ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 orí 12 ojú ìwé 105-110
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Sọ̀rọ̀ Ẹlòmíì Lẹ́yìn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Sọ̀rọ̀ Ẹlòmíì Lẹ́yìn?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn Tí Kì Í Pani Lára?
  • Máa Ṣọ́ Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ
  • Bí Wọ́n Bá Sọ̀rọ̀ Ẹ Lẹ́yìn
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dá Ìjíròrò Dúró Kó Tó Dọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn?
    Jí!—2007
  • Kí Ló Burú Nínú Òfófó Ṣíṣe?
    Jí!—1999
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 orí 12 ojú ìwé 105-110

ORÍ 12

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Sọ̀rọ̀ Ẹlòmíì Lẹ́yìn?

“Mo lọ síbi àpèjẹ kan lọ́jọ́ kan, nígbà tó sì máa fi di ọjọ́ kejì mo ti ń gbọ́ fìn-rìn fìn-rìn pé wọ́n ní ọkùnrin kan bá mi sùn níbẹ̀. Irọ́ pátápátá gbáà sì nìyẹn!”—Linda.

“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti hú u gbọ́ pé àwọn kan ní mò ń fẹ́ lágbájá, ẹni tí wọ́n sì ń sọ yìí, mi ò mọ̀ ọ́n rí! Àwọn olófòófó kì í wá òkodoro òtítọ́ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́ ẹlẹ́jọ́ kiri.”—Mike.

Ọ̀RỌ̀ ẹ̀yìn lè jẹ́ kó dà bíi pé o níṣòro bíi tàwọn tó o máa ń wò nínú fíìmù. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Amber lè sọ bó ṣe ń rí fún ẹ. Ó ní: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn. Ìgbà kan wà tí wọ́n ní mo lóyún, mo ṣẹ́yún, mo ń ta oògùn olóró, mò ń rà á, mo sì tún máa ń mu ún. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́ mọ́ mi gan-an? Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi!”

Ní báyìí táwọn èèyàn ti ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó ṣeé ṣe fún ọmọdékùnrin tàbí ọmọdébìnrin kan láti bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ láìsọ nǹkan kan. Gbogbo ohun tí wọ́n máa ṣe ò ju kí wọ́n tẹ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ sórí kọ̀ǹpútà láti fi bà ẹ́ lórúkọ jẹ́, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹgbàágbèje àwọn elétí ọfẹ! Nígbà míì, àwọn kan ti dìídì ṣí ìkànnì sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti ba ẹnì kan lórúkọ jẹ́. Títan irọ́ nípa àwọn èèyàn kálẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́, àwọn irọ́ yìí sì máa ń burú débi pé ẹni tó kọ ọ́ ránṣẹ́ gan-an ò jẹ́ sọ ọ́ jáde.

Àmọ́, ṣé gbogbo ìgbà ni kò dáa kéèyàn máa sọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì? Ṣáwọn ọ̀rọ̀ kan tiẹ̀ wà tá a lè pè ní . . .

Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn Tí Kì Í Pani Lára?

Fàmì sí òótọ́ tàbí irọ́ nínú gbólóhùn ìsàlẹ̀ yìí.

Gbogbo ìgbà ni sísọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì lẹ́yìn burú. □ Òótọ́ □ Irọ́

Ìdáhùn wo ló tọ̀nà? Ohun tó o fàmì sí lókè máa sinmi lórí bó o ṣe lóye “ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn” sí. Bó bá jẹ́ pé ohun tó o lóye ẹ̀ sí ni pé kéèyàn kàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlòmíì lásán, a jẹ́ pé àwọn ìgbà míì wà tí kì í pani lára. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé ká máa ní ‘ire àwọn ẹlòmíràn’ lọ́kàn. (Fílípì 2:4) Ìyẹn ò wá ní ká máa tojú bọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ o. (1 Pétérù 4:15) Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ọ̀rọ̀ tá ò ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ káwọn èèyàn ráwọn ìsọfúnni tó wúlò gbà, irú àwọn ọ̀rọ̀ bíi lágbájá ò ní pẹ́ ṣègbéyàwó tàbí tàmẹ̀dù ti bímọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sí bá a ṣe lè sọ pé a ní ire àwọn ẹlòmíì lọ́kàn tá ò bá sọ̀rọ̀ nípa wọn!

Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ lásán lè di òfófó tá ò bá ṣọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ẹnu lásán bíi ká sọ pé “Bọ́lá àti Báyọ̀ máa gbádùn ara wọn tí wọ́n bá fẹ́ra” lè di “Bọ́lá àti Báyọ̀ ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bọ́lá àti Báyọ̀ ò rò ó rí pé àwọn máa fẹ́ra. Torí pé ìwọ kọ́ ni Bọ́lá, ìwọ sì kọ́ ni Báyọ̀, o lè parí èrò sí pé ‘kí ló wá burú nínú ìyẹn’!

Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni Julie nígbà tí wọ́n ṣòfófó nípa ẹ bíi tòkè yìí, ó sì dùn ún gan-an. Ó ní: “Inú bí mi gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí fura sáwọn èèyàn.” Irú nǹkan báyìí náà ló ṣẹlẹ̀ sí Jane, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ó ní: “Mi ò ta sí bọ̀bọ́ tí wọ́n ní mò ń fẹ́ yẹn mọ́. Àmọ́, nígbà tó yá mo rí i pé ohun tí mò ń ṣe yẹn ò dáa tó, ọ̀rẹ́ ṣáà la pera wa, mo sì ronú pé ó yẹ ká lè máa ṣọ̀rẹ́ láìjẹ́ káwọn èèyàn máa rojọ́ wa kiri!”

Máa Ṣọ́ Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ

Báwo lo ṣe lè ṣọ́ ẹnu ẹ nígbà tó o bá rí i pé o ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfófó? Kó o tó dáhùn, ronú lórí ohun téèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ kó tó lè wa mọ́tò lórí títì márosẹ̀. Láìrò ó wò tẹ́lẹ̀, ó lè gba pé kó o kúrò lápá ọ̀tún kó o sì bọ́ sápá òsì lójijì, ó lè gba pé kó o rọra máa rìn, kódà ó lè gba kó o dúró pátápátá pàápàá. Bó o bá wà lójúfò, wàá rọ́ọ̀ọ́kán, ìyẹn á sì jẹ́ kó o lè tètè yíwọ́ pa dà.

Bó ṣe yẹ kó rí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu náà nìyẹn. Ó sábà máa ń rọrùn láti mọ̀ tí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ lẹ́nu bá ti ń dòfófó. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, yáa tètè ‘yíwọ́ pa dà.’ Torí bó ò bá tètè ṣe bẹ́ẹ̀, òfófó lè di ọ̀ràn ńlá sí ẹ lọ́rùn. Mike sọ pé: “Mo sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa ọmọbìnrin kan lẹ́yìn, pé ó fẹ́ràn ọkùnrin gan-an, ọ̀rọ̀ náà sì ta sí i létí nígbà tó yá. Mi ò lè gbàgbé bó ṣe bú mọ́ mi nígbà tó wá dojú kọ mí, ọ̀rọ̀ yẹn dùn ún gan-an ni. Òótọ́ ni pé a parí ìjà wa, àmọ́ inú mi kì í dùn tí mo bá rántí pé ohun tí mo ṣe bí i nínú tóyẹn!”

Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ lè múni bínú. Bíbélì gan-an tiẹ̀ sọ pé “ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Ìdí gan-an nìyẹn tó fi yẹ ká máa ro ọ̀rọ̀ dáadáa ká tó sọ ọ́ jáde! Òótọ́ ni pé, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu kéèyàn tó lè fòpin sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀. Síbẹ̀, bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Carolyn ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí, ó ní: “O ní láti máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ. Bó bá jẹ́ pé ibi tó o ti gbọ́rọ̀ yẹn ò ṣeé gbọ́kàn lé, ó lè jẹ́ pé irọ́ lò ń tàn kálẹ̀.” Torí náà, tó o bá gbọ́ ohun tó lè di òfófó, yáa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé kó o “fi í ṣe ìfojúsùn [rẹ] láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kí [o] má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.”—1 Tẹsalóníkà 4:11.

