Gbogbo Èèyàn Yóò Di Ẹni Iyì
“A gbọ́dọ̀ dá àwùjọ tuntun kan sílẹ̀, èyí tó dára gan-an ju ti ìsinsìnyí lọ, táwọn èèyàn á ti máa fọ̀wọ̀ fún ọmọnìkejì wọn.”—ÀÀRẸ AMẸ́RÍKÀ, HARRY TRUMAN, ÌPÍNLẸ̀ SAN FRANCISCO, CALIFORNIA, AMẸ́RÍKÀ, APRIL 25, 1945.
ÈRÒ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ni ààrẹ Truman náà ní. Ó gbà pé aráyé lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn kí wọ́n sì dá “àwùjọ tuntun kan” sílẹ̀, táwọn èèyàn á ti máa fi ọ̀wọ̀ fún ọmọnìkejì wọn. Àmọ́, ó báni nínú jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní yàtọ̀ síyẹn pátápátá. Àwọn èèyàn kì í buyì fún ọmọnìkejì wọn rárá. Ìdí ni pé àtọ̀dọ̀ èèyàn kọ́ ni ìṣòro náà ti wá, àtọ̀dọ̀ ẹ̀dá kan tó jẹ́ ọ̀tá èèyàn ni.
Ohun Tó Fa Ìṣòro Náà
Bíbélì pe ọ̀tá tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ní Sátánì Èṣù, ẹ̀dá ẹ̀mí búburú kan. Látìbẹ̀rẹ̀ ìran èèyàn ni kò ti fẹ́ kí Ọlọ́run ṣàkóso wọn. Àtìgbà tí Sátánì ti bá Éfà sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni Sátánì ti ní in lọ́kàn pé òun ò ní jẹ́ kí ọmọ aráyé sin Ẹlẹ́dàá wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Tiẹ̀ ronú ná nípa bí ìyọnu tó bá Ádámù àti Éfà ti pọ̀ tó nígbà tí wọ́n fara mọ́ ohun tí Èṣù sọ fún wọn! Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní gbàrà tí wọ́n ṣàìgbọràn sí òfin tí Ọlọ́run fún wọn ni pé, àwọn méjèèjì “lọ fara pa mọ́ kúrò ní ojú Jèhófà Ọlọ́run.” Kí nìdí? Ádámù jẹ́wọ́ pé: “Àyà fò mí nítorí pé mo wà ní ìhòòhò nítorí náà mo fi ara mi pa mọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-10) Àjọṣe tó wà láàárín Ádámù àti Bàbá rẹ̀ ọ̀run àti ojú tó fi ń wo ara rẹ̀ wá yí padà. Ìtìjú bá a, ara rẹ̀ kò sì balẹ̀ mọ́ nígbà tó ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀.
Kí nìdí tí Èṣù kò fi fẹ́ kí Ádámù níyì mọ́? Ìdí ni pé àwòrán Ọlọ́run la dá èèyàn, inú Sátánì á sì dùn láti rí i kí èèyàn máa hùwà lọ́nà tó máa tàbùkù sí gbígbé tó ń gbé ògo Ọlọ́run yọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Róòmù 3:23) Èyí jẹ́ ká lóye ìdí tí fífi àbùkù kan èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni fi wọ́pọ̀ gan-an nínú ìtàn aráyé. Nítorí pé Sátánì ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” ó ti ń gbé ìwà yìí lárugẹ látìgbà “tí ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 4:4; Oníwàásù 8:9; 1 Jòhánù 5:19) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn ò lè níyì mọ́ títí láé?
Jèhófà Máa Ń Pọ́n Àwọn Ẹ̀dá Rẹ̀ Lé
Dá ọkàn rẹ padà sí bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì kí Ádámù àti Éfà tó dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ, iṣẹ́ tó ń fún wọn láyọ̀, wọ́n sì tún nírètí pé àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa gbé ìgbé ayé àlàáfíà tí kò sì ní nípẹ̀kun. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé wọn ló fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì pọ́n wọn lé.
Ǹjẹ́ ojú tí Jèhófà fi ń wo iyì ọmọ èèyàn yí padà nígbà tí Ádámù àti Éfà di aláìpé? Rárá o. Ó gba tiwọn rò nítorí pé wọ́n wà ní ìhòòhò, ojú sì ń tì wọ́n. Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè ‘ẹ̀wù awọ gígùn’ láti fi rọ́pò ewé ọ̀pọ̀tọ́ tí wọ́n gán pọ̀ tí wọ́n fi ṣe bàǹtẹ́ fún ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 21) Kàkà kí Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ nínú ìtìjú wọn, ńṣe ló pọ́n wọn lé.
Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jèhófà ń bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò, ó fi àánú hàn sáwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó àtàwọn àjèjì. Irú àwọn wọ̀nyí sì làwọn èèyàn máa ń hùwà ìkà sí láwùjọ. (Sáàmù 72:13) Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe padà lọ pèéṣẹ́ oko wọn nígbà tí wọ́n bá ti kórè ọkà ólífì àti àjàrà oko wọn. Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn pé ‘àwọn àtìpó, àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti àwọn opó’ làwọn irè oko tó ṣẹ́ kù sórí igi wọ̀nyẹn wà fún. (Diutarónómì 24:19-21) Bí wọ́n bá tẹ̀lé òfin wọ̀nyí, kò ní jẹ́ káwọn èèyàn máa ṣagbe, á sì jẹ́ kí iṣẹ́ tó pọ́n èèyàn lé wà fáwọn tó tiẹ̀ kúṣẹ̀ẹ́ pàápàá.
Jésù Pọ́n Àwọn Èèyàn Lé
Nígbà tí Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ó ka àwọn èèyàn sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà ní Gálílì, ọkùnrin kan tó ní ẹ̀tẹ̀ tó burú gan-an wá bá a. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Òfin Mósè wí, kí àrùn yìí má bàa ran ẹlòmíràn, adẹ́tẹ̀ náà ní láti máa kígbe pé: “Aláìmọ́, aláìmọ́!” (Léfítíkù 13:45) Àmọ́, ọkùnrin yìí kò kígbe ìkìlọ̀ kankan bó ṣe ń sún mọ́ ọ̀dọ̀ Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dojú bolẹ̀ tó sì bẹ Jésù pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” (Lúùkù 5:12) Kí ni Jésù ṣe? Jésù kò bá ọkùnrin náà wí pé ó rú Òfin Mósè, bẹ́ẹ̀ ni kò pa á tì tàbí kó yẹra fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pọ́n adẹ́tẹ̀ náà lé, ó fọwọ́ kàn án ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.”—Lúùkù 5:13.
Láwọn ìgbà mìíràn, Jésù máa ń fi agbára tó ní láti woni sàn hàn láìfọwọ́ kan ẹni náà rárá, ó sì máa ń woni sàn láti òkèrè nígbà míì. Àmọ́ ní ti ọkùnrin adẹ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló fọwọ́ kàn án. (Mátíù 15:21-28; Máàkù 10:51, 52; Lúùkù 7:1-10) Nítorí pé ọkùnrin yìí “kún fún ẹ̀tẹ̀,” á ti pẹ́ gan-an tẹ́nì kan ti fara kàn án gbẹ̀yìn. Ẹ ò rí i pé ìtura ńlá ló jẹ́ fún un nígbà tí ẹnì kan tún padà fọwọ́ kàn án! Ohun tó ń retí ni pé kí Jésù kàn wo ẹ̀tẹ̀ òun sàn, kò tiẹ̀ retí pé kó fọwọ́ kan òun rárá. Àmọ́ ọ̀nà tí Jésù gbà wò ó sàn jẹ́ kó tún dẹni tó níyì lọ́wọ́ ara rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé bíbuyì féèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni bí irú èyí lè ṣẹlẹ̀ láwùjọ wa lónìí? Bó bá lè ṣẹlẹ̀, ọ̀nà wo lèèyàn á gbà ṣe é?
