ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 6/8 ojú ìwé 5-8
  • Bíborí Ìṣòro Dídá Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíborí Ìṣòro Dídá Wà
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Bá Ní Ìṣòro Dídá Wà
  • Ìwọ Náà Lè Borí Ìṣòro Dídá Wà
  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • O Lè Borí Ìnìkanwà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kí Ló Fà Á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Dá Wà?
    Jí!—2004
  • Tó O Bá Láwọn Ọ̀rẹ́, O Lè Borí Ìṣòro Ìdánìkanwà—Bí Bíbélì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 6/8 ojú ìwé 5-8

Bíborí Ìṣòro Dídá Wà

KÒ RỌRÙN láti borí ìṣòro dídá wà. Ó máa ń mú kéèyàn ro àròkàn. Báwo lèèyàn ṣe lè borí ìṣòro dídá wà? Kí lohun táwọn kan ṣe tí wọ́n fi borí rẹ̀?

Bó O Bá Ní Ìṣòro Dídá Wà

Ó máa ń wu Helena pé kó wà lóun nìkan bó bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu kan, ṣùgbọ́n ó rí i pé dídá wà léwu. Nígbà tó wà lọ́mọdé, kì í báwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí ò sì mọ bó ṣe lè fọ̀rọ̀ lọ̀ wọ́n, á kúkú tira ẹ̀ mọ́lé. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìṣòro àìlèjẹun. Àárẹ̀ ọkàn sì ń ṣe mí. Màá kàn tiẹ̀ sọ fúnra mi nígbà míì pé, ‘Èwo làbùrọ̀ máa yọ ara mi lẹ́nu nítorí ọ̀rọ̀ àwọn òbí mi, nígbà tí wọn ò yọ ara wọn lẹ́nu nítorí ọ̀rọ̀ tèmi náà?’ Lẹ́yìn náà ni mo wá ronú pé ìgbéyàwó á bá mi tán ìṣòro dídá wà mi. Mò ń wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ ti mo fi bí ara mi léèrè pé: ‘Kí ló dé tí màá fi ba ayé ẹni ẹlẹ́ni jẹ́? Ohun tí ǹ bá kọ́kọ́ ṣe ni pé kí n tún èrò ara mi pa!’ Mo gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo sì sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe mí fún un.

“Nínú Bíbélì, mo rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú gan-an, bí irú èyí tó wà nínú Aísáyà 41:10 pé: ‘Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.’ Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ gidigidi nítorí pé ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé mi ò ní bàbá. Ní báyìí mo ti ń ka Bíbélì déédéé, mo sì ń gbàdúrà sí Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Mo ti mọ bí mo ṣe lè borí ìṣòro dídá wà mi.”

Bí ẹni wa kan bá kú, ó máa ń bà wá nínú jẹ́ gan-an ni, ìyẹn sì lè fa kéèyàn dá wà. Luisa, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, sọ ohun tó ń dùn ún lọ́kàn pé: “Ọmọ ọdún márùn-ún ni mí nígbà tí wọ́n pa bàbá mi. Mo fara mọ́ ìyá bàbá mi kó lè tù mí nínú, ṣùgbọ́n mi ò rò pé ó fẹ́ràn mi. Kò sẹ́ni tó fìfẹ́ hàn sí mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé, lákòókò tí mo nílò rẹ̀ jù lọ. Láàárín ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́sàn-án, ìgbà mẹ́ta ni mo ti gbìyànjú àtipara mi. Mo rò pé ìyẹn ló máa pé ìdílé mi jù lọ nítorí pé gbogbo ara ni màmá mi fi ń ṣiṣẹ́ kó tó lè bọ́ èmi àtàwọn àǹtí mi mẹ́ta. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tọkọtaya kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí mi. Wọ́n máa ń sọ fún mi pé, ‘A mọrírì rẹ, a sì nílò rẹ.’ Ọ̀rọ̀ yẹn lásán, ‘A nílò rẹ’ fún mi lókun púpọ̀. Nígbà míì, mi ò lè sọ ohun tó ń ṣe mí fún ẹlòmíì, ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, nítorí pé àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ti jẹ́ kí n mọ̀ pé ó fẹ́ràn mi. Mo ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyípadà. Ní báyìí, èmi náà ti dẹni tó lè rẹ́rìn-ín músẹ́, mo sì lè sọ fún màmá mi bí ohun kan bá bà mí nínú jẹ́ tàbí tí mo bá láyọ̀. Nígbà míì, mo máa ń rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá o, ṣùgbọ́n kì í ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ tí mo máa ń gbìyànjú láti para mi tàbí nígbà tí mo dẹ́kun bíbá àwọn ìbátan mi sọ̀rọ̀. Nígbà gbogbo ni mo máa ń rántí ohun tí onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: ‘Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi ni èmi yóò ṣe sọ̀rọ̀ wàyí pé: “Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.”’”—Sáàmù 122:8.

