ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 10/8 ojú ìwé 9-11
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Fi Bojúbojú Ìpolongo Èké Bò Ọ́ Lójú!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Fi Bojúbojú Ìpolongo Èké Bò Ọ́ Lójú!
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Tòótọ́ Dojúùjà Kọ Ìpolongo Èké
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Sátánì Tàn Ẹ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Jẹ́ Kí Ọkàn Àyà Rẹ Fà Sí Ìfòyemọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìwọ́ Ha Lè Mú Ìfòyemọ̀ Dàgbà Sí I Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Fífi Ọgbọ́n Yí Ọ̀rọ̀ Po
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 10/8 ojú ìwé 9-11

Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Fi Bojúbojú Ìpolongo Èké Bò Ọ́ Lójú!

“Òmùgọ̀ ní í gba ohunkóhun gbọ́.”—ÒWE 14:15, TODAY’S ENGLISH VERSION.

ÌYÀTỌ̀ ńlá wà láàárín ìlàlóye àti ìpolongo èké. Ìlàlóye yóò fi bó ṣe yẹ kí o ronú hàn ọ́. Ìpolongo èké yóò sọ ohun tó yẹ kí o rò fún ọ. Olùkọ́ dáradára yóò ṣàlàyé gbogbo ohun tó bá wà nídìí ọ̀ràn kan fúnni, yóò sì fàyè sílẹ̀ fún ìjíròrò. Àwọn olùpolongo èké máa ń fipá múni láti tẹ́tí sí èrò tiwọn nìkan ni, wọn kì í sì í fàyè sílẹ̀ fún ìjíròrò. Lọ́pọ̀ ìgbà, ète wọn ní ti gidi kì í yéèyàn. Wọ́n a ṣa òtítọ́ lẹ́yọlẹ́yọ, wọ́n á lo èyí tó wúlò níbẹ̀ fún àǹfààní ara wọn, wọ́n á sì gbé àwọn yòókù pa mọ́. Wọ́n tún máa ń yí òtítọ́ po, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ògbógi nínú irọ́ pípa àti sísọ òtítọ́ láàbọ̀. Èrò rẹ ni wọ́n máa ń fẹ́ yí padà, wọn kì í fẹ́ kí o ronú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.

Olùpolongo èké máa ń rí i dájú pé ọ̀rọ̀ òun dà bí èyí tó tọ́ tó sì yẹ àti pé bí o bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ òun, o di èèyàn pàtàkì àti ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ nìyẹn. Pé ọ̀kan lára àwọn tó gbọ́n féfé ni ọ́, pé ẹ pọ̀ tí ẹ ní ànímọ́ yẹn, pé kò síyè méjì lọ́rọ̀ ẹ àti pé kò séwu lọ́rọ̀ ẹ—ohun tí wọ́n fẹ́ kí o gbà gbọ́ nìyẹn.

Báwo lo ṣe wá lè sá fún irú àwọn èèyàn tí Bíbélì pè ní “àwọn asọ̀rọ̀ tí kò lérè” àti “àwọn tí ń tan èrò inú jẹ”? (Títù 1:10) Gbàrà tí o bá ti mọ díẹ̀ lára ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí wọ́n máa ń lò, ó ti dájú pé o ní àǹfààní láti gbé ohunkóhun tí wọ́n bá sọ fún ọ yẹ̀ wò. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí o lè gbà ṣe é nìyí.

Máa ṣàṣàyàn: A lè fi ọkàn tó ń gba gbogbo nǹkan wé páìpù kan tí gbogbo nǹkan ń gba inú rẹ̀ kọjá—kódà ìdọ̀tí pàápàá. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n fi nǹkan burúkú ba òun lọ́kàn jẹ́. Sólómọ́nì, tí í ṣe ọba àti olùkọ́ni láyé àtijọ́, kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Nítorí náà, a ní láti máa ṣàṣàyàn. A ní láti ṣàyẹ̀wò fínnífínní nípa ohun tí wọ́n bá sọ fún wa, kí a pinnu ohun tí a óò tẹ́wọ́ gbà àti èyí tí a kò ní gbà.

