ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 21-23
  • Kí Ló Dé Tí Ẹnikẹ́ni Kì Í Dá Sí Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí Ẹnikẹ́ni Kì Í Dá Sí Mi?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Máa Ń Mú Kó Dunni
  • Ohun Tó O Lè Ṣe sí Dídá Wà
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́
    Jí!—2015
  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Máṣe Jẹ́ Kí Ìdánìkanwà Ṣe Ìgbésí-Ayé Rẹ Báṣabàṣa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Fọkàn Balẹ̀, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tí Ẹnikẹ́ni Kì Í Dá Sí Mi?

“Ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀, ṣe ló máa ń dà bíi pé gbogbo aráyé ló ń gbádùn ara wọn àfèmi nìkan.”—Renee.

“Àwọn ọ̀dọ́ á kóra jọ láti máa bára wọn ṣeré, èmi nìkan ló máa ń kù tí mo máa ń dá jẹ̀!”—Jeremy.

OJÚMỌ́ ti mọ́ kẹlẹlẹ, o ò lóko lọ, o ò sì lódò rè. Àmọ́, gbogbo ará yòókù ti mọ ohun táwọn á dáwọ́ lé. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ti níbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ gbádùn ara wọn. Síbẹ̀ náà, o ò rẹ́ni dá sí ẹ!

Ohun tí ò dáa ni kéèyàn máà rẹ́ni dá sóun, èyí tó tún wá burú jù ni ríronú nípa ohun tó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀. O lè máa rò ó nínú ara ẹ pé, ‘àbí nǹkan kan ń ṣe mí ni.’ ‘Kí ló dé tí gbogbo èèyàn ò rí tèmi rò?’

Ohun Tó Máa Ń Mú Kó Dunni

Kò sẹ́ni tí kì í wù pé kóun rẹ́ni fojú jọ, káwọn èèyàn sì máa gba tòun. Nítorí pé Ọlọ́run ò dá wa láti máa dá gbé, a ò lè ṣe ká má báwọn ẹlòmíì da nǹkan pọ̀. Kí Jèhófà tó dá Éfà ló ti sọ nípa Ádámù pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Kò sírọ́ ńbẹ̀, èèyàn laṣọ èèyàn; bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn. Ìyẹn náà ló sì fi máa ń dùn wá bá ò bá rẹ́ni dá sí wa.

Ká sòótọ́, kì í béèyàn lára mu bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn ẹlòmíì kì í dá sí tiẹ̀ tàbí tí wọ́n ń jẹ́ kó ríra ẹ̀ bí ẹni tí ò bẹ́gbẹ́ mu. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Marie sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kan wà tí wọ́n kóra jọ, gbogbo wọn ló sì ń dá bírà, àmọ́ o lè rí i kedere pé wọn ò kà ẹ́ kún ẹni tó lè wẹgbẹ́ àwọn.” Bó bá di pé àwọn míì ò fẹ́ kó o wẹgbẹ́ àwọn, ó di kó o máa ronú pé wọn ò fẹ́ dá sí ẹ, àti pé o ò ní rẹ́ni bá rìn.

Nígbà míì sì rèé, o lè wà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn síbẹ̀ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé ńṣe lo dá wà. Nicole sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè dà bí àsé, mo ṣì rántí pé mo ti wà níbi àpèjẹ kan rí, síbẹ̀ tó ń ṣe mí bíi pé ṣe ni mo dá wà. Mo ronú pé ohun tó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé mo wà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, síbẹ̀ bí àjèjì ni gbogbo wọn rí sí mi.” Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé bí àjèjì ni wọ́n máa ń rí bí wọ́n bá wà láwọn àpéjọ Kristẹni. Meagan sọ pé: “Ó dà bí ẹni pé gbogbo ará yòókù ló mọra wọn àfèmi nìkan!” Bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Maria náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé ọ̀rẹ́ ni gbogbo àwọn tó yí mi ká, síbẹ̀ mi ò ní èyíkéyìí nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́.”

Kò sẹ́ni tí kì í dùn bó bá dá wà, ìyẹn ò sì yọ àwọn tó dà bíi pé wọ́n gbajúmọ̀ tàbí tí wọ́n láyọ̀ sílẹ̀. Òwe inú Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora.” (Òwe 14:13) Béèyàn ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí dídá wà, ó lè muni lómi gan-an. Bíbélì sọ pé: “Nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn kà pé: “Ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.” (Òwe 15:13; Bibeli Mimọ) Bó o bá ti dààmú rí nítorí pé àwọn ẹlòmíì ò dá sí ẹ, kí lo lè ṣe?

Ohun Tó O Lè Ṣe sí Dídá Wà

Bó ò bá fẹ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, gbìyànjú kó o ṣe àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí.

