ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 3-4
  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ilẹ̀ Yúróòpù Lè Ṣọ̀kan Lóòótọ́?
    Jí!—2000
  • Awọn Nǹkan Ha Nsunwọn Sii Nitootọ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • Èé Ṣe Tí A Fi Dá Ilé Ẹjọ́ Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-èdè Europe Sílẹ̀?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 3-4

Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?

ÀWỌN èèyàn ń mutí. Ìdùnnú ṣubú layọ̀. Kí ló fa ìdùnnú? Ṣé ẹgbẹ̀rúndún tuntun tó wọlé dé ni? Ó tì o, ó dájú pé ohun tó ń fa ìdùnnú yìí ju ọ̀ràn títi ọdún 1999 bọ́ sí ọdún 2000 lọ. January 1, 1999 ni ohun tí a ń wí yìí ṣẹlẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni wọ́n ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ owó tuntun tí Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EU) lápapọ̀ yóò máa ná, orúkọ tí wọ́n pe owó náà ni yúrò (euro).

Púpọ̀ lára àwọn ará Yúróòpù ló wo ọ̀ràn níná irú owó kan náà gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ ńlá nínú ọ̀ràn ìṣọ̀kan tí ilẹ̀ Yúróòpù ti ń jẹ lẹ́nu tipẹ́tipẹ́. Ìwé ìròyìn èdè Dutch náà, De Telegraaf, sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ìfilọ́lẹ̀ owó yúrò, ó ní ó jẹ́ “ògo ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù.” Ní ti gidi, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń ronú nípa rẹ̀, tí wọ́n ti ń dá a bí ọgbọ́n, tí àwọn nǹkan bíi mélòó kan sì ti ń dí wọn lọ́wọ́, ó jọ pé ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù ti wá sún mọ́lé ju ti ìgbàkigbà rí lọ wàyí.

Òótọ́ ni pé àwọn tí kì í gbé ilẹ̀ Yúróòpù lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tó fa gbogbo ìdùnnú yìí. Owó yúrò tó wọlé dé àti gbogbo ìsapá lórí ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù lè ṣàìní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé tiwọn. Àmọ́, ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù yìí lè ṣokùnfà òwò àjọṣe tó tíì tóbi jù lọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà, yóò ṣòro kí èèyàn tó máà kọbi ara sí ọ̀ràn ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù táa ń sọ yìí—láìka ibi yòówù kí èèyàn máa gbé sí.

Fún àpẹẹrẹ, Igbákejì Olùdarí Ètò Òde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Marc Grossman, sọ fún àwùjọ àwọn ará Àríwá Amẹ́ríkà kan láìpẹ́ yìí pé: “A ò lè fọwọ́ rọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù tì bí a óò bá láásìkí.” Èé ṣe? Lára àwọn ohun tó sọ pé ó jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé, “bí a bá kó àwọn méjìlá jọ lára ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, ọ̀kan nínú wọn yóò máa ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ilé iṣẹ́ tí àwọn ará Yúróòpù dá sílẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.” Ìròyìn tún sọ pé owó tuntun tí wọ́n ṣe jáde ní ilẹ̀ Yúróòpù náà lè nípa lórí iye tí àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré sí Yúróòpù ń ta àwọn ọjà tí wọ́n ń kó wọ̀lú wọn, kódà yóò kan èlé tí wọ́n ń san lórí owó tí wọ́n yá pàápàá.

Àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lè jàǹfààní nínú ẹ̀. Lọ́nà wo? Ìwádìí kan sọ pé: “Fífi owó yúrò rọ́pò oríṣiríṣi owó tí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù ń ná á mú ọ̀ràn òwò àjọṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà àti Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù rọrùn.” Láfikún sí i, àwọn kan méfò pé ilé iṣẹ́ àwọn ará Japan àti tàwọn ará Amẹ́ríkà tó ń ṣòwò ní Yúróòpù pẹ̀lú á jàǹfààní. Ní báyìí tí owó yúrò ti jáde, kò ní sí ọ̀ràn ìlọsókè-lọsódò mọ́ nínú iye tí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù ń ṣẹ́ owó sí láàárín ara wọn. Ṣíṣe òwò ní ilẹ̀ Yúróòpù lè máà gbọ́nni lówó dànù mọ́.

Bóo bá ń wéwèé láti rìnrìn àjò ní ilẹ̀ Yúróòpù, ìwọ náà lè jẹ lára àǹfààní ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù. Láìpẹ́, wàá lè fi oríṣi owó kan, ìyẹn yúrò, tí agbára ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti dọ́là tí wọ́n ń ná ní Amẹ́ríkà, ra ọjà tàbí kí o fi sanwó iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe fún ẹ ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Àwọn arìnrìn-àjò ò ní máa ronú bí wọ́n á ṣe máa kó owó gulden, francs, lira, deutsche marks, àti ẹ̀rọ pẹnpẹ tí wọ́n fi ń ṣírò owó kiri mọ́.