Bó ti wù kó rí, a kò ní fẹ́ jẹ́ ẹni tí kì í fọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n, tí kì í gbé àwọn òkodoro òtítọ́ tó lè mú kí ìrònú wa sunwọ̀n sí i yẹ̀ wò. Báwo ni a ṣe lè ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì? Nípa níní ọ̀pá ìdiwọ̀n kan tí a óò fi máa díwọ̀n ìsọfúnni tuntun. Orísun ọgbọ́n ńláǹlà wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí Kristẹni kan lè mú lò. Ó ní Bíbélì lárọ̀ọ́wọ́tó gẹ́gẹ́ bí atọ́nà tí ó dájú tó lè fi tọ́ ìrònú rẹ̀ sọ́nà. Ní ọwọ́ kan, ọkàn rẹ̀ wà ní ṣíṣísílẹ̀, ìyẹn ni pé, ó ṣe tán láti tẹ́tí sí àwọn ìsọfúnni tuntun. Yóò gbé àwọn ìsọfúnni tuntun náà yẹ̀ wò dáadáa ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí a lànà rẹ̀ sínú Bíbélì, yóò wá mú èyí tó jẹ́ òtítọ́ lò nínú ìlànà ìrònú rẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọkàn rẹ̀ yóò rí ewu tó wà nínú àwọn ìsọfúnni tí kò bá àwọn ìwà ọmọlúwàbí tí a lànà rẹ̀ sínú Bíbélì mu.

Lo ìfòyemọ̀: Ìfòyemọ̀ jẹ́ “pípinnu lórí nǹkan lọ́nà tó fi òye hàn.” Ó jẹ́ “agbára tí èrò orí fi ń mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Ẹni tó ní agbára ìfòyemọ̀ lè mọ̀ bóyá àwọn èròǹgbà tàbí àwọn ohun kan jẹ́ àyínìke, ó sì ní òye.

Táa bá lo ìfòyemọ̀, a óò lè mọ àwọn tó wulẹ̀ ń lo “ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in àti ọ̀rọ̀ ìyinni” láti lè “sún ọkàn-àyà àwọn aláìlẹ́tàn dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 16:18) Ìfòyemọ̀ yóò jẹ́ kí o lè kọ àwọn ìsọfúnni tí kò mọ́yán lórí tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ṣini lọ́nà, yóò sì jẹ́ kí o lè pinnu bí ọ̀ràn ṣe rí gẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè mọ̀ tí nǹkan kan bá jẹ́ ohun ìṣìnà?

Wádìí òkodoro ọ̀rọ̀ náà: Jòhánù, tí í ṣe Kristẹni olùkọ́ kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò.” (1 Jòhánù 4:1) Bíi tìmùtìmù làwọn èèyàn kan rí; gbogbo nǹkan olómi ni wọ́n máa ń fà mu. Ó rọrùn gan-an láti gba ohunkóhun tí a bá rí gbọ́.

Ṣùgbọ́n ì bá dára gan-an kí olúkúlùkù yan ohun tí yóò máa gbà sọ́kàn rẹ̀. Àwọn kan máa ń sọ pé ohun tí a bá jẹ sínú wa ni wá, èyí sì lè kan ohun tí a ń jẹ sínú àti ohun tí a ń gbà sínú ọkàn wa. Ohun yòówù kí o máa kà tàbí kí o máa wò tàbí kí o máa gbọ́, gbìyànjú láti wádìí bóyá ó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìpolongo èké tàbí bóyá òtítọ́ ni.

Ní àfikún sí i, bí a bá fẹ́ ṣe ohun tó tọ̀nà, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa yẹ èrò tiwa alára wò léraléra bí a ti ń gba ìsọfúnni tuntun. A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé èròǹgbà lásán ni wọ́n. Bí wọ́n tó ohun tí àá gbẹ́kẹ̀ lé sinmi lórí bí àwọn ẹ̀rí táa ní ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó, lórí bí agbára ìrònú wa ṣe jẹ́ ojúlówó tó, àti lórí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tàbí ìlànà tí a yàn láti lò.

Béèrè ìbéèrè: Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ọ̀pọ̀ èèyàn wà lónìí tí wọn yóò fẹ́ láti ‘fi àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà mọ̀ọ́mọ̀ ṣì wá lọ́nà.’ (Kólósè 2:4) Nítorí náà, bí ẹnì kan bá ń ṣàlàyé nǹkan kan fún wa láti yí wa lérò padà, ó yẹ ká béèrè ìbéèrè.

