ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 27
  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó o lè bi ara rẹ nípa dídá wà
  • Ohun to yẹ kó o mọ̀ nípa níní ọ̀rẹ́ àti dídá wà
  • Bí o ṣe lè borí ìṣòro yìí
  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́
    Jí!—2015
  • Kí Ló Fà Á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Dá Wà?
    Jí!—2004
  • Bíborí Ìṣòro Dídá Wà
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 27
Ọmọbìnrin kan tínú rẹ̀ kò dùn torí pé ó dá wà

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?

O wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ò ń wo fọ́tò táwọn ọ̀rẹ́ rẹ yà níbi àríyá kan tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Gbogbo wọn ló wà níbẹ̀, ohun tó o rí sì fi hàn pé wọ́n ń gbádùn ara wọn. Ṣùgbọ́n ẹnì kan wà tí ò sí níbẹ̀. Ìwọ sì lẹni ọ̀hún.

O wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Kí ló dé tí wọn ò pè mí síbẹ̀?’

Kó o tó mọ̀, inú ti ń bí ẹ. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n dà ẹ́ nù! Àfi bíi pé pàbó ni gbogbo akitiyan tó o ṣe kó o tó di ọ̀rẹ́ wọn já sí. Ó wá dà bíi pé o ò lẹ́nì kankan, èyí mú kó o bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí tí mi ò fi ní ọ̀rẹ́ kankan?’

  • Ohun tó o lè bi ara rẹ nípa dídá wà

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa níní ọ̀rẹ́ àti dídá wà

  • Bí o ṣe lè borí ìṣòro yìí

  • Ohun tí àwọn ojúgbà rẹ sọ

  • Bó o ṣe lè borí ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù láti ní ọ̀rẹ́

Ohun tó o lè bi ara rẹ nípa dídá wà

Òótọ́ àbí Irọ́

  1. Tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá pọ̀ gan-an, o ò lè dá wà láéláé.

  2. Tó o bá wà lórí ìkànnì àjọlò, o ò lè dá wà láéláé.

  3. Tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ṣáá, o ò lè dá wà láéláé.

  4. Tó o bá ń ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì, o ò lè dá wà láéláé.

Irọ́ ni ìdáhùn sí gbólóhùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lókè yìí.

Kí nìdí?

Ohun to yẹ kó o mọ̀ nípa níní ọ̀rẹ́ àti dídá wà

  • Ti pé o ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ gan-an kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

    “Ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń jẹ mí lọ́kàn, àmọ́ nígbà míì, mi ò rò pé wọ́n rí tèmi rò. Tó o bá ń forí ṣe fọrùn ṣe kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè nífẹ̀ẹ́ rẹ, àmọ́ tó jọ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ lọ́nà kan náà tàbí pé wọn ò kà ẹ́ sí, ṣe ló máa dùn ẹ́ wọra pé o ò lẹ́nì kankan rárá.”​—Anne.

  • Ti pé o wà lórí ìkànnì àjọlò kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

    “Ṣe làwọn kan máa ń kó ọ̀rẹ́ jọ bí ìgbà téèyàn kó bèbí jọ. Béèyàn bá tiẹ̀ fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ to ilé, ìyẹn ò ní káwọn bèbí ọ̀hún yá mọ́ ọn tàbí kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí i. Lọ́nà kan náà, tó ò bá ní nǹkan gidi ṣe pẹ̀lú àwọn tó o fi ṣọ̀rẹ́, ṣe làwọn ọ̀rẹ́ tó o ní lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa dà bí bèbí lásán.”​—Elaine.

  • Ti pé ò ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ṣáá kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

    “Nígbà míì tó o bá wà níwọ nìkan, ṣe ni wà á máa yẹ fóònù rẹ wò ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá bóyá lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ. Àmọ́ tẹ́nì kankan ò bá wá fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ nírú àsìkò yìí, ó máa dùn ẹ́ gan-an!”​—Serena.

