ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 7/8 ojú ìwé 24-25
  • Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Wíwọkọ̀ Ọ̀fẹ́ Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Wíwọkọ̀ Ọ̀fẹ́ Kiri
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òmìnira Láti Lọ Síbikíbi
  • Bíbá àwọn Ará Ilé Sọ̀rọ̀
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • Ìrìn Àjò sí Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù
    Jí!—1997
  • Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 7/8 ojú ìwé 24-25

Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Wíwọkọ̀ Ọ̀fẹ́ Kiri

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ

Lọ́jọ́ kan báyìí, tóoru mú nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ní ọdún 1990, Paul Onions, ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún, gbé àpò ẹrù ẹ̀ pọ̀n sẹ́yìn bó ti dúró tó ń wá ọkọ̀ ọ̀fẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Títì Hume, ní gúúsù ìlú Sydney, ní Ọsirélíà. Inú Paul dùn nígbà tí àjèjì kan dúró láti fọkọ̀ ẹ̀ gbé e lọ́fẹ̀ẹ́. Kó fura rárá pé ọkọ̀ ọ̀fẹ́ tí òun wọ̀ yẹn á fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí òun.a

PAUL kò fura pé ewu ń bẹ, ló bá jókòó síwájú ọkọ̀ náà, ó sì ń bá awakọ̀ tàkúrọ̀sọ. Èyí tí a n wí yìí pẹ́ jù, ohùn awakọ̀ tó dàbí olóore náà ti bẹ̀rẹ̀ sí le, ó sì ń jiyàn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lawakọ̀ ọ̀hún bá ṣàdédé yà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní òun fẹ́ mú àwọn kásẹ́ẹ̀tì orin jáde lábẹ́ ìjókòó ọkọ̀. Ṣùgbọ́n kásẹ́ẹ̀tì kọ́ ló mú jáde o, ìbọn ló fà yọ—ló bá náà sí Paul nígbáàyà.

Gbogbo bí awakọ̀ náà ṣe ń pariwo mọ́ ọn pé kò gbọ́dọ̀ mira, Paul ò dáhùn o, kíá ló tú okùn tó fi de ara rẹ̀ mọ́ àga ọkọ̀, ó bẹ́ jáde kúrò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, ó sì ń fi gbogbo agbára sá lọ lójú pópó. Awakọ̀ náà mú un lé lójú gbogbo àwọn awakọ̀ mìíràn. Níkẹyìn, ó lé e bá, ó bu aṣọ alápá péńpé tó wọ̀ so, ó wọ́ ọ mọ́ra, ó sì tì í lulẹ̀. Pọ́rọ́ tí Paul bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ báyìí, ńṣe ló sáré lọ pàdé ọkọ̀ akẹ́rù kan tó ń bọ̀ níwájú ẹ̀, ìyẹn mú kí obìnrin awakọ̀ náà, tí ìbẹ̀rùbojo ti mú, tí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀ wà nínú ọkọ̀, dá ọkọ̀ dúró. Nítorí ẹ̀bẹ̀ tí Paul ń bẹ ìyá náà, ó gbà kó wọlé, ló bá yíjú ọkọ̀ padà sí òdìkejì, ó tẹná mọ́ ọkọ̀, ó sì sá lọ. Ẹ̀yìn náà ni wọ́n tó wá mọ̀ pé ńṣe ni ọkùnrin tó gbéjà ko Paul yìí ń pa àwọn ènìyàn ṣeré, ó sì ti gbẹ̀mí àwọn méje míì táwọn náà gbápò ẹrù pọ̀n sẹ́yìn, táwọn kan lára wọn jẹ́ àwọn tó ń wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri ní méjìméjì.

Kí ló dé tó jẹ́ irú àwọn èèyàn wọ̀nyí ni apànìyàn yìí fojú sùn? Níbi ìgbẹ́jọ́ apànìyàn náà, nǹkan tí adájọ́ sọ ni pé: “Ọ̀dọ́ ni gbogbo àwọn tó pa. Ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún sí méjìlélógún. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ti rìn jìnnà sílé, èyí tó túmọ̀ sí pé bí wọ́n bá tiẹ̀ ti sọnù tàbí tí wọ́n ti kú, wọn ò lè tètè mọ̀ nílé.”

Òmìnira Láti Lọ Síbikíbi

Àǹfààní láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì ti túbọ̀ ṣí sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lóde òní ju bó ti rí láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, láàárín ọdún márùn-ún, iye àwọn ará Ọsirélíà tó ṣèbẹ̀wò sí Éṣíà lé ní ìlọ́po méjì. Látàrí pé wọ́n ń wá ìrírí tàbí ìgbádùn mánigbàgbé kiri, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba àti àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ló ń wọ ọkọ̀ òfúúrufú tó ń lọ sáwọn ibi tó jìnnà tùn-ùnnù tun-unnu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn arìnrìn-àjò yìí ló máa ń ní in lọ́kàn láti wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kówó tí wọ́n máa ná lè dín kù. Ó dunni pé, ní àwọn ibi tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé, wíwọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri kì í tún ṣe ọ̀nà tó ń gbádùn mọ́ni tàbí tí kò léwu téèyàn lè gbà rìnrìn àjò bíi ti ìgbà kan mọ́, bóyá fún àwọn tó ń wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri tàbí àwọn awakọ̀ tó ń gbé wọn.

