Ìwọ Ha Ń Buyì fún Àwọn Ẹlòmíràn Nígbà Tí O Bá Ń Fúnni Nímọ̀ràn Bí?
ẸWO bí ó ti dára tí ó sì ṣàǹfààní tó pé kí a gbaninímọ̀ràn lọ́nà tí ó níyì! Edward sọ pé: “Ìmọ̀ràn onínúure, onígbatẹnirò, tí ó fi ìbìkítà hàn a máa yọrísí ipò-ìbátan dídára.” Warren jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí o bá nímọ̀lára pé olùgbaninímọ̀ràn náà fún ọ ní ọ̀wọ̀ àti ọlá nípa fífi ìmúratán hàn láti tẹ́tísí apá tí ó jẹ́ tìrẹ nínú ìtàn náà, ó máa ń rọrùn púpọ̀ gan-an láti gba ìmọ̀ràn náà.” Norman sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Nígbà tí olùgbaninímọ̀ràn kan bá bá mi lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, mo máa ń lómìnira láti tọ̀ ọ́ lọ, láti béèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ rẹ̀.”
Ẹ̀tọ́ Tí Ó Bá Ìwà-Ẹ̀dá Mu Tí Ènìyàn Ní fún Iyì
Ìmọ̀ràn ọlọ́yàyà, oníwà-bí-ọ̀rẹ́, àti onífẹ̀ẹ́ ní a máa ń tẹ́wọ́gbà nítòótọ́. Ó ṣàǹfààní láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìmọ̀ràn lọ́nà tí ìwọ yóò fẹ́ kí a gbà fún ọ nímọ̀ràn. (Matteu 7:12) Olùgbaninímọ̀ràn rere kan máa ń lo àkókò láti fetísílẹ̀ ó sì máa ń wá ọ̀nà láti lóye ẹni tí ó ń fún nímọ̀ràn—ìrònú rẹ̀, ipò rẹ̀, àti àwọn ìmọ̀lára rẹ̀—dípò ìfòfíntótó bániwí àti dídẹ́bi fúnni.—Owe 18:13.
Àwọn olùgbaninímọ̀ràn òde-ìwòyí, títíkan àwọn Kristian alàgbà, gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti buyì fún àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n bá ń fúnni nímọ̀ràn. Èéṣe? Fún ìdí rírọrùn náà pé ẹ̀mí-ìrònú kan tí ń gbilẹ̀ nínú ẹgbẹ́-àwùjọ ni láti bá àwọn ẹlòmíràn lò ní ọ̀nà tí kò níyì. Èyí sì ń gbèèràn. Lọ́pọ̀ ìgbà lemọ́lemọ́ àwọn wọnnì tí ìwọ retí ìbálò tí ó níyì láti ọ̀dọ̀ wọn ni wọ́n ń kùnà láti pèsè rẹ̀, ìbáà jẹ́ àwọn oníṣẹ́-àkọ́mọ̀ọ́ṣe, àwọn aṣáájú ìsìn, tàbí àwọn mìíràn. Láti ṣàkàwé, níbi iṣẹ́, ìlékúrò lẹ́nu iṣẹ́ máa ń mú ìdààmú wá ó sì máa ń kún fún másùnmáwo fún agbanisíṣẹ́ àti ẹni tí a gbàsíṣẹ́. Ó ń ba iyì ara-ẹni jẹ́, pàápàá jùlọ bí a kò bá bá ẹni tí a lé kúrò náà lò lọ́nà tí ó níyì. Àwọn olùṣàbójútó tí ń ṣiṣẹ́ lórí èyí gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe lè jábọ̀ “ìhìn-iṣẹ́ lílekoko náà kí ó baà lè ṣe kedere, kí ó ṣe ṣókí, kí ó sì bá ìlànà iṣẹ́ mu, láìtàbùkù sí iyì ẹni náà,” ni ìwé-ìròyìn The Vancouver Sun ròyìn. Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo ènìyàn ni ó tọ́ kí a bálò lọ́nà tí ó níyì.
