Fífi Ọgbọ́n Yí Ọ̀rọ̀ Po
“Nípa fífi ẹnúdùnjuyọ̀ lo ìpolongo èké, a lè sọ ọ̀run rere di ọ̀run àpáàdì mọ́ àwọn ènìyàn lọ́wọ́, kí á sì tún sọ ipò ti ẹni tó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ láyé di Párádísè.”—ADOLF HITLER, MEIN KAMPF.
BÍ Ọ̀NÀ ìfìsọfúnniránṣẹ́ ti wá pọ̀ sí i báyìí—láti orí ìwé títẹ̀ dé orí tẹlifóònù, rédíò, tẹlifíṣọ̀n, àti Íńtánẹ́ẹ̀tì—ńṣe ni àwọn ìsọfúnni tí a fi ń yíni lérò padà ń pọ̀ sí i lọ́nà tó ń gba àfiyèsí. Ìyípadà tó dé nínú ọ̀ràn ìfìsọfúnniránṣẹ́ yìí ti yọrí sí àpọ̀jù ìsọfúnni, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ibi gbogbo ni ìsọfúnni ń gbà wọlé tọ àwọn ènìyàn wá. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń fara mọ́ ìyọlẹ́nu yìí nípa títètè gba àwọn ìsọfúnni náà wọlé, tí wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gbà wọ́n láìbéèrè ìbéèrè tàbí kí wọ́n yẹ̀ wọ́n wò kínníkínní.
Àwọn olùpolongo èké tó lọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ sí irú àwọn ọ̀nà ẹ̀bùrú bẹ́ẹ̀—àgàgà àwọn ọ̀nà ìrònú tí kò jinlẹ̀. Ìpolongo èké máa ń fún èyí níṣìírí nípa ríru ìmọ̀lára àwọn èèyàn sókè, nípa kíké gbàjarè pé ewu ń bẹ, nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ abẹ́nú, àti nípa yíyí àwọn ìlànà ohun tó bọ́gbọ́n mu padà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn sọ, irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀ lè gbéṣẹ́ gan-an.
Ìtàn Nípa Ìpolongo Èké
Lónìí, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “propaganda” tí a tú sí ìpolongo èké ní ìtumọ̀ abẹ́nú tí kò dára, tó túmọ̀ sí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó kún fún àbòsí, ṣùgbọ́n látètèkọ́ṣe ohun tí wọ́n pète pé kó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà kọ́ nìyẹn. Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “propaganda” wá láti inú orúkọ àwùjọ àwọn kádínà Ìjọ Àgùdà lédè Látìn, ìyẹn Congregatio de Propaganda Fide (Ìgbìmọ̀ Agbẹ́sìnga). Póòpù Gregory Kẹẹ̀ẹ́dógún ló dá ìgbìmọ̀ náà, tí wọ́n ké orúkọ rẹ̀ kúrú sí Propaganda, sílẹ̀ ní ọdún 1622 láti máa bójú tó iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “propaganda,” wá túmọ̀ sí ìsapá èyíkéyìí láti tan ìgbàgbọ́ kan kálẹ̀.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni èròǹgbà ìpolongo èké dáyé. Láti ìgbà láéláé ni àwọn èèyàn ti ń lo gbogbo ohun tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn láti tan àwọn èròǹgbà kálẹ̀ tàbí láti mú kí òkìkí tàbí agbára wọn pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, láti ìgbà ayé àwọn fáráò ní Íjíbítì ni wọ́n ti ń lo iṣẹ́ ọnà láti fi ti ìpolongo èké lẹ́yìn. Àwọn ọba yẹn pilẹ̀ ṣe àwọn òkìtì aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ wọn láti fi bí agbára wọ́n ti tó àti bí wọ́n ṣe lè pẹ́ tó hàn. Bákan náà, nítorí ìṣèlú ni àwọn ará Róòmù ṣe kọ́ àwọn ilé wọn lọ́nà tí wọ́n gbà kọ́ ọ, láti gbé ògo orílẹ̀-èdè náà ga. Ọ̀rọ̀ náà, “ìpolongo èké” tó jẹ́ ìtumọ̀ Gẹ̀ẹ́sì yẹn di èyí tó gbé ìtumọ̀ òdì rù nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lò ó níbi gbogbo nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní fún kíkópa tí àwọn ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí kópa ní kíkún nínú dídarí ìsọfúnni tí àwọn oníròyìn ń tàn kálẹ̀ nípa ogun náà. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Adolf Hitler àti Joseph Goebbels fi hàn pé olùpolongo èké tó jáfáfá làwọn.
Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìpolongo èké wá bẹ̀rẹ̀ sí di lájorí ohun tí wọ́n fi ń gbé ìlànà ìjọba lárugẹ gan-an. Àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn àti Ìlà Oòrùn bẹ̀rẹ̀ ìkéde takuntakun láti mú kí ẹgbàágbèje àwọn èèyàn tí kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe gba tiwọn. Gbogbo apá ìṣàkóso ìjọba àti ìlànà ni wọ́n lò fún ète ìpolongo èké. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ń rí ẹ̀rí bí àwọn ọgbọ́n ìpolongo èké ṣe túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i nígbà ìpolongo ìbò, àti nínú ìpolówó ọjà táwọn ilé iṣẹ́ tábà ń ṣe. Wọ́n lo àwọn tí wọ́n pè ní ògbógi lẹ́nu iṣẹ́ wọn àti àwọn aṣáájú mìíràn láti fi hàn pé sìgá mímu ń gbádùn mọ́ni, ó sì ń mára le, pé kì í ṣe ohun tó jẹ́ gan-an, ìyẹn ewu fún ìlera àwọn ará ìlú.
Irọ́ Funfun Báláú!
Dájúdájú, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ táwọn olùpolongo èké máa ń lò jù lọ ni irọ́ ojúkorojú. Fún àpẹẹrẹ, ẹ wo irọ́ tí Martin Luther kọ sílẹ̀ ní ọdún 1543, nípa àwọn Júù ní ilẹ̀ Yúróòpù pé: “Wọ́n da májèlé sínú àwọn kànga, wọ́n pa àwọn èèyàn lóríṣiríṣi, wọ́n jí àwọn ọmọdé gbé . . . Olóró ni wọ́n, oníkèéta ni wọ́n, ẹlẹ́mìí ìgbẹ̀san ni wọ́n, paramọ́lẹ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni wọ́n, apààyàn ni wọ́n, ọmọ èṣù tí í ṣe adánilóró àti oníṣẹ́ ibi ni wọ́n.” Kí ló wá gba àwọn tí wọ́n pè ní Kristẹni níyànjú láti ṣe? “Ẹ dáná sun àwọn sínágọ́gù tàbí ilé ẹ̀kọ́ wọn . . . Ẹ wó ilé wọn palẹ̀ kí ẹ sì run wọ́n.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ ètò ìjọba àti àjọṣe ẹ̀dá tó ṣèwádìí nípa sáà yẹn sọ pé: “Ogun tí wọ́n gbé ti àwọn Júù kì í ṣe nítorí ìwà àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ohun tí àwọn tí ń gbógun ti àwọn Júù mọ̀ nípa irú ẹ̀dá tí àwọn Júù jẹ́.” Ó tún sọ pé: “Gbogbo ohun tí kò dára ni wọ́n máa ń kà sí àwọn Júù lọ́rùn, débi pé ohun tó máa kọ́kọ́ wá sọ́kàn èèyàn nígbà tí ìjábá àdánidá kan bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí rògbòdìyàn kan bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìlú ni pé ó lè jẹ́ àwọn Júù ló wà nídìí rẹ̀.”
Wọn Kì Í Sọ̀rọ̀ Síbi Tọ́rọ̀ Wà
Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mìíràn tí wọ́n fi ń polongo èké, tó sì ṣàṣeyọrí ni pé wọn kì í sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà. Ó jọ pé àìsọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà máa ń bo àwọn òkodoro òtítọ́ nípa ohun tí a ń sọ gan-an mọ́lẹ̀, wọ́n sì sábà máa ń lò ó láti fi tẹ́ńbẹ́lú odindi àwùjọ ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, gbólóhùn kan tí a sábà máa ń gbọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Yúróòpù ni pé: “Olè ni àwọn alárìnká ará Íńdíà [tàbí àwọn aṣíwọ̀lú].” Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ ni gbólóhùn yìí?
