Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Burú Nínú Òfófó Ṣíṣe?
“Ńṣe ló dà bí àjàkálẹ̀ àrùn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí mò ń lọ. A kì í jẹ oògùn, a ò níbọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì í jà—òfófó la máa ń ṣe. Ìṣòro ńlá nìyẹn.”—Michelle ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.a
ÀWỌN kan sọ pé ó ń gbádùn mọ́ni. Àwọn mìíràn sọ pé májèlé ni. Ìgbà gbogbo ni a máa ń rí i nínú àwọn ìwé ìròyìn àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n. Òun ló tún ń fadùn sí ọ̀pọ̀ ìjíròrò. Kí ni nǹkan náà? Ká kàn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn àti àwọn àlámọ̀rí wọn, òun ni a tún ń pè ni òfófó.
Bóyá kò tilẹ̀ sí ohun tí ń yára gba àfiyèsí wa tó àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Ǹjẹ́ o ti gbọ́ tuntun?” Ọ̀rọ̀ tó máa sọ tẹ̀ lé ìyẹn lè jẹ́ òtítọ́ tàbí ìtàn àròsọ—tàbí kí ó jẹ́ díẹ̀díẹ̀ lára ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, òòfà ọkàn láti lọ́wọ́ sí òfófó lè lágbára. Lori, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Kò rọrùn láti máà ní ọkàn ìfẹ́ sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. Àdéhùn kan tí a kò sọ jáde máa ń wà láàárín ìwọ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ pé ìgbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohun kan tó dùn mọ́ ọ, o gbọ́dọ̀ wá sọ fún wọn.”
Ìdí Tí A Fi Ń Ṣe É
Èé ṣe tí òfófó ṣíṣe fi ń gbádùn mọ́ni? Lọ́nà kan, ènìyàn jẹ́ ẹ̀dá tí ń kẹ́gbẹ́ mọ́ra. Ìyẹn ni pé ènìyàn ní ọkàn ìfẹ́ sí ènìyàn. Nígbà náà, ó wulẹ̀ jẹ́ ìwà àdánidá pé bó pẹ́ bó yá ìjíròrò wa yóò máa fì sórí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀.
Ṣé ó burú ni? Kì í ṣe ní gbogbo ìgbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ ń mú ìsọfúnni tó ṣàǹfààní wá, bí ìsọfúnni nípa ẹni tó ń gbéyàwó, ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, àti ẹni tó ń ṣàìsàn. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pàápàá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Éfésù 6:21, 22; Kólósè 4:8, 9) Ní tòótọ́, sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ọ̀nà tí a gbà ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀, ó sì lè mú kí a máa bá àjọṣepọ̀ tí ó dára nìṣó.
Ewu Tó Wà Nínú Òfófó Tí Ń Panilára
Àmọ́, yàtọ̀ sí àníyàn, nígbà mìíràn, nǹkan mìíràn máa ń fa ìjíròrò nípa ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, Deidra, ọmọ ọdún méjìdínlógún, sọ pé: “Àwọn ènìyàn ń ṣòfófó kí wọ́n lè gbajúmọ̀. Wọ́n rò pé àwọn ènìyàn yóò túbọ̀ [gba tiwọn] bí àwọn bá mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan tó dára ju èyí tí àwọn ènìyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ lọ.” Kódà ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn ènìyàn lè gba tirẹ̀ lè mú kí olófòófó náà yí òtítọ́ po. Rachel, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, sọ pé: “Bí o bá mọ ọ̀rọ̀ náà, o ní agbára láti yí i sí ibi tí o bá fẹ́. Ó dà bí àròsọ inú ìtàn kan ni, o sì lè yọ kúrò nínú ìtàn náà bó ṣe wù ọ́.”
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òfófó tí kò jóòótọ́ ní a máa ń lò bí ọ̀nà kan láti gbẹ̀san. Amy, ọmọ ọdún méjìlá, sọ pé: “Mo tan irọ́ kan kálẹ̀ nípa ọ̀rẹ́ mi nígbà kan. Mo ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó sọ ohun kan nípa mi.” Kí ni àbájáde rẹ̀? “Lákọ̀ọ́kọ́, mo ronú pé, ẹ̀n-hẹ́n-ẹ̀n, èmi náà ti ṣe tèmi fún un padà.” Àmọ́, Amy ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “Láìpẹ́, ó di ohun tí ọwọ́ kò ká mọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì wá bá mi gan-an nígbà tí mo ṣe bẹ́ẹ̀ ju bí ì bá ṣe rí ká ní mo ti gbé ẹnu mi dákẹ́ lákọ̀ọ́kọ́.”