Òfin Pàtàkì Tó Ń Mú Káwọn Èèyàn Fọ̀wọ̀ fún Ẹlòmíràn
Jésù sọ ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí ìtọ́ni tó ṣe pàtàkì jù lọ nípa àjọṣe ẹ̀dá èèyàn, ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Òfin pàtàkì yìí ń mú ká bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa, nítorí pé àwa náà fẹ́ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún wa.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn fi hàn, kò rọrùn láti tẹ̀ lé òfin pàtàkì yẹn ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé òdìkejì rẹ̀ gan-an láwọn èèyàn máa ń ṣe. Ọkùnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Harold sọ pé: “Kíkan àwọn èèyàn lábùkù máa ń múnú mi dùn gan-an. Gbólóhùn kan lásán tí mo bá sọ lè mú kí ọkàn wọn bà jẹ́, kí ìtìjú bá wọn, nígbà mìíràn ó tiẹ̀ lè mú kí wọ́n sunkún.” Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Harold jáwọ́ nínú fífi àbùkù kan àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ mi. Nígbà tí mo bá ronú padà sẹ́yìn, ojú máa ń tì mí nípa ohun tí mo ti sọ sí wọn àti ìwà tí mo hù sí wọn láwọn ìgbà kan. Àmọ́ wọn ò pa mí tì, díẹ̀díẹ̀, òtítọ́ látinú Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn ó sì mú kí n yí padà.” Lónìí, alàgbà ni Harold nínú ìjọ Kristẹni.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Harold fi hàn pé lóòótọ́ ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti wọnú ọkàn ẹni kó sì yí èrò àti ìwà ẹni padà. Ohun tó ń mú kéèyàn máa fọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni ni ìfẹ́ àtọkànwá láti ran ẹnì kejì ẹni lọ́wọ́ dípò kéèyàn máa bà á nínú jẹ́, àti ìfẹ́ téèyàn ní láti bọlá fún un dípò kéèyàn máa kàn án lábùkù.—Ìṣe 20:35; Róòmù 12:10.
Àwọn Èèyàn Yóò Máa Fọ̀wọ̀ fún Ọmọnìkejì Wọn Bó Ṣe Yẹ
Ìfẹ́ láti ran ọmọnìkejì wọn lọ́wọ́ ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa sọ fáwọn èèyàn nípa ìrètí àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì. (Ìṣe 5:42) Kò sí ọ̀nà mìíràn téèyàn lè gbà bọ̀wọ̀ fún èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kó sì buyì fún un ju kó sọ “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fún un. (Aísáyà 52:7) “Ohun tí ó dára jù” yẹn kan gbígbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, èyí tí yóò pa ‘ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́’ tó máa ń mú kéèyàn fẹ́ fàbùkù kan èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (Kólósè 3:5-10) Ohun tí ó dara jù tá à ń wí yìí tún kan ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe láìpẹ́ láti mú gbogbo ohun tó ń kó àbùkù bá ọmọ aráyé kúrò, títí kan Sátánì Èṣù tó dá gbogbo aburú wọ̀nyí sílẹ̀. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 20:1, 2, 10) Ìgbà tí ilẹ̀ ayé bá “kún fún ìmọ̀ Jèhófà” làwọn èèyàn á tó máa fọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn bó ṣe yẹ.—Aísáyà 11:9.
A rọ̀ ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun àgbàyanu tá à ń retí yìí. Tó o bá ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́, wàá rí i pé fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò máa ń mú kéèyàn bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni. Wàá sì tún kọ́ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú ‘àwùjọ tuntun kan tó dára ju ti ìsinsìnyí lọ’ wá láìpẹ́, ìyẹn àwùjọ kan táwọn èèyàn á ti máa “fi ọ̀wọ̀ fún ọmọnìkejì wọn,” níbi táwọn èèyàn kò ti ní fojú èèyàn bíi tiwọn gbolẹ̀ mọ́.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Híhu Ìwà Títọ́ Fi Hàn Pé Ẹni Iyì Ni Wọ́n
Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gemma La Guardia Gluck tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí ní àgọ́ Ravensbrück sọ nípa ọ̀nà títayọ táwọn Ẹlẹ́rìí gbà fi hàn pé àwọn jólóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ó sọ nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ My Story pé: “Nígbà kan, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó ń jẹ́ Gestapo kéde pé Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyíkéyìí tó bá sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó sì fọwọ́ síwèé pé òun ṣe bẹ́ẹ̀ ni a ó dá sílẹ̀ a ò sì ní ṣenúnibíni sí i mọ́.” Ohun tí obìnrin náà sọ nípa àwọn tó kọ̀ tí wọn ò fọwọ́ síwèé náà ni pé: “Wọ́n yàn láti máa jìyà lọ kí wọ́n sì máa fi sùúrù dúró de ayé tuntun.” Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Magdalena, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún báyìí, ṣàlàyé pé: “Jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ṣe pàtàkì ju dídá ẹ̀mí wa sí lọ́nàkọnà. Híhu ìwà títọ́ fi hàn pé a fi ọ̀wọ̀ wọ ara wa.”a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-ìṣọ́nà March 1, 1986, ojú ìwé 10-15 kó o lè túbọ̀ mọ nípa ìdílé Kusserow.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Jésù pọ́n àwọn tó wò sàn lé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń buyì fáwọn èèyàn nípa sísọ “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fún wọn