Richardos Someritis tí í ṣe akọ̀ròyìn, sọ pé ní orílẹ̀-èdè kan, irú èrò bẹ́ẹ̀ ṣokùnfà “ẹ̀mí máfojúkànlejò àti lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀tanú ẹ̀yà lọ́nà rírorò” sí àwọn àjèjì. Bó ti wù kó rí, ẹ̀rí ti wá fi hàn pé tó bá di ọ̀ràn pé àwọn èèyàn ń hùwàkiwà, àwọn tí wọ́n máa ń bá nídìí rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yẹn lè jẹ́ yálà àwọn ọmọ ibẹ̀ tàbí àwọn àjèjì. Fún àpẹẹrẹ, Someritis sọ pé ìwádìí ti fi hàn pé ní ilẹ̀ Gíríìsì, “àwọn ará [Gíríìkì] ni wọ́n ń hu mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ìwà ọ̀daràn.” Ó sọ pé: “Ọ̀ràn ìṣúnná owó àti àjọṣe ẹ̀dá ló ń fa ìwà ọ̀daràn, kì í ṣe ọ̀ràn ‘ẹ̀yà.’” Ó bá àwọn oníròyìn wí “fún fífọgbọ́n dá ẹ̀mí máfojúkànlejò àti ẹ̀tanú ẹ̀yà sílẹ̀” nípa gbígbè sẹ́yìn àwọn kan nígbà tí wọ́n ń ròyìn nípa ìwà ọ̀daràn.
Pípeni Lórúkọ Burúkú
Àwọn èèyàn kan máa ń hùwà ìwọ̀sí sí àwọn tí kò bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn nípa gbígbé ìbéèrè dìde nípa ìwà wọn tàbí ìdí tí wọ́n fi ṣe nǹkan kan dípò kí wọ́n wo àwọn òkodoro òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà. Pípeni lórúkọ burúkú máa ń sàmì burúkú síni, èyí tí àwọn èèyàn yóò máa tètè fi rántí ẹnì kan, àwùjọ kan, tàbí èròǹgbà kan. Ẹni tó ń pe èèyàn lórúkọ náà kò fẹ́ kí àmì náà parẹ́ lára èèyàn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn wá kọ ẹni náà sílẹ̀ tàbí èrò rẹ̀ látàrí orúkọ burúkú náà dípò kí wọ́n gbé ẹ̀rí tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò fúnra wọn, á jẹ́ pé ọgbọ́n tí ẹni tó ń peni lórúkọ burúkú náà lò ṣiṣẹ́ nìyẹn.
Fún àpẹẹrẹ, èrò tó lágbára nípa gbígbógun ti ẹ̀ya ìsìn gbalẹ̀ kan ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní Yúróòpù àti láwọn ibòmíràn láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Àṣà yìí mú àwọn èèyàn bínú, ó gbin èrò pé ọ̀tá kan wà níbì kan sọ́kàn wọn, ó sì mú kí ẹ̀tanú tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ túbọ̀ lágbára. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀ya ìsìn,” ni wọ́n máa ń lò láti fi yí àwọn èèyàn lérò padà. Lọ́dún 1993, Ọ̀jọ̀gbọ́n Martin Kriele, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Jámánì kọ̀wé pé: “‘Ẹ̀ya ìsìn’ ni ọ̀rọ̀ mìíràn fún ‘aládàámọ̀,’ bẹ́ẹ̀ kẹ̀, [ẹjọ́ ikú] ni wọ́n máa ń dá fún ẹni tó bá jẹ́ aládàámọ̀ ní ilẹ̀ Jámánì lónìí, bíi ti àtijọ́—bí wọn ò bá dáná sun ún . . . , á jẹ́ pé wọ́n á fọ̀rọ̀ èké bà á lórúkọ jẹ́, tàbí kí wọ́n lé e lọ sí àdádó tàbí kí wọ́n sọ ọ́ di ẹdun arinlẹ̀.”
Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ṣàyẹ̀wò Kúlẹ̀kúlẹ̀ Ìpolongo èké sọ pé, “orúkọ burúkú ti kó ipa tó lágbára gan-an nínú ìtàn ayé àti nínú ìdàgbàsókè àwa fúnra wa. Wọ́n ti ba orúkọ rere àwọn èèyàn jẹ́, . . . wọ́n ti gbé àwọn èèyàn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì ti mú orí àwọn èèyàn gbóná gan-an débi tí wọ́n fi ń gbógun ti ara wọn tí wọ́n sì ń pa èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn.”
Fífi Ọ̀rọ̀ Dorí Ẹni Rú
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ọ̀ràn ṣe rí lára ẹni lè má ṣe pàtàkì tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa sísọ òkodoro òtítọ́ tàbí àlàyé ọ̀rọ̀ nínú ìjíròrò kan, ṣùgbọ́n ó kó ipa pàtàkì kan nínú yíyí èèyàn lérò padà. Àwọn ògbóǹkangí aṣojú ilé iṣẹ́ ìròyìn ló máa ń wá ọ̀nà láti fọ̀rọ̀ dorí ẹni rú, wọ́n sì gbọ́n féfé nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.
Fún àpẹẹrẹ, ìbẹ̀rù jẹ́ ohun tó ń dorí ẹni rú tó lè máà jẹ́ kí èèyàn ṣèpinnu to dáa. Àti pé gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ìlara ṣíṣe, àwọn èèyàn lè fi ìbẹ̀rù téèyàn ní mú un. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà náà, The Globe and Mail, ti February 15, 1999, sọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí láti ìlú Moscow pé: “Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta kan gbẹ̀mí ara wọn ní ìlú Moscow lọ́sẹ̀ tó kọjá, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé ó lè jẹ́ pé agbawèrèmẹ́sìn, tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n.” Ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, “agbawèrèmẹ́sìn.” Bí ìwà ẹ̀dá, àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù àwọn onísìn tó bá jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, tó jọ pé wọ́n máa ń sún àwọn ọ̀dọ́ láti gbẹ̀mí ara wọn. Ṣé lóòótọ́ ni àwọn ọmọbìnrin tó bayé ara wọn jẹ́ yìí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nàkọnà?
Ìwé ìròyìn Globe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tó yá, àwọn ọlọ́pàá wá sọ pé àwọn ọmọbìnrin náà kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà]. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn ìkànnì kan lórí tẹlifíṣọ̀n ní Moscow tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀sọkúsọ nípa ẹ̀ya ìsìn náà, wọ́n ń sọ fún àwọn òǹwòran pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Adolf Hitler nígbà ìṣàkóso Násì ní Jámánì—bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ìtàn jẹ́rìí sí i pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn ló kú sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì.” Ojú pé bóyá ẹgbẹ́ awo tí ń gbẹ̀mí ara wọn tàbí alájọṣe pẹ̀lú ìjọba Násì ni àwọn tí wọ́n ti ṣì lọ́nà àti àwọn ará ìlú tó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù máa bà, fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
Ìkórìíra jẹ́ ohun tó ń dorí ẹni rú tó lágbára tí àwọn olùpolongo èké máa ń lò. Ní pàtàkì, àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ òdì ni wọ́n sábà máa ń lò láti ru ú sókè. Ó jọ pé àwọn ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí wọ́n sábà máa ń lò, tó sì máa ń ru ìkórìíra sókè sí ẹ̀yà, ìran, tàbí àwùjọ ìsìn pàtàkì kan kì í tán lẹ́nu wọn.