Gẹ́gẹ́ bí ògbógi kan nípa ìlera ọpọlọ ṣe sọ ọ́, ó rọrùn láti rí bí òfófó ṣe lè dà “bí iná tí ọwọ́ kò ká mọ́ ní kíámọ́sá.” (Fi wé Jákọ́bù 3:5, 6.) Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ó lè yọrí sí jàǹbá. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá lọ tan ohun kan tó yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí kálẹ̀ ńkọ́? Tàbí tí òfófó náà bá jẹ́ irọ́ ńkọ́, tí a sì ti fi títàn-án kálẹ̀ ba orúkọ rere tí ẹni kan ní jẹ́? Bill, ọmọ ọdún méjìlá, sọ pé: “Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́ kiri pé mo ń lo oògùn líle, bẹ́ẹ̀ sì rèé irọ́ ni. Ó sì dùn mi gan-an.”
Dídẹ́kun Ìfọ̀rọ̀ Èké Bani Jẹ́
Ìdí rere wà tí Bíbélì fi sọ pé “ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ wa lè jẹ́ ohun èlò ìkọ́lé tàbí kí ó jẹ́ ohun ìjà fún ìparun. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ń lo ahọ́n wọn fún ète tí a sọ kẹ́yìn yìí lónìí. Wọ́n dà bí àwọn kan tí onísáàmù náà, Dáfídì, ṣàpèjúwe pé, wọ́n ti “pọ́n ahọ́n wọn gẹ́gẹ́ bí idà, àwọn tí ó ti fi ọfà wọn, tí í ṣe ọ̀rọ̀ kíkorò, sun ibi ìfojúsùn, kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti àwọn ibi tí ó lùmọ́.”—Sáàmù 64:2-4.
Àwọn tó fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn kò gbọ́dọ̀ máa tan ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ kálẹ̀, nítorí pé Bíbélì sọ pé “ètè èké jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 12:22) Mímọ̀ọ́mọ̀ bẹ̀rẹ̀ tàbí ṣíṣe àtagbà ìròyìn tí o mọ̀ pé kì í ṣòótọ́ jẹ́ irọ́ pípa, Bíbélì sì sọ pé àwọn Kristẹni ní láti “fi èké ṣíṣe sílẹ̀,” àti pé “kí olúkúlùkù . . . máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.
Nítorí náà, kí o tó sọ ohunkóhun nípa ẹlòmíràn, bi ara rẹ pé: ‘Mo ha mọ òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ní gidi bí? Ǹjẹ́ ohun tí mo sọ lè mú kí ẹni tó ń gbọ́ mi fojú yẹpẹrẹ wo ẹni tí mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìdí tí mo fi ń sọ ọ́?’ Rántí pé: Jíjẹ́ tí ọ̀rọ̀ kan jẹ́ òtítọ́ pàápàá kò túmọ̀ sí pé ó dára láti máa tàn án kálẹ̀—ní pàtàkì tí ìsọfúnni náà bá lè ba orúkọ rere ẹnì kan jẹ́.
Ìbéèrè mìíràn tí a ní láti béèrè ni pé, ‘Ipa wo ni òfófó tí mo ń ṣe yóò ní lórí orúkọ rere mi?’ Dájúdájú, nípa ṣíṣe òfófó, o ń sọ nǹkan nípa ara rẹ. Fún àpẹẹrẹ, Kristen sọ pé: “Bí o bá ní àkókò púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa sọ̀rọ̀ àwọn mìíràn, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé tìrẹ fúnra rẹ kò dùn.” Lisa rí i pé ìfùsì òun gẹ́gẹ́ bí olófòófó mú kí òun pàdánù ìgbọ́kànlé ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ òun jù lọ. Ó sọ pé: “Ó le débi pé ọ̀rẹ́ mi wá ń kọminú bóyá mo ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ó burú jáì—mo ní láti fẹ̀rí hàn pé ó lè gbára lé mi.”
Bí a bá mọ̀ ẹ́ sí olófòófó, àwọn ènìyàn lè máa wò ẹ́ bí ẹni tó lè ṣe ìpalára, wọ́n sì lè máà fẹ́ bá ọ rìn mọ́. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Olófòófó ń lọ káàkiri láti tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta; má ṣe ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ẹni tí ẹnu rẹ̀ máa ń ṣí sílẹ̀ nígbà gbogbo.” (Òwe 20:19, Beck) Síbẹ̀, ǹjẹ́ o mọ̀ pé o lè lọ́wọ́ nínú ṣíṣe òfófó tí ń pani lára láìsọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan jáde?
