ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 24
  • Ìlera àti Àyíká

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlera àti Àyíká
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Àyíká—Ń ní Lórí Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
  • Ọ̀ràn Ìlera Ti Sunwọ̀n Sí i Jákèjádò Ayé—Àmọ́ Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jàǹfààní Rẹ̀
    Jí!—1999
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 24

Ìlera àti Àyíká

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Nàìjíríà

Lọ́dọọdún, káàkiri àgbáyé, mílíọ̀nù 49 ènìyàn ń kú. Nǹkan bí ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń kú yìí ló jẹ́ ikú àìtọ́jọ́, tí àyíká àti ọ̀nà ìgbésí ayé tí kò dára ń ṣokùnfà, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbé jáde ṣe sọ. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò:

◼ Àrùn jẹjẹrẹ ń pa àádọ́ta lérúgba ọ̀kẹ́ lọ́dọọdún. Àjọ WHO ròyìn pé, ọ̀pọ̀ lára ìwọ̀nyí “ni ìlọsókè nínú iye àwọn tí ń mu sìgá ní 30 ọdún tí ó kọjá fà.”

◼ Àrùn ìgbẹ́ gbuuru, tí ń pa iye tí ó lé ní àádọ́jọ ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé lọ́dọọdún, ló jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, oúnjẹ àti omi tí a ti kó èérí bá àti àìsí ètò ìmọ́tótó ló fà á.

◼ Ikọ́ fée, tí ń pa àádọ́jọ ọ̀kẹ́ lọ́dún, máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní àwọn àyíká tí ipò òṣì àti àpọ̀jù ènìyàn wà, ní pàtàkì jù lọ, níbi tí kò ti sí ètò ìmọ́tótó tí ó dára.

◼ Àrùn ọ̀nà èémí, èyí tí ògúnnágbòǹgbò rẹ̀ jẹ́ òtútù àyà, ń pa ọ̀kẹ́ márùnléláàádọ́sàn-án àwọn ògowẹẹrẹ tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún márùn-ún lọ́dún kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jẹ́ àwọn tí ń gbé inú ìlú ńlá tí wọ́n ṣíra payá sí ìwọ̀n ìbàyíkájẹ́ tí ó ga.

Yàtọ̀ sí àwọn okùnfà ikú wọ̀nyí, lọ́dọọdún, nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì àbọ̀—ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì gbogbo ènìyàn tí ń gbé ayé—ló ń ní àwọn àìsàn tí ń tinú omi tí kò tó, tàbí omi tí kò mọ́ àti àìsí ètò ìmọ́tótó wá. Ní àfikún sí i, àwọn nǹkan tí ń páni láyà ní lọ́ọ́lọ́ọ́, irú bí òjò omiró, ìpele sánmà adáàbòbo-ayé tí kò lágbára mọ́, àti mímóoru ilẹ̀ ayé ni àjọ WHO sọ pé ó ń fa ìlera ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ń bàjẹ́ sí i. Ìròyìn àjọ WHO sọ pé, lápapọ̀, ohun tí ó ju bílíọ̀nù méjì ènìyàn ní ń gbé ní àyíká tí ó léwu fún ìwàláàyè wọn tàbí tí ó léwu fún ìlera wọn.

Dókítà Hiroshi Nakajima, tí ó jẹ́ olùdarí àgbà fún àjọ WHO, kìlọ̀ pé: “Bí a kò bá ṣe ohun kankan nísinsìnyí, yánpọnyánrin tí ó wà lórí Ilẹ̀ Ayé àti àwọn olùgbé rẹ̀ yóò di èyí tí kò ṣeé fara dà mọ́ rárá, nígbà tí àyíká kò bá lè gbé ẹ̀mí wa ró mọ́.”

Bibeli ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mi.” (Isaiah 33:24) Èyí yóò ṣeé ṣe, kì í ṣe nípa agbára ènìyàn, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọrun, tí yóò mú àwọn àìsàn àti ohun tí ń fà á kúrò nílẹ̀.—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Godo-Foto

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́