Ìgbìmọ̀ Olùjíròrò Gíga Jùlọ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo pé: “Gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni a bí lómìnira tí wọ́n sì ní iyì àti ẹ̀tọ́ dídọ́gba. A fi ìrònú àti ẹ̀rí-ọkàn bùn wọ́n, wọ́n sì níláti fi ẹ̀mí jíjẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará hùwà sí ara wọn.” Níwọ̀n bí iyì ẹ̀dá ti wà lábẹ́ ìgbéjàkò, pẹ̀lú ìdí rere ni Òfin-Ìdásílẹ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ọ̀rọ̀-àkọ́sọ fún Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé fi dá ànímọ́ yìí mọ̀. Wọ́n tẹnumọ́ “ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣíṣepàtàkì, nínú iyì àti ìtóye ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan.”
Jehofa Dá Iyì Mọ́ Ènìyàn
Jehofa jẹ́ Ọlọrun tí ó níyì. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ní ìmísí sọ lọ́nà tí ó tọ̀nà pé, “[Iyì] òun ọlá wà níwájú rẹ̀,” àti pé, “Ó gbé [iyì] rẹ̀ ka orí àwọn ọ̀run.”—1 Kronika 16:27; Orin Dafidi 8:1.
Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun tí ó níyì àti Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, ó fi iyì jíǹkí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀, ti ọ̀run àti ti ilẹ̀-ayé. Ẹni tí ó tayọ jùlọ nínú irú àwọn tí ó bọlá fún lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ṣe lógo tí ó sì ń jọba, Ọba náà, Kristi Jesu. Dafidi kọ̀wé lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “[Iyì] àti ọlá ńlá ni ìwọ fi síi lára.”—Orin Dafidi 21:5; Danieli 7:14.
Ó baninínújẹ́ pé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣíṣekókó yìí ni a ti ṣìlò púpọ̀púpọ̀ jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn. Angẹli alágbára kan, tí ó tipasẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ di Satani Eṣu, gbé ìpèníjà dìde sí jíjẹ́ ẹ̀tọ́, òdodo, àti yíyẹ ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ó fi àìlọ́wọ̀ hàn fún Jehofa ó sì ṣàìbọlá fún orúkọ Rẹ̀ tí ó níyì bí ó ti ń pe ẹ̀tọ́ Rẹ̀ láti ṣàkóso níjà. Ó fi èrú gba iyì tí ó rékọjá ààlà fún araarẹ̀. Bíi ti Eṣu, àwọn ọba ènìyàn olùṣàkóso lílágbára, bíi Nebukadnessari ti ìgbà tí a kọ Bibeli, ti fi “líle agbára àti ọlá ńlá” wọn yangàn. Wọ́n ti gbéjàko iyì Jehofa, ní bíbuyì tí kò bọ́gbọ́nmu fún araawọn. (Danieli 4:30) Ìṣàkóso atẹnilóríba ti Satani, tí a gbékarí ayé aráyé ní kàn-ńpá, ti gbéjàko iyì ènìyàn ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó.
A ha ti ṣèpalára fún iyì rẹ rí bí? Nígbà tí a fún ọ ní ìmọ̀ràn, a ha ti mú ọ nímọ̀lára ẹ̀bi, ìtìjú, ẹ̀tẹ́, tàbí ìrẹ̀nípòwálẹ̀ lọ́nà tí ó rékọjá ààlà bí? “Èmi kò rí ìdàníyàn, ìyọ́nú, àti iyì. A mú mi nímọ̀lára àìníláárí,” ni André jẹ́wọ́, ó fikún un pé: “Èyí yọrísí àwọn ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ àti àníyàn, àní ìsoríkọ́ pàápàá.” Laura sọ pé: “Ó ṣòro láti gba ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan tí o nímọ̀lára pé kò ni ire rẹ dídára jùlọ lọ́kàn.”