◼ Pọkàn pọ̀ sórí àwọn ànímọ́ rere tó o ní. (2 Kọ́ríńtì 11:6) Bí ara ẹ pé, ‘Ibo ni mo dáa sí?’ Ronú nípa àwọn ẹ̀bùn tàbí ànímọ́ rere díẹ̀ tó o ní, kó o sì tò wọ́n sí àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Báwọn míì ò bá dá sí ẹ, rán ara ẹ létí pé ìwọ náà níbi tó o dáa sí, bí irú àwọn tó o tò sókè yẹn. Lóòótọ́, o láwọn ibi tó o kù sí, o sì gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe nípa wọn. Síbẹ̀, má ṣe jẹ́ káwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọ̀nyí kó ìdààmú bá ẹ. Máa fojú ẹni tó ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ wora ẹ. Bí gbogbo nǹkan ò tiẹ̀ rí bó o ṣe rò lójú ẹsẹ̀, díẹ̀díẹ̀ á máa bọ́ sójú ẹ̀. Àwọn tó bọ́ sójú ẹ yẹn gan-an ni kó o pọkàn pọ̀ lé lórí!

◼ Wẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Wá àwọn ẹlòmíì bá ṣọ̀rẹ́. Òótọ́ ni pé ìyẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Liz, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń ba èèyàn láti là gààrà lọ sáàárín àwọn tó ń kóra wọn jẹ̀, àmọ́ bó o bá tọ ọ̀kan lára wọn lọ tó o sì sọ pé ‘báwo ni nǹkan,’ kíá làwọn yòókù á rí ẹ bí ọ̀kan lára wọn.” (Wo àpótí tá a pè ní “Bo O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò.”) Wàyí o, lórí ọ̀rọ̀ ti rírí ẹni bá rìn tá à ń sọ yìí, rí i dájú pé ìwọ alára ń báwọn míì rìn, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Cori, tí ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá tàbí mọ́kànlá, mo ní ọ̀rẹ́ kan tó jù mí lọ dáadáa. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ làwa méjèèjì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣẹgbẹ́ mi.”

Ronú nípa àwọn àgbàlagbà méjì tí wàá fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ dunjú nínú ìjọ.

․․․․․

Ní ìpàdé ìjọ tó kàn tẹ́ ẹ máa ṣe, o ò kúkú ṣe tọ ọ̀kan lọ lára àwọn èèyàn tó o kọ orúkọ wọn sílẹ̀ yìí. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé báwo ló ṣe dẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o bá ṣe ń sapá tó láti máa wá ọ̀rẹ́ sáàárín “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,” bẹ́ẹ̀ náà ni wàá máa rí i pé kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣe ẹ́ bíi pé o ò rẹ́ni bá rìn tàbí pé o dá wà mọ́.—1 Pétérù 2:17.

◼ Sọ tinú ẹ fẹ́ni tó jù ẹ́ lọ. (Òwe 17:17) Bó o bá ń sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fáwọn òbí ẹ tàbí àgbàlagbà míì, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dín ṣíṣe tó ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà kù. Ohun tí ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún kan ṣàkíyèsí nìyẹn. Ó kọ́kọ́ máa ń dààmú jù bí ò bá rẹ́ni dá sí tiẹ̀. Ó tún sọ pé: “Ṣe ni mo máa ń ro ohun tó fà á táwọn èèyàn kì í fi í bá mi rìn ní àròtúnrò, bó bá sì wá ṣe, màá fi ọ̀rọ̀ náà tó màmá mi létí, á sì fún mi nímọ̀ràn lórí ohun tí mo lè ṣe sí i. Sísọ tí mò ń sọ tinú mi jáde lọ́nà yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni!”

Bó bá pọn dandan pé kó o wẹ́ni sọ fún nípa èrò dídá wà tí kò kúrò lọ́kàn ẹ bọ̀rọ̀, ta lo máa tọ̀ lọ?

․․․․․

◼ Ronú nípa àwọn ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Bíbélì sọ pé a kò gbọ́dọ̀, “máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wa] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Òótọ́ ni pé béèyàn ò bá rẹ́ni bá rìn, kò ní pẹ́ téèyàn á fi rẹ̀wẹ̀sì tàbí táá fi banú jẹ́. Àmọ́, dípò tí wàá fi máa sọ̀rètí nù síwájú àti síwájú sí i, o ò kúkú ṣe wá ọ̀nà tó o máa gbà ran àwọn aláìní lọ́wọ́? Àwọn míì sì lè tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ ẹ!

