ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 5-8
  • Ṣé Ilẹ̀ Yúróòpù Lè Ṣọ̀kan Lóòótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ilẹ̀ Yúróòpù Lè Ṣọ̀kan Lóòótọ́?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésẹ̀ Nípa Ṣíṣọ̀kan Lórí Ọ̀ràn Owó
  • Àwọn Nǹkan Míì Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nípa Ọ̀ràn Owó
  • Àwọn Míì Fẹ́ Wọ Ẹgbẹ́ EU Lákọ̀tun
  • Ìkórìíra, Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni, àti Àìríṣẹ́ṣe
  • Ta Ni Olórí?
  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?
    Jí!—2000
  • Báwo Ni Ìwà Àwọn Èèyàn Ṣe Rí Láyé Ìsinyìí?
    Jí!—2000
  • Àìláàbò—Ìṣòro Tó Kárí ayé
    Jí!—1998
  • Ìṣòro Àìríṣẹ́ṣe
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 5-8

Ṣé Ilẹ̀ Yúróòpù Lè Ṣọ̀kan Lóòótọ́?

BÓ BÁ ṣòro fún ẹ láti gbà gbọ́ pé àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù ò fi ọ̀ràn ìṣọ̀kan yìí ṣeré, ìwọ sáà ti gbéra, kóo lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ńṣe làwọn èèyàn ń lọ fàlàlà káàkiri àwọn ilẹ̀ tó para pọ̀ jẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EU). Kò tún sí pé èèyàn ń dúró pẹ́ ní àwọn ẹnubodè orílẹ̀-èdè míì kó tó wọlé. Ó dájú pé inú àwọn arìnrìn-àjò dùn sí èyí—ṣùgbọ́n àwọn nìkan kọ́ ló ń jàǹfààní ẹ̀. Ní báyìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tó wà lára ẹgbẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù lè lọ kàwé ní èyíkéyìí lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU, wọ́n lè lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀, wọ́n tiẹ̀ lè dá iṣẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ pàápàá. Èyí sì ti mú kí ètò ọrọ̀ ajé àwọn tí kò lọ́rọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU gbé pẹ́ẹ́lí sí i.

Ó dájú pé ìyípadà pàtàkì gbáà ni rírọrùn tó rọrùn féèyàn láti lè sọdá sí orílẹ̀-èdè míì láìsí ìṣòro. Nígbà náà, ṣé ká kúkú sọ pé ilẹ̀ Yúróòpù ti ṣọ̀kan ni, pé kò sí ohun tó ń dènà ìṣọ̀kan mọ́? Rárá o, ìdíwọ́ ń bẹ níwájú rẹpẹtẹ, àwọn kan lára ìdíwọ́ náà sì ń múni lọ́kàn pami. Ṣùgbọ́n ká tó gbé wọn yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó lágbára jù tí wọ́n tíì gbé nípa ìṣọ̀kan yẹ̀ wò. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò lè lóye ìdí tí àwọn èèyàn fi ní ìrètí pé ìṣọ̀kan á dé.

Ìgbésẹ̀ Nípa Ṣíṣọ̀kan Lórí Ọ̀ràn Owó

Ọ̀ràn bíbójútó ètò ibodè lè ná orílẹ̀-èdè lówó tó pọ̀ gan-an. Nígbà kan, àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ EU máa ń ná nǹkan bíi bílíọ̀nù méjìlá owó yúrò lọ́dún lórí ọ̀ràn iṣẹ́ àwọn aṣọ́bodè. Abájọ tí mímú tí wọ́n mú nǹkan rọrùn báyìí ní àwọn ẹnubodè orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù fi jẹ́ kí ètò ọrọ̀ ajé gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Bóo bá ronú nípa bí mílíọ̀nù ọ̀ọ́dúnrún ó lé àádọ́rin èèyàn tó ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU ṣe ń lọ láti ibì kan sí òmíràn fàlàlà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jọ wà nínú ètò òwò àjùmọ̀ṣe, wàá rí i kedere pé ètò ọrọ̀ ajé wọ́n ń gbérí lọ́nà tó ta yọ. Kí ló mú kí irú ìtẹ̀síwájú yẹn ṣeé ṣe?