Fún ìdí yìí, àwọn Kristian alábòójútó ni a fún ní ìṣílétí láti bójútó agbo Ọlọrun pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ọlá. (1 Peteru 5:2, 3) Bí àwọn ipò-ọ̀ràn bá dìde nínú èyí tí ó ti pọ̀ndandan tí ó sì ṣàǹfààní láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìmọ̀ràn, báwo ni ó ṣe lè dáàbòbo araarẹ kúrò nínú ìrònú àti ìwà àwọn ènìyàn ayé, tí wọ́n ń gbéjàko iyì àwọn ẹlòmíràn, láìlọ́tìkọ̀? Kí ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa iyì àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ, àti tìrẹ pẹ̀lú mọ́?—Owe 27:6; Galatia 6:1.
Àwọn Ìlànà Tí Ń Pa Iyì Mọ́
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò panumọ́ lórí kókó-ẹ̀kọ́ yìí. Olùgbaninímọ̀ràn kan tí ó jáfáfá yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kàkà kí ó yíjú sí ọgbọ́n ayé yìí. Ìwé Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ ní ìmọ̀ràn ṣíṣeyebíye nínú. Nígbà tí a bá tẹ̀lé wọn, wọ́n ń buyì fún olùgbaninímọ̀ràn àti ẹni náà tí a ń fún ní ìtọ́ni. Nípa báyìí, ìtọ́sọ́nà Paulu fún Kristian alábòójútó náà Timoteu ni pé: “Máṣe bá alàgbà wí, ṣùgbọ́n kí o máa gbà á níyànjú bíi baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin; àwọn àgbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.” (1 Timoteu 5:1, 2) Ẹ wo bí ìkárísọ, ìmọ̀lára tí a kẹ́dùn bá, àti ìkójútìbáni tí a lè yẹra fún yóò ti pọ̀ tó bí a bá kọbiara sí àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n wọ̀nyí!
Ṣàkíyèsí pé kọ́kọ́rọ́ náà sí ìgbaninímọ̀ràn yíyọrísírere ni ọ̀wọ̀ yíyẹ fún ẹnìkejì àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ pé kí a báa lò lọ́nà tí ó níyì, tí ó fi ìbìkítà hàn. Àwọn Kristian alàgbà, títíkan àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, níláti sakun láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ní wíwá ọ̀nà láti pinnu ìdí tí ẹni tí ó nílò àtúnṣebọ̀sípò náà fi ronú tí ó sì gbégbèésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe. Wọ́n gbọ́dọ̀ fẹ́ láti gbọ́ ojú ìwòye rẹ̀, kí wọ́n sì sapá ní gbogbo ọ̀nà láti yẹra fún dídójútini, rírẹnisílẹ̀, tàbí bíbẹ̀tẹ́ lu ẹni náà tí wọ́n ń ràn lọ́wọ́.
Gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan, jẹ́ kí arakúnrin rẹ mọ̀ pé o bìkítà o sì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ìṣòro rẹ̀. Ohun tí dókítà dídára kan máa ń ṣe nìyẹn nígbà tí o bá ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì rẹ̀ fún àyẹ̀wò ìlera. Èrò nípa bíbọ́rasílẹ̀ nínú iyàrá títutù, tí ó parọ́rọ́ kan lè kótìjú bá ọ kí o sì nímọ̀lára ìtẹ́lógo. Wo bí ìwọ ti mọrírì dókítà kan tí ó fi ẹ̀mí-ìmọ̀lára hàn fún iyì ara-ẹni rẹ̀ tí ó sì buyì fún ọ pẹ̀lú aṣọ ìbora kan nígbà tí ó ń ṣe àyẹ̀wò pípọndandan náà láti pinnu okùnfà àmódi rẹ tó! Ní irú ọ̀nà kan-náà, Kristian olùgbaninímọ̀ràn kan tí ó fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún ẹnìkan jẹ́ onínúure àti adúróṣinṣin, síbẹ̀ ó ń fi iyì wọ olùgbàmọ̀ràn náà láṣọ. (Ìfihàn 2:13, 14, 19, 20) Ní ìdàkejì, ìmọ̀ràn lílekoko, títutù, tí kò fi ìmọ̀lára hàn dàbí bíbọ́niláṣọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tí ń mú kí o nímọ̀lára ìtìjú, ẹ̀tẹ́, àti pé a fi iyì dù ọ́.