Fífetísílẹ̀—Apá Kejì Tí Òfófó Ní
Ó kéré tán, ẹni méjì ló ń kópa nínú òfófó ṣíṣe—olùbánisọ̀rọ̀ kan àti olùgbọ́ kan. Bí ó tilẹ̀ dà bí pé olùgbọ́ náà kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi tó ẹni tí ń sọ̀rọ̀, Bíbélì fi ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ hàn nípa ọ̀ràn náà. Nínú Òwe 17:4, a kà á pé: “Aṣebi ń fetí sí ètè ìṣenilọ́ṣẹ́. Aṣèké ń fi etí sí ahọ́n tí ń fa àgbákò.” Nítorí náà, olùfetísílẹ̀ sí òfófó ní ẹrù wíwúwo láti gbé. Òǹkọ̀wé, Stephen M. Wylen sọ pé: “Ní àwọn ọ̀nà kan, ó tilẹ̀ burú láti fetí sí òfófó ju láti sọ ọ́ lọ.” Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wylen ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nípa híháragàgà láti gbọ́, o ń fún ẹni tí ń sọ̀rọ̀ náà níṣìírí láti máa bá a nìṣó.”
Kí ni o wá lè ṣe nígbà náà, tí òfófó tí ń pani lára bá dé etíìgbọ́ rẹ? Láìfara rẹ hàn bí olódodo àṣelékè, o kàn lè sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká wá nǹkan mìíràn sọ’ tàbí, ‘Mi ò fẹ́ ká máa bá ọ̀rọ̀ yìí lọ. Ó ṣe tán, kò sí níbí láti gbèjà ara rẹ̀.’
Àmọ́, tí àwọn ènìyàn bá wá ń sá fún ọ nítorí pé o kọ̀ láti máa bá wọn jókòó rojọ́ ńkọ́? Lọ́nà kan, èyí lè jẹ́ ààbò fún ọ. Báwo? Ní ti gidi, rántí pé ẹni tó ń ṣòfófó àwọn ẹlòmíràn fún ọ lè ṣòfófó ìwọ alára fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, o lè gba ara rẹ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ọkàn nípa sísúnmọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbà tí wọn kì í fi ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ba àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Wylen sọ pé: “Ìyà yòówù kí ó jẹ ọ́ nítorí pé o kò ṣe òfófó yóò wá hàn sí ọ láìpẹ́ pé o kò pàdánù nǹkan kan bí kò ṣe àkókò tí ìwọ ì bá ti sọ ara rẹ di aláìláyọ̀. Níkẹyìn, ìwọ ni yóò borí, nítorí pé wàá jèrè orúkọ rere gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”
Ní pàtàkì jù lọ, ìwọ yóò ní orúkọ rere pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ní ọkàn ìfẹ́ sí bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlòmíràn, nítorí pé Jésù Kristi kìlọ̀ pé: “Gbogbo àsọjáde aláìlérè tí àwọn ènìyàn ń sọ, ni wọn yóò jíhìn nípa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́; nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni a ó polongo rẹ ní olódodo, nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì ni a óò dá ọ lẹ́bi.”—Mátíù 12:36, 37.
Ó mọ́gbọ́n dání nígbà náà, láti tẹ̀ lé ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Kí ẹ . . . fi í ṣe ìfojúsùn yín láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kí ẹ má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.” (1 Tẹsalóníkà 4:11) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti láti ní ìdúró rere pẹ̀lú Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
“Irin Iṣẹ́ Òfófó Tó Lágbára Jù Lágbàáyé”
Ṣé o ti gbọ́ tuntun tó dé? Ìhùmọ̀ fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, ti mú kí òfófó wọnú ìmọ̀ ẹ̀rọ báyìí. Ní tòótọ́, òǹkọ̀wé, Seth Godin pe ìfìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà ní “irin iṣẹ́ òfófó tó lágbára jù lágbàáyé.” Nígbà tí ó ń sọ àwọn àǹfààní rẹ̀, ó kìlọ̀ pé: “Ẹnì kan lè bẹ̀rẹ̀ ohun kan tí ó jẹ́ òtítọ́ tàbí àṣìsọ ọ̀rọ̀ kan, lójijì kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sì sọ ọ́ di tiwọn.”
A lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní kíámọ́sá lórí kọ̀ǹpútà. Godin sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tuntun tó kọ́kọ́ jáde tó pa ìjẹ́pàtàkì ohun tí a ń rò pọ̀ mọ́ èyí tí a kọ sílẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ èsì tẹlifóònù ní kíámọ́sá.” Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé bí o bá ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, kí o rí i dájú pé ète ọ̀rọ̀ tí o ń kọ ránṣẹ́ ṣe kedere. Àti pé ní gbogbo ọ̀nà, má ṣe fi ìsọfúnni tí kò bá dá ọ lójú ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹni tí ń ṣòfófó àwọn ẹlòmíràn . . . lè ṣòfófó ìwọ alára fún àwọn ẹlòmíràn