Àwọn olùpolongo èké kan máa ń ru ẹ̀mí ìgbéraga sókè. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ń gbìyànjú láti ru ẹ̀mí ìgbéraga sókè nípa wíwò bóyá ó ń sọ àwọn òkò ọ̀rọ̀ bí: “Ẹnikẹ́ni tó bá lọ́gbọ́n lórí á mọ̀ pé . . . ” tàbí, “Ẹni tó kàwé tó bí o ṣe kàwé yóò wulẹ̀ mọ̀ pé . . . ” Lílo ọ̀rọ̀ òdì láti ru ẹ̀mí ìgbéraga sókè yìí máa ń dorí ẹni rú tí yóò múni rò pé èèyàn ti wá dà bí òpònú lójú wọn. Àwọn tó mọ iṣẹ́ yíyí èèyàn lérò padà dunjú mọ nípa èyí dáadáa.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìwúrí àti Àmì
Àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò ṣe kedere, tí wọ́n máa ń lò láti fi èrò tí èèyàn ní nípa ọ̀ràn kan tàbí ohun tí èèyàn fẹ́ ṣe nípa rẹ̀ hàn. Nítorí àìṣekedere wọn, ó rọrùn láti tẹ́wọ́ gbà wọn.
Fún àpẹẹrẹ, láwọn àkókò tí yánpọnyánrin tàbí ìforígbárí bá ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan, àwọn olùgbèjà mẹ̀kúnnù lè máa lo àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí bíi “Ti orílẹ̀-èdè mi ni mo ṣe, yálà ó tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà,” “Ilẹ̀ baba wa, Ẹ̀sìn wa, Ìdílé wa,” tàbí “Òmìnira tàbí Ikú.” Àmọ́, ṣé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn máa fara balẹ̀ gbé ọ̀ràn tó fa yánpọnyánrin tàbí ìforígbárí náà yẹ̀ wò dáadáa? Àbí wọ́n kàn gba ohun tí wọ́n wí fún wọn láìjanpata ni?
Nígbà tí Winston Churchill ń kọ̀wé nípa Ogún Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé: “Àmì tó ń runi sókè kan ṣoṣo péré ló gbà láti yí ògìdìgbó àwọn mẹ̀kúnnù ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí padà di ogunlọ́gọ̀ tí yóò máa fara wọn ya sí wẹ́wẹ́.” Ó tún sọ síwájú sí i pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tí wọ́n bá sọ fún wọn láti ṣe nǹkan kan, wọn kì í ronú wò kí wọ́n tó ṣe é.
Olùpolongo èké tún ní onírúurú àmì tó fi máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀—yíyìnbọn sáfẹ́fẹ́ nígbà mọ́kànlélógún, ìkíni ológun, àti àsíá. Wọ́n tún lè ru ìfẹ́ àwọn òbí ẹni sókè. Nípa bẹ́ẹ̀, irú lílo àwọn àmì bí ilẹ̀ baba ẹni, ilẹ̀ ìbí wa, tàbí ìjọ tí wọ́n bí wa sí jẹ́ irin iṣẹ́ táwọn ayíniléròpadà tó gbọ́n féfé ń lò.
Nítorí náà, ọgbọ́n àrékérekè ìpolongo èké lè ra iyè ẹni, ó lè máà jẹ́ kí èèyàn ronú dáadáa, kó sì lo ìfòyemọ̀, ó sì lè sọ èèyàn di ẹni tó ń ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe. Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ọgbọ́n àrékérekè ìpolongo èké lè ra iyè ẹni, ó sì lè máà jẹ́ kéèyàn ronú dáadáa, kó sì lo ìfòyemọ̀
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
ṢÉ ÌPOLONGO ÈKÉ NI IṢẸ́ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?
Àwọn kan tí wọ́n ń ṣàtakò sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń tan èké nípa àwọn Júù kálẹ̀. Àwọn mìíràn fẹ̀sùn kàn wọ́n pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ń gbé ètò ìjọba Kọ́múníìsì lárugẹ. Síbẹ̀, àwọn mìíràn tún sọ pé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé èrò àti ìfẹ́ “Amẹ́ríkà láti máa gbókèèrè ṣàkóso” lárugẹ. Àwọn kan sì tún wà tí wọ́n ń sọ pé adárúgúdù sílẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí, pé ète tí wọ́n fi ń da ìlú rú jẹ́ láti dojú ètò àwùjọ ẹ̀dá, ọrọ̀ ajé, ìṣèlú, tàbí ètò òfin rú. Ṣùgbọ́n, ó hàn gbangba pé gbogbo ẹ̀sùn tó forí gbárí wọ̀nyí kò lè jẹ́ òtítọ́.