  • Ti pé ò ń ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

    “Mo máa ń fáwọn ọ̀rẹ́ mi ní nǹkan lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ mo kíyè sí i pé wọn kì í ṣe bákan náà sí mi. Kì í ṣe pé mo kábàámọ̀ pé mò ń fún wọn ní nǹkan o, àmọ́ ó rí bákan lára mi pé wọn ò tiẹ̀ fìgbà kan fún èmi náà ní nǹkan.”​—Richard.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun téèyàn ń rò ló máa ń mú kó ṣe é bí i pé ó dá wà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jeanette sọ pé: “Ohun tá à ń rò nínú wa lọ́hùn-ún ló ń fà á, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn ṣe sí wa.”

Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lọ́rẹ̀ẹ́ kankan tó o sì dá wà?

Bí o ṣe lè borí ìṣòro yìí

Ọmọbìnrin kan tó ń fojú kéré ara rẹ̀

Má fojú kéré ara rẹ.

“Téèyàn bá ń fojú kéré ara rẹ̀, ó lè mú kó má a dá wà. Tó o bá ń wo ara rẹ bíi pé o ò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bá ṣọ̀rẹ́, á ṣòro fún ẹ láti bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́, o sì lè má lọ́rẹ̀ẹ́.”​—Jeanette.

Bíbélì sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Gálátíà 5:14) Tá a bá fẹ́ láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, a ò ní máa fojú kéré ara wa, àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká máa gbéra ga o.​—Gálátíà 6:3, 4.

Ọmọkùnrin kan tó ti ro ara rẹ̀ pin

Má ro ara rẹ pin.

“Tó bá máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, ṣe ló dà bí ìgbà tó o wà nínú irà. Bó o bá ṣe ń pẹ́ sí i nínú rẹ̀ ló ṣe máa ṣòro fún ẹ láti jáde, wà á kàn máa rì ni. Lọ́nà kan náà, tó o bá lọ jẹ́ kí bó o ṣe ń dá wà gbà ẹ́ lọ́kàn pátápátá, ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún ẹ, ìyẹn láá wá burú jù.”​—Erin.

Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tá a bá ń ro tara wa nìkan ṣáá, a ò ní fi bẹ́ẹ̀ rí tàwọn èèyàn rò, ó sì ṣeé ṣe káwọn èèyàn máà fẹ́ bá wa ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 12:15) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà: Tó bá jẹ́ pé ìwà táwọn míì ń hù sí ẹ ló ń pinnu bóyá o máa láyọ̀ tàbí o ò ní láyọ̀, o ò ní lè ṣàṣeyọrí kankan! Sísọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Wọn ò pe fóònù mi rí” tàbí pé “Wọn ò pè mí síbì kankan rí” fi hàn pé àwọn ẹlòmíì ló ń pinnu bóyá o máa láyọ̀. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé o ti gbé agbára lé wọn lọ́wọ́ báyìí?

Ọmọkùnrin kan tí kò gbà láti mu sìgá

Má kàn fi ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́.

“Àwọn tó ń dá wà máa ń fẹ́ káwọn èèyàn yá mọ́ wọn, ó sì lè le lára wọn débi pé wọ́n á máa wá ọ̀rẹ́ kiri lójú méjèèjì, ẹni yòówù kó jẹ́. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣáà rí ẹni tá á rí tiwọn rò. Ó máa dáa kó o fi sọ́kàn pé àwọn míì á ṣe bí ọ̀rẹ́, àmọ́ ṣe ni wọ́n á lò ẹ́, tí wọ́n á sì pa ẹ́ tì. Háà, ìyẹn ló máa wá burú jù!”​—Brianne.

Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sóhun tí ẹni tébi ti fẹ́ pa kú ò lè jẹ. Lọ́nà kan náà, àwọn tó bá ń wá ọ̀rẹ́ lójú méjèèjì lè wá a débi tí kò yẹ. Wọ́n tiẹ̀ lè bọ́ sọ́wọ́ àwọn tó máa sọ wọ́n di bí wọ́n ṣe dà, wọ́n á sì rò pé kò sóhun tó burú nínú níní irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ àti pé àwọn ò lè rí ọ̀rẹ́ míì tó dáa jùyẹn lọ.