Ronú nípa ẹnì kan, bóyá nínú ìdílé ẹ tàbí nínú ìjọ táá fẹ́ kí ìwọ àtòun jọ ṣe nǹkan pọ tàbí tó máa nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ láwọn ọ̀nà míì. Kọ orúkọ ẹni náà sí àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà tó o fẹ́ gbà ràn án lọ́wọ́ síbẹ̀.

․․․․․

Bó o bá ń ronú nípa àwọn ẹlòmíì jura ẹ lọ tó o sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa dá wà mọ́. Èyí ẹ̀wẹ̀, sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa ro èrò rere, kójú ẹ máa fani mọ́ra, káwọn èèyàn sì máa fẹ́ láti bá ẹ ṣọ̀rẹ́. Òwe 11:25 sọ pé: “Ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”

◼ Wá ẹni rere bá ṣọ̀rẹ́. (Òwe 13:20) Ó sàn kéèyàn ní ìwọ̀nba ojúlówó ọ̀rẹ́ tí wọ́n á máa ro tẹni mọ́ tiwọn ju kéèyàn ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tó fojú jọ̀rẹ́ tí wọ́n lè kóni sí ìṣòro. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ìwọ wo àpẹẹrẹ ti Sámúẹ́lì ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kójú ti máa ro òun náà nínú àgọ́ ìjọsìn. Òun, Hófínì àti Fíníhásì ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, ìwàkiwà tó kún ọwọ́ Hófínì àti Fíníhásì ò jẹ́ kí Sámúẹ́lì lè yàn wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ àlùfáà àgbà ni wọ́n. Bí Sámúẹ́lì bá fi ọ̀ranyàn mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ló fi ń ṣeré yẹn. Àmọ́ Sámúẹ́lì ò jẹ́ gbà kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀! Bíbélì sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” (1 Sámúẹ́lì 2:26) Àwọn èèyàn wo ni Bíbélì ń sọ ná? Ó dájú pé wọn ò lè jẹ́ Hófínì àti Fíníhásì, àwọn tó jẹ́ pé àfàìmọ̀ kí wọ́n má ti pa Sámúẹ́lì tì nítorí pó ń hùwà rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ àtàtà tí Sámúẹ́lì ní sọ ọ́ di ẹni ọ̀wọ́n fáwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà gan-an lo lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́!

◼ Máa ro èrò tó dáa. (Òwe 15:15) Bó ti wù ó rí, kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ àwọn ẹlòmíràn kù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Dípò tí wàá fi máa ro èrò tí ò dáa, gbìyànjú láti máa fọkàn ẹ ro nǹkan tó dáa. Kó o sì rántí pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tó o lè ṣe nípa gbogbo ohun tó máa dé bá ẹ láyé, o ṣì lè ṣe mẹ́wàá nípa ojú tí wàá fi máa wò irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, bó bá dà bíi pé o ò rẹ́ni dá sí ẹ, wá nǹkan ṣe nípa ẹ, yálà kó o ṣe ohun táwọn èèyàn á fi máa rí ẹ bí ọ̀rẹ́ tàbí kó o yí ojú tó o fi ń wo irú ipò bẹ́ẹ̀ padà. Máa rántí ní gbogbo ìgbà pé Jèhófà mọ irú ẹni tó o jẹ́, nítorí náà ó mọ àwọn nǹkan tó o ṣaláìní àti nǹkan tóun lè ṣe sí i. Bí èrò pé o dá wà bá ń dà ẹ́ láàmú lemọ́lemọ́, gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe báwọn èèyàn ò bá dá sí mi?

◼ Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa fojú tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì wo ara mi dípò tí màá fi jẹ́ kí èrò búburú gbà mí lọ́kàn?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò

◼ Rẹ́rìn-ín músẹ́. Bó o bá yá mọ́ni, á máa wu àwọn míì láti bá ẹ sọ̀rọ̀.

◼ Sọ ẹni tó o jẹ́. Sọ orúkọ ẹ àti ibi tó o ti wá.

◼ Wá nǹkan béèrè. Láìṣe bí ẹní ń tojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn, o lè béèrè ìbéèrè tó bá yẹ nípa ibi tí ẹnì kan ti wá.

◼ Fetí sílẹ̀. Má wulẹ̀ máa ronú nípa ohun tí wàá fi fèsì ọ̀rọ̀. Ṣáà rí i pé o kọ́kọ́ máa ń fetí sílẹ̀. Wẹ́rẹ́ báyìí sì ni ìbéèrè tàbí ọ̀rọ̀ tó o máa fi fèsì á wá sí ẹ lọ́kàn.

◼ Fara balẹ̀! Bíbá àwọn ẹlòmíì jíròrò máa ń jẹ́ kí ọ̀rẹ́ téèyàn ní pọ̀ sí i. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àǹfààní yìí fò ẹ́ dá!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́