ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 12/8 ojú ìwé 15-18
  • Wíwádìí Ìròyìn náà Wò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwádìí Ìròyìn náà Wò
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kì Í Ṣe Àwọn Áńgẹ́lì Lọ̀pọ̀ Èèyàn Gbà Gbọ́
  • Àwọn Áńgẹ́lì Nífẹ̀ẹ́ sí Ipò Tẹ̀mí Wa
  • Àwọn Olùṣòtítọ́ Áńgẹ́lì Kò Ta Ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • “Kíké Pe Gbogbo Áńgẹ́lì!”
  • Lórúkọ Àwọn Áńgẹ́lì
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 12/8 ojú ìwé 15-18

Wíwádìí Ìròyìn náà Wò

ORÍṢIRÍṢI ọ̀nà ni àwọn èèyàn ń gbà hùwà padà lóde òní tí wọ́n bá gbọ́ tí àwọn èèyàn ń sọ pé àwọn bá áńgẹ́lì pàdé lọ́nà kan tàbí òmíràn. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn kan wà tí wọ́n máa ń gbà wọ́n gbọ́. Wọ́n máa ń sọ pé nítorí pé àwọn irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ pọ̀ gan-an, ó sì tàn káàkiri, ó ní láti jẹ́ pé òótọ́ ni. Oríṣi àwọn kejì ni àwọn tó ń ṣiyè méjì. Wọ́n máa ń sọ pé kò sí ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti fi gbe ohun tí wọ́n ń sọ lẹ́yìn. Wọ́n ní ti pé ọ̀pọ̀ èèyàn gba ohun kan gbọ́ kò mú kó jẹ́ òótọ́. Ṣebí nígbà kan, àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé ṣẹjaṣènìyàn ẹ̀dá kan wà lálẹ̀ odò tí wọ́n ń pè ní àrọ̀gìdìgbà. Oríṣi àwọn kẹta ni àwọn tí wọn ò sọ pé òótọ́ ni tí wọn ò sì sọ pé irọ́ ni. Nígbà tí ìwé Angels—Opposing Viewpoints ń sọ nípa ojú ìwòye àwọn tí wọn ò fara mọ́ ọ̀tún tí wọn ò sì fara mọ́ òsì yìí, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọ́n rí áńgẹ́lì. Wọn ò lè fẹ̀rí èyí hàn; ẹ̀mí ìgbàgbọ́ láìjanpata ló mú káwọn èèyàn gbà pé òótọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tó ń ṣiyè méjì ò lè fẹ̀rí hàn pé irọ́ ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára wọ́n gbìyànjú.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Bíbélì jẹ́ orísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nípa ilẹ̀ ọba ẹ̀mí.a Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìròyìn tí a ń gbọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì lóde òní. Bóyá o mọ̀ pé Bíbélì mú un dá wa lójú pé ẹ̀dá ẹ̀mí gidi, tó lágbára, tó sì lógo ni àwọn áńgẹ́lì. Bíbélì ròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ń jíṣẹ́ tí wọ́n sì ń yọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ewu.—Sáàmù 104:1, 4; Lúùkù 1:26-33; Ìṣe 12:6-11.

Bíbélì tún sọ pé àwọn áńgẹ́lì burúkú wà pẹ̀lú. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí ń tan ènìyàn jẹ, wọ́n sì ń ṣi ènìyàn lọ́nà, wọ́n ń mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Fún àpẹẹrẹ, kí a tó gba àwọn àwítẹ́lẹ̀ ẹni tó pe ara rẹ̀ ní wòlíì gbọ́, yóò bọ́gbọ́n mu ká fi ohun tó ń sọ wéra pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó lè sọ pé òun ń ṣojú fún. Dájúdájú, a lè retí pé bí a bá tọpinpin àwọn ìròyìn tí a ń gbọ́ lóde òní nípa ìfarahàn àwọn áńgẹ́lì, òótọ́ ọ̀rọ̀ ló yẹ ká bá níbẹ̀. Nígbà náà, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn ìròyìn nípa bíbá àwọn áńgẹ́lì pàdé lóde òní àti àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́?

