Ta Ni Yóò Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ wa?
Ó JẸ́ ìṣírí láti mọ̀ pé híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé ti wá di ohun tí gbogbo àgbáyé kà sí ìṣòro báyìí. Àwọn ìdáwọ́lé bí Àpéjọ Stockholm Láti Gbéjà Ko Lílo Àwọn Ọmọdé fún Iṣẹ́ Aṣẹ́wó, níbi tí àwọn aṣojú láti àádóje orílẹ̀-èdè tó pésẹ̀ síbẹ̀ ti gbé ìṣòro yìí yẹ̀ wò.
Ní àfikún sí i, àwọn orílẹ̀-èdè kan ti ń gbé òfin kalẹ̀ lòdì sí àwọn tí ń rìnrìn àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀ àti àwọn tí ń fi àwọn ọmọdé rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Àwọn kan tilẹ̀ ní ìwé tí wọ́n ń kọ orúkọ àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe tí wọ́n bá mọ̀ sí, wọn kì í sì í fàyè gbà wọ́n láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé.
Àwọn kan tún wà tí wọ́n wá ìgbésí ayé tí ó dára fún àwọn ọmọdé nípa ṣíṣe òfin láti dáàbò bò wọ́n. Àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ àti àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ń kọ̀ láti ra ohun tí àwọn ọmọdé tí a ń kó ṣiṣẹ́ bá ṣe jáde.
Nígbà tí ó dájú pé gbogbo wa ni a gbóríyìn fún àwọn ìsapá tí a ń ṣe láti dá híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé dúró ní àwùjọ wa, a gbọ́dọ̀ mọ̀ ní àmọ̀dunjú kí a sì gbà pé jíjẹ ọmọdé níyà ti ta gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Yóò jẹ́ àìfi nǹkan pè láti ronú pe ojútùú ráńpẹ́ bíi ṣíṣe òfin lásán lè dáàbò bo àwọn ọmọ wa pátápátá. Ọ̀pọ̀ òfin ni a ti ṣe, síbẹ̀ ìṣòro náà kò tán. Ó hàn gbangba pé ìwà àwọn àgbàlagbà nínú ayé bàjẹ́ bàlùmọ̀ débi pé a ní láti ṣe òfin kí a tó lè dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ nígbà èwe.
Àwọn òfin kọ́ ni àṣekágbá ààbò fún àwọn ọmọ. Ká ṣáà máa retí àbájáde àwọn òfin kíkọyọyọ bíi ti ìpàdé Àjọ UN Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọdé tí ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkóso fọwọ́ sí ni. Ó hàn gbangba nínú ìwé àkọsílẹ̀ pe ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkóso wọ̀nyí pàápàá tí ìṣòro ọrọ̀ ajé ń ká lọ́wọ́ kò ni kò ṣe tó bí ó ṣe yẹ láti dá yíyan àwọn ọmọdé jẹ dúró. Híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé sì jẹ́ ìṣòro ńlá kan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
Púpọ̀ Wà Tí Àwọn Òbí Lè Ṣe
Iṣẹ́ ńlá ni láti jẹ́ òbí tó ṣàṣeyọrí. Ó ń béèrè ìfara-ẹni-rúbọ. Àmọ́, àwọn òbí tó bìkítà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé wọn kò fi àwọn ọmọ wọn rúbọ. Ìwé ìròyìn Maclean’s sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà, “a máa ń fojú wo iṣẹ́ jíjẹ́ òbí bí ẹni pé ó jẹ́ ìgbòkègbodò àfipawọ́.” A lè ba ohun ìṣiré kan jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a lè jáwọ́ nínú ìgbòkègbodò àfipawọ́ kan, ṣùgbọ́n ẹrù iṣẹ́ òbí jẹ́ èyí tí Ọlọ́run yàn fúnni.
Jíjẹ́ tí o jẹ́ òbí rere jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù tí o lè fún ọmọ rẹ, níwọ̀n bí yóò ti ràn án lọ́wọ́ láti láyọ̀, kí ó sì wà láàbò nígbà èwe rẹ̀. Irú ìfọ̀kànbalẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò sinmi lórí ipò ẹni láwùjọ tàbí bí a ṣe lówó tó. Ọmọ rẹ nílò rẹ—ó nílò ìfẹ́ àti ìfẹ́ni rẹ, ó fẹ́ mọ̀ pé o wà lẹ́yìn òun nígbà tí wọ́n bá fòòró rẹ̀, ó sì nílò àkókò rẹ pẹ̀lú. Ọmọ rẹ fẹ́ kí o máa sọ ìtàn fún òun, ó fẹ́ fi ọ́ ṣe àwòkọ́ṣe, ó sì ń fẹ́ ìbáwí onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ rẹ.