Àwọn alábòójútó Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ní pàtàkì máa ń ṣọ́ra láti fúnni ní ìmọ̀ràn lọ́nà tí ó níyì. Nígbà tí wọ́n bá ń fún àwọn àgbàlagbà nímọ̀ràn, wọ́n máa ń fi irú ìfẹ́ kan-náà tí wọn yóò fihàn fún àwọn òbí wọn nípa ti ara hàn. Wọ́n ní ìgbatẹnirò, wọ́n níwà-bí-ọ̀rẹ́, wọ́n sì lọ́yàyà. Irú ẹ̀mí-ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ pọndandan. Ó ń pèsè àyíká kan tí ń ṣèrànlọ́wọ́ fún fífúnni ní ìmọ̀ràn àti gbígbà á lọ́nà yiyẹ.
Ẹ̀yin alàgbà, ẹ fi sọ́kàn pé ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ ń gbeniga, ó ń fúnni níṣìírí, ó ń gbéniró, ó sì ń ṣàǹfààní. Efesu 4:29 ṣàlàyé pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó dára fún ẹ̀kọ́, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́.”
Kò sí ìdí fún lílo àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀, ọ̀nà ìgbà sọ̀rọ̀, tàbí ìrònú lílekoko. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀wọ̀ fún ẹnìkejì náà àti ìfẹ́-ọkàn láti pa ìmọ̀lára ìtóye àti iyì rẹ̀ mọ́ yóò sún ọ láti gbé àwọn ọ̀ràn kalẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́, tí ń gbéniró. Fi ìgbóríyìn olótìítọ́-inú, tí ó jẹ́ ojúlówó fún àwọn kókó tàbí ànímọ́ rẹ̀ dídára bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-àkíyèsí èyíkéyìí dípò títẹnumọ́ àwọn ojú-ìwòye tí yóò mú kí o nímọ̀lára ìjákulẹ̀ àti àìníláárí. Bí ìwọ bá ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan, lo ‘ọlá-àṣẹ rẹ láti gbéniró kìí ṣe láti biniṣubú.’—2 Korinti 10:8.
Bẹ́ẹ̀ni, ìyọrísí ìmọ̀ràn èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristian alábòójútó níláti jẹ́ láti fúnni ní ìṣírí tí a nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fúnni. Kò níláti múnirẹ̀wẹ̀sì tàbí ‘dẹ́rùbani.’ (2 Korinti 10:9) Kódà ẹni tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo pàápàá ni a níláti fi ìwọ̀n ọ̀wọ̀ ara-ẹni àti iyì fún. A gbọ́dọ̀ mú kí ìmọ̀ràn wàdéédéé pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìbáwí onínúure, síbẹ̀ kí ó dúrósinṣin, láti lè sún un sí ìrònúpìwàdà.—Orin Dafidi 44:15; 1 Korinti 15:34.
Lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì, Òfin Ọlọrun fún Israeli kó àwọn ìlànà kan-náà wọ̀nyí mọ́ra. Ó fàyègba ìmọ̀ràn àti ìbáwí ti ara-ìyára pàápàá, nígbà tí ó jẹ́ pé lẹ́sẹ̀kan náà ó ń pa ẹ̀tọ́ ẹnìkan mọ́ dé ìwọ̀n fífún un ní iyì ti ara-ẹni kan. Nínanilẹ́gba ‘ní iye kan gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú ẹni náà’ ni a fàyègbà, ṣùgbọ́n èyí kò gbọ́dọ̀ rékọjá ààlà. A pààlà sí iye ẹgba tí a óò fi nani kí oníwà-àìtọ́ náà má baà “di gígàn” nítòótọ́.—Deuteronomi 25:2, 3.
