilẹ́yìn ní àkókò wàhálà.​—⁠Owe 17:17; 18:⁠24.

Ṣugbọn, mọ̀ dájú pé, nitori ìrora ọkàn rẹ, iwọ lè mú kí ó ṣòro níti gidi fún awọn ọ̀rẹ́ lati ràn ọ́ lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Òǹkọ̀wé Jeffrey Young ṣàlàyé pé: “Awọn ènìyàn kan tí wọn nímọ̀lára ìdánìkanwà . . . ń lé awọn tí ó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ sẹ́yìn, yálà nipa rírakakalé ìjíròrò tabi nipa sísọ awọn nǹkan tí ó kóninírìíra tabi tí kò yẹ. Lọ́nà kan tabi òmíràn, awọn tí ìdánìkanwà ti di bárakú fún sábà máa ń ba ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ jẹ́.”​—⁠U.S.News & World Report, September 17, 1984.

Nígbà mìíràn, o lè mú kí awọn nǹkan burú síi nipa yíya araàrẹ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ awọn ènìyàn mìíràn. Ìyẹn ni ohun tí Peter, ọkùnrin kan tí ó ti lé ní 50 ọdún ṣe. Lẹ́yìn tí aya rẹ̀ kú, ó rí i pé oun ń fàsẹ́yìn lọ́dọ̀ awọn ẹlòmíràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ninu araarẹ̀ lọ́hùn-⁠ún ó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ wọn. Ó sọ pé, “Awọn ọjọ́ kan wà tí ó jẹ́ pé n kò ṣáà lè kojú wíwà láàárín awọn ẹlòmíràn ni, bí ọjọ́ sì ti ń gorí ọjọ́ mo rí i pé mo kàn ń ya araàmi sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ awọn ènìyàn.” Èyí lè léwu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awọn sáà dídáwà máa ń ṣàǹfààní, yíya ara ẹni sọ́tọ̀ lè panilára. (Owe 18:1) Peter nírìírí èyí. Ó sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín mo borí èyí, mo kojú àyíká ipò mi, ati, pẹlu ìrànlọ́wọ́ awọn ọ̀rẹ́ mi, ó ṣeéṣe fún mi lati tún ìgbésí-ayé mi ṣe.”

Bí ó ti wù kí ó rí, máṣe rò pé, ó pọndandan fún awọn ẹlòmíràn lati ṣèrànlọ́wọ́. Gbìyànjú lati máṣe dí ẹni tí ń múni lápàpàǹdodo. Fi ayọ̀ gba inúrere èyíkéyìí tí a ba fihàn, kí o sì fi ìmọrírì hàn fún un. Ṣugbọn fi ìmọ̀ràn rere tí a tún rí ninu Owe 25:17 yii sọ́kàn pé: “Fa ẹsẹ̀ sẹ́yìn kúrò ní ilé aládùúgbò rẹ; kí agara rẹ ó má baà dá a, oun a sì kórìíra rẹ.” Frances, ẹni tí ó dojúkọ ìdánìkanwà jíjinlẹ̀ nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú lẹ́yìn ìgbéyàwó ọlọ́dún 35, nímọ̀lára pé irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ó sọ pé, “Jẹ́ afòyebánilò ninu ohun tí iwọ ń retí, kí o má sì ṣe béèrè ohun pupọ jù lọ́wọ́ awọn ẹlòmíràn. Máṣe máa ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹnìkan lemọ́lemọ́ ní wíwá ìrànlọ́wọ́.”

Jehofa Bìkítà

Kódà bí awọn ọ̀rẹ́ tí wọn jẹ́ abánikẹ́dùn bá já ọ kulẹ̀ nígbà mìíràn, o ṣì lè ní Jehofa Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rẹ́ rẹ. Mọ̀ dájú pé oun bìkítà fún ọ. Jẹ́ kí ìgbọ́kànlé rẹ ninu rẹ̀ lágbára, kí o sì máa báa nìṣó ní wíwa ìsádi lábẹ̀ ìtọ́jú aláàbò rẹ̀. (Orin Dafidi 27:10; 91:1, 2; Owe 3:​5, 6) Ọmọbìnrin Moabu naa Rutu ṣe èyí a sì bùkún un ní yanturu. Họ́wù, ó tilẹ̀ di ìyá-ńlá Jesu Kristi!​—⁠Rutu 2:12; 4:17; Matteu 1:​5, 16.

