ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 4/8 ojú ìwé 13
  • Ayé Kan Tí Sìgá Mímu Ti Di Bárakú Fún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Kan Tí Sìgá Mímu Ti Di Bárakú Fún
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Láti Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu?
    Jí!—2000
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
    Jí!—1996
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 4/8 ojú ìwé 13

Ayé Kan Tí Sìgá Mímu Ti Di Bárakú Fún

BILL jẹ́ onínúure, ọlọ́pọlọ pípé, gìrìpá ọkùnrin. Ó fẹ́ràn ìdílé rẹ̀. Ṣùgbọ́n o, kékeré ló ti bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá. Ó wá kórìíra àṣà yìí nígbà tó dàgbà tán. Àní bí èéfín sìgá ṣe ń rú túú lẹ́nu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fáwọn ọmọ ẹ̀ pé òun ò gbọ́dọ̀ rí sìgá lẹ́nu wọn, ó ní àṣàkáṣà ni. Àìmọye ìgbà ló ti fi ọwọ́ rẹ̀ tó le bí irin rún odindi páálí sìgá, táá fìbínú jù ú nù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan iyàrá, táá wá bẹ̀rẹ̀ sí lérí pé àmugbẹ̀yìn òun nìyẹn. Àmọ́, láìpẹ́ láìjìnnà, á tún bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá—á kọ́kọ́ máa yọ́ ọ mu, tó bá yá, gbangba òde lá ti máa mu ún.

Bill kú ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, àrùn jẹjẹrẹ ló pa á, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù ìrora gógó. Ká ní kò mu sìgá ni, bóyá ì bá ṣì wà láàyè lónìí. Bóyá ìyàwó rẹ̀ ì bá ṣì lọ́kọ; bóyá àwọn ọmọ rẹ̀ ì bá ṣì ní bàbá.

Ikú Bill gbo ìdílé rẹ̀ gan-an, àmọ́, irú ikú bẹ́ẹ̀ pọ̀ lọ jàra. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé àwọn àìsàn tí tábà ń fà ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn lọ́dọọdún, ìyẹn jẹ́ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní ìṣẹ́jú àáyá mẹ́jọ mẹ́jọ. Tábà lílò ni lájorí ohun tó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tí ń fa àìsàn lágbàáyé. Bó bá sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, ní ogún ọdún sígbà táa wà yìí, sìgá mímu ni yóò di òléwájú lára àwọn ohun tí ń ṣekú pani, tó sì ń sọni di olókùnrùn, yóò máa pa àwọn èèyàn púpọ̀ ju àrùn éèdì, ikọ́ ẹ̀gbẹ, ikú abiyamọ, jàǹbá ọkọ̀, ìpara ẹni, àti ìpànìyàn lọ, táa bá pa gbogbo rẹ̀ pọ̀.

Sìgá ń pààyàn. Bẹ́ẹ̀ rèé, kò síbi táwọn tó ń mu ún ò sí. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ó kéré tán, ó lé ní bílíọ̀nù kan èèyàn tó ń mu sìgá lágbàáyé. Ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo àwọn tó ti tójúúbọ́ lágbàáyé.

Àwọn alálàyé fojú díwọ̀n pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iléeṣẹ́ sìgá ń san ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù owó dọ́là fáwọn tó pè wọ́n lẹ́jọ́, owó ìdákọmu nìyẹn jẹ́, ní ìfiwéra pẹ̀lú èrè ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là tí ń wọlé fún wọn. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, iye sìgá táwọn iléeṣẹ́ sìgá ń ṣe lójoojúmọ́ pọ̀ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀. Kárí ayé, àwọn iléeṣẹ́ àdáni àtàwọn iléeṣẹ́ ìjọba tó ń ṣe sìgá ń ta iye tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún bílíọ̀nù sìgá lọ́dọọdún!

Kí ló dé tọ́pọ̀ èèyàn ranrí mọ́ àṣà gbẹ̀mígbẹ̀mí yìí? Bí ìwọ bá ń mu sìgá, báwo lo ṣe lè jáwọ́ ńbẹ̀? A óò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́