Bí Mo Ṣe Sapá Láti Ṣe Yíyàn Tó Bọ́gbọ́n Mu
BÍ GUSTAVO SISSON TI SỌ Ọ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ràn láti máa lúwẹ̀ẹ́ gan-an nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo pinnu pé iṣẹ́ dókítà ni mo máa ṣe. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ kan náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí ìyẹn, mo fẹ́ láti di òjíṣẹ́ kan. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí onírúurú nǹkan tí mo ní lọ́kàn láti dà nígbèésí ayé mi? Ṣé wọ́n bára mu?
NÍ ỌDÚN 1961, Olive Springate, míṣọ́nnárì kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brazil, bẹ̀rẹ̀ sí bá èmi àti ìyá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí àtakò tí bàbá mi tó jẹ́ oníṣègùn òyìnbó tí àwọn èèyàn kà sí ní Pôrto Alegre, ṣe sí wa, a ò ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Síbẹ̀, Olive ṣì ń dé ọ̀dọ̀ wa, nígbà tó sì yá, mo rí àmì pé òtítọ́ ni ohun tí mo ti kọ́. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn, ìlúwẹ̀ẹ́ kò jẹ́ kí n tún rí àyè fún àwọn ọ̀ràn ti ẹ̀mí.
Nígbà tí mo dẹni ọdún mọ́kàndínlógún, mo pàdé ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ arẹwà obìnrin kan, tí ń jẹ́ Vera Lúcia, ní ibi tí mo ti máa ń lúwẹ̀ẹ́, bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ àjọrìn nìyẹn. Màmá sọ fún un nípa àwọn ohun tí a gbà gbọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ sí wọn. Nítorí náà, mo kàn sí Olive, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láìka àtakò bàbá Vera Lúcia sí.
Vera Lúcia ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, ìmọ̀ rẹ̀ nípa Bíbélì sì pọ̀ sí i. Kódà, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn òṣìṣẹ́ ibi tí mo ti máa ń lúwẹ̀ẹ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní tèmi, mo pọkàn pọ̀ sórí ìdálẹ́kọ̀ọ́ mi fún ìdíje ìlúwẹ̀ẹ́ tó ń bọ̀ lọ́nà lórílẹ̀-èdè náà.
Lẹ́yìn tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni fún ohun tí ó ju ọdún kan lọ, bàbá Vera Lúcia bẹ̀rẹ̀ sí fura pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí a dé láti ìpàdé, ó ti ń dúró dè wá, ó sì béèrè pé ibo la lọ. Mo dáhùn pé ìpàdé Kristẹni la lọ àti pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn lè má ṣe pàtàkì lójú rẹ̀, ọ̀ràn ìyè àti ikú ló jẹ́ fún àwa. Ó mí kanlẹ̀, ó sì wí pé: “Ó dáa, bó bá jẹ́ ọ̀ràn ìyè àti ikú, a jẹ́ pé mo ní láti fara mọ́ bọ́ràn bá ṣe rí.” Láti ọjọ́ yẹn lọ, ìwà rẹ̀ yí padà, bó sì tilẹ̀ jẹ́ pé kò di ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, ó sì máa ń dúró tì wá lákòókò àìní.
Ṣíṣe Àwọn Yíyàn
Mo ti pinnu láti jáwọ́ kíkópa nínú ìdíje ìlúwẹ̀ẹ́ lẹ́yìn ìdíje ìlúwẹ̀ẹ́ ti àpapọ̀ orílẹ̀-èdè tí a ó ṣe, ṣùgbọ́n ipò àkọ́kọ́ tí mo gbà lẹ́ẹ̀mejì àti àkọsílẹ̀ rere tí mo ti ní ní ilẹ̀ Brazil nígbà tí mo fi ìlúwẹ̀ẹ́ dábírà fún irínwó mítà, tí mo tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ mítà ló mú kí wọ́n tún pè mí síbi Eré Ìdárayá Àwùjọ Àwọn Ará Amẹ́ríkà ní Cali, ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, ní ọdún 1970. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Vera Lúcia kò fẹ́ kí n lọ, mo bẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún eré ìdárayá náà.