Lórí kókó ẹ̀kọ́ nípa ìwà rere ti ìbálòpọ̀—ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ kí àjọṣepọ̀ àárín yín nínú ilé àti ọ̀wọ̀ fún èrò inú àti ara àwọn ọmọ yín wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn ọmọdé máa ń tètè mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí ń ré ìlànà ìwà rere tí àwọn òbí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú wọn kọjá. A ní láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ máa hùwà nínú ilé àti níta. Bí o bá kùnà láti ṣe èyí, ẹlòmíràn yóò bá ọ kọ́ wọn, ìyọrísí rẹ̀ sì lè máà tẹ́ ọ lọ́rùn. Kọ́ wọn ní ohun tí wọn yóò ṣe bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ń fòòró wọn láti ba ìwà rere wọn jẹ́. Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí ẹ̀yà ara wọn tí kò hàn síta wà fún, kí o sì kọ́ wọn pé àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí ni a kò gbọ́dọ̀ fi ṣèṣekúṣe. Sọ ohun ti wọn yóò ṣe fún wọn bí ẹnikẹ́ni bá sún mọ́ wọn tí ó fẹ́ fi ọmọdé yàn wọ́n jẹ.
Rí i dájú pé o mọ ibi tí àwọn ọmọ rẹ wà ní gbogbo ìgbà kí o sì mọ ẹni tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ ọmọ rẹ jù? Àwọn wo ló ń bá ọ tọ́jú ọmọ rẹ nígbà tí o kò bá sí ní tòsí? Ṣe wọ́n ṣeé fọkàn tẹ̀? Àmọ́, ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pe òbí yóò máa fura sí gbogbo ènìyàn. Gbé ìṣesí àwọn àgbàlagbà tí ó yí ọmọ rẹ ká yẹ̀ wò dáradára, wò ré kọjá ìrísí òde ara.
Ronú nípa ìbànújẹ́ ọkàn tí àwọn òbí tí wọn kò tètè mọ̀ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn olùkọ́, àti àwọn ìbátan tí ó sún mọ́ wọn pàápàá ti hùwà àìdáa sí àwọn ọmọ wọn máa ń ní. Yóò dára kí ìwọ tí o jẹ́ òbí bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì mi fàyè gba híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé tàbí wọ́n máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀? Ǹjẹ́ ìsìn mi ń lo ìlànà gíga ti ìwà rere?’ Ìdáhùn sí irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yan ọ̀nà tí ó dára jù ní dídáàbò bo àwọn ọmọ rẹ.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìlànà Ẹlẹ́dàá kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí yóò ṣèrànwọ́ láti yọ wọ́n nínú ewu. Nígbà tí àwọn ọmọ bá rí ọ̀wọ̀ tí àwọn òbí wọn ní fún ìlànà gíga ti ìwà rere, wọn yóò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere yìí.
Ojútùú Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Tí Ó Wà
Dájúdájú, kì í ṣe àwọn òfin tàbí ìfinisẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́pípẹ́ ni yóò dáàbò bo àwọn ọmọ wa. Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ni ó lè tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mí sí, Bíbélì, mú ìwà mímọ́ wá, nípa yíyí èrò ọkàn àwọn ẹni bí ẹranko padà sí ti onífẹ̀ẹ́ àti oníwà rere nínú ẹgbẹ́ àwùjọ èyíkéyìí.
A ti fi hàn wá pé èyí ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ ló ti pa ọ̀nà ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn àtijọ́ tì. Wọ́n ń fi ẹ̀rí agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn nísinsìnyí. Síbẹ̀ bí èyí tilẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ sí títọ ọ̀nà tí ó tọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùṣe búburú ni kò ní yí padà. Ìdí nìyí tí Jèhófà Ọlọ́run fi ṣe ìlérí pé gbogbo àwọn tí ń rẹ́ àwọn ọmọ wa jẹ nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọdé ni a óò mú kúrò ní ayé—pẹ̀lú ọgbọ́n èrò-orí wọn, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, àti ìwọra wọn.—1 Jòhánù 2:15-17.
Lẹ́yìn náà, nínú ayé tuntun Ọlọ́run, nígbà tí ipò òṣì kò ní sí mọ́, gbogbo àwọn ọmọ ni yóò gbádùn ìgbà ọmọdé oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí a kò ní fòòró ẹ̀mí wọn, ìyẹn ni ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run fún wọn. Èyí kò ní jẹ́ òpin sí jíjẹ àwọn ọmọdé níyà nìkan bí kò ṣe òpin sí gbogbo ìrántí onírora tí ó ba ayé àwọn ènìyàn jẹ́ lónìí: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17.
Nítorí náà, nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Kristi yóò ní ìtumọ̀ kíkọyọyọ ní ti gidi pé: “Ẹ jọ̀wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké jẹ́ẹ́, ẹ sì dẹ́kun dídí wọn lọ́wọ́ wíwá sọ́dọ̀ mi, nítorí ìjọba ọ̀run [ṣíṣàkóso lé ilẹ̀ ayé, tí ó jẹ́ Párádísè tí àwọn ènìyàn yóò gbé, lórí] jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”—Mátíù 19:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Fi ọgbọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ohun tí wọn yóò ṣe bí a bá fi ìbálòpọ̀ fòòró wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jíjẹ́ tí o jẹ́ òbí rere jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye fún àwọn ọmọ rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ète àti ìlànà Ẹlẹ́dàá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, gbogbo àwọn ọmọ ni yóò gbádùn ìgbà ọmọdé wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́