Ìyípadà Kíkàmàmà Tí Yóò Kóre Dé
“Ní ọdún 1900, ayé ń múra àtiwọnú ọ̀kan lára àwọn sànmánì ìyípadà tó kàmàmà nínú ìtàn ẹ̀dá. Ètò ògbólógbòó fẹ́ kọjá lọ, tuntun sì fẹ́ wọlé dé.”—The Times Atlas of the 20th Century.
ÌWÉ àwòrán ilẹ̀ táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí sọ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, “ayé kó wọnú sànmánì rúgúdù àti ìwà ipá tó bùáyà.” Ogun tó jà ní ọ̀rúndún yìí nìkan pọ̀ ju ti ọ̀rúndún èyíkéyìí, àní iye àwọn tó bógun lọ lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù.
Nínú sànmánì yìí ni ogun ti pa àwọn aráàlú púpọ̀ jù lọ. Nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó bógun lọ jẹ́ àwọn aráàlú. Ṣùgbọ́n nínú Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn aráàlú tó kú pọ̀ ju àwọn ológun tó kú ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tó ti bógun lọ láti ìgbà yẹn, àwọn aráàlú ló pọ̀ jù lọ. Gbogbo ìwà ipá yìí ti mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ nípa ẹni tí ń gun “ẹṣin aláwọ̀ iná,” tí a “yọ̀ǹda fún láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 6:3, 4; Mátíù 24:3-7.
Ìyípadà Ti Dé Bá Ìwà Ọmọlúwàbí
Àsọtẹ́lẹ̀ 2 Tímótì 3:1-5 ti ní ìmúṣẹ sí ọ̀rúndún ogún lára, àsọtẹ́lẹ̀ náà kà pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”
Kì í ṣòní, kì í ṣàná làwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ti ń hu irú àwọn ìwà yìí títí dé àyè kan. Ṣùgbọ́n ní ọ̀rúndún ogún, ìṣarasíhùwà yẹn wá túbọ̀ peléke, ó sì tún tàn kálẹ̀. Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn tó bá ń hu irú ìwà táa mẹ́nu kàn lókè yìí, ojú ọ̀bàyéjẹ́ la fi ń wò wọ́n—ìyẹn tá ò bá tilẹ̀ pè wọ́n ní òkú òǹrorò. Àmọ́ ní báyìí o, “àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run” pàápàá kò róhun tó burú nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Láyé ọjọ́un, àwọn èèyàn olùfọkànsìn gbà pé èèwọ̀ ni kí ọkùnrin àtobìnrin máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó. Ojú àbùkù ni wọ́n fi ń wo obìnrin tó bá lọ gboyún níta, ojú yẹn sì ni wọ́n fi ń wo ẹni tó ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀. Ní tiwọn, oyún ṣíṣẹ́ kò ṣeé gbọ́ sétí, ìkọ̀sílẹ̀ sì burú jáì. Ìwà burúkú gbáà ni jìbìtì lílù. Ṣùgbọ́n lónìí ńkọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti wí, “àyè ti wá gba olè, ó ti gbọ̀lẹ.” Ó ṣe wá rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “ìgbàkugbà yìí tẹ́ àwọn tó fẹ́ máa ṣe bó ṣe wù wọ́n lọ́rùn.”
Pípa táwọn èèyàn ti pa ìwà ọmọlúwàbí tì ní ọ̀rúndún yìí ti mú kí ìyípadà dé bá ohun táwọn èèyàn kà sí pàtàkì. Ìwé The Times Atlas of the 20th Century ṣàlàyé pé: “Lọ́dún 1900, iyì ṣe pàtàkì ju owó lọ lójú àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn. . . . Ṣùgbọ́n lápá ìparí ọ̀rúndún yẹn, orílẹ̀-èdè tó bá di ọlọ́rọ̀ ni wọ́n gbà pé ó ti gòkè àgbà. . . . Irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ dé bá ojú táwọn èèyàn fi ń wo ọrọ̀.” Lóde òní, tẹ́tẹ́ títa níbi gbogbo ń fa ìfẹ́ owó, bẹ́ẹ̀ náà ni rédíò, tẹlifíṣọ̀n, sinimá, àti fídíò ń gbé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lárugẹ. Àní àwọn eré bí eré àṣedárayá àti àwọn ìdíje àṣegbẹ̀bùn táwọn ọlọ́jà fi ń polówó ọjà wọn, gbogbo ẹ̀, ọ̀rọ̀ gbogbo lórí owó ni.
Wíwà Pa Pọ̀ Láìsí Àjọṣepọ̀
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, abúlé ni ọ̀pọ̀ jù lọ ń gbé. Ṣùgbọ́n à ń gbọ́ báyìí pé tó bá máa fi di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, yóò ju ìdajì àwọn olùgbé ayé tí yóò máa gbé ní àwọn ìlú ńlá. Ìwé náà 5000 Days to Save the Planet sọ pé: “Iṣẹ́ takuntakun gbáà ló jẹ́ láti pèsè gbogbo ohun kòṣeémánìí fáwọn olùgbé ìlú ńlá lónìí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pípèsè nǹkan wọ̀nyí fún ìran ọjọ́ iwájú.” Ìwé ìròyìn tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe náà, World Health, sọ pé: “Ṣe ni iye àwọn èèyàn tí ń gbé ìlú ńlá túbọ̀ ń pọ̀ sí i. . . . Ní báyìí, ẹgbàágbèje . . . ló ń gbé nínú ipò tó ń ṣàkóbá fún ìlera wọn, tó sì ń fi ẹ̀mí wọn sínú ewu.”