Lákọ̀ọ́kọ́, wádìí wò bóyá ọ̀ràn ẹ̀tanú ni. Kí ló mú kí wọ́n wá sọ ọ̀rọ̀ náà? Bí ìsọfúnni náà bá kún fún ọ̀rọ̀ pípe èèyàn ní orúkọ burúkú, tí ọ̀rọ̀ burúkú sì pọ̀ nínú rẹ̀, kí ló fa ìyẹn? Yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ burúkú tó kún inú rẹ̀, àwọn àǹfààní wo ló wà nínú ìsọfúnni náà? Bákan náà, bó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti yẹ àkọsílẹ̀ nípa ohun tí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ náà ti gbé ṣe nínú ìgbésí ayé wọn wò. Ǹjẹ́ a mọ̀ wọ́n sí ẹni tó máa ń sọ òtítọ́? Bí wọ́n bá tọ́ka sí “àwọn ọlá àṣẹ tàbí ìwé,” ta ni wọ́n tọ́ka sí tàbí kí ni ohun náà jẹ́? Èé ṣe tó fi yẹ kí o ka ẹni náà—tàbí àjọ tàbí ìwé náà—sí ògbógi tó ní ìmọ̀ tàbí sí ìsọfúnni tó ṣeé gbíyè lé nípa ọ̀ràn tó ń sọ? Bí o bá ṣàkíyèsí pé ó ń gbìyànjú láti yí ọ lérò padà ni, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Bí a bá mú ọ̀ràn ti yíyíni lérò padà kúrò nínú ìsọfúnni yìí, àwọn àǹfààní wo ló wà nínú rẹ̀?’

Má fi ṣe ọ̀ràn màá ṣe ohun táyé ń ṣe: Bí o bá rí i pé ohun tí gbogbo èèyàn ń rò nípa rẹ̀ kò fi dandan tọ̀nà, o lè gbìyànjú láti sapá láti ronú gba ibòmíràn ní tìẹ. Bó tilẹ̀ jọ pé gbogbo àwọn yòókù ń ronú gba ibì kan náà, ṣe ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìwọ náà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń ronú lọ́nà kan náà kì í ṣe ọ̀pá ìdiwọ̀n tó dára láti fi pinnu ohun tó jẹ́ òtítọ́. Láti ọdúnmọ́dún ni àwọn èèyàn ti ń tẹ́wọ́ gba onírúurú èròǹgbà, àmọ́ tí wọ́n wá rí i níkẹyìn pé kò tọ̀nà. Òtítọ́ ni, ìtẹ̀sí náà pé kí àwọn èèyàn sùn kí wọ́n sì kọrí síbì kan náà kì í tán bọ̀rọ̀. Àṣẹ tí a rí nínú Ẹ́kísódù 23:2 jẹ́ ìlànà rere, ó ní: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.”

Ìmọ̀ Tòótọ́ Dojúùjà Kọ Ìpolongo Èké

A ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Bíbélì ni atọ́nà tó dájú tó ń ṣamọ̀nà sí ìrònú tó ṣe kedere. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù bá Ọlọ́run sọ gbọ́, wọ́n sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Èyí jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run, tó jẹ́ Orísun Bíbélì, ni “Ọlọ́run òtítọ́.”—Sáàmù 31:5.

Dájúdájú, ní sànmánì yìí tó jẹ́ pé ìpolongo èké dídùn mọ̀ràn-ìn-mọran-in ló gbòde, a lè gbọ́kàn lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí orísun òtítọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, èyí yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ‘fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó wa nífà.’—2 Pétérù 2:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Agbára ìfòyemọ̀ yóò jẹ́ kí o lè kọ àwọn ìsọfúnni tí kò mọ́yán lórí tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ṣini lọ́nà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Wádìí ohunkóhun tí o ń kà tàbí tí o ń wò dáadáa láti mọ̀ bóyá òótọ́ ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Èròǹgbà tó wọ́pọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣeé gbíyè lé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

A lè fi ìgbọ́kànlé yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí orísun òtítọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́