ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 3/8 ojú ìwé 20-23
  • Bí Mo Tilẹ̀ Fọ́jú, Mo Wúlò, Mo Sì Láyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Mo Tilẹ̀ Fọ́jú, Mo Wúlò, Mo Sì Láyọ̀
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Kọ́ Mi Láti Kórìíra Ọlọ́run
  • Bí Ẹranko Kan Nínú Àgò
  • Bàbá Mi Ràn Mí Lọ́wọ́
  • Jíjèrè Ojú Ìríran Tẹ̀mí
  • Ìgbéyàwó Tú Ká
  • Ìgbésí Ayé Aláyọ̀ Tí Ń Méso Jáde
  • Ọlọ́run Mi Mú Mi Dúró
  • Mo ti lè ran àwọn míì lọ́wọ́ báyìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Lílajú Sí Ìhìnrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jèhófà La Ojú Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 3/8 ojú ìwé 20-23

Bí Mo Tilẹ̀ Fọ́jú, Mo Wúlò, Mo Sì Láyọ̀

Gẹ́gẹ́ bí Polytimi Venetsianos ṣe sọ ọ́

Èmi àti àwọn ọmọ ìyá mi mẹ́ta àti ìbátan mi kan la ń ṣeré nígbà tí ohun kékeré kan fò wọlé láti ojú fèrèsé. Bọ́ǹbù abúgbàù tí wọ́n kẹ́ ni, nígbà tó sì bú, àwọn ọmọ ìyá mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló pa, ó sì fọ́ èmi náà lójú pátápátá.

DÉÈTÌ ọjọ́ náà ni July 16, 1942, nígbà tí mo jẹ́ ọmọdébìnrin ọlọ́dún márùn-ún péré. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni mo fi ń dákú dájí. Nígbà tí mo wá jí pátápátá, mo béèrè àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi. Bí mo ṣe gbọ́ pé wọ́n ti kú, mo ronú pé ì bá dára ká ní èmi náà ti kú.

Erékùṣù Gíríìsì ti Sálámísì, nítòsí Piraiévs, tí ó jẹ́ èbúté Áténì ni ìdílé mi ń gbé nígbà tí wọ́n bí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìní, a ń gbé lálàáfíà. Gbogbo ìyẹn dópin nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1939. Bàbá mi jẹ́ atukọ̀ òkun lójú agbami Mẹditaréníà nígbà náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń yẹ̀ fún àwọn ọkọ̀ ogun ńláńlá tí ń rìn lábẹ́ omi, ọkọ̀ ogun kéékèèké tí ń rìn lábẹ́ omi, ọta abúgbàù tí a kẹ́ sábẹ́ omi, àti bọ́ǹbù àwọn Orílẹ̀-Èdè Apawọ́pọ̀jagun àti ti Orílẹ̀-èdè Onígbèjà. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ítálì àti Germany ló gba gbogbo ilẹ̀ Gíríìsì nígbà náà.

Wọ́n Kọ́ Mi Láti Kórìíra Ọlọ́run

Bí ipò nǹkan ṣe burú gan-an ní àkókò ogun náà mú kí ọmọ kẹrin kú mọ́ Màmá lọ́wọ́. Ó wá ní ìsoríkọ́ tí ó burú jáì, ó tún ní ikọ́ ẹ̀gbẹ, níkẹyìn, ó kú ní August 1945 lẹ́yìn tí ó bí ọmọ rẹ̀ kẹfà tán. Àwọn tó jẹ́ onísìn ládùúgbò wa bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wá. Ńṣe ni àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì tí ń gbìyànjú láti fún wa níṣìírí tún ń ba nǹkan jẹ́ sí i ní sísọ pé Ọlọ́run mú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi lọ sí ọ̀run láti fi wọ́n ṣe áńgẹ́lì kéékèèké.

