Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dá Ìjíròrò Dúró Kó Tó Dọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn?
“Mo lọ sóde àríyá lọ́jọ́ kan, nígbà tó fi máa dọjọ́ kejì, ìròyìn ti lọ yíká pé ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin tó wá síbẹ̀ ti bá mi sùn. Bẹ́ẹ̀ kò sóhun tó jọ ọ́!”—Linda.a
“Ìgbà míì wà tí mo máa ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ kiri pé mò ń bá ẹnì kan jáde, lẹ́ni tí mi ò tiẹ̀ mọ̀ rí! Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ èèyàn lẹ́yìn kì í wulẹ̀ wádìí bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́.”—Mike.
Ọ̀RỌ̀ ẹ̀yìn máa ń dùn mọ́ ẹni tí wọ́n bá ń sọ ọ́ fún ju eré sinimá tó mìrìngìndìn lọ. Ìwọ gbọ́ ohun tọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Amber sọ, ó ní: “Lemọ́lemọ́ làwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn. Wọ́n ń sọ kiri pé mo ti lóyún, wọ́n ní mo ti ṣẹ́yún lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ní mò ń ta egbòogi, mò ń ra egbòogi, mo sì ń lo oògùn olóró. Kí ló fà á táwọn èèyàn fi ń sọ gbogbo èyí nípa mi? Bí mo bá ló yé mi, irọ́ ni mo pa!”
Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn Ti Rìn Jìnnà
Nígbà táwọn òbí ẹ ṣì wà léwe, ẹnu làwọn èèyàn fi ń tan ìròyìn tó bá gbòde kálẹ̀. Àmọ́, lóde tòní, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ti rìn jìnnà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ní èyí tí ayé ti dayé lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà àti lílo tẹlifóònù alágbèéká láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ yìí, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan tó ní èrò búburú lọ́kàn lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ láìsọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo. Gbogbo ohun tó máa ṣe ò ju pé kó tẹ ohun tó fẹ́ sọ nípa ẹ sórí kọ̀ǹpútà tàbí tẹlifóònù alágbèékà kó sì fi ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń hára gàgà láti gbọ́ tuntun.
Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé Íńtánẹ́ẹ̀tì ti bẹ̀rẹ̀ sí gborí lọ́wọ́ tẹlifóònù gẹ́gẹ́ bí ohun èlò táwọn èèyàn fẹ́ràn láti máa fi sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn báyìí. A tiẹ̀ ráwọn kan tí wọ́n ní ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí ò sí ohun méjì tí wọ́n ń lò ó fún ju kí wọ́n máa fi yẹ̀yẹ́ àwọn èèyàn lọ. Èyí tó wá wọ́pọ̀ jù lọ báyìí ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tí ò ṣeé sọ lójúkojú tó kún inú àwọn ibi àdáni orí kọ̀ǹpútà táwọn èèyàn ń tọ́jú àwòrán, fídíò àti ọ̀pọ̀ nǹkan sí, títí kan àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n máa ń tọ́jú ìsọfúnni nípa ara wọn sí. Kódà, nínú ìwádìí kan, méjìdínlọ́gọ́ta lára ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé wọ́n ti sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ nípa àwọn rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Ṣé a wá lè sọ pé gbogbo ọ̀rọ̀ téèyàn bá ṣáà ti sọ nípa ẹlòmíì ni kì í dáa? Ǹjẹ́ ohun kan tiẹ̀ wà tá a lè pè ní . . .
Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn Tí Ò Burú?
Kí lèrò ẹ nípa gbólóhùn yìí ná?
Gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ ẹ̀yìn máa ń burú. ◻ Bẹ́ẹ̀ ni ◻ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Ìdáhùn wo ló tọ̀nà? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ó sinmi lórí ohun téèyàn bá gbà pé “ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn” túmọ̀ sí. Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ téèyàn wulẹ̀ sọ lẹ́yìn ọlọ́rọ̀ lásán ló túmọ̀ sí, nígbà náà, a jẹ́ pé àwọn ìgbà kan á wà tí kò ní burú. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ fún wa pé ká máa ‘mójú tó ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn.’ (Fílípì 2:4) Kì í ṣe pé ká máa gbọ́ teku wí fẹ́yẹ, ká sì máa ṣe àyọnusọ o. (1 Pétérù 4:15) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó wúlò la sábà máa ń gbọ́ nínú àjọsọ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, àwọn ìsọfúnni bí ẹní ń gbéyàwó, ẹni tó bímọ àti ẹni tó nílò irú ìrànlọ́wọ́ kan. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sí bá a ṣe lè sọ pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lógún bí a kì í bá sọ ohunkóhun nípa wọn.
Síbẹ̀, ìtàkúrọ̀sọ lásán lè fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yí padà di àhesọ ọ̀rọ̀ tó lè bani lórúkọ jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máà sóhun tó burú nínú sísọ pé: “Á ti lọ wà jù bí Fẹ́mi àti Lọlá bá lè fẹ́ra wọn,” àmọ́ táwọn èèyàn bá máa tún un sọ, wọ́n lè ní “Fẹ́mi àti Lọlá ti fẹ́ra wọn.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Fẹ́mi àti Lọlá lè má mọ nǹkan kan nípa ìfẹ́ táwọn èèyàn ń fẹnu pè sí wọn lára yìí. Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé, ‘Kò sóun tó le nínú ìyẹn.’ Òótọ́ ni pé o lè máà rí ìṣòro tó wà ńbẹ̀, àyàfi bó bá jẹ́ pé ìwọ ni Fẹ́mi tàbí Lọlá!
Julie, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún ni wọn sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn bẹ́ẹ̀ rí, ó sì dùn ún gan-an. Ó sọ pé: “Ó múnú bí mi, ó sì mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni màá tún lè finú tán àwọn èèyàn mọ́.” Bọ́rọ̀ Jane, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún náà ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ṣe ni mo tiẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í sá fún ọmọkùnrin tí wọ́n sọ pé èmi àti ẹ̀ jọ ń bára wa jáde.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Ìkà gbáà làwọn tó ń sọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn, nítorí pé èmi àti ọmọkùnrin náà ò ṣẹra wa rí, mo sì rò pó yẹ ká lè máa bára wa sọ̀rọ̀ láìsí pé àwọn èèyàn ń gbéborùn nípa wa.”
Dájúdájú, kékeré kọ́ ni wàhálà tí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tó lè bani lórúkọ jẹ́ máa ń dá sílẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn táwọn èèyàn ti sọ àhesọ ọ̀rọ̀ nípa wọn ò ní ṣàìgbà pé àwọn náà ti sọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì lẹ́yìn rí. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, báwọn èèyàn bá ń sọ ohun tí ò dáa nípa ẹnì kan, ṣe láá máa ṣèèyàn bíi kéèyàn bá wọn dá sí i. Kí ló fà á tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Phillip, ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: “Ọ̀nà kan téèyàn fi lè bo tara ẹ̀ mọ́lẹ̀ ló jẹ́. Arítẹni-mọ̀-ọ́n-wí làwọn èèyàn, ńṣe ni wọ́n máa ń fi àpáàdì jàn-àn-ràn bo tiwọn mọ́lẹ̀.” Ọgbọ́n wo lo wá lè ta sí i bó bá di pé ọ̀rọ̀ lásán fẹ́ di ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tó lè pani lára?
Mọ Bó O Ṣe Lè Darí Ìjíròrò Gba Ibòmíì!
Wo béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ já fáfá tó kó tó lè wakọ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀. Ohun kan lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ táá mú kó pọn dandan fún ẹ láti gba apá ibòmíì, kó o fọ̀nà sílẹ̀ fún ọkọ̀ míì, tàbí kó o dúró pátápátá. Bó o bá wà lójúfò tó ò sì fẹ́ wa àwàjáàmù, iwájú ẹ ni wàá máa tẹjú mọ́ kó o lè darí ọkọ̀ ẹ gba ibòmíì bó o bá rí i pé ewu ń bọ̀.