Kì Í Ṣe Àwọn Áńgẹ́lì Lọ̀pọ̀ Èèyàn Gbà Gbọ́

Ẹ jẹ́ ká mú un láti ibi ṣíṣàlàyé ohun méjì tó wọ́pọ̀ tí àwọn èèyàn ń ṣì lóye nípa àwọn áńgẹ́lì. Yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, àwọn áńgẹ́lì kò fìgbà kan jẹ́ èèyàn rí láyé wọn. Wọ́n ti wà lọ́run tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá ohun alààyè sórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì sọ pé nígbà tí Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ . . . , gbogbo àwọn [áńgẹ́lì] ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.”—Jóòbù 38:4-7.

Ohun mìíràn tí àwọn èèyàn máa ń sọ lóde òní tí kò tọ̀nà ni pé àwọn áńgẹ́lì gba gbẹ̀rẹ́, wọ́n sì ń gba ìwà àìtọ́ láyè. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì máa ń gbé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run lárugẹ, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ọlọ́run ni wọ́n ń sìn, kì í ṣe èèyàn.—Sáàmù 103:20.

Àwọn Áńgẹ́lì Nífẹ̀ẹ́ sí Ipò Tẹ̀mí Wa

Ọ̀rọ̀ nípa gbígbani sílẹ̀ nínú ewu pọ̀ nínú ìròyìn tí àwọn èèyàn ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì lóde òní. Nínú ìwé kan táwọn èèyàn rà gan-an, a kà nípa ọ̀dọ́bìnrin tí ẹnì kan tí kò rí rọra fà á lọ́wọ́ jáde nínú ilé kan tí iná ń jó. Ìwé mìíràn tún sọ nípa àwọn ọmọ yunifásítì méjì tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọ́n rì sínú òjò dídì. Lójijì ni ọkọ̀ akẹ́rù kan yọ, ó sì yọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn kúrò níbẹ̀, àmọ́ wọn ò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ̀! Níbòmíràn, ìròyìn mìíràn sọ nípa Ann, tí àrùn jẹjẹrẹ kọ lù. Ó ku ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ abẹ fún un nílé ìwòsàn ni ọkùnrin gíga kan tí kò mọ̀ rí ṣàdédé wọlé tọ̀ ọ́ wá. Ọkùnrin náà ní Thomas lorúkọ òun, ó sì sọ pé Ọlọ́run ló rán òun wá. Thomas gbé ọwọ́ sókè, Ann sì nímọ̀lára pé ìmọ́lẹ̀ ríràn yòò, tó gbóná wọnú ara òun lọ. Nígbà tó dé ilé ìwòsàn tí wọ́n ti fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, ẹnu ya àwọn dókítà. Àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe é ti lọ!

Ó ṣe kedere pé àwọn ìròyìn yìí gbé ìbéèrè kan dìde, Bí olúkúlùkù èèyàn bá ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ó, èé ṣe tí wọ́n ń yọ àwọn kan nínú ewu ṣùgbọ́n tí wọn kì í yọ ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn? Ẹgbàágbèje èèyàn ni àrùn, ogun, ìyàn, àti ìjábá ti pa. Dájúdájú, ọ̀pọ̀ lára wọn ló gbàdúrà àtọkànwá pé kí a ran àwọn lọ́wọ́. Kí ló dé tí áńgẹ́lì aláàbò kò dáàbò bò wọ́n?

Bíbélì pèsè ìrànlọ́wọ́ lórí ìbéèrè yìí. Ó sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. (Ìṣe 10:34) Síwájú sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ṣe ń ṣe sí nípa ti ara jẹ àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run lógún, ipò tẹ̀mí wa ló jẹ wọ́n lógún jù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn nípa bíbéèrè pé: “Gbogbo [àwọn áńgẹ́lì] kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?” (Hébérù 1:14) Ríràn wá lọ́wọ́ nípa tí ara ń ṣe wá láǹfààní fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí lè ṣe wá láǹfààní ayérayé.