Máa gbàdúrà sí Jehofa nígbà gbogbo. (Orin Dafidi 34:⁠4; 62:7, 8) Margaret rí i pé àdúrà jẹ́ orísun okun ńlá ní kíkojú ìdánìkanwà. O lọ́wọ́ ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún pẹlu ọkọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ọkọ rẹ̀ fi kú nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin. Ó sọ pé, “Nígbà gbogbo ni mo máa ń rí i pé ó dára lati gbàdúrà sókè kí n sì sọ ohun gbogbo fún Jehofa, gbogbo ìbẹ̀rù ati àníyàn mi. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ lati lè fi ojú tí ó tọ́ wo awọn nǹkan nígbà tí mo bá nímọ̀lára ìdánìkanwà. Rírí i pé Jehofa ń dáhùn awọn àdúrà wọ̀nyẹn fún mi ní ìgbọ́kànlé.” Ó jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ lati inú títẹ̀lé ìmọ̀ràn aposteli Peteru pé: “Nitori naa ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọrun, kí oun kí ó lè gbé yin ga ní àkókò. Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yin lé e; nitori tí oun ń ṣe ìtọ́jú yin.”​—⁠1 Peteru 5:​6, 7; Orin Dafidi 55:⁠22.

Ìpò ìbátan dídára pẹlu Jehofa yoo ràn ọ́ lọ́wọ́ lati ní ohun kan tí awọn ènìyàn tí wọn ń nímọ̀lára ìdánìkanwà lọ́pọ̀ ìgbà ń pàdánù​—⁠iyì ara-ẹni. Nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa ọkọ rẹ, akọ̀ròyìn náà Jeannette Kupfermann kọ̀wé nipa “níní ìmọ̀lára iyì ara-ẹni tí ó dínkù ati àìníláárí.” Ó sọ pé: “Èrò àìníláárí yii ni ó ń sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn opó tí wọn fi fẹ́rẹ̀ máa ń fi ìsoríkọ́ pa araawọn.”

Rántí pé Jehofa kà ọ́ sí gan-⁠an ni. Oun kò rò pé o jẹ́ aláìníláárí. (Johannu 3:16) Ọlọrun yoo tì ọ́ lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ti awọn ènìyàn rẹ̀ ọmọ Israeli lẹ́yìn nígbà àtijọ́. Ó sọ fún wọn pé: “Emi kò ní ta ọ́ nù, iwọ má bẹ̀rù; nitori mo wà pẹlu rẹ; má fòyà; nitori èmi ní Ọlọrun rẹ: emi óò fún ọ ní okun; nítòótọ́, èmi óò ràn ọ́ lọ́wọ́; nítòótọ́, emi ó fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi gbé ọ sókè.”​—⁠Isaiah 41:​9, 10.

Máṣe Dá Ọlọrun Lẹ́bi

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máṣe dá Ọlọrun lẹ́bi fun ìdánìkanwà rẹ. Jehofa kò jẹ̀bi. Ète rẹ̀ ti fi ìgbà gbogbo jẹ́ pé kí iwọ, ati gbogbo ìran ènìyàn, gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere, tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá. Nígbà tí Ọlọrun dá Adamu, ó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin naa kí ó nìkan máa gbé; èmi óò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ̀ fún un.” (Genesisi 2:18) Oun tí Ọlọrun sì ṣe nìyẹn nigba tí ó dá Efa, obìnrin àkọ́kọ́. Bí kò bá jẹ́ nitori ìṣọ̀tẹ̀ Satani, ọkùnrin ati obìnrin ati awọn ìdílé tí wọn bá mú jáde kì bá tí nírìírí ìdánìkanwà.

Àmọ́ ṣáá o, fífi tí Jehofa ti fàyègba ìwà-ibi fun ìgbà díẹ̀, ti fàyègba ìdánìkanwà lati gbèrú kí awọn ìjìyà mìíràn sì ṣẹlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, jẹ́ kí ó yé ọ pé èyí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Awọn àdánwò ìdánìkanwà dàbí ohun tí kò ṣòro jù lati faradà nígbà tí o bá fi ojú-ìwòye ohun tí Ọlọrun yoo ṣe fún ọ́ ninu ayé titun rẹ̀ wò ó. Ní bayi ná, oun yoo tì ọ́ lẹ́yìn yoo sì tù ọ́ ninu.​—⁠Orin Dafidi 18:⁠2; Filippi 4:​6, 7.

Mímọ èyí lè fun ọ lókun. Nígbà tí Frances (tí a mẹ́nukàn lẹ́ẹ̀kan) di opó, ó rí ìtùnú ńláǹlà lati inu awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 4:8, ní pàtàkì ní òru: “Emi óò dùbúlẹ̀ pẹlu ní àlàáfíà, èmi óò sì sùn; nitori iwọ, Oluwa, nìkanṣoṣo ni ó ń mú mi jókòó ní àìléwu.” Ṣàṣàrò lórí irú awọn ìrònú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ irú èyí tí a rí ninu ìwé Orin Dafidi. Ronú lórí bí Ọlọrun ṣe bìkítà nipa rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ ninu Orin Dafidi 23:​1-⁠3.

Bawo Ni A Se Lè Ran Awọn tí Wọn Dánìkanwà Lọ́wọ́?

