Kí Ló Fà Á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Dá Wà?
LÁWÙJỌ òde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dá wà. Èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí tọmọdé tàgbà, látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ipò wọn láwùjọ yàtọ̀ síra, tí ẹ̀sìn wọn ò sì pa pọ̀. Ṣé o ti dá wà rí? Ṣé o dá wà báyìí? Dájúdájú, gbogbo wa náà ló ti ṣe rí bíi ká ní alábàárò—ká rẹ́ni tẹ́tí sí wa, ká rẹ́ni fi wá lọ́kàn balẹ̀, tàbí ká rẹ́ni tí ìrònú ẹ̀ bá tiwa mu tàbí tó lóye ohun tó ń ṣe wá, tá á sì mọ̀ wá mọ irú ẹni tá a jẹ́. À ń fẹ́ ẹnì kan tí yóò lè máa ro tiwa mọ́ tiẹ̀.
Àmọ́ ṣá o, wíwà láwa nìkan ò fi dandan túmọ̀ sí pé a dá wà. Èèyàn lè wà lóun nìkan fún àkókò gígùn, kó sì máa gbádùn ohun tó ń ṣe láìmọ̀ pé òun dá wà. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn kan wà tí wọn ò lè dá wà rárá àti rárá ni. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The American Heritage Dictionary, sọ pé: “Ìtumọ̀ tí ìnìkanwà gbé yọ ni pé kéèyàn kankan máà sí lọ́dọ̀ ẹni, kò fi dandan túmọ̀ sí pé kéèyàn máà láyọ̀. . . . Èèyàn sì tún lè sọ pé òun dá wà nígbà mìíràn bójú bá ń ro ó nítorí àìrẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀, [àmọ́] èèyàn tún lè dá wà lọ́nà kan bí àárò bá ń sọ ọ́ nítorí àìsí alábàárò kankan,” ìyẹn ni pé kí inú rẹ̀ bà jẹ́, kí ọkàn rẹ̀ dà rú, tàbí kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Olúwarẹ̀ á wá nílò agbọ̀ràndùn àtẹni tó fẹ́ ẹ dénú kára rẹ̀ tó lè padà yá gágá. Lákòótán, ìwé atúmọ̀ èdè náà wá sọ pé “àpapọ̀ dídá wà tó ń mú kójú roni àtèyí tó ń mú kí àárò máa sọni, ló ń sọni di ẹni tó wà ní gàdàmù, tàbí tó ya ara rẹ̀ láṣo . . . Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí sábà máa ń túmọ̀ sí kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ máa yẹra fẹ́gbẹ́.”
Dídá wà máa ń káni lára gan-an, ó sì máa ń dunni wọnú egungun. Lábayọ̀jẹ́ ni, ó máa ń mú kí gbogbo nǹkan tojú súni. Á máa ṣeni bíi pé wọ́n dẹ́yẹ síni, bíi pé wọ́n léni kúrò láàárín ará yòókù. Nǹkan lè tètè máa dun èèyàn, kẹ́rù sì tún máa bani. Ṣé ó ti ṣe ẹ báyìí rí? Kí ló lè fa kéèyàn dá wà?
Àwọn ìṣòro tó ń jẹ yọ, ipò tó yí olúkúlùkù ká, àti bí nǹkan ṣe ń lọ sí máa ń nípa lórí àwọn èèyàn ní onírúurú ọ̀nà. Ó ṣeé ṣe kó o rò pé nítorí ìrísí rẹ, ẹ̀yà, tàbí ìsìn làwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ fi pa ọ́ tì. Bí àwọn ìyípadà bá wáyé, bíi lílọ sí ilé ìwé míì, bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun tàbí kíkó lọ sí àgbègbè, ìlú, tàbí orílẹ̀-èdè míì, ó lè mú kó ṣe ọ́ bí ẹni pé o dá wà nítorí pé o ní láti dágbéré fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́. Ikú àwọn òbí tàbí ikú ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó lè mú kéèyàn ní ìṣòro dídá wà, èyí sì lè máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bákan náà, bá a ti ń dàgbà sí i, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn ojúlùmọ̀ gbogbo á máa yí padà, wọ́n á máa dín kù, tàbí ká má tiẹ̀ rí wọn mọ́.
Ìgbéyàwó kì í fìgbà gbogbo gbani kúrò lọ́wọ́ dídá wà o. Àìgbọ́ra-ẹni-yé tàbí àìbára-ẹni-mu lè fa másùnmáwo tó lè mú kí ọkọ, aya, àtàwọn ọmọ máà mọ èwo ni ṣíṣe, tó sì tún lè mú kí wọ́n di ẹni tá a pa tì. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí ìnìkanwà tó máa ń wáyé nígbà tí ìbátan ẹni bá kú, nígbà tí tọkọtaya bá kọra wọn sílẹ̀, tàbí nípa wíwulẹ̀ ya ara ẹni láṣo tàbí nítorí àìlálábàárò, irú ìnìkanwà míì tún wà tó lè nípa tó pọ̀ gan-an lórí wa. Irú èyí máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tá ò bá ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run tó sì dà bí ẹni pé a ti sọ ara wa di àjèjì sí i.
Ǹjẹ́ èyíkéyìí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí lára àwọn nǹkan tá a ṣàpèjúwe nínú àpilẹ̀kọ yìí? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó o borí ìṣòro dídá wà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé, látorí lílọ sí ilé ìwé míì títí dórí ikú ọkọ tàbí aya ẹni, lè mú kéèyàn dá wà