Ọkọ Martha ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ látọdún méjìlélógún sẹ́yìn, ó sì tọ́ ọmọ kan dàgbà láàárín àkókò náà. Ó sọ pé: “Èrò àìjámọ́ nǹkan kan àti dídá wà tún máa ń wáyé bí mo bá ronú ohun kan tí mi ò ṣe láṣeyọrí.” Báwo ló ṣe borí èrò yìí? Ó ṣàlàyé pé: “Mo ti wá rí i pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti borí wọn ni pé kí n tètè sọ fún Jèhófà Ọlọ́run nípa wọn. Nígbà tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ pé ń kò dá wà. Jèhófà mọ̀ mí ju bí mo ṣe mọ ara mi lọ. Mo tún máa ń wá ọ̀nà tí mo lè gbà fi hàn pé mo ní ire àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí mò ń ṣe ló ràn mí lọ́wọ́ jù lọ láti ṣẹ́pá àwọn èrò òdì . Béèyàn bá sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run téèyàn sì wá rántí pé àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ ò ní ìrètí kankan tí wọn ò sì rò pé ìṣòro àwọn lè yanjú, ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìdí tó túbọ̀ lágbára téèyàn á fi fẹ́ láti wà láàyè kó sì máa sapá nìṣó.”

Elba, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún tí ọmọ kan ṣoṣo tó bí sì ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè mìíràn, sọ fún wa bó ṣe borí ìṣòro náà pé: “Nígbà tí wọ́n ké sí ọmọbìnrin mi àti ọkọ ẹ̀ láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, mo rí i tí ojú wọ́n kún fáyọ̀, mo sì bá wọn yọ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n rán wọn láti lọ sìn ní ilẹ̀ àjèjì, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mí bí i pé kí wọ́n má lọ. Mo mọ̀ pé wọn ò ní sí nítòsí mi mọ́, ó sì dùn mí bákan ṣá. Bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára mi dà bíi ti Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ orí kọkànlá. Mo ní láti gbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú omijé lójú, mo tọrọ ìdáríjì rẹ̀. Ọmọ mi àti ọkọ ẹ̀ máa ń kàn sí mi déédéé. Mo mọ̀ pé ọwọ́ wọ́n di gan-an ni, ṣùgbọ́n níbikíbi yòówù tí wọ́n bá ti ń sìn, wọn ò jẹ́ gbàgbé mi, wọ́n máa ń fi ìrírí tí wọ́n bá ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ránṣẹ́ sí mi. Àkàtúnkà ni mo máa ń ka àwọn lẹ́tà tí wọ́n bá kọ sí mi. Ńṣe ló dà bí ẹni pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń bá mi sọ̀rọ̀, mo sì dúpẹ́ gidigidi fún ìyẹn. Bákan náà, àwọn Kristẹni alàgbà tó wà nínú ìjọ wa máa ń bójú tó àwa arúgbó àtàwọn aláìlera, wọ́n máa ń rí sí i pé mọ́tò tí yóò gbé wa lọ sí ìpàdé wà, wọ́n sì tún máa ń pèsè àwọn nǹkan mìíràn tá a bá ṣaláìní. Mo máa ń ka àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi sí ẹ̀bùn tí Jèhófà pèsè fún mi.”