Ó jọ pé àsọdùn ni ọ̀pọ̀ ìròyìn tí àwọn èèyàn ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì. Wọ́n ní àwọn áńgẹ́lì bá ìyá kan tó ti rẹ̀ tẹ́ aṣọ tuntun sórí bẹ́ẹ̀dì, pé wọ́n rán ẹni tó ń nájà létí láti ra ìṣáná, pé wọ́n sì ń ran àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ láti rí ibi gbé ọkọ̀ sí. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń gbé Scotland ń rẹ́rìn-ín bó ti ń sọ̀rọ̀ pé: “Ó ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí mo ti gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi síbi tí kò yẹ kí n gbé e sí ní Òpópó St Mary, mo sì sọ fún áńgẹ́lì mi láti fi ìfẹ́ àti ìyọ́nú ràdọ̀ bò ó. Bí ọlọ́pàá èyíkéyìí tó ń darí ohun ìrìnnà bá lọ sídìí rẹ̀, ìmọ̀lára ìfẹ́ á kó sí wọn lórí débi pé wọn ò ní mú ọkọ̀ mi. Wọn ò mú mi rí.” Abájọ tí àwọn kan ń fi áńgẹ́lì adáàbòboni ti òde òní wé yèyé ẹ̀mí tàbí Bàbá Kérésì ti àwọn àgbàlagbà.

Àwọn Olùṣòtítọ́ Áńgẹ́lì Kò Ta Ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Àwọn òwe àti àmọ̀ràn tí wọ́n sọ pé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí ló ti wá ló kún inú àwọn ìwé tó ń sọ nípa áńgẹ́lì. Fún àpẹẹrẹ, ìwé kan sọ pé àwọn ẹ̀kọ́ tí Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì fi ránṣẹ́ sí obìnrin kan ní Colorado, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló wà nínú òun. Lára àwọn “ọ̀rọ̀” tí Máíkẹ́lì sọ ni pé: “Gbogbo ọ̀nà ló ń sinni lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀sìn, gbogbo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ló ń sinni lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Lòdì sí èyíinì, Jésù sọ pé ọ̀nà méjì ni ẹ̀sìn pín sí, àti pé ọ̀kan ṣoṣo lára wọn ló lè múni rí ojúrere Ọlọ́run àti ìyè ayérayé. Èkejì ń yọrí sí ìdálẹ́bi àti ìparun ayérayé. (Mátíù 7:13, 14) Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí kò lè jẹ́ òótọ́.

Ìhà wo ni “àwọn áńgẹ́lì” ti “ipò tẹ̀mí tuntun” kọ sí ọ̀ràn ìgbéyàwó àti ìwà rere? Nínú ìwé kan, ẹnì kan kà nípa Roseann tí “áńgẹ́lì” rẹ̀ sọ fún pé: “Àwọn èèyàn tóo ní láti bá sọ̀rọ̀ pọ̀ gan-an, jíjókòó ti [ọkọ rẹ] kò sì bá ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ mu mọ́. Òótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí òun náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ, àmọ́ ó tó àkókò wàyí láti ya ara yín.” Bó ṣe kọ ọkọ ẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn o. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láìsídìí gúnmọ́ kan. (Málákì 2:16) Ìròyìn mìíràn sọ nípa ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ṣe panṣágà, tí wọ́n sì gbà gbọ́ pé àwọn áńgẹ́lì ń wo àwọn pẹ̀lú ìdùnnú àti pé wọ́n tún ràdọ̀ bo àwọn. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.”—Ẹ́kísódù 20:14.

