Èdè—Òun Ló Ń Ṣínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, Òun Náà Ló Ń Dènà Rẹ̀
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ
“Kò sí ìtàn tó lè ṣàlàyé tó pé pérépéré fún wa nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rere tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn kan, tàbí nípa ẹgbẹ́ àwùjọ wọn, ìgbàgbọ́ wọn, àti ẹ̀dùn ọkàn wọn tó lè dà bí èyí tí àyẹ̀wò èdè wọn lè ṣe.”—MARTÍN ALONSO.
NÍNÚ gbogbo ìtàn táa ti gbọ́, èdè—orísun rẹ̀, bó ṣe wà lónírúurú, àti bó ṣe ń yí padà léraléra—ti fa àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mọ́ra. Kódà, ohun tó fà wọ́n mọ́ra nípa rẹ̀ tilẹ̀ wà nípamọ́—gẹ́gẹ́ bí a ṣe pa èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ mọ́—ká dúpẹ́ lọ́wọ́ èdè gan-an fúnra rẹ̀. Láìsí àní-àní, èdè ni ẹ̀dá ènìyàn fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.
Ní báyìí, àwọn kan lára àwọn onímọ̀ èdè púpọ̀ fojú díwọ̀n pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà èdè tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ làwọn èèyàn ń sọ láyé, láìka àwọn èdè àdúgbò mọ́ ọn. Èdè táwọn èèyàn ń sọ jù lọ ni Mandarin Chinese, iye àwọn tó ń sọ ọ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rin [800] mílíọ̀nù. Lẹ́yìn tiẹ̀, èdè mẹ́rin táwọn èèyàn tún ń sọ jù lọ ni Gẹ̀ẹ́sì, èdè Spanish, Hindi, àti Bengali, àmọ́, ó lè máà jẹ́ bí a ṣe tò wọ́n níhìn-ín.
Bí àwọn èèyàn tó wá láti inú àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí èdè wọn sì yàtọ̀ síra bá wá pàdé ara wọn láìròtẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, báwo ni wíwà tí àwùjọ àwọn èèyàn kan wà ní àdádó ṣe kan èdè wọn? Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣe ń ṣí sílẹ̀ àti bó ṣe ń dí.
Èdè Tí A Mú Rọrùn, Àdàlú Èdè, àti Èdè Àjọgbà
Ètò ìgbókèèrè-ṣàkóso, ìṣòwò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àti híhá èèyàn mọ́ àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti mú kí àwọn èèyàn ronú pé ó yẹ kí àwọn ṣínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nítorí pé wọn ò gbédè ara wọn. Nítorí náà, wọ́n á wá máa lo oríṣi èdè tí kò le, tàbí tí wọ́n mú rọrùn. Wọ́n á mú ìṣòro dídíjú ti títẹ̀lé gírámà èdè kúrò, wọn ò ní lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ púpọ̀, wọ́n á sì jẹ́ kó mọ sórí ohun táwọn méjèèjì mọ̀ nípa rẹ̀. Báyìí ni a ṣe ń ṣẹ̀dá àwọn èdè tí a mú rọrùn. Bó ti wù kí èdè kan tí a mú rọrùn jẹ́ gbáàtúù tó, òun náà ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ ọ́. Ṣùgbọ́n bí ohun tó mú ká máa sọ ọ́ bá kásẹ̀ nílẹ̀, òun náà lè pòórá.
Nígbà tí èdè tí a mú rọrùn bá wá di lájorí èdè tí gbogbo àwọn ènìyàn àgbègbè kan ń sọ, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ tuntun kún un, wọ́n á sì ṣàtúnṣe gírámà rẹ̀. Á wá di àdàlú èdè. Àdàlú èdè máa ń fi àwùjọ táwọn èèyàn ti wá hàn, ìyẹn kò sì rí bẹ́ẹ̀ ní ti èdè tí a mú rọrùn. Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èdè tí a mú rọrùn àti àdàlú èdè—tí a ṣẹ̀dá láti inú Gẹ̀ẹ́sì, èdè Faransé, Potogí, Swahili, àti àwọn èdè mìíràn—làwọn èèyàn ń sọ lágbàáyé. Àwọn kan tiẹ̀ ti di èdè tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn bíi Tok Pisin ní Papua New Guinea àti Bislama ní Vanuatu.
