ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 12/8 ojú ìwé 19-20
  • Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 12/8 ojú ìwé 19-20

Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

GẸ́GẸ́ bí a ti rí i, àwọn èrò àti ìròyìn tí a sábà máa ń gbọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì kì í sábà bá ohun tí Bíbélì fi kọ́ni mu. Bó bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra, ṣé ó ṣe nǹkan ni? Ṣé ìpalára kan tiẹ̀ wà nínú gbígba ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́wọ́ gbà nípa àwọn áńgẹ́lì gbọ́ ni? Dájúdájú, ó wà.

Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa irú ìṣarasíhùwà tí a ń fi ọ̀ràn “ipò tẹ̀mí tuntun” gbé lárugẹ. Àwọn ìwé ìgbàlódé tó ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì ń fún ìṣarasíhùwà ṣíṣe bí ọmọdé lárugẹ, dípò lílo agbára ìrònú ẹni. Wọn kì í sábà fún àwọn tó ń kà wọ́n níṣìírí láti yanjú ìṣòro ara wọn tàbí kí wọ́n wádìí kí wọ́n lè lóye Bíbélì àti ìmọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìwé tó ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì ń mú un dá wa lójú pé áńgẹ́lì oníwà pẹ̀lẹ́ tó sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́ máa ń wà pẹ̀lú wa jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wa àti pé kò sí ìdí láti dààmú, níwọ̀n bí a ti ń gbé ilẹ̀ ayé tó kún fún ayọ̀ tí gbogbo nǹkan sì ń lọ déédéé. Bí ìṣòro bá yọjú, ká kàn káwọ́ lẹ́rán máa retí kí àwọn áńgẹ́lì wá yanjú ẹ̀ ni. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, kí nìdí tí Bíbélì fi ní ká “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́”?—Júúdà 3.

Ohun tí ọ̀pọ̀ ìwé tí ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì ń ru sókè nínú ènìyàn ni ẹ̀mí ìgbéraga àti ìṣefọ́nńté. Ìmọtara-ẹni-nìkan ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a gbọ́ láti àwọn orísun yẹn ti wí, àwọn áńgẹ́lì ìgbàlódé ń fẹ́ ká mọ bí a ṣe lẹ́wà, tí a sì ń dán tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti ní èrò tó dára nípa ara wa, lájorí ohun tí ọ̀ràn nípa “ipò tẹ̀mí tuntun” náà dá lé lórí ni láti nífẹ̀ẹ́ ara ẹni lọ́nà tí kò láfiwé. Òǹkọ̀wé kan sọ pé àṣẹ àkọ́kọ́, tó sì lágbára jù ni láti “nífẹ̀ẹ́ Ara Rẹ, bí Olúwa.” Èyí ta ko ọ̀rọ̀ Jésù gidigidi! Òun sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ. Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” (Mátíù 22:36-39) Inú wa yóò máa dùn gan-an bí a bá ń wá ire Ọlọ́run ṣáájú tiwa.

Dídarí àfiyèsí gbogbo sórí àwọn áńgẹ́lì kò bá jíjẹ́ Kristẹni tòótọ́ mu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó lòdì láti máa jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì. (Kólósè 2:18) Láti jọ́sìn túmọ̀ sí “láti bọlá fúnni tàbí láti forí balẹ̀ fúnni bí òrìṣà àkúnlẹ̀bọ tàbí ẹni tí agbára rẹ̀ ju ti ẹ̀dá.” Bẹ́ẹ̀ rèé, ńṣe ni ọ̀pọ̀ ìwé tó gbajúmọ̀ ń rọ àwọn tó ń kà wọ́n láti máa bọlá fún àwọn áńgẹ́lì kí wọ́n sì máa forí balẹ̀ fún wọn. Àmọ́ ṣá o, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sátánì ní kí Jésù jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Jésù dá a lóhùn pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Lúùkù 4:8) Lákòókò mìíràn, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù wólẹ̀ níwájú áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà wí fún un pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù. Jọ́sìn Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 19:10.

Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló yẹ ká ti wá ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́, kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì. Ó ṣe tán, inú rẹ̀ ń dùn sí fífi ìfẹ́ hàn sí gbogbo ẹni tó bá pa ọ̀nà òdodo tó ń fẹ́ mọ́. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè, a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 5:14, 15.

Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí a kò mọ̀ nípa àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ pé Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn, wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti mú ète rẹ̀ ṣẹ, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Wọ́n ń fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:6, 7) Wọn kò fẹ́ ìjọsìn wa. Níwọ̀n bí a kò ti lè rí wọn, a kò mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n tó láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ń dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń tọ́ wọn sọ́nà lápapọ̀.

Àpẹẹrẹ rere mà làwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì wọ̀nyí ń fi lélẹ̀ fún wa o! Wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń fògo fún un. (Sáàmù 148:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní agbára ìrònú àti agbára tẹ̀mí tó pọ̀, síbẹ̀ wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà. (Júúdà 9) Ìmúṣẹ àwọn ète Ọlọ́run jẹ wọ́n lọ́kàn gan-an. (1 Pétérù 1:11, 12) Òótọ́ ni, inú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a ti kẹ́kọ̀ọ́ nǹkan wọ̀nyí. Bíbélì ni ìwé tó ń sọ òtítọ́ fún wa nípa àwọn áńgẹ́lì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà wí pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́