Àwọn Èèyàn Kì Í Buyì Fáwọn Èèyàn Ẹlẹgbẹ́ Wọn
“Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ló ń fàbùkù kan ọmọ èèyàn.”—MAGDALENA KUSSEROW REUTER, ẸNI TÓ YÈ BỌ́ NÍNÚ ÀGỌ́ ÌṢẸ́NINÍṢẸ̀Ẹ́ ÌJỌBA NÁSÌ.
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé àbùkù tí wọ́n fi kan àwọn èèyàn ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì burú jáì, síbẹ̀ fífi àbùkù kan ọmọ èèyàn ti wà tipẹ́ kò sì tíì dáwọ́ dúró títí dòní. Tá a bá ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tàbí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ohun kan tó dájú ni pé: “Fífi àbùkù kan ọmọ èèyàn” ti wà tipẹ́tipẹ́ ó sì ti fìyà jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn.
Àmọ́ ṣá o, fífi ojú àwọn èèyàn gbolẹ̀ kò mọ sáwọn ìwà ìkà tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ tún máa ń wáyé láwọn ọ̀nà tí kò fí bẹ́ẹ̀ hàn síta. Irú bíi káwọn kan máa fi ọmọ kan ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé ó lábùkù ara. Tàbí káwọn kan máa fi ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé àwọn àṣà rẹ̀ yàtọ̀. Tàbí kẹ̀ káwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀tanú ẹnì kan nítorí pé àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ tàbí nítorí orílẹ̀-èdè tó ti wá. Àwọn tí wọ́n ń hu irú ìwà yẹn lè rò pé eré lásán làwọn ń ṣe ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ àti ìtìjú tó máa ń kó bá àwọn tí wọ́n ń fàbùkù kàn kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá.—Òwe 26:18, 19.
Kí Ni Bíbuyì fún Èèyàn Ẹlẹgbẹ́ Ẹni Túmọ̀ Sí?
Jíjẹ́ ẹni iyì túmọ̀ sí kéèyàn jẹ́ ẹni tá a kà sí, ẹni táwọn èèyàn ń fojú tó dáa wò, tàbí ẹni tá a ń bọ̀wọ̀ fún. Nípa bẹ́ẹ̀, iyì ní í ṣe pẹ̀lú ojú tá a fi ń wo ara wa àti ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà bá wa lò. Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń nípa lórí ojú tá a fi ń wo ara wa. Àmọ́, ojú táwọn èèyàn fi ń wò wá tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá wa lò lohun tó kó ipa tó pọ̀ jù lọ lórí irú ẹni tá a ka ara wa sí.
Ibi gbogbo láyé ni àwọn tálákà wà àtàwọn tí kò lẹ́nu ọ̀rọ̀. Àmọ́, kì í ṣe wíwà ní irú ipò yẹn ni kì í jẹ́ kéèyàn ní iyì. Èrò àti ìwà àwọn èèyàn sí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ló ń tàbùkù sí iyì èèyàn. Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé àwọn tí nǹkan kò ṣẹnuure fún làwọn èèyàn máa ń fojú pa rẹ́ tí wọ́n sì máa ń fàbùkù kàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń gbọ́ táwọn èèyàn máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “aláìníláárí,” “ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan,” àti “alábùkù” láti fi ṣáátá àwọn arúgbó, àwọn tálákà, tàbí àwọn aláìsàn ọpọlọ tàbí àwọn aláàbọ̀ ara!
Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń fàbùkù kan àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn? Ǹjẹ́ ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á máa buyì fáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò fún wa ní ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.