Ní February 1992, àwọn olórí ìjọba gbégbèésẹ̀ pàtàkì kan tó lè mú ìṣọ̀kan wá, wọ́n fọwọ́ sí ìwé Àdéhùn Nípa Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, tàbí Àdéhùn ti Maastricht. Àdéhùn náà fìpìlẹ̀ níní ètò òwò àjùmọ̀ṣe lélẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù, ṣíṣí báńkì àpapọ̀, àti níná oríṣi owó kan náà. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí wọ́n tún ṣe nǹkan pàtàkì míì, ìyẹn ni pé: kí wọ́n ṣe é kí iye tí wọ́n máa ń ṣẹ́ owó wọn sí yéé yí padà. Nítorí pé àìdúró sójú kan iye tí wọ́n ṣẹ́ owó sí lè mú káwọn tó ń ṣòwò rí èrè gidi jẹ lọ́jọ́ kan, kí èrè tọjọ́ kejì ẹ̀ má sì fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan.

Wọ́n mú ìṣòro tó ń dènà ìṣọ̀kan yìí kúrò nípa gbígbé Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìṣúnná Owó àti Ètò Ìnáwó (EMU) kalẹ̀, wọ́n sì tún ṣe owó yúrò jáde tí gbogbo wọn á máa ná. Ọ̀ràn nípa iye tí wọ́n ń ṣẹ́ owó sí ti wá kúrò wàyí, kò sì sí ìdààmú mọ́ nípa pé kí òwò wọn máà fọ́ nítorí ewu tó lè tìdí iye tí wọ́n ń ṣẹ́ owó sí wá. Àbájáde ẹ̀ ni pé wọn kì í da owó púpọ̀ sórí òwò mọ́, wọ́n sì túbọ̀ ń rí ṣe lọ́dọ̀ àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Tó bá sì yá, èyí lè mú kí iṣẹ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, kí àwọn èèyàn sì lè fowó ra nǹkan lọ́pọ̀kúyọ̀kú—ìyẹn á sì ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní.

Dídá tí wọ́n dá Báńkì Àpapọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù sílẹ̀ ní ọdún 1998 jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì míì sípa níná irú owó kan náà. Báńkì tó dá dúró yìí, tó wà ní ìlú Frankfurt, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ló làṣẹ lórí gbogbo ọ̀ràn owó tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè tó wà lára ẹgbẹ́ náà. Ó ń gbìyànjú láti máà jẹ́ kí ọjà wọ́n gógó ní àwọn ibi tí wọ́n pè ní agbègbè ilẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn ní àwọn orílẹ̀-èdè mọ́kànlá tó jùmọ̀ ń kópa nínú rẹ̀,a ó sì mú kí iye tí wọ́n ń ṣẹ́ owó yúrò, dọ́là, àti owó yen yéé yí padà látìgbàdégbà.

Nítorí náà, tó bá jẹ́ ní ti owó ni, wọ́n ti tẹ̀ síwájú gan-an sípa ìṣọ̀kan. Bó ti wù kó rí, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nípa ọ̀ràn owó tún ṣàpèjúwe bí àìṣọ̀kan ṣì ṣe rinlẹ̀ tó láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nípa Ọ̀ràn Owó

Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ nínú ẹgbẹ́ EU pẹ̀lú ní ìkùnsínú tiwọn. Wọ́n ronú pé àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ gan-an nínú ẹgbẹ́ náà kì í jẹ́ kí àwọn rí jẹ nínú ọrọ̀ wọn tó bó ti yẹ. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ náà tí kò gbà pé ó yẹ kí àwọn fowó ran àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù tí kò lọ́rọ̀, táwọn jọ ń ṣẹgbẹ́ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ gan-an náà lérò pé àwọn ní ìdí pàtàkì táwọn ò fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ti Jámánì yẹ̀ wò. Ìtara tí orílẹ̀-èdè yẹn ní láti máa náwó sórí ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù ti ń dín kú báyìí, pàápàá nísinsìnyí tí ẹrù ìnáwó tòun alára ti ga pelemọ. Owó tí wọ́n ń nìkan ná lórí mímú Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì ṣọ̀kan ò kéré, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún. Ìyẹn jẹ́ ìdá mẹ́rin iye tí orílẹ̀-èdè náà ń wéwèé láti ná lọ́dún! Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti mú kí gbèsè tí ìjọba ilẹ̀ Jámánì jẹ pọ̀ gan-an débi pé ilẹ̀ Jámánì ní láti sapá gan-an kó tó lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí ẹgbẹ́ EMU là sílẹ̀ fún orílẹ̀-èdè tó bá fẹ́ wọ ẹgbẹ́ wọn.