Báwo lo ṣe lè ní ire àwọn ẹlòmíì lọ́kàn, kó o má sì máa tojú bọ̀ràn wọn? Kó o tó sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan, béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé: ‘Ṣé mo mọ òkodoro òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí? Kí nìdí tí mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀ yìí? Báwo lọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ lẹ́yìn ọlọ́rọ̀ yìí ṣe máa kan ojú táwọn èèyàn á máa fi wò mí?’ Ìbéèrè tó o bi ara rẹ kẹ́yìn yẹn ṣe pàtàkì gan-an, torí ìwọ làwọn èèyàn máa mọ̀ sí olófòófó, ìyẹn sì máa burú ju tẹni tó ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ.

Bí Wọ́n Bá Sọ̀rọ̀ Ẹ Lẹ́yìn

Kí lo lè ṣe táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ ẹ lẹ́yìn? Ìwé Oníwàásù 7:9 kìlọ̀ pé kó o “má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ní sùúrù. Bíbélì sọ pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ, . . . nítorí ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.”—Oníwàásù 7:21, 22.

Ká sòótọ́, kò sí àwíjàre kankan téèyàn lè ṣe nípa òfófó. Síbẹ̀, fífara ya ju bó ti yẹ lọ tún lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ ju òfófó tí wọ́n ṣe nípa ẹ lọ! O ò ṣe kúkú ṣe ohun tó ran Renee lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Ó máa ń dùn mí gan-an táwọn èèyàn bá sọ ohun tí ò dáa nípa mi, àmọ́ mo máa ń gbìyànjú láti na sùúrù sí i. Bó bá máa fi dọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, ọ̀rọ̀ ẹlòmíì tàbí nǹkan míì ni wọ́n á mú sọ.”a

Máa fọgbọ́n hùwà, kó o sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ kó má lọ di pé ò ń ṣòfófó. Táwọn èèyàn bá sì sọ̀rọ̀ ẹ láìda, má fara ya ju bó ṣe yẹ lọ. Jẹ́ kí ìwà rere tó ò ń hù dá ẹ láre. (1 Pétérù 2:12) Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àárín ìwọ àtàwọn èèyàn máa gún, àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run á sì túbọ̀ dán mọ́rán sí i.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà míì, ó máa dáa kó o lọ bá olófòófó yẹn, kó o sì fọgbọ́n sọ fún un. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà kì í fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan torí pé “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹni tí ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ń ṣí ètè rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu—ìparun yóò jẹ́ tirẹ̀.”—Òwe 13:3.

ÌMỌ̀RÀN

Bẹ́nì kan bá ń ṣòfófó fún ẹ, o lè sọ pé: “Jẹ́ ká wá nǹkan míì sọ. Kò kúkú sí níbí láti gbèjà ara ẹ̀.”

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Pé o tiẹ̀ tẹ́tí gbọ́ òfófó lásán lè mú kíwọ náà pín nínú ẹ̀bi rẹ̀. Tó o bá ń jẹ́ kí olófòófó máa sọ̀rọ̀ fún ẹ, ńṣe lò ń gbà á láyè láti máa yára tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀!

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bó bá tún ṣe mí bíi kí n ṣòfófó, màá ․․․․․

Báwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ mi láìdáa, bí mo ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ìgbà wo ló dáa kéèyàn sọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì lẹ́yìn?

● Ṣáwọn èèyàn ti ṣòfófó nípa ẹ rí, tó bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn?

● Báwo ni òfófó ṣíṣe ṣe lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 107]

Ìgbà tí mo ṣòfófó nípa ẹnì kan, tó gbọ́, tó sì gbéjà wá bá mi ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ bí òfófó ṣe léwu tó. Kò sí àwáwí kankan tí mo lè ṣe! Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ó sàn kéèyàn máa finú kan bá àwọn èèyàn lò ju kó máa sọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn lọ!’’—Paula

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 108]

Bí idà ṣe máa ń pani lára, bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣe lè bani lórúkọ jẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́