Ìdàníyàn fún ìmọ̀lára oníwà-àìtọ́ tí ó fi ìrònúpìwàdà hàn tún jẹ́ àmì-ànímọ́ Jesu. Nípa rẹ̀, Isaiah sọtẹ́lẹ̀ pé: “Iyè fífọ́ ni òun kì yóò ṣẹ́, òwú tí ń rú èéfín ni òun kì yóò pa: yóò mú ìdájọ́ wá sí òtítọ́.”—Isaiah 42:3; Matteu 12:17, 20; Luku 7:37, 38, 44-50.
Èyí tí ó tún tẹnumọ́ àìní náà síwájú síi fún ẹ̀mí-ìfọ̀rànrora-ẹni ni àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nínú Ìwàásù Lórí Òkè: “Nítorí náà gbogbo ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́.” (Matteu 7:12) Ìlànà yìí ṣekókó tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ fún gbígbé ipò-ìbátan rere lárugẹ tí a fi ń pè é ní Òfin Oníwúrà lọ́nà wíwọ́pọ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Kristian alàgbà kan, báwo ni ó ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá àwọn ẹlòmíràn lò pẹ̀lú inúrere àti iyì nígbà tí ó ba ń fúnni nímọ̀ràn?
Fi sọ́kàn pé ìwọ pẹ̀lú ń ṣe àwọn àṣìṣe. Gẹ́gẹ́ bí Jakọbu ti kíyèsi, “nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣì í ṣe.” (Jakọbu 3:2) Rírántí èyí yóò ṣèrànlọ́wọ́ láti pẹ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀-àkíyèsí rẹ kí o sì ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ nígbà tí ó bá pọndandan láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa àwọn àìdójú-ìwọ̀n wọn. Mọ ẹ̀mí-ìmọ̀lára wọn dájú. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìfòfíntótó bániwí tí ó rékọjá ààlà, tí ń darí àfiyèsí sí àwọn àṣìṣe tàbí àléébù wọn tí kò ṣe pàtàkì. Jesu tẹnumọ́ èyí nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ máṣe dáni ní ẹjọ́, kí a má baà dá yín ní ẹjọ́. Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni a ó fi wọ̀n fún yín.”—Matteu 7:1, 2.
Buyì fún Àwọn Ẹlòmíràn—Dojúùjàkọ Eṣu
Satani wéwèé àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀ láti gba iyì kúrò lọ́wọ́ rẹ, láti mú àwọn ìmọ̀lára jíjẹ́ ẹni ẹ̀tẹ́, aláìníláárí, àti àìnírètí jáde. Ṣàkíyèsí bí ó ti lo ènìyàn kan gẹ́gẹ́ bí aṣojú láti ru àwọn èrò-ìmọ̀lára òdì sókè nínú Jobu olùṣòtítọ́. Elifasi alágàbàgebè jẹ́wọ́ pé: “Òun [Jehofa] kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn angẹli rẹ̀ ni ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀. Áḿbọ̀tórí àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀ [àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀], ẹni tí ìpilẹ̀ wọn jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.” (Jobu 4:18, 19) Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ìníyelórí Jobu níwájú Ọlọrun kò ju ti kòkòrò kan lọ. Nítòótọ́, bí ìmọ̀ràn Elifasi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti jìnnà pátápátá sí èyí tí ń gbéniró, ìbá ti mú kí Jobu pàdánù iyè-ìrántí àwọn àkókò tí nǹkan sàn jù pàápàá. Lójú ìwòye tiwọn ìṣòtítọ́ rẹ̀ àtijọ́, ìdálẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ̀, ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun, àti àwọn ẹ̀bùn àánú rẹ̀ kò jámọ́ nǹkankan.