Ọ̀nà pàtàkì kan lati ran awọn tí wọn dánìkanwà lọ́wọ́ ni lati fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Léraléra ní Bibeli ń fún awọn ènìyàn Ọlọrun ní ìṣírí lati fi ìfẹ́ hàn sí ẹnìkínní-kejì, ní pàtàkì nígbà àdánwò. Aposteli Paulu kọ̀wé pé, “Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yin.” (Romu 12:10) Ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí sọ pé: “Ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé.” (1 Korinti 13:8) Bawo ni o ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí awọn wọnnì tí wọn ba dánìkanwà?

Dípò kíkọ awọn ènìyàn tí wọn dánìkanwà sílẹ̀ tabi ṣíṣàìbìkítà nipa wọn, awọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ọ̀ràn kàn lè fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ wọn hàn nipa fífi sùúrù ràn wọn lọ́wọ́ níbikíbi tí ó bá ti ṣeéṣe. Wọn lè dàbí ọkùnrin naa Jobu, tí ó wí pé: “Nitori tí mo gba tálákà tí ń sọkún, ati aláìníbaba, ati aláìní olùrànlọ́wọ́. . . . Emi sì mú àyà opó kọrin fun ayọ̀.” (Jobu 29:​12, 13) Awọn alàgbà tí a yànsípò ninu ìjọ Kristian ati awọn ọ̀rẹ́ oníyọ̀ọ́nú lè hùwà lọ́nà ìgbatẹnirò kan naa, nipa pípèsè awọn ohun kòṣeémánìí fún ènìyàn bíi òye, ọ̀yàyà, ati ìtùnú. Wọn lè fi ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni hàn, wọn sì lè kúnjú àìní naa fún ọ̀rọ̀ àṣírí nígbà mìíràn.​—⁠1 Peteru 3:⁠8.

Lọ́pọ̀ ìgbà, awọn ohun kéékèèké tí awọn ọ̀rẹ́ máa ń ṣe fún awọn ènìyàn tí wọn dánìkanwà ni ohun tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà ṣíṣekókó. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́-ẹni bá pàdánù olólùfẹ́ kan ninu ikú, ọ̀pọ̀ awọn ohun rere ni a lè ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ ìwà onínúure tí ó jẹ́ tí ojúlówó ọ̀rẹ́. Máṣe fojú kékeré wo inúrere ráńpẹ́, bíi ìkésíni fún oúnjẹ, jíjẹ́ olùfetísílẹ̀ abánikẹ́dùn, tabi ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ń fúnni níṣìírí. Awọn nǹkan wọ̀nyí lè gbéṣẹ́ gidigidi ní ríran ẹnìkan lọ́wọ́ lati gbéjàko ìdánìkanwà.​—⁠Heberu 13:⁠16.

Lati ìgbà dé ìgbà ó ṣeéṣe kí gbogbo wa ní ìrírí ìkọlù ìdánìkanwà. Síbẹ̀, kò yẹ kí ìdánìkanwà di pàṣán. Jẹ́ kí ìgbésí-ayé rẹ kún fún awọn ìgbòkègbodò tí ó nítumọ̀, tí ó sì lè ṣeniláǹfààní. Jẹ́ kí awọn ọ̀rẹ́ ṣèrànwọ́ nígbà tí wọn bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìgbọ́kànlé ninu Jehofa Ọlọrun. Fí ìlérí afúnniníṣìírí tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ sinu Orin Dafidi 34:19 sọ́kàn pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣugbọn Oluwa gbà á ninu wọn gbogbo.” Yíjú sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́, kí ó má sì ṣe jẹ́ kí ìdánìkanwà ṣe ìgbésí-ayé rẹ báṣabàṣa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

AWỌN Ọ̀NÀ DÍẸ̀ TÍ A LÈ GBÀ GBÉJÀKO ÌDÁNÌKANWÀ

▪ Súnmọ́ Jehofa

▪ Wá ìtùnú nipa kíka Bibeli

▪ Dí ojú-ìwòye ìfojúsọ́nà-fún-rere ti Kristian mú

▪ Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí fún ìgbòkègbodò tí ó nítumọ̀

▪ Mú kí awọn ọ̀rẹ́ rẹ pọ̀ síi

▪ Mú kí ó rọrùn fun awọn ọ̀rẹ́ lati ṣèrànlọ́wọ́

▪ Máṣe ya araàrẹ sọ́tọ̀, ṣugbọn mú ìfẹ́ oníwà-bí-ọ̀rẹ́ dàgbà

▪ Ní ìgbọ́kànlé pé Jehofa bìkítà fún ọ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

BÍ O ṢE LÈ ṢÈRÀNLỌ́WỌ́ FÚN AWỌN TÍ WỌN DÁNÌKANWÀ

▪ Pèsè òye, ọ̀yàyà, ati ìtùnú

▪ Kúnjú àìní fún ọ̀rọ̀ àṣírí

▪ Lo ìfaradà ní ṣíṣe awọn ohun kéékèèké tí ń ṣèrànlọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Láìka awọn àyíká ipò rẹ̀ tí ó ṣòro sí, kò sí awọn ìtọ́kasí kankan pé Rutu jẹ́ kí ìdánìkanwà ṣe ìgbésí-ayé oun báṣabàṣa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́