Àwọn Míì Fẹ́ Wọ Ẹgbẹ́ EU Lákọ̀tun

Ní kúkúrú, àwọn tó fara mọ́ níní oríṣi owó kan ṣoṣo retí pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU tí wọn ò tíì sí nínú ẹgbẹ́ EMU á borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní kó tó di ọdún 2002, nígbà tí wọ́n ń retí àtifowó wẹ́wẹ́ àti owó oníbébà yúrò rọ́pò owó táwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù ń ná lónìí. Bí Denmark, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti Sweden ò bá fọ̀ràn wíwọ ẹgbẹ́ falẹ̀, owó yúrò lè rọ́pò owó pound, kroner, àti kronor tiwọn.

Ní báyìí ná, àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fà míì láti ilẹ̀ Yúróòpù ń fẹ́ wọ ẹgbẹ́ EU. Àwọn orílẹ̀-èdè náà ni Estonia, Hungary, Kípírọ́sì, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, Poland, àti Slovenia. Orílẹ̀-èdè márùn-ún míì ń retí kí wọ́n mú àwọn náà wọ ẹgbẹ́, àwọn ni, Bulgaria, Latvia, Lithuania, Romania, àti Slovakia. Wọn ò lè wọ ẹgbẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́. Wọn ti fojú díwọ̀n pé láàárín ọdún 2000 sí 2006, ẹgbẹ́ EU ní láti kó ọgọ́rin bílíọ̀nù owó yúrò sílẹ̀ láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé mẹ́wàá náà láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù.

Ṣùgbọ́n, iye tí àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé náà ní láti ní lọ́wọ́ kí wọ́n baà lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí ẹgbẹ́ EU ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ wọ ẹgbẹ́ pọ̀ ju iye tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ EU lọ fíìfíì. Fún àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Hungary ní láti ná bílíọ̀nù méjìlá owó yúrò sórí títún àwọn ọ̀nà àti ojú irin rẹ̀ ṣe. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech yóò ná iye tó ju nǹkan bí bílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ owó yúrò lọ sórí títún omi ṣe nìkan, ilẹ̀ Poland sì gbọ́dọ̀ ná bílíọ̀nù mẹ́ta owó yúrò sórí dídín imí ọjọ́ tó ń tú sáfẹ́fẹ́ kù. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó fẹ́ wọ ẹgbẹ́ yìí lérò pé àǹfààní tó máa tibẹ̀ wá pọ̀ ju ohun tó máa ná àwọn lọ. Ohun kan dájú ṣá o, ìyẹn ni pé òwò tí wọ́n ń bá àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU ṣe á pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n, ó lè béèrè pé kí àwọn tó fẹ́ wọ ẹgbẹ́ yìí ṣì dúró fún ìgbà díẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú ti sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹ̀yìn ìgbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó ti wà nínú ẹgbẹ́ EU bá yanjú ọ̀ràn ìṣòro owó tiwọn ni wọ́n máa tó gba àwọn orílẹ̀-èdè míì wọlé.

Ìkórìíra, Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni, àti Àìríṣẹ́ṣe

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sapá púpọ̀ láti rí i pé ìṣọ̀kan pọ̀ sí i, ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ilẹ̀ Yúróòpù àti lẹ́yìn odi rẹ̀ ni ìdàgbàsókè Kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Bákan náà ni ọkàn ò balẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà, irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè Balkan tó pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—ogun Bosnia làkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, ogun Kosovo. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lára ẹgbẹ́ EU kì í fohùn ṣọ̀kan lórí bó ṣe yẹ kí wọ́n yanjú irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tó ń bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù àti àwọn ibòmíràn. Níwọ̀n bí ẹgbẹ́ EU kì í ti í ṣe àkójọ àwọn ìpínlẹ̀ tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà nínú rẹ̀ kò sì ní àkọsílẹ̀ ìlànà kan náà fún bíbá ilẹ̀ òkèèrè lò, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni sábà máa ń fara hàn. Ó hàn kedere nígbà náà pé, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni jẹ́ ìdènà ńlá fún ‘Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù.’

