ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 9-12
  • Ìfiniṣẹrú Lóde Òní—Òpin Rẹ̀ Dé Tán!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfiniṣẹrú Lóde Òní—Òpin Rẹ̀ Dé Tán!
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyí Ọkàn Padà
  • Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba àti Ọ̀wọ̀ fún Iyì Ẹ̀dá
  • Yíyí Ìjọba Padà
  • Ìwọ Ha Ń Bọlá fún Iyì Wọn Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìwọ Ha Ń Buyì fún Àwọn Ẹlòmíràn Nígbà Tí O Bá Ń Fúnni Nímọ̀ràn Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Gbogbo Èèyàn Yóò Di Ẹni Iyì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 9-12

Ìfiniṣẹrú Lóde Òní—Òpin Rẹ̀ Dé Tán!

“Òmìnira èèyàn kan ṣoṣo jẹ́ apá pàtàkì lára òmìnira gbogbo gbòò. O ò lè pa ọ̀kan lára láìṣe ìkejì léṣe.”—Victor Schoelcher, Ọmọ Ilẹ̀ Faransé, Tó Jẹ́ Akọ̀ròyìn Àti Òṣèlú, Ọdún 1848.

“IRÚ ìwà ibi wo ló wà lọ́kàn ẹ̀dá, tó ń mú kó máa tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, kó máa tẹ̀ ẹ́ lórí ba, kó sì máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀? Báwo ló sì ṣe jẹ́ tí wọn kì í fìyà jẹ àwọn tó ń hu irú ìwà burúkú yìí sí àwọn èèyàn, pàápàá látìgbà tí ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti ń jẹ ẹ̀dá lọ́kàn?” Àwọn olóòtú ìwé ìròyìn UNESCO Courier ló béèrè ìbéèrè yìí.

Ìdáhùn ẹ̀ lọ́jú pọ̀. Ìwọra ló ń fà á táwọn èèyàn fi ń wá káwọn ọmọdé máa ṣiṣẹ́ fún wọn, nítorí kò ní ná wọn lówó púpọ̀, ìwọra kan náà yìí ló ń fa ìfinisọfà. Ipò òṣì àti àìkàwé ni wọ́n máa ń sọ pé ó fà á tí wọ́n fi ń ta àwọn ọmọdébìnrin sóko aṣẹ́wó, tí wọ́n sì ń fi wọ́n fọ́kọ tá máa lò wọ́n nílò omi òjò. Ààtò ẹ̀sìn àti àwọn àṣà ìbílẹ̀ ló máa ń fa ìfiniṣẹrú nítorí ẹ̀sìn. Ní ti àwọn ọkùnrin tí ń wá àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin ẹlẹ́jẹ̀ tútù, tí kò lárùn éèdì lára lọ sí Bangkok tàbí Manila, ìtorí àtiní ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ àti ìṣekúṣe ni wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ apá kan ayé tí àwọn èèyàn ti jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò,” bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí í ṣe amòfin ní ọ̀rúndún kìíní, ṣe sọ ọ́. (2 Tímótì 3:1-5) Ó jẹ́ apá kan ayé tí ‘a kò ti lè mú èyí tí ó wọ́ tọ́, tí èyí tí ó sì kù káàtó kò ṣeé kà,’ bí olórí orílẹ̀-èdè kan láyé àtijọ́, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sólómọ́nì, ṣe sọ ọ́.—Oníwàásù 1:15.

Yíyí Ọkàn Padà

Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí ohun tí a lè ṣe láti mú àṣà ìfiniṣẹrú táa bá láyé tàbí èyí tí wọ́n ń ṣe láyé ìsinyìí kúrò pátápátá ni? Rárá o!

Ilé Iṣẹ́ Ọ̀gá Àgbà Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (OHCHR) sọ pé ọ̀ràn ìfiniṣẹrú jẹ́ “ọ̀ràn tó kan èrò inú,” ó tún sọ pé: “Kódà tí a bá fòpin sí àṣà ìfiniṣẹrú, kì í tán bọ̀rọ̀. Àwọn tí wọ́n fi ṣẹrú àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn àti àwọn táwọn tó ń dáṣà náà fi lé lọ́wọ́ ṣì lè máa ronú kàn án, kódà nígbà pípẹ́ gan-an lẹ́yìn tí wọ́n ti fòfin dè é.”

Nítorí náà, ọ̀nà kan tí a lè gbà fòpin sí àṣà ìfiniṣẹrú yóò jẹ́ nípa yíyí ìrònú àti ọkàn àwọn èèyàn padà jákèjádò ayé. Ìyẹn sì kan yíyí ẹ̀kọ́ tí a ń kọ́ wọn padà—kí á máa kọ́ àwọn èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa fọ̀wọ̀ wọ ara wọn. Ó túmọ̀ sí pé a ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mú ìwọra kúrò lọ́kàn wọn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti ìwà rere. Ta ló lè kọ́ni ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀? Ilé iṣẹ́ OHCHR sọ pé, “gbogbo wa la ní ohun tí a lè ṣe láti mú kí ètò àgbáyé kan dé, èyí tí kò ní fàyè gba yíyan àwọn èèyàn jẹ.”