Bó ti wù kó rí, ìgbésẹ̀ dídi kọ́ńtínẹ́ǹtì tó ṣọ̀kan tí ilẹ̀ Yúróòpù gbé tún mú ohun kan tó túbọ̀ fani lọ́kàn mọ́ra wá, ìrètí sì ni ohun náà. Ìwọ ròó wò, ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ńṣe logun ń jà káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù. Tí a bá ti ibẹ̀ yẹn wò ó, ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbàfiyèsí ni ọ̀ràn ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù. Ńṣe làwọn èèyàn níbi gbogbo lágbàáyé kà á sí ohun tó gbayì.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ò yéé rò ó pé bóyá ni ìfojúsọ́nà fún ìṣọ̀kan àgbáyé ò ní di àlá tó máa ṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ohun táwọn èèyàn ń fẹ́ gbáà ni! Ǹjẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ilẹ̀ Yúróòpù gbé nípa ìṣọ̀kan yìí lè mú kí aráyé sún mọ́ ipò wíwà ní ìṣọ̀kan? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, a ní láti fojú ṣùnnùkùn wo ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù náà. Àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ tó lè dí ìṣọ̀kan lọ́wọ́ wo ni wọ́n ṣì ní láti mú kúrò ná?

[Àpótí/Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 4]

ṢÉ ÌṢỌ̀KAN TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÉ?

Ọ̀ràn nípa ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù kì í ṣe nǹkan tuntun. Wọ́n ṣọ̀kan dé àyè kan nígbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù, àti lẹ́yìn náà lábẹ́ ìṣàkóso Charlemagne, àti níkẹyìn nígbà àkóso Napoléon Kìíní. Nínú àwọn ọ̀ràn tí a mẹ́nu kàn wọ̀nyí, nípasẹ̀ ipá àti ìṣẹ́gun ni wọ́n fi mú àwọn èèyàn ṣọ̀kan. Àmọ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tí ogun ti fọ́ túútúú wá rí i pé ó yẹ kí ìṣọ̀kan tó dá lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wà. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ní i lọ́kàn pé irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ á yọrí sí ìmúsunwọ̀n ètò ọrọ̀ ajé, yóò sì tún jẹ́ kí wọ́n lè fòfin de ogun. Díẹ̀ lára àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì pàtàkì tó ṣamọ̀nà sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí la kọ sísàlẹ̀ yìí:

• 1948 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olórí orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù ṣèpàdé ní ìlú Hague, lórílẹ̀-èdè Netherlands, wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “A ò ní bá ara wa jagun mọ́ láé.”

• 1950 Ilẹ̀ Faransé àti Jámánì bẹ̀rẹ̀ àjọṣe láti lè dáàbò bo àwọn ilé iṣẹ́ èédú àti ti irin lílẹ̀ wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè míì tún dara pọ̀ mọ́ wọn, èyí wá yọrí sí dídá ẹgbẹ́ Àwùjọ Ilẹ̀ Yúróòpù Tí Ń Ṣe Èédú àti Irin Lílẹ̀ (ECSC) sílẹ̀. Ẹgbẹ́ ECSC bẹ̀rẹ̀ sí gbéṣẹ́ ṣe lọ́dún 1952, àwọn orílẹ̀-èdè tó sì wà nínú ẹgbẹ́ náà ni Belgium, Faransé, Ítálì, Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì, Luxembourg, àti Netherlands.

• 1957 Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fà tó wà nínú ẹgbẹ́ ECSC tún dá ẹgbẹ́ méjì míì sílẹ̀, àwọn ni: Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ètò Ọrọ̀ Ajé Ilẹ̀ Yúróòpù (EEC) àti Àjọ Agbára Átọ́míìkì Ilẹ̀ Yúróòpù (Euratom).

• 1967 Ẹgbẹ́ EEC dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ECSC àti Euratom, gbogbo wọ́n sì di ẹgbẹ́ kan tó ń jẹ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EC).

• 1973 Ẹgbẹ́ EC gba orílẹ̀-èdè Denmark, Ireland, àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sínú ẹgbẹ́ wọn.

• 1981 Orílẹ̀-èdè Gíríìsì wọ ẹgbẹ́ EC.

• 1986 Orílẹ̀-èdè Potogí àti Sípéènì wọ ẹgbẹ́ EC.

• 1990 Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ EC tún pọ̀ sí i nígbà tí Ìwọ̀ Oòrùn àti Ìlà Oòrùn Jámánì dọ̀kan, èyí sì mú kí orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Jámánì tẹ́lẹ̀ ráyè wọ ẹgbẹ́ náà.

• 1993 Ìsapá láti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ EC túbọ̀ ṣọ̀kan nínú ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣèlú ṣamọ̀nà sí dídá ẹgbẹ́ tí wọ́n pè ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù (EU), sílẹ̀.

• 2000 Orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló wà nínú ẹgbẹ́ EU, àwọn ni Austria, Belgium, Denmark, Finland, Faransé, Gíríìsì, Ireland, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ítálì, Jámánì, Luxembourg, Netherlands, Potogí, Sípéènì, àti Sweden.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Owó yúrò á rọ́pò ọ̀pọ̀ owó tí wọ́n ń ná nílẹ̀ Yúróòpù

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Owó yúrò àti àwọn àmì owó yúrò lójú ewé 3, 5-6, àti 8: © European Monetary Institute

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́