Ìṣòro míì tún ń yọ ilẹ̀ Yúróòpù lẹ́nu gidigidi, ìyẹn ni, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ríṣẹ́ ṣe. Ní ìpíndọ́gba, ìpín mẹ́wàá lára àwọn tó ti tó ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ni ò ríṣẹ́ ṣe. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn tí kò ríṣẹ́ ṣe níbẹ̀ lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ pé àwọn ló fẹ́rẹ̀ẹ́ kó ìdá mẹ́rin gbogbo àwọn olùgbé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU, ti sapá gan-an láti wá iṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn ò ríṣẹ́. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rò pé gbígbógun ti àìríṣẹ́ṣe tó pọ̀ yìí ni lájorí ìpèníjà tí ilẹ̀ Yúróòpù ní! Títí di báyìí, wọn ò tíì ṣàṣeyọrí nínú ìsapá wọn láti yanjú ìṣòro àìríṣẹ́ṣe.

Bó ti wù kó rí, ìdènà ńlá kan tún ṣì wà tó ń dènà ìṣọ̀kan o.

Ta Ni Olórí?

Ọ̀ràn ẹni tó nipò àṣẹ ṣì jẹ́ ìdènà tó tóbi jù lọ tó ń ṣàkóbá fún ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ náà gbọ́dọ̀ fohùn ṣọ̀kan lórí ìwọ̀n tó yẹ kí wọ́n fínnúfíndọ̀ yááfì ọ̀ràn gbígbé orílẹ̀-èdè wọn ga dé. Ète ẹgbẹ́ EU ni láti gbé ètò ìṣàkóso tí kò sí lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè kan pàtó kalẹ̀. Ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé, bí wọn ò bá lè ṣàṣeyọrí èyí, “àṣeyọrí tí ò tọ́jọ́” ni mímú ọ̀ràn ti owó yúrò wọ̀ ọ́ á wulẹ̀ jẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣòro fún àwọn orílẹ̀-èdè kan tó wà nínú ẹgbẹ́ náà láti jọ̀wọ́ agbára ìjẹgaba wọn. Fún àpẹẹrẹ, olórí ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EU sọ pé wọ́n “dá orílẹ̀-èdè òun láti jẹ́ olórí àwọn orílẹ̀-èdè ni, kì í ṣe láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn wọn.”

Abájọ tí àwọn orílẹ̀-èdè kéékèèké tó wà nínú ẹgbẹ́ náà fi ń bẹ̀rù pé bó bá yá, àwọn orílẹ̀-èdè ńlá á gba ipò àkóso, wọ́n á sì kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn ìpinnu tó bá lè jin ohun tí wọ́n ń fẹ́ lẹ́sẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn orílẹ̀-èdè kéékèèké ń ṣe kàyéfì nípa bí ẹgbẹ́ náà ṣe máa pinnu àwọn ilẹ̀ tí àwọn orílé-iṣẹ́ ẹgbẹ́ EU máa wà. Ìpinnu pàtàkì ni èyí jẹ́ nítorí pé bí àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyẹn bá wà ní orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn ibẹ̀ á túbọ̀ ríṣẹ́ ṣe.

Lójú gbogbo ìdènà tó ń jin ìṣọ̀kan lẹ́sẹ̀ wọ̀nyí—irú bí ètò ọrọ̀ ajé tó ń forí ṣánpọ́n, ogun, àìríṣẹ́ṣe, àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni—ó dà bí pé ó rọrùn láti gbà pé wọ́n ò múra sílẹ̀ tó lórí ọ̀ràn ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù. Bó ti wù kó rí, òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n ti ṣàṣeyọrí àrà ọ̀tọ̀. Ohun tí kò dájú ni bí ìtẹ̀síwájú tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò ṣe pọ̀ tó. Èyí tó pọ̀ jù lára ìṣòro táwọn tó ń gbìyànjú láti mú ilẹ̀ Yúróòpù ṣọ̀kan ń ní ni irú àwọn ìṣòro kan náà tó ń yọ gbogbo ìjọba èèyàn lẹ́nu.

Ǹjẹ́ yóò ṣeé ṣe láé kí ìjọba kan wà tó lè yanjú àwọn ìṣòro bí ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà, àìríṣẹ́ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn, ipò òṣì, àti ogun? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti ronú nípa ayé kan tí àwọn èèyàn á ti máa gbé pọ̀ níṣọ̀kan? Ìdáhùn tí àpilẹ̀kọ tó kàn máa dá lé lè yà ọ́ lẹ́nu.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn orílẹ̀-èdè náà ni Austria, Belgium, Finland, Faransé, Ireland, Ítálì, Jámánì, Luxembourg, Netherlands, Potogí, àti Sípéènì. Nítorí ìdí bíi mélòó kan, Denmark, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìsì, àti Sweden ò tíì sí lára wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Owó Yúrò Tẹ́ẹ Lẹ́ẹ̀ Mọ̀ Ré O!