Lákòótán: Kò sẹ́ni tí kì í dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó kàn jẹ́ pé bá a ṣe máa ń mọ̀ ọ́n lára yàtọ̀ síra ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bá a ṣe dá wà lè bà wá nínú jẹ́ gan-an nígbà míì, ó yẹ ká máa rántí pé, ohun tá à ń rò ló ń mú kó ṣe wá bí i pé a dá wà. Ohun tá à sì ń rò ló máa ń sọ bí nǹkan ṣe máa rí lára wa, àmọ́ a lágbára láti pinnu ohun tá a máa gbé sọ́kàn.

Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o má máa retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Jeanette tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé “Má rò pé gbogbo ọ̀rẹ́ tó o bá ní ló máa jẹ́ kòríkòsùn rẹ títí ayé, àmọ́ ó dájú pé wàá rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ látọkàn wá. Àbí kí ló tún kù? Ìyẹn gan-an ni ò sì ní jẹ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà ní gbogbo ìgbà.”

Ṣé o fẹ́ mọ̀ sí i? Ka Apá tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Borí Ohun Tó Ń Bà Ẹ́ Lẹ́rù Láti Ní Ọ̀rẹ́.” O tún lè wa ẹ̀dà PDF abala “Ohun Tí Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ń Dá Wà.”

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Vanessa

“Fi ọ̀rọ̀ rẹ lọ ẹnì kan tó o mọ̀, sọ fún un bó ṣe ń ṣe ẹ́ tó o bá ń dá wà. Má pa á mọ́ra. Kó o sì máa wò ó, kì í ṣe ìwọ nìkan o, ọ̀pọ̀ àwọn tó o mọ̀ nírú ẹ̀ máa ń ṣe. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ọ̀rẹ́ kan tó máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ lo nílò.”​—Vanessa.

Taylor

“O ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé àwọn ẹlòmíì ló ń fa bó o ṣe dá wà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ìwọ gan-an lo ya ara rẹ sọ́tọ̀. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti tún bá àwọn èèyàn rẹ́. Tí ìyẹn ò bá bọ́ sí i, gbìyànjú láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, ó tiẹ̀ lè jẹ́ àwọn tó ò kì í fi bẹ́ẹ̀ bá ṣọ̀rọ̀.”​—Taylor.

Bó o ṣe lè borí ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù láti ní ọ̀rẹ́

“Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe é bí i pé ó dá wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó ṣì máa ń ṣe é bíi pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọn ò sì rí tiẹ̀ rò. Ṣe ló máa ń lejú kiri káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé nǹkan kan ń ṣe é. Àmọ́ bí kì í ṣeé dá sẹ́nì kankan yìí mú kó túbọ̀ ṣòro fún un láti ní ọ̀rẹ́. Ohun tó máa ń wá sọ́kàn àwọn tó bá pàdé rẹ̀ ni pé ẹni tára rẹ̀ kì í yá mọ́ọ̀yàn ni. Èyí sì máa ń mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn, pàápàá àwọn tí nǹkan kì í pẹ́ sú.

“Ohun míì tí kì í jẹ́ kí ọ̀rẹ́ mi yìí sún mọ́ àwọn èèyàn ni pé, ẹ̀rù máa ń bà á pé wọ́n lè já òun kulẹ̀. Torí náà, táwọn èèyàn bá fẹ́ yàn án lọ́rẹ̀ẹ́, ṣe ló máa ronú pé ohun tí ò dáa ni wọ́n ní lọ́kàn tàbí pé kò sí bí okùn ọ̀rẹ́ àwọn ò ṣe ní já. Ó máa ń ṣe é bíi pé ó dá wà torí ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, bẹ́ẹ̀ òun gan-an ni kì í túra ká, kì í sì í sọ tinú rẹ̀ jáde fún wọn.

“Ohun kan wà tó yẹ kí ọ̀rẹ́ mi yìí mọ̀, ìyẹn ni pé, téèyàn bá ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, èyí máa jẹ́ kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú wọn, wọ́n á sì lè mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Ó máa jẹ́ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí ẹ, bó o ṣe fẹ́. Ó wù mí pé kó yí èrò rẹ̀ pa dà, kó sì kọ́ bó ṣe máa borí ohun tó ń bà á lẹ́rù láti ní ọ̀rẹ́.”​—Elaine.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́