Pé èèyàn lẹ́mìí tó dára tàbí pé inú ẹ̀ ń dùn nítorí àtirìnrìn àjò kò dà bí kéèyàn fara balẹ̀, kó ní ọgbọ́n tó ṣeé mú lò. Ìwé kékeré kan tí wọ́n kọ nítorí àwọn ìdílé tó ń wá àwọn ọmọ wọn tó sọnù sọ pé: “Ìháragàgà àwọn ọ̀dọ́ láti rìnrìn àjò sábà máa ń túmọ̀ sí pé wọ́n á kàn gbéra ni láìmúra sílẹ̀ dáadáa fún ìrìn-àjò náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ewu tó ń bẹ níbẹ̀ tàbí ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe.”

Ìwé kékeré náà fi kún un pé: “Ó ṣọ̀wọ́n káwọn èèyàn tó lè sọnù tí wọ́n bá bá àwùjọ kan tí wọ́n ṣètò ìrìn-àjò wọn rìn, tí wọ́n lọ nítorí iṣẹ́, tàbí tí wọ́n tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ bí wọ́n ṣe máa rìnrìn àjò wọn. Ì báà jẹ́ ní Ọsirélíà ni o tàbí ní orílẹ̀-èdè míì, ó jọ pé àwọn tó gbápò ẹrù wọn pọ̀n tí wọ́n sì ń wá ọkọ̀ olówó pọ́ọ́kú ló pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń kà mọ́ àwọn tó sọnù nígbẹ̀yìngbẹ́yín.”

Bóyá èèyàn wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri o tàbí kò wọ̀ ọ́, rírìnrìn àjò láìṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìrìn àjò—bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí kò fẹ́ kí nǹkankan ká wọn lọ́wọ́ kò máa ń nífẹ̀ẹ́ sí i, lè túbọ̀ fi ẹnì kan sínú ewu. Nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ kò bá mọ apá ibi tí arìnrìn-àjò kan gbà lọ, wọn ò ní lè ṣèrànwọ́ tí ìṣòro bá ṣẹlẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe máa rí ká ní arìnrìn-àjò kan wà ní ọsibítù níbi tó dákú sí, tí ẹnì kankan nílé ò sì mọ ibi tó wà?

Bíbá àwọn Ará Ilé Sọ̀rọ̀

Richard Shears, akọ̀ròyìn ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ nínú ìwé rẹ̀ Highway to Nowhere nípa àwọn méje kan tó ń wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri tí wọ́n sì di àwátì “tó jẹ́ pé àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n dáwọ́ bíbá àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ dúró.” Ó dájú pé, àwọn ìdílé lè máà kọ́kọ́ mọ̀ bóyá mọ̀lẹ́bí wọn ti sọnù tàbí pé àwọn ò kàn gbúròó wọn ni. Èyí lè máà jẹ́ kí wọ́n tètè sọ fún àwọn agbófinró nígbà tí wọn ò bá gbúròó àwọn arìnrìn-àjò náà.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀kan lára àwọn tó ń wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri náà ti ṣíwọ́ bíbá àwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù nígbà tí kò bá sówó lọ́wọ́ ẹ̀ mọ́. Nígbà táwọn òbí ẹ̀ sì ti fura pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn, wọ́n wá rọ àwọn ìdílé tó kù pé kí àwọ́n fi káàdì tẹlifóònù ránṣẹ́ sáwọn ọmọ àwọn tàbí kí àwọ́n ṣètò ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà fi bá ará ilé sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe èyí lè máà dá ẹ̀mí ọ̀dọ́mọbìnrin yìí sí, àmọ́ bíbá àwọn ará ilé sọ̀rọ̀ déédéé lè ran arìnrìn-àjò náà lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà láti má ṣe kó sínú àwọn ìṣòro kéékèèké, tàbí ó kéré tan, á jẹ́ kó lè kojú wọn.

Àwọn méje tó gbápò ẹrù wọn pọ̀n sẹ́yìn náà, tí wọ́n sì kú lẹ́yìn náà lè ti ka àwọn ìwé to sọ pé Ọsirélíà ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó láàbò jù lọ lágbàáyé fún àwọn tó ń wọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri. Síbẹ̀síbẹ̀, wíwọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri lẹ́ẹ̀kan sí i jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ fẹ̀mí ara ẹni wewu—èèyàn ì báà lọ ní méjìméjì tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ ni orílẹ̀-èdè tó “láàbò jù lọ.” Ó sàn púpọ̀ kéèyàn kúkú wo ọ̀ràn bó ti rí gan-an, kó yẹra fún ewu, kó sì padà sílé láyọ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òfin ò fàyè gba wíwọkọ̀ ọ̀fẹ́ kiri láwọn ibì kan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn òbí lè yẹra fún ṣíṣàníyàn láìnídìí tí wọ́n bá pèsè káàdì tẹlifóònù fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí wọ́n ṣètò ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà fi bá ará ilé sọ̀rọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́