Ọ̀ràn Ìlera Ti Sunwọ̀n Sí i Jákèjádò Ayé—Àmọ́ Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jàǹfààní Rẹ̀
GẸ́GẸ́ bí ìròyìn The World Health Report 1998, tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO), ṣe ti sọ, ó jọ pé ara àwọn èèyàn ń le sí i, ẹ̀mí wọn sì ń gùn sí i kárí ayé. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tó wà nínú ìròyìn náà nìyí:
Ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àwọn èèyàn púpọ̀ sí i túbọ̀ ń rí àwọn ohun èlò ìmọ́tótó lò, omi tó dára, àti àwọn ohun ṣíṣekókó fún àbójútó ìlera wọn. Ní àfikún síyẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé lágbàáyé ni a ti fún lábẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí àwọn àrùn mẹ́fà tó le tó máa ń bá ọmọdé jà.a Èyí ti jẹ́ kí iye àwọn ọmọdé tó ń kú dín kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mílíọ̀nù mọ́kànlélógún ọmọdé tí kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún ló kú lọ́dún 1955, iye yẹn dín kù sí nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́wàá lọ́dún 1997. Bákan náà, iye àwọn tí àrùn ọkàn ń pa ti dín kù gan-an ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí ní àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tó ń mú iwájú nínú iṣẹ́ ẹ̀rọ.
Bó ti wù kó rí, ìròyìn náà fi kún un pé ọ̀ràn ìlera tó ń sunwọ̀n sí i yìí kò ṣàìkù síbì kan. Fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn éèdì ṣì ń wu ẹ̀mí àwọn èèyàn léwu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1981 laráyé tó gbúròó àrùn éèdì, ó ti gbẹ̀mí èèyàn tí a fojú díwọ̀n pé wọ́n lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlá ààbọ̀ láti ìgbà tí àrùn náà ti bẹ̀rẹ̀ sí jà. Bẹ́ẹ̀, kò tíì sí oògùn ẹ̀. Ní ọdún 1996, ogún ọ̀kẹ́ [400,000] ọmọdé tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló kó fáírọ́ọ̀sì HIV. Ní ọdún 1997, iye àwọn ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn sún mọ́ ìyẹn, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó fáírọ́ọ̀sì náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000].
Ipò Òṣì Ṣì Ń Kó Bá Ìlera
Ní pàtàkì, ọ̀ràn ìlera àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí ipò òṣì gbé dè kò sunwọ̀n sí i. Wọ́n sábà máa ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ tí ìṣòro àrùn ti pọ̀, tí kò sí ìrètí lọ́jọ́ iwájú, tí ẹ̀mí àwọn èèyàn kì í sì í gùn. Dókítà Hiroshi Nakajima, olùdarí àgbà àjọ WHO tẹ́lẹ̀ rí sọ pé: “Ó kéré tán, ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀ràn àbójútó ìlera àwọn ọlọ́rọ̀ àti ti àwọn òtòṣì ṣì pọ̀ tó bó ṣe rí ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn.” Ògbógi kan ní àjọ WHO sọ pé, ó ṣeni láàánú pé ìyàtọ̀ yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni, nítorí pé “ìyọnu alápá méjì ti dé bá àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Kì í ṣe àwọn àrùn bárakú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú lóde òní nìkan ni wọ́n ń gbógun tì ṣùgbọ́n wọ́n ń gbógun ti àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru tí kò tíì fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀.”
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò sọ pé ká má ṣàṣeyọrí. Ní gidi, púpọ̀ lára àwọn ikú tí ń pani láìtọ́jọ́ ló ti ṣeé yàgò fún. Fún àpẹẹrẹ, Dókítà Nakajima sọ pé, “ó kéré tán mílíọ̀nù méjì ọmọdé ni àwọn àrùn tí a ní abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ń pa lọ́dọọdún.” Nígbà tí Dókítà Nakajima ń sọ̀rọ̀ pé ìyàtọ̀ tó wà nínú ọ̀ràn àbójútó ìlera láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn òtòṣì gbọ́dọ̀ dín kù, ó fi kún un pé: “Ó tó àkókò wàyí láti mọ̀ pé ọ̀ràn tó kan gbogbo ayé ni ọ̀ràn nípa ìlera.” Láìjáfara, aráyé nílò “àgbájọ ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé lórí ọ̀ràn ìlera, tó dá lórí àìṣègbè láwùjọ ẹ̀dá, ẹ̀tọ́ ọgbọọgba àti ìfìmọ̀ṣọ̀kan.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò àgbájọ ọwọ́ yìí lè má tètè bẹ̀rẹ̀, ìròyìn The World Health Report 1998 sọ pé, orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lè ṣe ohun púpọ̀ ná láti mú kí ọ̀ràn ìlera àwọn èèyàn wọ́n sunwọ̀n sí i. Lọ́nà wo? Nípa dídá àwọn èèyàn wọ́n lẹ́kọ̀ọ́ láti ní “òye tí wọ́n nílò láti máa wà nìṣó àti ọ̀nà ìgbésí ayé gbígbámúṣé” tó ń dènà àrùn tàbí tó ń dín in kù. Ìwé Òfin Àjọ WHO sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ìlàlóye àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn aráàlú ṣe pàtàkì gan-an nínú ọ̀ràn mímú kí ipò ìlera sunwọ̀n sí i.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àrùn mẹ́fà tó máa ń bá ọmọdé jà ni àrùn olóde, rọpárọsẹ̀, ikọ́ ẹ̀gbẹ, akọ èfù, ikọ́ àìperí (ikọ́ àwúbì), àrùn ipá.