Inú bí Bàbá. Báwo ní Ọlọ́run ṣe ní láti já àwọn ọmọdé kéékèèké mẹ́rin gbà lọ́wọ́ ìdílé kan tí ó tòṣì nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn áńgẹ́lì wà pẹ̀lú rẹ̀? Ìgbàgbọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní yìí ru ẹ̀mí àìnífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àìnífẹ̀ẹ́ ìsìn sókè nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn mọ́. Ó kọ́ mi láti kórìíra Ọlọ́run àti láti tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, ní títẹnu mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló ṣokùnfà ìrora wa àti ipò ìnira tí a wà.

Bí Ẹranko Kan Nínú Àgò

Gẹ́rẹ́ tí màmá mi kú ní 1945 ni ikọ́ ẹ̀gbẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe Bàbá, wọ́n sì fi sí ibùgbé àwọn aláìsàn. Wọ́n gbé àbúrò mi obìnrin kékeré jòjòló lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ ọwọ́. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Bàbá jáde ní ibùgbé àwọn aláìsàn, tó wá lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé náà láti lọ gbé àbúrò mi ni wọ́n sọ fún bàbá mi pé ó ti kú. Wọ́n fi mí sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú, ibẹ̀ ni mo ti lo ọdún mẹ́jọ tí ó tẹ̀lé e nínú ìgbésí ayé mi. Lákọ̀ọ́kọ́ ìbànújẹ́ bá mi. Àwọn ọjọ́ tí àwọn ènìyàn ń bẹ̀ wá wò ló máa ń burú jù. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn afọ́jú ẹlẹgbẹ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́ ló ń ní ẹnì kan tí ń bẹ̀ wọ́n wò, àmọ́ kò sí ẹni tí ń bẹ èmi wò.

Mo ń hùwà bí ẹranko kan nínú àgò. Wọ́n ń pè mí ní àgbákò tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń nà mí, wọ́n sì máa ń gbé mi jókòó sínú ‘àga tí a ti ń fìyà jẹ àwọn aláìgbọràn.’ Mo sábà máa ń ronú pípa ara mi. Àmọ́, bí àkókò ti ń lọ, ó wá hàn kedere sí mi pé mo gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn. Mo wá rí ìtẹ́lọ́rùn nípa ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn afọ́jú ẹlẹgbẹ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́, mo sábà máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wọṣọ tàbí láti tún bẹ́ẹ̀dì wọn ṣe.

Àlùfáà sọ fún wa pé Ọlọ́run fọ́ wa lójú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì tí àwọn òbí wa ti dá. Èyí mú kí ń túbọ̀ kórìíra Ọlọ́run, tí ó dà bí pé ó jẹ́ ẹni tí ń múni bínú tí ó sì ní ẹ̀tanú. Ẹ̀kọ́ ìsìn kan tí ó bà mí lẹ́rù tí ó sì mú kí inú bí mi jù lọ ni pé ẹ̀mí àwọn òkú ń lọ káàkiri láti yọ àwọn alààyè lẹ́nu. Nípa bẹ́ẹ̀, mo ń bẹ̀rù “ẹ̀mí” àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi àti ti màmá mi tó ti kú bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn.

Bàbá Mi Ràn Mí Lọ́wọ́

Láìpẹ́, Bàbá ṣe alábàápàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó yà á lẹ́nu láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé kì í ṣe Jèhófà ló ń fa ìrora àti ikú bí kò ṣe Sátánì. (Sáàmù 100:3; Jákọ́bù 1:13, 17; Ìṣípayá 12:9, 12) Láìpẹ́, òye tí bàbá mi ti ní mú kí ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe ìrìbọmi ní 1947. Ó ti gbé ìyàwó mìíràn ní oṣù díẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn, ó sì ti bí ọmọkùnrin kan. Láìpẹ́, ìyàwó rẹ̀ tuntun dara pọ̀ mọ́ ọn ni jíjọ́sìn Jèhófà.

Ìgbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mo fi ilé ẹ̀kọ́ afọ́jú sílẹ̀. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìtùnú tó láti padà wá sínú ìdílé Kristẹni ọlọ́yàyà! Wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n pè ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé, wọ́n sì máa ń pè mí síbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í fi bẹ́ẹ̀ fiyè sí i, mo sáà ń wá síbẹ̀ láti fi ọ̀wọ̀ àti ìwà ọmọlúwàbí hàn. Èrò búburú jáì tí mo ní sí Ọlọ́run àti ìsìn ṣì le gan-an.

Ìdílé náà ń fi ìwé kékeré God’s Way Is Love ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ n kò ní ọkàn-ìfẹ́ sí i, àmọ́, mo wá gbọ́ tí Bàbá ń jíròrò ipò tí àwọn òkú wà. Èyí gbà mí láfiyèsí. Wọ́n ka Oníwàásù 9:5, 10 nínú Bíbélì pe: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.”

Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ pé ẹ̀rù tí ń bà mí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ìyá mi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi, àti àwọn àbúrò mi tó ti kú kò lè pa mí lára. Ìjíròrò náà wá sún kan ọ̀rọ̀ lórí àjíǹde. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sílẹ̀ dáradára. Ayọ̀ kún inú ọkàn mi gan-an nígbà tí mo gbọ́ ìlérí ti Bíbélì ṣe pé lábẹ́ ìṣàkóso Kristi, àwọn òkú yóò jíǹde! (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 20:12, 13) Mo wá ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà wàyí. Mo wá ń fojú sọ́nà gan-an fún ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yìí, mo sì ń múra sílẹ̀ dáadáa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ríran.

Jíjèrè Ojú Ìríran Tẹ̀mí

Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ìrònú òdì tí mo ní nípa Ọlọ́run àti àwọn ọ̀nà tí ó gbà ń ṣe nǹkan parẹ́ pátápátá. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló sọ èmi tàbí ẹnikẹ́ni di afọ́jú, àmọ́ pé Elénìní rẹ̀, Sátánì Èṣù ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo. Mo mà kábàámọ̀ gan-an o, pé àìmọ̀kan ti mú kí n dẹ́bi fún Ọlọ́run! Pẹ̀lú ìháragàgà, mo túbọ̀ gba ìmọ̀ Bíbélì sí i. Mo ń lọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni, mo sì ń nípìn-ín nínú wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ kìlómítà ni ibi tí a ń gbé wà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo tún ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, láìjẹ́ kí àìríran mi ṣèdíwọ́.

Ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó nígbà tí mo ṣe ìrìbọmi ní July 27, 1958, tí ó fi díẹ̀ lé ní ọdún mẹ́rìndínlógún tí mo kàgbákò tó sọ mi di afọ́jú! Mo bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun, mo sì kún fún ìrètí àti ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára. Nísinsìnyí, ìgbésí ayé mi ní ète nínú—láti sin Bàbá mi onífẹ̀ẹ́ tó wà lọ́run. Ìmọ̀ nípa rẹ̀ ti dá mi sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ẹ̀kọ́ èké, ó sì ti fún mi ní ìgboyà láti forí ti ipò àìríran tí mo wà àti ìṣòro tí ó rọ̀ mọ́ ọn pẹ̀lú ìpinnu àti ìrètí. Mo ń ya wákàtí márùndínlọ́gọ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sọ́tọ̀ lóṣù láti wàásù ìhìn rere ológo náà fún àwọn ẹlòmíràn.

Ìgbéyàwó Tú Ká

Ní ọdún 1966, mo ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin kan tí a jọ ní góńgó kan náà nínú ìgbésí ayé. Ó dà bí pé a óò gbádùn ìgbéyàwó aláyọ̀ bí a ṣe jùmọ̀ ń sakun láti mú kí ìgbòkègbodò wa nínú iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i. Ní àwọn oṣù kan, a máa ń ya ọ̀pọ̀ wákàtí sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yẹn. A kó lọ sí àgbègbè àdádó kan nítòsí Livadiá, àárín gbùngbùn Gíríìsì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aninilára ológun ló ń ṣe ìjọba ní Gíríìsì láàárín ọdún 1970 sí 1972 tí a fi wà níbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n sì di Kristẹni tí a batisí. Inú wa tún dùn láti ṣèrànwọ́ fún ìjọ kékeré tí ó jẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè yẹn.

Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọkọ mi kò ka ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni sí mọ́, níkẹyìn ó pa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tì pátápátá. Èyí fa ọ̀pọ̀ àìfararọ nínú ìgbéyàwó wa, tí ó yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀ ní ọdún 1977. Ó dà mí lọ́kàn rú gan-an ni.

Ìgbésí Ayé Aláyọ̀ Tí Ń Méso Jáde

Ní àkókò tí ìsoríkọ́ tó burú jáì yìí dé bá mi nínú ìgbésí ayé, Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ tún gbé ìrànwọ́ dìde. Kristẹni arákùnrin kan tí ó nífẹ̀ẹ́ ṣàlàyé fún mi pé, bí mo bá jẹ́ kí ohun tí ọkọ mi àtijọ́ ṣe sọ mi di aláìláyọ̀, a jẹ́ pé mo fẹ́ sọ ara mi di ẹrú rẹ̀ nìyẹn. Òun ni yóò sì wá máa dí ayọ̀ mi lọ́wọ́. Àkókò yìí ni àgbàlagbà obìnrin kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni béèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe dáradára sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Láìpẹ́, mo wá kó wọnú ohun tó fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ jù—lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà!

Lẹ́yìn náà, Kristẹni mìíràn fún mi ní ìmọ̀ràn pé: “O lè máa bá a lọ ní ṣíṣèrànwọ́ ní àwọn ibi tí a ti nílò rẹ jù. O lè jẹ́ ilé kan tí a tan ìmọ́lẹ̀ sí tí Jèhófà Ọlọ́run ń lò.” Èrò amúniláyọ̀ lèyí o! Kí afọ́jú jẹ́ “ilé kan tí a tan ìmọ́lẹ̀ sí tí Jèhófà Ọlọ́run ń lò” kẹ̀! (Fílípì 2:15) Láìjáfara rárá, mo kúrò ní Áténì mo sì lọ ń gbé ní abúlé Amárinthos, ni ìhà gúúsù Évvoia, àgbègbè kan tó jẹ́ pé àwọn díẹ̀ péré ló ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin níbẹ̀, mo kọ́ ilé kan mo sì ń bójú tó àwọn àìní mi dáadáa.

Nítorí náà, fún ohun tó lé ní ogún ọdún báyìí, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti ya àwọn oṣù mélòó kan sọ́tọ̀ lọ́dọọdún láti túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú àwọn oríṣi ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù tí a mú gbòòrò. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo ń tiraka láti nípìn-ín nínú gbogbo apá tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní, títí kan títọ àwọn ènìyàn lọ nínú ilé wọn, bíbá àwọn tó ní ọkàn-ìfẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní ojú pópó. Nísinsìnyí, mo ní àǹfààní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ sí Ẹlẹ́dàá wa. Ẹ wo bí mo ṣe láyọ̀ tó láti ri pé ìjọ mẹ́ta ti fìdí múlẹ̀ ní àgbègbè yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ará díẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ ní ogún ọdún sẹ́yìn!

Ìgbà méjì lóṣù ni mo máa ń rìnrìn àjò tí ó lé ní ọgọ́ta kìlómítà lálọ àti àbọ̀ lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, mo sì pinnu láti má ṣe pa èyíkéyìí nínú wọn jẹ. Nígbà tí mo bá ri pé n kò pọkàn pọ̀ sórí ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ ní àkókò tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ nítorí pé n kò rí i, mo máa ń lo àkànṣe ìwé àdàkọ mi tí a ṣe fún afọ́jú láti ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí. Ní ọ̀nà yìí, mo ń sapá láti fi etí sílẹ̀ kí n sì pọkàn pọ̀. Síwájú sí i, mo tún ní àǹfààní pé a ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé ìjọ ní ilé mi. Àwọn ènìyàn ń wá ìpàdé tí a ń pè ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti àwọn abúlé tó wà nítòsí. Dípò kí n máa retí pé kí àwọn ènìyàn máa wá bẹ̀ mí wò ní ilé, mo máa ń dánú ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, ìyẹn sì máa ń yọrí sí ìṣírí tọ̀túntòsì nígbà mìíràn.—Róòmù 1:12.

Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba tí mò ń gbé lọ́dọ̀ bàbá mi, kò fìgbà kan rí bá mi lò bí ọmọ tó fọ́ lójú. Pẹ̀lú sùúrù àti ìfaradà, ó lo ọ̀pọ̀ àkókò ní kíkọ́ mi láti fi ọwọ́ mi ṣe àwọn nǹkan. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti tọ́jú oko etílé mi àti ìwọ̀nba ohun ọ̀sìn díẹ̀ tí mo ní. Mo ń ṣiṣẹ́ kára nínú ilé, mo ń tún ilé ṣe tónítóní mo sì máa ń gbọ́únjẹ. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé a lè rí ìgbádùn àti ayọ̀ nínú àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ìgbésí ayé, ìyẹn nínú ohun tí a ní. Ó ti ṣeé ṣe fún mi láti ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ nǹkan pẹ̀lú àwọn agbára ìmòye mi mẹ́rin tó ṣẹ́ kù—ìgbọ́ròó, ìgbóòórùn, ìtọ́wò, àti ìfọwọ́bà—èyí sì fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn tí kò ṣeé díye lé. Èyí sì tún ti jẹ́ ẹ̀rí àgbàyanu fún àwọn ará ìta.

Ọlọ́run Mi Mú Mi Dúró

Bí mo ṣe ní ojú ìwòye tí ó dára àti ìtẹ́lọ́rùn láìka ipò tí mo wà sí ń ya ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́nu. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹni tó yẹ láti fi ìyìn fún ni Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Lẹ́yìn tí ojú mi fọ́ tán, mo sábà máa ń ronú pípa ara mi. Nípa bẹ́ẹ̀, n kò gbà pé mo lè wà láàyè di òní yìí tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà àti òtítọ́ Bíbélì. Mo ti wá rí i pé Ẹlẹ́dàá wa ti fún wa ní àwọn ẹ̀bùn púpọ̀—tí kì í ṣe ti ìríran nìkan—tí a bá sì lò wọ́n, a lè láyọ̀. Nígbà kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń wàásù ní abúlé mi, obìnrin kan sọ nípa mi fún wọn pé: “Ọlọ́run tí ó ń sìn ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí!”

Gbogbo àwọn àdánwò mi ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run sí i. Èyí sì ti mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára gan-an. Ó rán mi létí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà dojú kọ ohun tí ó pè ní ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ tí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìsàn kan tí ń ṣe é lójú. (2 Kọ́ríńtì 12:7; Gálátíà 4:13) Èyí kò sì dá a dúró ní mímú kí ‘ọwọ́ rẹ̀ dí jọ́jọ́’ nínú ìhìn rere náà. Gẹ́gẹ́ bíi tirẹ̀, mo lè sọ pé: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi . . . Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”—Ìṣe 18:5; 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó dájú pé ìrètí mi tí a gbé ka Bíbélì pé mo lè fi ojú ara mi rí ìyá mi ọ̀wọ́n, àwọn ẹ̀gbọ́n, àti àwọn àbúrò mi nínú àjíǹde ti nípa lórí mi lọ́nà tí ó dára tí ó sì ṣàǹfààní. Bíbélì ṣèlérí pé “ojú àwọn afọ́jú yóò là” àti pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Aísáyà 35:5; Ìṣe 24:15) Irú ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀ mú kí n mọ̀ pé nǹkan yóò dára, ó sì ń mú kí n máa fi ìháragàgà wọ̀nà fún ọjọ́ ọ̀la ológo náà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Bàbá mi, tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ní ilé ìdáná mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́