Ìwọ Náà Lè Borí Ìṣòro Dídá Wà

Yálà ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, àpọ́n tàbí ẹni tó ti ṣègbéyàwó, ọmọ lọ́dọ̀ òbí tàbí ọmọ òrukàn, bóyá ẹnì kan sì ti kú fún ọ rí tàbí kó jẹ́ pé nǹkan míì ló fà á tó o fi dá wà, ọ̀nà wà tó o lè gbà kojú àwọn ìmọ̀lára rẹ. Jocabed, ọmọ ọdún méjìdínlógún tí bàbá rẹ̀ pa ìdílé ẹ̀ tí gbogbo wọn jẹ́ ẹni mẹ́fà tì tó sì lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, sọ pé: “Má ṣe bo ohun tó ń ṣe ọ́ mọ́ra! Ó ṣe pàtàkì pé ká sọ bó ṣe ń ṣe wá fáwọn èèyàn. Bá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tí ohun tó ń ṣe wá máa yé o.” Ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé: “Yé ro àròkàn, nítorí pé àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ùndá. Wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó dàgbà dénú, má ṣe lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ipò wọn lè burú ju tìẹ lọ.” Luisa tá a ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tẹ́lẹ̀, sọ pé: “Àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà máa ń jẹ́ ká rí ìrànlọ́wọ́ tá a bá nílò láti rí ọ̀nà àbáyọ nígbà tá a bá sún kan ògiri.” Jorge, tí ìyàwó rẹ̀ ti ṣaláìsí, ṣàlàyé nípa bó ṣe ń kojú ìṣòro dídá wà: “Má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ọ́. Níní ire àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. ‘Níní ẹ̀mí ìgbatẹnirò’ nígbà tá a bá ń jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lè mú kí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ nítumọ̀ ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ànímọ́ rere táwọn ẹlòmíì ní.”—1 Pétérù 3:8.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tá a lè ṣe ká má bàa máa dá wà. Ṣùgbọ́n, ṣé ọjọ́ kan á jọ́kan tí ìṣòro dídá wà á ti dohun àtijọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo nìyẹn á ṣe ṣẹlẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn á dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà máa ń jẹ́ ká rí ìrànlọ́wọ́ tá a bá nílò láti rí ọ̀nà àbáyọ nígbà tá a bá sún kan ògiri.”—Luisa

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun Tó O Lè Ṣe Nípa Dídá Wà

◼ Fi sọ́kàn pé ohun tó ń ṣe ọ́ lè yí padà, kì í ṣe ohun tí kò látùn-únṣe ṣùgbọ́n ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmíì ni.

◼ Má ṣe máa retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara ẹ.

◼ Máa jẹ́ kí ohun tó o bá ṣe tẹ́ ọ lọ́rùn.

◼ Máa jẹ oúnjẹ tó dáa síkùn ara ẹ, máa ṣeré ìdárayá kó o sì máa sun oorun tó pọ̀ tó.

◼ Máa lo àkókò tó o bá dá wà láti ṣe iṣẹ́ ọwọ́ àti láti máa kọ́ àwọn nǹkan tuntun.

◼ Má máa fojú àwọn ohun tó o mọ̀ nípa àwọn èèyàn tẹ́lẹ̀ wo àwọn tó ò ń bá pàdé.

◼ Mọyì àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ànímọ́ tí wọ́n ní. Wá bó o ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára. Fọgbọ́n àwọn tó dàgbà tí wọ́n sì nírìírí jù ọ́ lọ ṣọgbọ́n.

◼ Máa ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn—rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, sọ̀rọ̀ onínúure sí wọn, jíròrò ohun kan látinú Bíbélì pẹ̀lú wọn. Mímọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn kà wá kún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú dídá wà.

◼ Má ṣe fàwọn gbajúmọ̀ òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn èèyàn inú ìwé ìtàn lálàá ọ̀sán gangan, kó o sì wá máa ronú pé ò ń ní àjọṣe pẹ̀lú wọn.

◼ Bó o bá ti ṣègbéyàwó, má ṣe retí pé gbogbo ohun tó bá ń dùn ọ́ lọ́kàn lẹnì kejì rẹ á máa rí nǹkan ṣe sí. Ẹ kọ́ bẹ́ ẹ ṣe lè máa gbà fúnra yín, bẹ́ ẹ ṣe lè máa ran ara yín lọ́wọ́ àti bẹ́ ẹ ṣe lè máa ti ara yín lẹ́yìn.

◼ Kọ́ bó o ṣe lè bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, kó o sì mọ bá a ṣeé tẹ́tí sẹ́lòmíì. Máa kọbi ara sáwọn ẹlòmíì kí ire wọn sì máa jẹ ọ́ lọ́kàn. Máa fọ̀ràn rora ẹ wò.

◼ Mọ̀ pé o ní ìṣòro dídá wà, kó o sì fọ̀ràn lọ ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà dénú, ẹnì kan tó o lè gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́. Má ṣe rún ìyà mọ́ra.

◼ Má ṣe máa mu ọtí àmujù, tàbí kó o má ṣe mutí rara. Ọtí líle ò lè mú ìṣòro rẹ kúrò, bí ọtí bá dá lójú ẹ, àwọn ìṣòro náà á tún yọjú.

◼ Má ṣe gbéra ga. Forí ji àwọn tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́, kó o sì bá wọn rẹ́ padà. Má ṣe jẹ́ kí ojú ẹ máa le jù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Báwo ni ẹnì kan ṣe lè borí ìṣòro dídá wà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́