Ṣé Kí N Máa Lo Oògùn Aspirin Lójoojúmọ́—Àbí Kí N Má Lò Ó?
Ohun táa fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi ni o, dókítà kan ló sọ ọ́. Ó fi ìṣòro tó máa ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ hàn.
Ẹ̀RÙ ń ba gbogbo mẹ́ńbà ìdílé. Ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí ba dókítà alára. Dókítà sọ pé: “Bí ẹ̀jẹ̀ ò bá yé dà lára ẹ̀, bóyá la ò ní fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára.”
Láti ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ni ìfun ọkùnrin yìí ti ń ṣẹ̀jẹ̀ díẹ̀díẹ̀, dókítà sì ṣàwárí pé ohun tó ń fa ìṣòro náà ni pé ikùn rẹ̀ ń wú. Gbogbo ẹ̀ ti tojú sú dókítà náà, àmọ́, ó wá béèrè pé: “Ṣé ó dá ẹ lójú pé o kì í lo àwọn oògùn kan?”
Ọkùnrin náà sọ pé: “Rárá o. Àfi oògùn apàrora yìí tí mo rà lórí igbá, tí mo ń lò fún oríkèé ara tó máa ń ro mí.”
Etí dókítà nà. Ó ní: “Mú un wá, jẹ́ kí n wò ó.” Ló bá fara balẹ̀ ka ìwé àlàyé tí wọ́n kọ àwọn èròjà inú rẹ̀ sí, lójú ẹ̀ bá ta kán rí ohun tó ń wá. Ásíìdì acetylsalicylic! Àbùṣe bùṣe. Nígbà tí aláìsàn náà jáwọ́ lílo àwọn oògùn náà tó ní èròjà aspirin nínú, tí wọ́n sì fún un ní oògùn tó ní èròjà iron àti àwọn oògùn kan tó ń wo ìṣòro ikùn sàn, ni ẹ̀jẹ̀ bá dá, ẹ̀jẹ̀ tó wà lára ẹ̀ náà sì tún pọ̀ sí i.
Nígbà Tí Oògùn Bá Ń Mú Kẹ́jẹ̀ Dà Lára
Lóde òní, ìṣòro ńlá kan táwọn oníṣègùn ń bá jà ni ọ̀ràn kí ìfun máa ṣẹ̀jẹ̀ nítorí oògùn téèyàn ń lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ oògùn ló lè ṣàkóbá náà, ṣùgbọ́n àwọn oògùn tí wọ́n fi ń wo àìsàn oríkèé ara to ń roni àti ìrora ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Àwọn oríṣi oògùn tí wọ́n ń pè ní NSAIDS tí kì í jẹ́ kí iṣan le, tí kì í sì í jẹ́ kára wú pẹ̀lú ń fà á. Orúkọ tí wọ́n ń pè é lórílẹ̀-èdè kan lè yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń pè é lórílẹ̀-èdè míì.
Èròjà aspirin máa ń wà nínú púpọ̀ lára àwọn oògùn tí wọ́n ń tà lórí igbá, bákan náà ni ìwọ̀n aspirin táwọn èèyàn ń lo lójúmọ́ ti pọ̀ sí i láwọn ọdún àìpẹ́ yìí ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Èé ṣe?
