Àìláàbò—Ìṣòro Tó Kárí ayé
ǸJẸ́ o máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé ìgbésí ayé rẹ àti ọ̀nà tí o ń gbà gbé e lè wà nínú ewu àti pé kò láyọ̀lé? Ìwọ nìkan kọ́ lo ń ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Bí àwọn ti ààlà orílẹ̀-èdè, ìsìn, tàbí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kò ti lè dá àìláàbò dúró, ńṣe ló ń jà kálẹ̀ bí àrùn, ó ń bá àwọn ènìyàn fínra láti Moscow títí dé Manhattan.
Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé, nígbà tí ẹ̀mí wa bá wà nínú ewu, a máa “ń kó sínú ìbẹ̀rù àti ìdààmú.” Ìdààmú jẹ́ wàhálà ìmọ̀lára tí ń fa àìfararọ, tí ó lè pa ìlera wa lára. Àmọ́, kí ló dé tí a ń dààmú, tí a sì ń ronú nípa àìláàbò?
Ìdààmú ní Yúróòpù
Láàárín Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EU), ẹnì kan lára àwọn 6 ni owó ìgbọ́bùkátà tí ń wọlé fún un kò tó ti ẹni tí a kà sí òtòṣì, àwọn mílíọ̀nù 18 ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́, àìlóǹkà àwọn mìíràn ní ń bẹ̀rù pípàdánù iṣẹ́ wọn. Ní àwọn ilẹ̀ àwùjọ EU mélòó kan, àwọn òbí ń bẹ̀rù ewu àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe lórí àwọn ọmọ wọn. Ní orílẹ̀-èdè kan tí ó wà lára àwùjọ EU, ẹni 2 lára àwọn 3 ní ń dààmú nípa kíkó séwu ìwà ọ̀daràn. Àwọn mìíràn tí ń gbé àwùjọ EU ń bẹ̀rù sí i nítorí ìmọ̀ọ́mọ̀ ba ohun ìní jẹ́, ìpániláyà, àti ìbàyíkájẹ́.
Kì í ṣe nítorí àwọn rúdurùdu tí ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nìkan ni ẹ̀mí àti ìgbésí ayé fi wà nínú ewu bi kò ṣe nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdánidá pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ní 1997 àti 1998, òjò ọlọ́gbàrá, ọ̀gbàrá ẹrẹ̀, àti ẹ̀fúùfù ńlá sọ àwọn ibì kan dahoro ní United States. Ní 1997, àkúnya omi rọ́ lu Àáríngbùngbùn Yúróòpù nígbà tí odò Oder àti Neisse ya. Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilẹ̀ Poland náà, Polityka, sọ pé, àwọn oko ńláńlá, àti ìlú ńláńlá òun ìlú kéékèèké tí àpapọ̀ wọ́n jẹ́ 86 àti nǹkan bí 900 abúlé ni omi náà ya bò. Nǹkan bí 50,000 ìdílé ni irè oko wọn run, nǹkan bí 50 ènìyàn sì kú. Ìṣàn ọ̀gbàrá ẹrẹ̀ kan tí ó sẹ̀ láti inú ilẹ̀ ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1998 pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ní gúúsù Ítálì.
Ọ̀ràn Ààbò Ara Ẹni
Àmọ́, ṣé wọn kò mú un dá wa lójú pé ìgbésí ayé láàbò ju bí ó ṣe rí ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lọ ni? Ṣé òpin Ogun Tútù kò túmọ̀ sí dídín àwọn ìgbòkègbodò ológun kù ni? Lóòótọ́, ààbò orílẹ̀-èdè lè ti sunwọ̀n sí i. Àmọ́, ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé àti ní òpópó ń nípa lórí ààbò ẹnì kọ̀ọ̀kan. Bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ wa tàbí bí a bá fura pé adigunjalè tàbí abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan ń fẹsẹ̀ palẹ̀ níta, nígbà náà bí ó ti wù kí a fòpin sí ohun ìdìhámọ́ra tó, ìdààmú yóò bá wa, a óò sì mọ̀ pé a kò láàbò.
Báwo ni àwọn ènìyàn kan ṣe ń kojú àìláyọ̀lé ìgbésí ayé? Ní pàtàkì jù lọ, ọ̀nà kan ha wà tí a lè gbà dáàbò bo ìwàláàyè olúkúlùkù ènìyàn—àti tìrẹ—títí lọ? A óò gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì tí ó tẹ̀ lé èyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
FỌ́TÒ UN 186705/J. Isaac
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò FAO/B. Imevbore