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù á ṣì máa ná àwọn owó wẹ́wẹ́ àti owó oníbébà tó jẹ́ ti ilẹ̀ wọn títí di ọdún 2002, owó yúrò ni wọ́n fi ń ṣèṣirò àkọsílẹ̀ ọjà wọn. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni àwọn iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú owó jẹ́ fún àwọn báńkì. Ṣùgbọ́n, ní báyìí, iye kan pàtó ti wà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ náà fi ń ṣẹ́ owó wọn sí owó yúrò. Àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá pẹ̀lú ti ń fi owó yúrò ṣírò iye ìpín ìdókòwò wọn. Ọ̀pọ̀ ilé ìtajà àti àwọn oníṣòwò ti wá ń fi owó yúrò àti owó ilẹ̀ wọn díye lé ọjà.

Irú ọjà àjùmọ̀ná bẹ́ẹ̀ ń béèrè fún àwọn àtúnṣe kánmọ́kánmọ́—pàápàá lọ́wọ́ àwọn arúgbó tí ò ní lè ná owó deutsche mark, franc, tàbí lira wọn tí wọ́n ti mọ̀ dunjú mọ́. Kódà, wọ́n ní láti tún àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣírò ọjà ṣe, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tó ń dá gba owó tó sì ń sanwó fáwọn èèyàn. Láti lè mú kí ìyípadà náà dán mọ́rán dáadáa, wọ́n ti ṣètò láti ṣàlàyé fáwọn èèyàn nípa owó yúrò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà àti bí wọ́n á ṣe máa ná an.

Ohun yòówù kí àwọn ìdènà yòókù jẹ́, owó yúrò ti ń fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ká sọ tòótọ́, wọ́n tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹyọ owó yúrò àti owó yúrò oníbébà. Iṣẹ́ ńlá gbáà sì ni. Kódà ní orílẹ̀-èdè tó kéré bí Netherlands, tí àwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tó bá fi máa di January 1, 2002, á pé ọdún mẹ́ta gbáko tí àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe owó níbẹ̀ ti wà lẹ́nu ṣíṣe nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́ta owó wẹ́wẹ́ àti ogún ó dín ní irínwó mílíọ̀nù owó bébà. Bí wọ́n bá dá gbogbo owó bébà wọ̀nyí jọ, á ga tó ogún kìlómítà lóròó!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé “Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù Fọ́ Yángá” Ni?

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, ẹgbẹ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, tí í ṣe ẹgbẹ́ alábòójútó fún Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EU), jàjà mórí bọ́ nínú ìfàsẹ́yìn bíburú jáì kan tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn èrú, ìwà ìbàjẹ́, àti ṣíṣe ojúsàájú fún ará ìlú ẹni kan ẹgbẹ́ náà. Ní wọ́n bá gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti ṣèwádìí àwọn ẹ̀sùn náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìwádìí fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, ìgbìmọ̀ náà rí i pé ọwọ́ ẹgbẹ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ò mọ́, wọ́n ti ṣèrú, wọn ò sì ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ìgbìmọ̀ tó ṣèwádìí ọ̀rọ̀ náà kò rí ẹ̀rí kan tó lè fi gbá àwọn aṣojú náà mú pé wọ́n kówó ẹgbẹ́ jẹ láti fi sọra wọn di ọlọ́rọ̀.

Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìròyìn tí ìgbìmọ̀ náà kọ jáde, gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ ní March 1999—ohun tí ò ṣẹlẹ̀ rí. Yánpọnyánrin tí ọ̀ràn yìí dá sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ EU kúrò ní kèrémí. Nígbà tí ìwé ìròyìn Time máa wí, ó ní “ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù fọ́ yángá.” Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àá máa rí ipa tí yánpọnyánrin yìí yóò ní lórí ọ̀ràn ètò ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù tó ń lọ lọ́wọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ó ti rọrùn gan-an láti sọdá lẹ́nubodè àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọdún 1998 ni wọ́n ṣí Báńkì Àpapọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù, nílùú Frankfurt, lórílẹ̀-èdè Jámánì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́