Bíbẹ́ Mọ́ Oògùn Aspirin
Ní ọdún 1995, lẹ́tà ìròyìn Harvard Health Letter sọ pé, “lílo aspirin déédéé ń gba ẹ̀mí là.” Àwọn olùwádìí tọ́ka sí àwọn ìwádìí mélòó kan tí wọ́n ti ṣe lọ́pọ̀ ìgbà káàkiri ayé, láti ìgbà náà wá, wọ́n wá sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tí àrùn ọkàn tàbí àrùn ẹ̀gbà ti ṣe rí, tí àyà ti dùn rí, tàbí tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ iṣan òpójẹ̀ fún nípa lílo òpójẹ̀ àtọwọ́dá ló yẹ kó máa lo tábúlẹ́ẹ̀tì aspirin kan àtààbọ̀ lójoojúmọ́ àyàfi bí wọ́n bá léèwọ̀ ara fún oògùn náà.”a
Àwọn olùwádìí mìíràn sọ pé lílo aspirin lójoojúmọ́ máa ń ṣàǹfààní fáwọn ọkùnrin tó ti lé ní àádọ́ta ọdún, tó ṣeé ṣe kí àrùn ọkàn ṣe wọ́n àti àwọn obìnrin pẹ̀lú. Síwájú sí i, àwọn ìwádìí kan wà tó fi hàn pé lílo aspirin lójoojúmọ́ lè dín ewu níní àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun ńlá kù àti pé tí ẹni tó lárùn àtọ̀gbẹ bá lò ó tó pọ̀ gan-an fúngbà pípẹ́, ó lè dín ìwọ̀n ṣúgà tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kù.
Báwo ni aspirin ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí yóò fi lè ṣe àwọn àǹfààní tí wọ́n sọ yìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀ kọ́ ni wọn mọ̀, ẹ̀rí fi hàn pé bí aspirin bá ń ṣiṣẹ́, kì í jẹ́ kí àwọn sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lẹ̀ mọ̀dẹ̀mọ̀dẹ̀, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ṣíṣẹ̀dá èròjà tó ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì. A lè sọ pé ó ń ṣiṣẹ́ láti dènà dídí àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ kéékèèké tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ọkàn-àyà àti ọpọlọ, táá sì wá tipa bẹ́ẹ̀ dènà bíba àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì jẹ́.
Pẹ̀lú gbogbo àǹfààní tí wọ́n gbà pé aspirin ń ṣe yìí, kí ló wá dé tí gbogbo èèyàn ò máa lò ó? Ohun kan ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọn ò tíì mọ̀ nípa rẹ̀. Kódà, wọn ò tíì mọ ìwọ̀n tó yẹ kéèyàn máa lò. Ìwọ̀n tí wọ́n máa ń kọ féèyàn bẹ̀rẹ̀ láti orí odindi tábúlẹ́ẹ̀tì kan lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́ dé orí ẹyọ aspirin ọmọdé kan lójoojúmọ́. Ṣé ó yẹ kí ìwọ̀n tí obìnrin máa lò yàtọ̀ sí ti ọkùnrin? Àwọn dókítà ò lè sọ ní pàtó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè wò ó pé àwọn aspirin tí kì í túká nínú agbẹ̀du títí yóò fi dénú ìfun wúlò, síbẹ̀síbẹ̀, àríyànjiyàn ṣì wà lórí àǹfààní tí aspirin tí ò ní kẹ́míkà nínú ń ṣe.
Àwọn Ìdí Táa Fi Gbọ́dọ̀ Ṣọ́ra
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé táa bá wo aspirin dáadáa, egbòogi tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ dá ni—inú èèpo igi pankẹ́rẹ́ ni àwọn Àmẹ́ríńdíà ti ń yọ àwọn èròjà ẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn jàǹbá tó máa ń ṣe fún ara pọ̀. Yàtọ̀ sí pé aspirin ń fa kí ẹ̀jẹ̀ máa dà lára àwọn èèyàn kan, àwọn ìṣòro míì wà tó lè fà, títí kan àmì èèwọ̀ ara tí aspirin máa ń jẹ́ kó yọ lára àwọn èèyàn kan. Ó hàn kedere pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ni lílo aspirin lójoojúmọ́ bá lára mu.