Ronú nípa ètò ẹ̀kọ́ tí ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni táa mọ̀ sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé kalẹ̀ jákèjádò ayé. Ètò yìí ti kẹ́sẹ járí nínú kíkọ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn pé kí wọ́n má gba àṣà yíyan àwọn èèyàn jẹ́ láyè. Nípasẹ̀ ètò náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ ni wọ́n ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bí wọn ó ṣe máa fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn ọmọnìkejì wọn. Kí ló mú kí ètò yìí kẹ́sẹ járí?

Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé a gbé e karí Bíbélì, ìwé tí Ẹlẹ́dàá èèyàn mí sí. Ìwé náà gbé iyì ẹ̀dá lárugẹ. Àwọn tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé kalẹ̀ wá mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà, fúnra rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run iyì. (1 Kíróníkà 16:27) Ó fi iyì jíǹkí gbogbo ohun tó dá. Lára wọn ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin, láti ẹ̀yà gbogbo, láti onírúurú àwùjọ, àtolówó àti tálákà.—Wo àpótí táa pè ní “Òmìnira àti Iyì Ẹ̀dá—Ibo Ló Ti Máa Wá?”

Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba àti Ọ̀wọ̀ fún Iyì Ẹ̀dá

Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run “dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 17:26) Nípa bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tó lè sọ pé òun lọ́lá ju ọmọnìkejì òun lọ tàbí pé òun ní ẹ̀tọ́ láti máa ni àwọn ẹlòmíràn lára tàbí láti máa yàn wọ́n jẹ. Àwọn tí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ wá mọrírì òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, nítorí àǹfààní láti ní àjọṣe pẹ̀lú Rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Àní, “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Ẹ̀kọ́ tí a gbé karí Bíbélì yìí ní ipa jíjinlẹ̀ lórí àkópọ̀ ìwà èèyàn. Nípasẹ̀ rẹ̀, a lè sọ ọkàn àti èrò inú àwọn èèyàn “di tuntun pátápátá.” (Éfésù 4:22-24, Today’s English Version) Ó ń mú kí wọ́n fi iyì àti ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn. Wọ́n múra tán láti “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Kò sẹ́ni tó lè jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kó tún máa lọ́wọ́ nínú yíyan àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ tàbí kó máa ni wọ́n lára. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé àwọn jẹ́ ẹgbẹ́ Kristẹni bíi ti ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, níbi tí ‘kò ti sí Júù tàbí Gíríìkì, tí kò sí ẹrú tàbí òmìnira. Ẹnì kan ṣoṣo ni gbogbo wọn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.’—Gálátíà 3:28.

Yíyí Ìjọba Padà

Ṣùgbọ́n kí onírúurú ìfiniṣẹrú tó lè dópin títí láé, ó ń béèrè pé kí ìyípadà tó múná dóko ṣẹlẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá. Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé sọ pé láti fòpin sí àṣà yíyan èèyàn jẹ, a ní láti “yí àwọn àṣà àti ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tó ń gba” irú àṣà bẹ́ẹ̀ “láyè padà.” Díẹ̀ lára àwọn àbá tí àjọ yẹn tún dá ni pé, kí àwọn èèyàn àgbáyé gbégbèésẹ̀, kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí àwùjọ àgbáyé múra tán láti ṣe nǹkan sí i.

A ó retí pé èyí yóò nílò agbára tó lè ṣàkóso gbogbo pílánẹ́ẹ̀tì wa, agbára tó lè mú òmìnira àgbáyé dá wa lójú. Boutros Boutros-Ghali, tí í ṣe akọ̀wé àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé àwọn ìṣòro náà gan-an tó ń yọ pílánẹ́ẹ̀tì wa lẹ́nu jẹ́ àwọn èyí tí a gbọ́dọ̀ ṣera wa lóṣùṣù ọwọ̀, ká yanjú wọn “jákèjádò ayé.” Ṣùgbọ́n gbogbo èèyàn kọ́ ló fi bẹ́ẹ̀ dá lójú pé èyí lè ṣẹlẹ̀. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé onímọtara-ẹni-nìkan àti anìkànjọpọ́n gbáà ni púpọ̀ àwọn tó ń ṣèjọba tó bá kan ọ̀ràn ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ jákèjádò ayé.