Àwọn èdè mìíràn tó ń ṣínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ni àwọn èdè àjọgbà. Èdè àjọgbà ni èdè kan tó yé onírúurú àwùjọ àwọn èèyàn tí èdè ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Fún àpẹẹrẹ, ní Central African Republic, olúkúlùkù wọn tí wọ́n ń sọ èdè ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra lè fi èdè Sango bá ara wọn sọ̀rọ̀. Láàárín àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè, èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Faransé ni àwọn èdè àjọgbà tí wọ́n ń sọ. Àwọn èdè tí a mú rọrùn jẹ́ èdè àjọgbà, àwọn àdàlú èdè pẹ̀lú sì lè jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ní àwọn onírúurú ẹkùn ilẹ̀ tó wà nínú orílẹ̀-èdè kan, wọ́n lè máa sọ oríṣiríṣi ẹ̀ka èdè lára èdè orílẹ̀-èdè wọn, èyí tí a ń pè ní èdè àdúgbò. Bí ẹkùn ilẹ̀ náà bá ṣe dá dúró sí ni àwọn ìyàtọ̀ náà ṣe lè pọ̀ tó. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn èdè àdúgbò kan máa ń yàtọ̀ gan-an sí èdè tó ti wà lágbègbè náà tẹ́lẹ̀ débi tí àwọn pẹ̀lú á wá di èdè mìíràn. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, kì í rọrùn fún àwọn onímọ̀ èdè púpọ̀ láti mọ ìyàtọ̀ láàárín èdè kan àti èdè àdúgbò. Bákan náà, níwọ̀n bí èdè ti máa ń yí padà léraléra, nígbà mìíràn àwọn èdè àdúgbò àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ tó tan mọ́ wọn máa ń di ohun ìgbàgbé táwọn èèyàn ò bá sọ wọ́n mọ́.
Ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni èdè jẹ́. (Ẹ́kísódù 4:11) Bí èdè ṣe ń yí padà lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra ń fi bí ẹ̀bùn náà ṣe rọrùn láti tẹ̀ síhìn-ín tàbí sọ́hùn-ún hàn. A tún lè rí i láti inú èdè pé àwùjọ àwọn ènìyàn kan kò yọrí ọlá ju òmíràn lọ, nítorí kò sí èdè tí a lè pè ní èdè tó rẹ̀yìn. Bó ṣe rí pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn mìíràn tí Ọlọ́run fúnni, èdè pẹ̀lú wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn, láìka ẹgbẹ́ àwùjọ wọn tàbí ibi tí wọ́n ń gbé sí. Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, èdè tí gbogbo ènìyàn ń sọ pé pérépéré fún ìlò wọn. Ó yẹ ká mọyì ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, láìka iye èèyàn tó ń sọ ọ́ sí.
Ọ̀ràn Ti Ìtàn àti Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà
Àbùdá kíkó ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà jọ tí ènìyàn ní máa ń fara hàn nínú èdè. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí ẹgbẹ́ àwùjọ méjì bá pàdé—èyí sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀—ẹ̀rí ṣì máa ń wà nínú èdè àwùjọ àwọn èèyàn náà lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé wọ́n ti pàdé rí.
Fún àpẹẹrẹ, nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wá láti inú èdè Lárúbáwá tó kún inú èdè Spanish tí wọ́n kà sí èdè Látìn tí wọ́n ṣàtúnṣe, ó ní àkọsílẹ̀ kan nípa bí àwọn Mùsùlùmí ṣe ṣẹ́gun àgbègbè ìpínlẹ̀ Sípéènì ní ọ̀rúndún kẹjọ. Bákan náà ni a lè rí ẹ̀rí ipa tí èdè Gíríìkì, èdè Faransé, èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti àwọn èdè mìíràn ní lórí èdè Spanish. Síwájú sí i, èdè Spanish tí wọ́n ń sọ ní Amẹ́ríkà ṣì ń fí ẹ̀rí hàn nípa àwọn tó gbé kọ́ńtínẹ́ǹtì náà láyé àtijọ́. Fún àpẹẹrẹ, èdè Spanish tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ní ọ̀rọ̀ púpọ̀ nínú tó wá láti inú èdè Nahuatl ti àwọn Aztec ní Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà.
Gẹ́gẹ́ bí èdè ìbílẹ̀ ẹnì kan ti ń fi orílẹ̀-èdè tó ti wá hàn àti irú ẹ̀sìn rẹ̀ pàápàá, ìlò èdè lè fi agbo àwọn ènìyàn tí ẹnì kan ti wá hàn, irú bí iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe, òwò, ẹgbẹ́ eléré ìbílẹ̀ àti eléré ìdárayá, tàbí ẹgbẹ́ ọ̀daràn pàápàá. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pọ̀ lọ jàra. Àwọn onímọ̀ èdè púpọ̀ máa ń pe àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì yìí ní àkànlò ọ̀rọ̀, àkúfọ́ ọ̀rọ̀, tàbí nígbà mìíràn èdè àdúgbò pàápàá.
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tàbí àwọn ẹ̀yà tàbí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ bá ń ṣe kèéta ara wọn, èdè kì í ṣe aṣínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ mọ́. Ó lè di ìdènà tó ń dá kún ìpínyà láàárín àwọn èèyàn.