Àbí àwọn ìròyìn tí a ń gbọ́ lóde òní wọ̀nyí jẹ́ àtúnṣe ohun tó wà nínú Bíbélì ni? Rárá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í yí padà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ẹnu yà mí pé ní kíákíá bẹ́ẹ̀ ni a fẹ́ mú yín kúrò lọ́dọ̀ Ẹni tí ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi pè yín, lọ sínú oríṣi ìhìn rere mìíràn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe òmíràn; kìkì pé àwọn kan wà tí wọ́n ń kó ìdààmú bá yín, tí wọ́n sì ń fẹ́ láti yí ìhìn rere nípa Kristi po. Àmọ́ ṣá o, àní bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere ohun tí ó ré kọjá nǹkan tí a ti polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, kí ó di ẹni ègún.”—Gálátíà 1:6-8.

“Kíké Pe Gbogbo Áńgẹ́lì!”

Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa ké pe àwọn áńgẹ́lì láti wá bá wa yanjú àwọn ìṣòro kí wọ́n sì yọ wá nínú ewu tó kún inú ayé? Ohun tí ọ̀pọ̀ ìwé fi ṣe àkọlé wọn nìyẹn. A óò gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò. Wọ́n sọ pé ìwé Ask Your Angels ń ṣàlàyé fún àwọn tó ń kà á ‘bí wọ́n ṣe lè ṣeé kí agbára àwọn áńgẹ́lì ṣàtúnṣe ìmọ̀lára ọkàn wọn tí wọ́n ti pàdánù àti bí wọ́n ṣe lè lé àwọn góńgó wọn bá.’ Ìwé mìíràn tó dà bí ìyẹn ni Calling All Angels!: 57 Ways to Invite an Angel Into Your Life.

Bó ti wù kó rí, Bíbélì kò fìgbà kan rí rọ̀ wá láti máa ké pe àwọn áńgẹ́lì. Jésù ṣàlàyé kókó yìí nínú àdúrà àwòṣe. Ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run . . . ’” (Mátíù 6:9) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Lórúkọ Àwọn Áńgẹ́lì

“Ipò tẹ̀mí tuntun” tí a ń sọ yìí ka mímọ orúkọ àwọn áńgẹ́lì sí ohun pàtàkì gan-an. Àwọn ìwé tó wọ́pọ̀ ń tẹ ẹgbàágbèje orúkọ tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ti àwọn áńgẹ́lì jáde. Nítorí kí ni? Kì í ṣe nítorí àtitẹ́ ìfẹ́ ìtọpinpin lásán kan lọ́rùn; kí àwọn èèyàn lè máa ké pe àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí ni. Èyí tan mọ́ idán pípa. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Angels sọ pé ní àfikún sí ààtò oníjọsìn, àwọn ohun èlò àfipidán, àti ìwúre, “pípe ‘àwọn orúkọ agbára,’ tàbí orúkọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pàtó kan, ń fa ìgbọ̀nrìrì ńlá tó ń ṣínà àárín ilẹ̀ ayé àti ilẹ̀ ọba ẹ̀dá ẹ̀mí sílẹ̀, èyí tó ń jẹ́ kí àwọn onídán lè . . . bá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí sọ̀rọ̀.” Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ ní kedere pé: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ pidán.”—Léfítíkù 19:26.

Méjì péré lára àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì ni Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ orúkọ wọn, àwọn ni Máíkẹ́lì àti Gébúrẹ́lì. (Dáníẹ́lì 12:1; Lúùkù 1:26) Bíbélì sọ orúkọ wọ̀nyí fún wa ká lè mọ̀ pé ẹ̀dá ẹ̀mí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn áńgẹ́lì. Kí ló dé tí kò sọ orúkọ àwọn mìíràn? Ó lè jẹ́ nítorí àtimáà jẹ́ kí àwọn èèyàn máa bọlá tí kò tọ́ sí àwọn áńgẹ́lì fún wọn ni—ohun tí àwọn áńgẹ́lì fúnra wọn kò retí kí a ṣe fún àwọn. Nítorí náà, nígbà tí Jékọ́bù ní kí áńgẹ́lì kan sọ orúkọ rẹ̀ fún òun, áńgẹ́lì náà kọ̀ jálẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 32:29) Lẹ́yìn ìyẹn, áńgẹ́lì tó fara han Jóṣúà kò sọ orúkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ó sọ pé òun ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà.” (Jóṣúà 5:14) Bákan náà, nígbà tí bàbá Sámúsìnì béèrè orúkọ áńgẹ́lì kan lọ́wọ́ rẹ̀, ó bi í léèrè pé: “Èé sì ti ṣe tí o fi ń béèrè nípa orúkọ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé àgbàyanu ni?” (Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18) Ọlọ́run ni àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run ń fẹ́ kí a bọlá fún kí a sì máa ké pè, kì í ṣe àwọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti rí ìsọfúnni tó ń fi ìdí tí Bíbélì fi jẹ́ orísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé hàn, wo ìwé pẹlẹbẹ Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

