Ipa Tí Àyíká—Ń ní Lórí Ìlera Rẹ
LÁÌPẸ́ yìí, Dókítà Walter Reed, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àjọ Tí Ń Mójú Tó Ohun Àmúṣọrọ̀ Ayé, sọ fún Rédíò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé àìdáa téèyàn ti ṣe sí ètò ìṣiṣẹ́ àyíká ilẹ̀ ayé ti kúrò ní kèrémí, àní ó ti burú débi pé èèyàn “ti dabarú ètò yìí bàjẹ́bàjẹ́.” Dókítà Reed sọ pé ìbàjẹ́ yìí, ẹ̀wẹ̀, wà lára nǹkan tó ń ṣàkóbá fún ìlera kárí ayé. Ìwé ìròyìn Our Planet tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń tẹ̀ jáde, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n fi ṣàtúnyẹ̀wò ìwé World Resources 1998-99, àpilẹ̀kọ yìí sì to díẹ̀ lára nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn èèyàn. Lára wọn nìyí:
□ Bíba afẹ́fẹ́ inú ilé àti tìta jẹ́ wà lára ohun tí ń fa ìṣòro àìlèmí dáadáa tí ń ṣekú pa àwọn ọmọdé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rin lọ́dọọdún.
□ Àìsí omi tó mọ́ àti ìmọ́tótó ń dá kún gbígbèèràn tí àwọn àìsàn tí ń fa ìgbẹ́ gbuuru, tí ń gbẹ̀mí mílíọ̀nù mẹ́ta ọmọdé lọ́dọọdún, ń gbèèràn. Fún àpẹẹrẹ, kọ́lẹ́rà tí wọ́n rò pé wọ́n ti ṣẹ́gun tipẹ́tipẹ́ ní Látìn Amẹ́ríkà, tún yọ kúlẹ́ níbẹ̀, ó sì pa ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá èèyàn lọ́dún 1997 nìkan.
Lójoojúmọ́, ní àwọn àgbègbè tó tòṣì jù lọ láyé, a gbọ́ pé ó lé ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] ọmọdé tí ń kú nítorí ìbàjẹ́ àyíká. Sáà tiẹ̀ rò ó wò ná—ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ènìyàn lójoojúmọ́ ayé, bó ṣe pé èrò ọkọ̀ ni wọ́n ni, wọ́n á mà kún inú ọkọ̀ òfuurufú gbẹ̀ǹgbẹ̀ tó tó márùndínlọ́gọ́rin!
Ṣùgbọ́n o, kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan ni ipò àyíká ń ba ìlera wọn jẹ́. Ìwé Our Planet ṣàlàyé pé “ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn ní Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà tó ṣì ń fi imú kó afẹ́fẹ́ burúkú,” èyí ló sì fà á tí ikọ́ fée fi túbọ̀ ń gbèèràn sí i. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìrìn àjò àti òwò ṣíṣe kárí ayé tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i wà lára ohun tó mú kí nǹkan bí ọgbọ̀n àrùn tí ń ran ènìyàn tàn dé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Ní àfikún sí i, ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn àìsàn táa ti kápá tẹ́lẹ̀ “ti padà dé báyìí láti wá gbẹ̀san.”
Ohun tó bani nínú jẹ́ níbẹ̀ ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àìsàn wọ̀nyí tí ipò àyíká ń ṣokùnfà ló ṣeé dènà nípasẹ̀ lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó, lówó pọ́ọ́kú sì ni. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àrùn ni a lè ṣẹ́gun tí wọ́n bá pèsè omi tó mọ́ fún gbogbo èèyàn, tí wọ́n sì ṣètò ìmọ́tótó níbi gbogbo. Eélòó ni ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí yóò ná aráyé? Rédíò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn Nípa Ìtẹ̀síwájú Ènìyàn Lọ́dún 1998, èyí ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde, ti wí, pípèsè omi tó mọ́ fún gbogbo èèyàn àti ṣíṣètò ìmọ́tótó níbi gbogbo yóò ná aráyé ní bílíọ̀nù mọ́kànlá dọ́là—tó kéré sí owó táwọn ará Yúróòpù fi ń ra áísìkiriìmù lọ́dún kan!
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Fọ́tò: Casas, Godo-Foto