Bí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe rí náà nìyẹn. Kò sí bó ò ṣe ní mọ̀ bí ìjíròrò kan bá ti fẹ́ máa di ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tó lè pani lára. Kí wá ni ṣíṣe nígbà náà? Bíi ti awakọ̀, o ò kúkú ṣe darí ìjíròrò náà gba ibòmíì? Bó o bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ibi tó máa já sí ò ní dáa. Mike sọ pé: “Nígbà tí mo sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa ọmọbìnrin kan pé ọkùnrin ti jàrábà ayé ẹ̀, tí ẹnì kan sì wá sọ ọ́ lójú ẹ̀, ojú tì mí nígbà tó gbé ọ̀rọ̀ náà kò mí lójú. Ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí mo sọ dùn ún wọnú eegun. A yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara wa, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà tí mo bá ń rántí pé mo ti to àtòjáàmù ló máa ń dùn mí gan-an!”
Òótọ́ ni pé ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè fòpin sí ìjíròrò kan tó ti di ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tó lè pani lára. Síbẹ̀, bí Carolyn ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ṣe sọ ló rí: “O gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó bá ń tẹnu ẹ jáde. Bó ò bá gbọ́rọ̀ náà látọ̀dọ̀ ẹni tó mọ̀ nípa ẹ̀, ó lè jẹ́ pé irọ́ lò ń tàn kálẹ̀ yẹn.”
Bó ò bá fẹ́ máa dá sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn tó lè pani lára, máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí:
“Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19) Bó o bá ń sọ̀rọ̀ jù, àfàìmọ̀ lo ò ní í sọ ohun kan tó o máa kábàámọ̀ ẹ̀ bó bá yá. Nítorí náà, ó sàn káwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀, dípò kí wọ́n mọ̀ ẹ́ sí alátòjáàmù!
“Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn ẹni burúkú máa ń tú àwọn ohun búburú jáde.” (Òwe 15:28) Máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀!
“Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Kó o tó sọ ohunkóhun, rí i pé ó dá ẹ lójú.
“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Kó o tiẹ̀ tó sọ ohun tó jóòótọ́ nípa ẹlòmíì pàápàá, ó máa dáa kó o kọ́kọ́ bi ara ẹ pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi bó bá jẹ́ pé èmi ni onítọ̀hún, tí ẹnì kan sì wá tú gbogbo àṣírí yìí nípa mi?’
“Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Bọ́rọ̀ bá jóòótọ́ pàápàá, ó lè pani lára bí kò bá gbéni ró.
“Ẹ sì fi í ṣe ìfojúsùn yín láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kí ẹ má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn, kí ẹ sì máa fi ọwọ́ yín ṣiṣẹ́.” (1 Tẹsalóníkà 4:11) Má ṣe máa dá ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó sàn jùyẹn lọ ló wà tó o lè fàkókò ẹ ṣe.
Bó Bá Jẹ́ Pé Ìwọ Ni Wọ́n Ń Sọ̀rọ̀ Ẹ̀ Lẹ́yìn Ńkọ́?
Ohun kan ni pé kéèyàn máa kó ahọ́n ẹ̀ níjàánu kéèyàn sì jáwọ́ nínú sísọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì lẹ́yìn. Bó bá wá jẹ́ pé ìwọ làwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn, ọ̀rọ̀ náà lè bọ́ síbi tí ò dá a rárá lára ẹ. Joanne, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, táwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ẹ láìdáa sọ pé: “Mo ronú pé mi ò ní bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́ mọ́. Àwọn ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ẹkún ni màá sun títí tí màá fi sùn. Ó ń ṣe mí bíi pé orúkọ mi ti bà jẹ́ pátápátá!”
Kí lo lè ṣe báwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ ẹ láìdáa?