Ọjọ́ Iwájú Èdè
Ọ̀ràn tó díjú ni ọ̀ràn nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ jẹ́. Lọ́nà kan, ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn lóde òní ni láti mú ìdènà tí èdè ní kúrò, ní pàtàkì nítorí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ti sọ, ẹnì kan lára àwọn méje ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ti di lájorí èdè tàbí èdè kejì tí wọ́n ń sọ. Èyí ti wá mú kó jẹ́ èdè àjọgbà táwọn èèyàn ń sọ jù lọ lágbàáyé. Sísọ táwọn èèyàn ń sọ ọ́ ti ṣínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó túbọ̀ gbòòrò sílẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n lè ṣàjọpín àwọn ìsọfúnni tó ṣàǹfààní.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ìdènà tí èdè ní ti dá kún ìpínyà, ìkórìíra, àti ogun. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Bí gbogbo ènìyàn bá ń sọ èdè ìbílẹ̀ kan náà, . . . ìfẹ́ inú rere yóò pọ̀ sí i láàárín àwọn orílẹ̀-èdè síra wọn.” Àmọ́ ṣá o, irú ìfẹ́ inú rere bẹ́ẹ̀ yóò béèrè ìyípadà tó jinlẹ̀ gan-an ju wíwulẹ̀ máa sọ èdè àjọgbà kan. Ẹlẹ́dàá èdè tó jẹ́ òun nìkan ṣoṣo ló gbọ́n lè ṣe é kí gbogbo ènìyàn máa sọ èdè kan ṣoṣo.
Bíbélì, tó jẹ́ lájorí ohun tí Ọlọ́run fi ń bá ènìyàn sọ̀rọ̀, fi hàn ní kedere pé láìpẹ́ Ọlọ́run yóò mú ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí kúrò yóò sì fi ìjọba kan tí ń ṣàkóso láti ọ̀run—ìyẹn Ìjọba rẹ̀, rọ́pò. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yẹn yóò mú gbogbo aráyé ṣọ̀kan nínú ètò àwọn nǹkan tuntun òdodo, tó kún fún àlàáfíà, lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín.—Mátíù 6:9, 10; 2 Pétérù 3:10-13.
Kódà, nísinsìnyí, èdè mímọ́ gaara tẹ̀mí—òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀—ń mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti inú gbogbo èdè, orílẹ̀-èdè, àti àwọn ìsìn àtijọ́ ṣọ̀kan. (Sefanáyà 3:9) Nípa bẹ́ẹ̀, ó dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, òun yóò túbọ̀ mú aráyé ṣọ̀kan nípa fífún gbogbo ènìyàn ní èdè kan, yóò sì yí ohun tó ṣe ní Bábélì padà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Orísun Èdè
Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá tí í ṣe ọlọ́gbọ́n gbogbo ń lo èdè níbi tó ti ń ṣàkóso lókè ọ̀run táwọn áńgẹ́lì wà. (Jóòbù 1:6-12; 1 Kọ́ríńtì 13:1) Nígbà tó dá ènìyàn, ó fi àwọn àkànlò ọ̀rọ̀ sínú wọn àti agbára láti mú un gbòòrò sí i. Kò sí ẹ̀rí pé èdè kan wà láyé àtijọ́ tó jẹ́ pé híhan láwọn èèyàn ń han tàbí kí wọ́n máa kùn hùnnùhùnnù tí wọ́n bá fẹ́ sọ ọ́. Ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣàlàyé nípa èdè Sumer, tó tíì pẹ́ jù lọ lára àwọn èdè tí a mọ̀ pé wọ́n ń kọ sílẹ̀, ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Sumer, tó ní . . . onírúurú àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, àfòmọ́ àárín ọ̀rọ̀, àti àfòmọ́ ìparí ọ̀rọ̀ fi hàn pé èdè náà le gan-an.”
Ní nǹkan bí ọ̀rúndún ogún ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ènìyàn lòdì sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí wọ́n “kún ilẹ̀ ayé,” wọ́n gbìyànjú láti ṣàkóso gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣínárì ní Mesopotámíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Ilé Gogoro Bábélì fún ìjọsìn. Onírúurú èdè bẹ̀rẹ̀ sí dìde nígbà tí Ọlọ́run da èdè kan ṣoṣo tí wọ́n ní rú, ó sì da ìwéwèé eléwu tó burú jáì tí wọ́n ní rú.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 11:1-9.
Àkọsílẹ̀ Bíbélì kò sọ pé láti inú èdè àkọ́kọ́ ni gbogbo èdè ti wá. Ní Ṣínárì, Ọlọ́run mú kí wọ́n mọ ọ̀pọ̀ àkànlò ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀nà ìrònú tuntun, tó mú kí onírúurú èdè wà. Nípa bẹ́ẹ̀, asán ni gbogbo ìsapá láti tọpa èdè tó jẹ́ àkọ́kọ́ láti inú èyí tí gbogbo àwọn yòókù ti wá ń já sí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ní Bábélì, Ọlọ́run da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn rú