Bó ti wù kó rí, Bíbélì—ìwé kan náà tó ti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti bọ̀wọ̀ fún iyì ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn—fi hàn pé Ọlọ́run ti pète láti gbé irú ìjọba àgbáyé bẹ́ẹ̀ kalẹ̀. Wàá rí ọ̀pọ̀ ìlérí nípa ayé tuntun òdodo nínú Bíbélì. (Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13) Ète Ọlọ́run ni láti mú ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run ti fi ète rẹ̀ hàn láti gbé ìjọba àgbáyé kan kalẹ̀ tí yóò fi òdodo ṣàkóso aráyé. Jésù ní kí a máa gbàdúrà fún ìjọba yẹn nínú àdúrà tí a sábà máa ń pè ní Àdúrà Olúwa.—Mátíù 6:9, 10.

Yíyan èèyàn jẹ àti gbogbo onírúurú àṣà ìfiniṣẹrú kì yóò sí lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba yìí nítorí pé Kristi Ọba yóò máa ṣàkóso “nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo.” (Aísáyà 9:7) Àwọn tí wọ́n ń ni lára yóò rí ìtúsílẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso òdodo rẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12-14.

Bí o bá fẹ́ rí bí òpin yóò ṣe dé bá onírúurú àṣà ìfiniṣẹrú—a ké sí ọ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ète Ọlọ́run láti fìdí ìjọba àgbáyé tí yóò sọni dòmìnira yìí múlẹ̀. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

ÒMÌNIRA ÀTI IYÌ Ẹ̀DÁ—IBO LÓ TI MÁA WÁ?

Olúkúlùkù wa ló ní ànímọ́ àbínibí ti fífẹ́ iyì àti òmìnira. Kofi Annan, Akọ̀wé Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn àwọn èèyàn lágbàáyé nígbà tó béèrè pé: “Ta ló lè sọ pé gbogbo wa kọ́ la fẹ́ wà láìsíbẹ̀rù, láìsí ìfìyàjẹni àti láìsí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́? . . . Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ọ rí kí ẹni tó lómìnira máa sọ pé òun fẹ́ kí òmìnira dópin? Ibo lẹ ti gbọ́ ọ rí kí ẹrú máa sọ pé àṣà fífi èèyàn ṣẹrú dáa?”

Irú èrò wọ̀nyẹn kì í ṣe tuntun. Seneca, ará Róòmù, tí í ṣe ọlọ́gbọ́n èrò orí ní ọ̀rúndún kìíní, bẹnu àtẹ́ lu èrò náà pé a bí àwọn kan láti jẹ́ ẹrú, ó sọ nínú ìwé rẹ̀ Letters to Lucilius pé: “Jọ̀ọ́ rántí pé bí wọ́n ṣe bí ẹ ni wọ́n bí ẹni tóò ń pè lẹ́rú ẹ yẹn, rántí pé ọ̀run kan náà lẹ jọ kọ àtàrí sí, afẹ́fẹ́ kan náà lẹ jọ ń mí símú, ayé kan náà lẹ jọ ń gbé, bákan náà ni ẹ ó sì ṣe kú!”

Ìmáàmù ʽAlī, tí àwọn èèyàn ń júbà gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ kẹrin sí Muḥammad, sọ pé nínú ọ̀ràn ẹ̀dá “àparò kan ò ga jùkan lọ.” Saʽdī, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Páṣíà, tó máa ń kéwì ní ọ̀rúndún kẹtàlá, sọ pé: “Ara kan náà ni àwọn ọmọ Ádámù, ohun kan náà ni Ọlọ́run sì fi dá wọn. Tí ayé bá ń fìyà pá ẹ̀yà kan nínú ara náà lórí, àwọn ẹ̀yà yòókù kò lè lálàáfíà.”

Àkọsílẹ̀ ìtàn tó ní ìmísí láti ọ̀run tó wà nínú Bíbélì sọ àwọn kókó pàtàkì nípa iyì gbogbo èèyàn. Fún àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 1:27 ṣàpèjúwe ìṣẹ̀dá ènìyàn, ó sọ pé: “Ọlọ́run . . . bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Ọlọ́run òmìnira ni Ẹlẹ́dàá wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Nígbà tí Jèhófà ń dá èèyàn ní àwòrán àti ìrí rẹ̀, ó fi ìwọ̀n ọlá, iyì, àti ọ̀wọ̀ jíǹkí èèyàn. Nípa gbígba èèyàn tó dá kúrò lọ́wọ́ “ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,” òun yóò tún ṣe é kí àwọn èèyàn máa gbádùn irú òmìnira àti iyì yẹn títí láé.—Róòmù 8:21.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gbogbo èèyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ sí iyì àti òmìnira

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ TẸNU MỌ́ BÍBỌ̀WỌ̀ FÚN IYÌ Ẹ̀DÁ, Ó SÌ MÚ ÌRÈTÍ AYÉ TUNTUN TÍ Ń BỌ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ DÁNI LÓJÚ

Wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé ní Benin

Ẹwà omi Náílì Aláwọ̀ Búlúù tó ń tú jáde yìí ní Etiópíà ń fi hàn bí párádísè tí a ó mú bọ̀ sípò ṣe máa rí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́