ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 10/8 ojú ìwé 3
  • Ìpolongo Èké Lè Ṣekú Pani

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpolongo Èké Lè Ṣekú Pani
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Sátánì Tàn Ẹ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Fífi Ọgbọ́n Yí Ọ̀rọ̀ Po
    Jí!—2000
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Fi Bojúbojú Ìpolongo Èké Bò Ọ́ Lójú!
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 10/8 ojú ìwé 3

Ìpolongo Èké Lè Ṣekú Pani

“Òtítọ́ dọ́jà ó kùtà, owó lọ́wọ́ ni wọ́n ń rèké.”—Wọ́n ní MARK TWAIN pa òwe kan tó jọ èyí.

“ÌWỌ Júù alákọrí yìí!” Bí olùkọ́ kan ṣe kígbe mọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méje ní kíláàsì rẹ̀ nìyẹn, ó sì tún di ìgbájú rù ú. Ó tún ní kí àwọn ọmọdé yòókù ní kíláàsì náà máa tò kọjá níwájú rẹ̀ kí wọ́n sì máa bẹ́tọ́ lù ú lójú.

Olùkọ́ náà àti akẹ́kọ̀ọ́ yẹn—tó jẹ́ ìbátan olùkọ́ náà—mọ̀ dáadáa pé ọmọdékùnrin náà àti àwọn òbí rẹ̀ kì í ṣe ìran Júù. Àti pé wọ́n kì í ṣe ẹlẹ́sìn Júù. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Àǹfààní pé àwọn èèyàn ní ẹ̀tanú sí àwọn Júù níbi gbogbo ni olùkọ́ náà ń lò kí àwọn èèyàn bàa lè kórìíra akẹ́kọ̀ọ́ náà. Tipẹ́tipẹ́ ni olùkọ́ tí a ń sọ yìí àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ti gbọ́ lẹ́nu àwọn àlùfáà pé aláìníláárí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti máa ń sọ pé àwọn òbí ọmọdékùnrin náà wà nínú ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì, àti pé wọ́n jẹ́ aṣojú àwọn àjọ CIA (Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà). Ìdí nìyẹn tí àwọn ẹlẹgbẹ́ ọmọ náà fi tò, tí wọ́n ń hára gàgà láti bẹ́tọ́ lu “Júù alákọrí” lójú.

Ọmọdékùnrin náà là á já, òun fúnra rẹ̀ ló sì sọ ìtàn náà. Àmọ́, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ fún mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù tó ń gbé Jámánì àti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn. Wọ́n fi ẹ̀tanú lo ìpolongo èké láti gbẹ̀mí àwọn Júù wọ̀nyẹn ní ìyẹ̀wù tí wọ́n ti ń fi afẹ́fẹ́ olóró pani àti àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí ìjọba Násì kọ́. Ìkórìíra àwùjọ àwọn Júù lọ́nà rírorò níbi gbogbo, tí kò sì sẹ́ni tó máa bini ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ka àwọn Júù sí ọ̀tá tó yẹ tó sì tọ́ láti pa. Nípa bẹ́ẹ̀, ìpolongo èké wá di ohun ìjà tí wọ́n lò láti pa àwọn èèyàn lápalù.

Dájúdájú, ìpolongo èké ni a máa ń ṣe ní gbangba nípa lílo àwọn ohun tí ń ṣàpẹẹrẹ ìkórìíra bí àsíá swastika tàbí nípa ṣíṣe àwọn yẹ̀yẹ́ tí kò bójú mu, lọ́nà àrékérekè. Fífi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yíni lérò padà náà ni àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀, àwọn òṣèlú, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn olùpolówó ọjà, àwọn olùtajà, àwọn oníròyìn, àwọn gbajúmọ̀ orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò, àwọn aṣojú ilé iṣẹ́, àti àwọn mìíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí dídarí ìrònú àti ìwà àwọn èèyàn sábà máa ń lò.

Lóòótọ́, wọ́n lè lo àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ ìpolongo láti ṣàṣeyọrí àwọn ohun tó ń ṣe àwùjọ ẹ̀dá láǹfààní, bíi ti ìkéde láti dín wíwakọ̀ nígbà téèyàn bá ti mutí kù. Ṣùgbọ́n wọ́n tún lè lo ìpolongo èké láti gbé ìkórìíra àwọn ẹ̀yà tàbí ìsìn tí kò lérò púpọ̀ lárugẹ tàbí láti fi fa àwọn èèyàn mọ́ra láti ra sìgá. Àwọn olùwádìí náà, Anthony Pratkanis àti Elliot Aronson sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń fi ìjíròrò ayíni-lérò-padà ọlọ́kan-ò-jọ̀kan yọ wá lẹ́nu. Kì í ṣe nípa ìfèròwérò àti iyàn jíjà ni wọ́n ń gbà lo àwọn ìjíròrò yìí láti fi yí wa lérò padà, bí kò ṣe nípa fífọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo àwọn ohun ìwúrí àti dídarí ìmí ẹ̀dùn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Yálà ó bí ire tàbí aburú, sànmánì tiwa yìí jẹ́ sànmánì ìpolongo èké.”

Báwo ni wọ́n ṣe ń lo ìpolongo èké láti yí ìrònú àti ìṣesí ẹ̀dá padà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún? Kí ni o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ìpolongo tó léwu? Ǹjẹ́ orísun ìsọfúnni kan wà tó ṣeé gbíyè lé? Àwọn ìbéèrè yìí àti àwọn mìíràn ni a óò jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Wọ́n lo ìpolongo èké láti fìyà jẹ àwọn Júù nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́