“Fún àwọn tí wọ́n ń rò pé Ọlọ́run àti àwọn òfin rẹ̀ ti ká àwọn lọ́wọ́ kò jù, . . . àwọn áńgẹ́lì [Sànmánì Tuntun] wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí olùtùnú . . . onínúure, tí kì í fìwà ẹni dáni lẹ́jọ́. Wọ́n sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó olúkúlùkù.”—Ìwé ìròyìn Time

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

“Ṣíṣalábàápàdé” Àwọn Áńgẹ́lì àti Àwọn Abàmì Ẹ̀dá Lóde Òní

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń sọ pé àwọn ti rí áńgẹ́lì àti pé àwọn bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn mìíràn sọ pé àwọn ti bá abàmì ẹ̀dá tí wọ́n wá láti àwọn ilẹ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn pàdé. Ìwé náà, Angels—An Endangered Species, ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó jọra nínú àwọn ìròyìn wọ̀nyí, ó sọ pé àlàyé àwọn méjèèjì lè dọ́gba.b Ohun tí a tò sísàlẹ̀ yìí jẹ́ àkójọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó jọra tó wà nínú ìwé náà.

1. Àwọn áńgẹ́lì àti àwọn abàmì ẹ̀dá wọ̀nyẹn wá láti àwọn ilẹ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn.

2. Àwọn méjèèjì jẹ́ oríṣi ẹ̀dá onípò gíga, yálà nípa tẹ̀mí tàbí ti ìmọ̀ ẹ̀rọ.

3. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló jẹ́ èwe, wọ́n sì jojú ní gbèsè, wọ́n sì jẹ́ onínúure tó kún fún ìyọ́nú.

4. Àwọn méjèèjì kò níṣòro èdè sísọ, ketekete ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ lédè ẹni tó ń gbọ́ wọn.

5. Ọ̀gá làwọn méjèèjì nínú fífò kiri.

6. Ńṣe ni ara àwọn áńgẹ́lì àti àwọn àjèjì náà ń kọ mànà.

7. Àwọn méjèèjì wọṣọ dáadáa, tó sábà máa ń jẹ́ ẹ̀wù àlọ́mọ́ra tàbí ẹ̀wù àwọ̀lékè tí kò lápá tó gbẹ mọ́ wọn lára. Àwọ̀ funfun tàbí àwọ̀ búlúù ni wọ́n sábà máa ń wọ̀.

8. Àwọn méjèèjì sábà máa ń ga ní ìwọ̀n ẹ̀dá ènìyàn.

9. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáráyé àti pílánẹ́ẹ̀tì ń ṣe àwọn méjèèjì láàánú.

10. Ẹ̀rí ṣíṣalábàápàdé àwọn àjèjì àti áńgẹ́lì sinmi lórí ohun tí ẹni tó rí wọn bá sọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Àlàyé tó jọra nínú méjèèjì ni pé ó dájú pé àwọn ẹ̀mí búburú, tàbí ẹ̀mí èṣù, ló wà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ irú “ìpàdé” bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14)—Wo Jí!, July 8, 1996, ojú ìwé 26.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bíbélì ní àwọn ìròyìn tòótọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì tó fara han àwọn èèyàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́