Àmọ́ ṣá o, ẹni tó ṣeé ṣe kó ní àrùn ọkàn tàbí àrùn ẹ̀gbà tàbí tí àwọn ohun kan pàtó tó ń fa àrùn ń yọ lẹ́nu, lè béèrè lọ́wọ́ dókítà rẹ̀ nípa àwọn ewu àti àǹfààní tó lè tìdí lílo aspirin lójoojúmọ́ wá. Dájúdájú, aláìsàn náà ní láti rí i dájú pé òun ò ní ìṣòro ẹ̀jẹ̀ dídà lára, pé ara òun ò kọ aspirin, àti pé kì í fún òun níṣòro nínú agbẹ̀du tàbí nínú ìfun. Kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, ó yẹ kóo kọ́kọ́ bá dókítà jíròrò àwọn ìṣòro míì tó lè yọjú tàbí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bóo bá lò ó pọ̀ mọ́ àwọn oògùn mìíràn.
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, lílo àwọn oògùn aspirin àti àwọn oògùn tó dà bí aspirin máa ń fa ewu kẹ́jẹ̀ máa dà lára. Èèyàn sì lè má mọ̀ pé òun ń da ẹ̀jẹ̀ lára, ó lè má tètè fara hàn, kí ìṣòro náà sì máa pọ̀ sí i bí àkókò ti ń lọ. A tún ní láti gbé àwọn oògùn mìíràn yẹ̀ wò dáadáa, ní pàtàkì àwọn oògùn mìíràn tí ń gbógun ti ara wíwú. Rí i dájú pé o sọ fún dókítà rẹ tóo bá ń lo èyíkéyìí lára wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, yóò bọ́gbọ́n mu láti má ṣe lo oògùn náà mọ́ gbàrà tó bá kù díẹ̀ kóo ṣe iṣẹ́ abẹ́. Bóyá ṣíṣàyẹ̀wò déédéé láti mọ bí ẹ̀jẹ̀ ṣe pọ̀ tó lára lè ṣèrànwọ́.
Báa bá fẹ́ dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ìṣòro ọjọ́ iwájú, a óò fi òwe Bíbélì sílò, ó wí pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Nínú ọ̀ràn nípa ìtọ́jú táa ń sọ yìí, kí Ọlọ́run jẹ́ ká wà lára àwọn afọgbọ́nhùwà, ká má bàa jìyà o.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe pé Jí! ń dámọ̀ràn oríṣi ìtọ́jú pàtó kan féèyàn o.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn Tí Lílo Oògùn Aspirin Lójoojúmọ́ Tọ́ Sí
● Àwọn tí wọ́n ní àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn-àyà tàbí tí òpójẹ̀ tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ sórí wọn kéré (ìyẹn àwọn òpójẹ̀ pàtàkì tó wà lọ́rùn).
● Àwọn tí wọ́n ti ní àrùn ẹ̀gbà oríṣi kan báyìí èyí tí ẹ̀jẹ̀ dídì nínú ara máa ń fà, tàbí àwọn tí àìsàn kan tó fẹ́ jọ àrùn ẹ̀gbà ti dá wọn gúnlẹ̀ fúngbà díẹ̀ rí.
● Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti lé ní àádọ́ta ọdún, tí wọ́n ní ọ̀kan tàbí mélòó kan lára àwọn ohun tó lè fa àrùn inú òpójẹ̀ tó lọ sínú ọkàn-àyà irú bíi: sìgá mímu, ẹ̀jẹ̀ ríru, àtọ̀gbẹ, àpọ̀jù èròjà cholesterol lára, àìtó èròjà protein nínú ẹ̀jẹ̀, ìsanra jọ̀bọ̀tọ̀, mímutí jù, àwọn tí ìbátan wọ́n ti ní àrùn inú iṣan ọpọlọ rí (àrùn ọkàn láìtíì pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta) tàbí àrùn ẹ̀gbà, àti ìgbésí ayé jíjókòó tẹtẹrẹ sójú kan.
● Àwọn obìnrin tó ti lé ní àádọ́ta ọdún tó ní méjì tàbí mélòó kan lára àwọn ohun wọ̀nyẹn tó máa ń fa àrùn.
Bóyá wàá fẹ́ bá dókítà rẹ jíròrò kóo tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí lórí ọ̀ràn yìí.
[Credit Line]
Orísun: Consumer Reports on Health