Bákan náà lónìí, àwọn oníwà-àìtọ́ tí wọ́n ronúpìwàdà ní wọ́n tètè máa ń ní irúfẹ́ ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ jùlọ, ewu sì wà pé kí wọ́n di ẹni tí ‘ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ bòmọ́lẹ̀.’ Ẹ̀yin alàgbà, nígbà tí ẹ bá ń fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nímọ̀ràn, “ẹ fi ìfẹ́ yín hàn dájú” fún wọn nípa fífàyègbà wọ́n láti máa ní ìwọ̀n iyì kan nìṣó. (2 Korinti 2:7, 8) William gbà pé: “Àìbánilò lọ́nà tí ó níyì máa ń mú kí ó nira láti gba ìmọ̀ràn.” Ó ṣekókó pé kí a mú ìgbàgbọ́ wọn lókun pé wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọrun. Rán wọn létí pé Jehofa “kìí ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ [wọn] àti ìfẹ́ tí [wọ́n] fihàn sí orúkọ rẹ̀” lákòókò àwọn ọdún iṣẹ́-ìsìn ìṣòtítọ́ wọn tí ó ti kọjá.—Heberu 6:10.
Àwọn kókó-abájọ mìíràn wo ní àfikún ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti buyì fún àwọn ẹlòmíràn nígbà tí o bá ń fúnni nímọ̀ràn? Mọ̀ pé gbogbo ènìyàn ni ó lẹ́tọ̀ọ́ sí iyì lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, níwọ̀n bí a ti dá wọn ní àwòrán Ọlọrun. Wọ́n ṣeyebíye lójú Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi; ìpèsè alápá méjì ti ìràpadà àti àjíǹde jẹ́rìí sí òtítọ́ yẹn. Jehofa buyì fún àwọn Kristian síwájú síi nípa “yíyàn [wọ́n] sí iṣẹ́ rẹ̀,” ní lílò wọ́n láti pàrọwà fún ìran búburú kan láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun.—1 Timoteu 1:12.
Ẹ̀yin alàgbà, ẹ rántí pé èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn Kristian arákùnrin yín ń fojúsọ́nà láti jẹ́ mẹ́ḿbà ìpilẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn titun nínú ayé tí a fọ̀mọ́ náà. Gẹ́gẹ́ bí irú ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ṣeyebíye tí ó sì jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀, wọ́n tọ́ sí fífi ọlá fún. Nígbà tí ó bá ń fúnni nímọ̀ràn, rántí bí Jehofa àti Jesu ṣe fi ìgbatẹnirò hàn fún wọn, sí máa báa nìṣó láti máa ṣe ipa tìrẹ láti ran àwọn arákùnrin rẹ lọ́wọ́ láti máa ní ìmọ̀lára jíjẹ́ ẹni tí ó níyì àti ìtóye ti ara-ẹni nìṣó lójú àwọn ìpèníjà Satani.—2 Peteru 3:13; fiwé 1 Peteru 3:7.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìmọ̀ràn Tí Ń Buyì Fúnni
(1) Fúnni ní ìgbóríyìn tí ó jẹ́ ojúlówó àti olótìítọ́-inú. (Ìfihàn 2:2, 3)
(2) Jẹ́ olùfetísílẹ̀ rere. Fi inúrere dá ìṣòro àti ìdí fún ìmọ̀ràn náà mọ́ lọ́nà ṣíṣe kedere. (2 Samueli 12:1-14; Owe 18:13; Ìfihàn 2:4)
(3) Gbé ìmọ̀ràn rẹ karí Ìwé Mímọ́. Jẹ́ olùfojúsọ́nà fún rere, olùgbatẹnirò, àti afúnni níṣìírí, kí o sì fi ìfọ̀rànrora-ẹni-wò hàn. Máṣe tàbùkù sí iyì àti ìtóye ara-ẹni olùgbàmọ̀ràn. (2 Timoteu 3:16; Titu 3:2; Ìfihàn 2:5, 6)
(4) Mú kí ó dá olùgbàmọ̀ràn lójú pé ìbùkún ń ti inú gbígba ìmọ̀ràn náà àti fífi í sílò wá. (Heberu 12:7, 11; Ìfihàn 2:7)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ó yẹ kí àwọn Kristian alàgbà buyì fún àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n bá ń fúnni ní ìmọ̀ràn