Ká sọ tòótọ́, kò sí èyíkéyìí lára àwọn àpèjúwe òkè yìí tó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu. Òótọ́ ọkàn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣègbọràn sí ṣíṣe iṣẹ́ tí Jésù Kristi pa láṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe pe: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní gedegbe, ohun kan ṣoṣo tí iṣẹ́ wọ́n dá lé lórí ni ìhìn rere Ìjọba ọ̀run—ohun tí Ọlọ́run yóò lò láti mú àlàáfíà wá sí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:10; 24:14.
Àwọn tí ń ṣàkíyèsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwùjọ àwọn Kristẹni wọ̀nyí da ètò ìlú èyíkéyìí rú rí.
Ọ̀pọ̀ àwọn akọ̀ròyìn, àwọn adájọ́, àti àwọn mìíràn ló ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣètìlẹ́yìn lọ́nà tó ń ṣàǹfààní ní àwọn àdúgbò tí wọ́n ń gbé. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Lẹ́yìn tí akọ̀ròyìn kan láti ìhà gúúsù Yúróòpù lọ sí àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣe ara wọn lóṣùṣù ọwọ̀ gan-an, wọ́n ti kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ àti láti máa lo ẹ̀rí ọkàn wọn kí wọ́n má bàa pa àwọn ẹlòmíràn lára.”
Oníròyìn mìíràn, tó ní èrò òdì tẹ́lẹ̀ rí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí, sọ pé: “Wọ́n ń gbé ìgbésí ayé àwòfiṣàpẹẹrẹ. Wọn kì í tẹ ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà rere àti ohun tó tọ́ lójú.” Ògbógi kan nínú ìmọ̀ ìṣèlú pẹ̀lú sọ ohun kan náà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Wọ́n máa ń fi inú rere, ìfẹ́ àti ìwà pẹ̀lẹ́ tó jinlẹ̀ bá àwọn ẹlòmíràn lò.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi kọ́ni pé ohun tó tọ́ ni láti tẹrí ba fún àwọn tó wà ní ipò àṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí aráàlú tó ń pa òfin mọ́, wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa àìlábòsí, ìṣòtítọ́, àti ìmọ́tónítóní. Wọ́n ń fìdí ìwà rere múlẹ̀ nínú àwọn ìdílé wọn, wọ́n sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ bí àwọn pẹ̀lú ṣe lè ṣe bákan náà. Wọ́n ń gbé lálàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn, wọ́n kì í bá wọn ṣe àwọn ìwọ́de bàsèjẹ́, tàbí àwọn ìyípadà tegbòtigaga ti ìṣèlú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú láti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin táwọn aláṣẹ ènìyàn ń ṣe, bí wọ́n ti ń fi sùúrù dúró de Aláṣẹ Gíga Jù Lọ náà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, láti mú àlàáfíà pípé àti ìjọba òdodo wá sí ayé yìí.
Bákan náà, iṣẹ́ tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe. Nípa lílo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ iṣẹ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn jákèjádò ayé láti máa ronú nípa àwọn ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ọ̀pá ìdíwọ̀n títọ́ àti ìwà rere dàgbà. Wọ́n ń gbé àwọn ìwà ọmọlúwàbí lárugẹ, èyí tó ń mú kí ìgbésí ayé ìdílé sunwọ̀n sí i kó sì ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti máa kojú àwọn ìṣòro tó ń yọ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu. Wọ́n tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí okun tí wọ́n lè fi borí àwọn ìwà burúkú àti láti mọ̀ bí wọ́n ṣe lè máa gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Yóò ṣòro láti wá pe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ní “ìpolongo èké.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, ní àyíká tí èrò ènìyàn ti máa ń tàn kálẹ̀ fàlàlà, “ìpolongo èké yàtọ̀ sí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”
[Àwọn àwòrán]
Ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ìwà ọmọlúwàbí àti ìlànà ìwà rere nínú ìdílé lárugẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìpolongo èké tó ń gbé ogun àti sìgá mímu lárugẹ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń ṣekú pa ọ̀pọ̀ ènìyàn