◼ Ronú ohun tó mú wọn sọ ohun tí wọ́n sọ. Gbìyànjú láti lóye ohun tó máa ń mú káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn. Torí káwọn kan lè gbajúmọ̀ ni wọ́n ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, kó lè dà bí ẹni pé gbogbo nǹkan ni wọ́n mọ̀. Karen, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa ronú pé àwọn ríta nítorí pé àwọn ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlòmíràn.” Torí pé àwọn ọ̀dọ́ kan ò mohun táwọn èèyàn ń rò nípa àwọn, wọ́n máa ń fẹ́ fọ̀rọ̀ ba àwọn ẹlòmíì jẹ́ láti lè bàṣírí ara wọn. Renee, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, tún sọ ìdí míì táwọn èèyàn fi máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn. Ó sọ pé: “Nǹkan tètè máa ń sú àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń wá ohun tí wọ́n á fi dára yá, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń dá ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn sílẹ̀.”
◼ Má Ṣe Bínú Kọjá Àyè. Bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ ẹnì kan ní búburú tí onítọ̀hún ò sì kó ara ẹ̀ níjàánu nítorí pé ohun tí wọ́n sọ dùn ún tàbí nítorí pé inú bí i, ó ṣeé ṣe kó hùwà lọ́nà tó máa kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá. Òwe 14:17 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yára bínú yóò hu ìwà òmùgọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ mọ́ra, irú àkókò yìí gan-an ló yẹ kéèyàn túbọ̀ kóra ẹ̀ níjàánu gidigidi. Bó o bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kó sínú pańpẹ́ kan náà tẹ́ni tó sọ̀rọ̀ ẹ lẹ́yìn kó sí.
◼ Ronú ohun tó ṣeé ṣe kó mú ẹni náà sọ̀rọ̀ ẹ lẹ́yìn. Bí ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: Ǹjẹ́ ó dá mi lójú pé ọ̀rọ̀ mi ni wọ́n ń sọ? Ṣé ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ni àbí àìgbọ́ra-ẹni-yé? Ṣé kì í ṣe pé ara ti ń ta mí jù? Òótọ́ ni pé kò dáa kéèyàn máa sọ̀rọ̀ ẹlòmíì ní búburú. Síbẹ̀, béèyàn bá ki àṣejù bọ bó ṣe fìbínú hàn, ó lè jẹ́ ìyẹn gan-an lá á bà á lórúkọ jẹ ju ọ̀rọ̀ ẹ̀ tí wọ́n sọ láìdáa lọ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò kúkú ṣe firú ojú tó ran Renee lọ́wọ́ wo ọ̀ràn náà. Ó sọ pé: “Ó máa ń dùn mí gan-an bí ẹnikẹ́ni bá sọ ohun tí ò dáa nípa mi, àmọ́ n kì í jẹ́ kó ká mi lára jù. Torí mo mọ̀ pé lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹlòmíì tàbí nǹkan míì ni wọ́n á máa sọ̀rọ̀ lé lórí.”b
Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Jù Lọ
Bíbélì sọ gbangba pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà,” ó sì fi kún un pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa fọwọ́ líle mú gbogbo ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn bá ṣáà ti ń sọ nípa wa. Oníwàásù 7:22 sọ pé: “Ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.”
Báwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ ẹ ní búburú, ohun tó o lè fi gbara ẹ kalẹ̀ ni pé kó o máa hùwà rere. Jésù sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Nítorí náà má ṣe yí ìwà ẹ padà, máa hùwà bí ọ̀rẹ́. Ó le yà ẹ́ lẹ́nu bí ìyẹn á ṣe tètè fòpin sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn náà, tàbí kó kúkú rọrùn fún ẹ láti fara dà á.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Láwọn ìgbà míì, ì bá kúkú sàn jù kéèyàn tọ ẹni tó sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn lọ, kẹ́ ẹ sì fọgbọ́n yanjú rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ìyẹn tiẹ̀ lè má pọn dandan, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Báwo lo ò ṣe ní máa tan ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn nípa àwọn ẹlòmíì kálẹ̀?
◼ Kí ni wàá ṣe bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ ẹ lẹ́yìn?