Ó mà ṣe o, pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń gbé pa pọ̀ nínú ìlú ńlá nísinsìnyí, ṣe ni wọ́n dà bí ọmọ awùsá tí ń gbé inú ilé kan náà láìkì í fojú gán-án-ní ara wọn! Tẹlifíṣọ̀n, tẹlifóònù, àti ọ̀nà táa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà táa mọ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti rírajà nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan wọ̀nyí wúlò láyè ara wọn, wọ́n ti bẹ́gi dí àjọṣepọ̀ lójú kojú. Ìdí nìyẹn tí ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà, Berliner Zeitung, fi sọ pé: “Ọ̀ràn àpọ̀jù èèyàn nìkan kọ́ ni ìṣòro ọ̀rúndún ogún. Ọ̀rúndún ìnìkanwà tún ni pẹ̀lú.”
Èyí máa ń yọrí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́, irú èyí tó ṣẹlẹ̀ nílùú Hamburg, ní Jámánì, níbi tí wọ́n ti rí òkú ọkùnrin kan nínú ilé rẹ̀, lẹ́yìn ọdún márùn-ún gbáko tó ti kú! Ìwé ìròyìn Der Spiegel sọ pé: “Bó kú, bó yè ni o, kò sẹ́ni tó mọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ ò mọ̀, àwọn aládùúgbò ò mọ̀, kódà ìjọba ò mọ̀,” ó wá fi kún un pé: “Ẹtì lèyí jẹ́ fún ọ̀pọ̀ aráàlú, nítorí pé ọlọ́mọ ò mọ ọmọ mọ́ nínú àwọn ìlú ńlá o, àní ó ti di kóńkó jabele, kálukú ló ń ṣe tiẹ̀.”
Kì í kàn-án ṣe ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ló lẹ̀bi irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bẹ́ẹ̀. Àfọwọ́fà àwọn èèyàn ni. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọ̀rúndún yìí ti sọ àwọn èèyàn di “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aláìlọ́pẹ́, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, . . . aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-5.
Ọdún Abàmì Lọdún 1914
Winston Churchill sọ pé, “nígbà tí ọ̀rúndún ogún bẹ̀rẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni pé ó máa san wá, tó máa tù wá lára.” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé sànmánì náà yóò mú wá ni ire owó, ire àlàáfíà. Síbẹ̀, lọ́dún 1905, Ilé Ìṣọ́ September 1 [Gẹ̀ẹ́sì], kìlọ̀ pé: “Ogun ń bọ̀ láìpẹ́ láìjìnnà,” ó tún sọ pé “rúgúdù ńlá” yóò bẹ́ lọ́dún 1914.
Àní, láti ọdún 1879 ni ìwé ìròyìn yẹn ti tọ́ka sí i pé 1914 yóò jẹ́ ọdún mánigbàgbé. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ó sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nínú ìwé Dáníẹ́lì tọ́ka sí i pé ọdún yẹn ni àkókò tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fìdí múlẹ̀ ní ọ̀run. (Mátíù 6:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe 1914 ni Ìjọba náà gba agbára láti máa ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé, ọdún yìí ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ti ọjọ́ wa], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yẹn, tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn èèyàn olùbẹ̀rù Ọlọ́run jọ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, àwọn tó fẹ́ láti jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀.—Aísáyà 2:2-4; Mátíù 24:14; Ìṣípayá 7:9-15.
Ní ìṣekòńgẹ́ pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run, 1914 ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀, ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ sáà tí yóò dópin nígbà ìparun ètò àwọn nǹkan tó wà lóde yìí. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé sáà yìí yóò jẹ́ sáà ogun àgbáyé, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá, àti ìwà àìlófin tó légbá kan àti pé ìfẹ́ àwọn èèyàn fún Ọlọ́run àti fún aráyé yóò di tútù. Ó sọ pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.”—Mátíù 24:3-12.
Ayé Tuntun Yóò Dé Láìpẹ́
Ó ti pé ọdún márùnlélọ́gọ́rin báyìí táa ti bẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” òpin ètò àwọn nǹkan aláìtẹ́nilọ́rùn yìí sì ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run, lábẹ́ Kristi, “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tó wà lóde báyìí] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44; 2 Pétérù 3:10-13.
Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run yóò mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì mú ayé tuntun wá fún àwọn olóòótọ́ ọkàn. “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:21, 22.
Ìròyìn ayọ̀ mà lèyí o—àní ìròyìn tó yẹ ká polongo níbi gbogbo ni! Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò yanjú àwọn ìṣòro tí ọ̀rúndún ogún ti mú le koko: ogun, ipò òṣì, àìsàn, ìwà ìrẹ́nijẹ, ìkórìíra, ẹ̀tanú, àìríṣẹ́ṣe, ìwà ọ̀daràn, ìbànújẹ́, ikú.—Wo Sáàmù 37:10, 11; 46:8, 9; 72:12-14, 16; Aísáyà 2:4; 11:3-5; 25:6, 8; 33:24; 65:21-23; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:3, 4.
Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti máa gbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo nínú ayọ̀ ńláǹlà? Gbọ́ ìsọfúnni púpọ̀ sí i lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọn yóò fi hàn ẹ́ láti inú ẹ̀dà Bíbélì rẹ pé àwọn ọdún ìyípadà gígadabú tó dé ní ọ̀rúndún ogún máa tó dópin, àti pé lẹ́yìn èyí, yóò ṣeé ṣe fún ẹ láti gbádùn àwọn ìbùkún tí kò lópin!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ayé tuntun yóò dé láìpẹ́