Nígbà tí mo lúwẹ̀ẹ́ dáadáa ní Cali, àwọn tó ń dá mi lẹ́kọ̀ọ́ béèrè bóyá màá fẹ́ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún eré Òlíńpíìkì. Mo ronú nípa ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn tí mi ò tíì parí àti àgbàyanu òtítọ́ tí mo ti kọ́ nípa àwọn ète Jèhófà, mo sì jáwọ́ nínú ríronú nípa sísọ ìlúwẹ̀ẹ́ di iṣẹ́ mi. Láti ìgbà yẹn lọ, ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí yára kánkán. Ní ọdún 1972, tí wọ́n ṣe eré Òlíńpíìkì ní Munich, ní orílẹ̀-èdè Jámánì, èmi àti Vera Lúcia ṣe ìrìbọmi láti fi àmì ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà hàn. Èyí fún Màmá ní ìṣírí láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀, kò sì pẹ́ tí òun náà fi ṣe ìrìbọmi.
Lẹ́yìn tí Màmá ṣe ìrìbọmi, àtakò Bàbá túbọ̀ pọ̀ sí i. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ìdílé wa tú ká, bó sì ti jẹ́ pé mo ṣì wà ní yunifásítì, owó ìfẹ̀yìntì táṣẹ́rẹ́ tí Màmá ń gbà àti iye tí a rí nígbà tí a ta ilé wa ni a fi ń gbọ́ bùkátà. Nítorí èyí, èmi àti Vera sún ìgbéyàwó wa síwájú. Ní ti gidi, ẹ̀kọ́ àtàtà tí mo ti kọ́ lọ́dọ̀ Bàbá ràn mí lọ́wọ́ láti yan àwọn ohun tí mo yàn. Ó sábà máa ń sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù láti dá yàtọ̀,” ó sì tún máa ń sọ pé, “Ti pé èrò pọ̀ síbì kan kò túmọ̀ sí pé wọ́n tọ̀nà.” Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tó fẹ́ràn láti máa sọ ni pé, “Ohun tí ẹnì kan bá fún àwọn ẹlòmíràn ni a fi máa ń mọ bó ṣe jẹ́ ọkùnrin tó.”
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi ìmọ̀ràn àtàtà tí Bàbá fún mi sílò dáadáa. Ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni mo wà nígbà tó fi kú ní ọdún 1986. A ti tún di ọ̀rẹ́ ara wa, a sì bọ̀wọ̀ fún ara wa. Mo gbà gbọ́ pé ó lè fi mí yangàn, nítorí pé èmi náà di dókítà bíi tirẹ̀.
Láàárín àkókò yẹn, mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn ní ọdún 1974. Mo pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣègùn tó kó onírúurú ẹ̀ka ìtọ́jú pọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, lẹ́yìn tí mo túbọ̀ ronú lórí ọ̀ràn yìí, mo pinnu pé yóò ṣeé ṣe fún mi láti túbọ̀ ran àwọn Kristẹni ará lọ́wọ́ nípa dídi dókítà tí ń ṣiṣẹ́ abẹ. (Ìṣe 15:28, 29) Nítorí náà, mo gbà láti kojú ìpèníjà náà, mo sì lọ lo ọdún mẹ́ta láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ abẹ.
Ọ̀ràn Ẹjọ́ Tí Ń Peni Níjà
Ọ̀ràn kan tó bani nínú jẹ́ gidigidi tó kàn mí ni ti ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tí ẹ̀jẹ̀ ń ya nínú rẹ̀ lọ́hùn-ún. Àwọ̀ ara rẹ̀ ti ṣì, ìfúnpá rẹ̀ sì ti lọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n, òye yé e, ó sì pinnu láìyẹhùn pé òun kò ní gba ẹ̀jẹ̀. Lẹ́yìn mímú kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i, mo fi awò wo ibi tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ya yẹn, mo sì fi èròjà olómi tútù tó rí bí omi iyọ̀ fọ ibẹ̀ kí ẹ̀jẹ̀ yẹn lè dá. Lákọ̀ọ́kọ́, ara rẹ̀ le sí i, ṣùgbọ́n ní wákàtí mẹ́rìndínlógójì lẹ́yìn náà, nígbà tó ń gba ìtọ́jú àkànṣe, ẹ̀jẹ̀ yíya náà tún bẹ̀rẹ̀ lójijì. Láìka bí dókítà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ṣe sapá gidigidi tó sí, kò ṣeé ṣe fún un láti dá ẹ̀jẹ̀ tó ń ya náà dúró, ìyẹn mú kí ẹ̀jẹ̀ ọmọbìnrin náà dín kù, ó sì kú.
Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, ìgbìmọ̀ tí ń rí sí ọ̀ràn nípa ìlànà ìṣègùn dá ìdálẹ́kọ̀ọ́ mi dúró, wọ́n sì gbé ẹjọ́ mi lọ sọ́dọ̀ ẹgbẹ́ oníṣègùn ẹlẹ́kùnjẹkùn. Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mo rú òfin mẹ́ta nínú ìlànà ìṣègùn, èyí sì lè jẹ́ kí wọ́n fagi lé ìwé ẹ̀rí iṣẹ́ ìṣègùn mi, bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, yóò ṣòro fún mi láti máa gbọ́ bùkátà ara mi.
Ìgbìmọ̀ kan fún mi ní ọgbọ̀n ọjọ́ láti fi kọ̀wé, kí n sì ṣàlàyé ara mi. Àwọn agbẹjọ́rò mi ṣe àlàyé tó bá òfin àti ìlànà mu, mo sì ṣe àlàyé tó bá ìlànà ìṣègùn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tó wà ládùúgbò yẹn, ìyẹn àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n máa ń gbìyànjú láti mú kí ilé ìwòsàn àti aláìsàn fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ náà, ìgbìmọ̀ náà béèrè àwọn ìbéèrè ní pàtàkì nípa ipò mi gẹ́gẹ́ bíi dókítà àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, orí àlàyé ní ti ìṣègùn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àkọsílẹ̀ látọwọ́ àwọn oníṣẹ́ abẹ tí a kà sí ni mo dìídì gbé àwíjàre mi kà.
Ẹ̀rí tí a gbé kalẹ̀ fi hàn pé aláìsàn náà kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ sára àti pé èmi kọ́ ni mo tì í ṣe ìpinnu yẹn. Ìgbẹ́jọ́ náà tún mú kí ó ṣe kedere pé lára àwa dókítà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n gbé ọmọ náà wá bá fún ìtọ́jú, èmi nìkan ni mo bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú aláìsàn náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́, tó sì bá ipò àìlera rẹ̀ mu.
Wọ́n wá gbé ẹjọ́ mi lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ tí yóò dìbò nígbà tí ẹsẹ̀ gbogbo àwọn tó yẹ kó wà níbi ìjókòó náà bá pé. Mo fẹnu ara mi ṣàlàyé fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá, mo sì gbé àlàyé mi ka orí ọ̀ràn ìṣègùn ní pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe nínú àlàyé tí mo kọ sínú ìwé ní ìṣáájú. Nígbà tí wọ́n gbọ́ tẹnu mi, méjì nínú àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ náà sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára, ìtọ́jú tí mo lò bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu dáadáa. Dókítà mìíràn ṣàlàyé pé ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ gbéṣẹ́ àti pé kì í sábà yọrí sí ikú. Mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ tó sọ̀rọ̀ kẹ́yìn sọ pé ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí kì í ṣe pé bóyá fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára jẹ́ ìtọ́jú tó dára tàbí kò dára làwọ́n ń sọ, ṣùgbọ́n bóyá dókítà kan lè tọ́jú aláìsàn nípa fífi agbára lo ìtọ́jú ìṣègùn tí aláìsàn náà kò fẹ́, mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ yẹn kò sì ronú pé dókítà kan ní irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ méjìlá ló dìbò pé kí wọ́n fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, tí àwọn méjì sì sọ pé kí wọ́n má fagi lé wọn, èyí sì jẹ́ kí wọ́n dá mi láre.
Jíjà fún Ẹ̀tọ́ Aláìsàn
Àwọn oníṣègùn kan gba àṣẹ ilé ẹjọ́ láti fagbára mú àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti gba ẹ̀jẹ̀ sára. Láwọn ìgbà míì sì rèé, mo ti fi àwọn ẹ̀rí hàn nígbà ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́, ó sì ti ṣèrànwọ́ láti yí irú àwọn àṣẹ bẹ́ẹ̀ padà. Ọ̀ràn kan ni ti Ẹlẹ́rìí kan tí àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ wú, ìṣòro yìí sì mú kí ẹ̀jẹ̀ máa ya gidigidi nínú agbẹ̀du rẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi gbé e dé ilé ìwòsàn, ẹ̀jẹ̀ kò tó lára rẹ̀ mọ́ rárá—ìwọ̀n àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dín díẹ̀ ní gíráàmù márùn-ún nínú ìdá mẹ́wàá lítà kan ẹ̀jẹ̀.a Lákọ̀ọ́kọ́, wọn kò fagbára mú un pé kí ó gba ẹ̀jẹ̀, wọ́n sì fún un ní ìtọ́jú díẹ̀ ná.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí aláìsàn náà ti lo ọ̀sẹ̀ kan ní ilé ìwòsàn, ó yà á lẹ́nu láti rí òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ kan tó mú ìwé àṣẹ ìfàjẹ̀sínilára wá fún un. Ní àkókò yìí, ìwọ̀n àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ti pọ̀ sí i, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó gíráàmù mẹ́fà àbọ̀ nínú ìdá mẹ́wàá lítà kan ẹ̀jẹ̀, àyẹ̀wò sì fi hàn pé ara rẹ̀ ti ń balẹ̀. Ó dà bíi pé orí ìwọ̀n àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ti àkọ́kọ́ ni adájọ́ gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà, kì í ṣe orí ti ẹlẹ́ẹ̀kejì tó túbọ̀ pọ̀ sí i yìí.
Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn wá láti ṣèrànwọ́. Aláìsàn náà sọ pé kí n ṣàyẹ̀wò òun. Mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì ṣàṣeyọrí lẹ́yìn náà láti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn kan tí wọ́n ti lè tọ́jú rẹ̀ láìlo ẹ̀jẹ̀. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn lọ́yà rẹ̀ tako àṣẹ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn náà lára.
Wọ́n pè mí lọ síwájú adájọ́ náà lákòókò ìgbẹ́jọ́ kan, ó sì béèrè nípa ipò aláìsàn náà lọ́wọ́ mi. Nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, ó fún mi láṣẹ pé kí n máa tọ́jú aláìsàn náà, pé àwọn yóò sì jíròrò bóyá àṣẹ tí ilé ẹjọ́ pa yẹ bẹ́ẹ̀. Nígbà ìgbẹ́jọ́ mìíràn, ara aláìsàn náà ti le sí i, wọ́n sì ti ní kó padà sílé. Nígbà tí wọ́n ní kí n tún wá jẹ́rìí, agbẹjọ́rò ilé ìwòsàn pè mí níjà pé kí n fẹ̀rí hàn pé ìtọ́jú tí mo dámọ̀ràn rẹ̀ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Ojú tì í nígbà tí mo mú àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn nípa ìṣègùn tí ilé ìwòsàn tó ń ṣojú fún gan-an tẹ̀ jáde, tí ó sì dámọ̀ràn irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀!
Nígbà tí ilé ẹjọ́ sọ ìdájọ́ rẹ̀, inú wa dùn láti gbọ́ pé wọ́n dá ìpinnu wa láti gbára lé ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ láre. Wọ́n pàṣẹ pé kí ilé ìwòsàn náà san gbogbo owó tó náni, títí kan owó tí a fi ṣe ẹjọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìwòsàn náà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ńṣe ló tún jẹ̀bi bọ̀.
Bíbójútó Ìdílé Wa
Láti ìgbà tí mo ti di Ẹlẹ́rìí, tọkàntọkàn ni Vera Lúcia fi ń ṣètìlẹ́yìn fún mi gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́, ó sì ti jẹ́ aya tó dáńgájíá àti ìyá tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún àwọn ọmọ wa. Báwo ló ṣe kojú gbogbo àwọn ìṣòro ti títọ́jú ilé àti títọ́jú àwọn ọmọ, tí wọ́n ti di ọ̀dọ́ abarapá báyìí? Ìfẹ́ tí ó ní sí Jèhófà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí òbí, a ti fi àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wa láti ìgbà ọmọdé jòjòló. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí, a máa ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún láàárín àwọn oṣù mélòó kan nínú ọdún. A sì máa ń sa gbogbo ipá wa láti máa tẹ̀ lé ètò tí a ṣe, lára wọn ni kíka Bíbélì déédéé, jíjíròrò ẹsẹ Bíbélì kan lójoojúmọ́, àti sísọ àwọn ohun tí a gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìdílé wa sábà máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi méjìlá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.
Èmi àti Vera Lúcia tún máa ń gbìyànjú láti mú kí àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò wa, lọ́wọ́ kan náà, a máa ń fún wọn láyè láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ràn. A gbà gbọ́ pé ohun mẹ́ta pàtàkì ṣe kókó bí àwọn òbí yóò bá bójú tó ìdílé wọn lọ́nà yíyẹ. Èkíní ni ẹ̀kọ́ tí ó tọ́, tí a gbé karí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èkejì ni àpẹẹrẹ tí ó tọ́, tó máa ń fún àwọn ọmọ ní ẹ̀rí kedere pé àwọn òbí àwọn bẹ̀rù Ọlọ́run ní tòótọ́. Ẹ̀kẹta sì ni, ìbákẹ́gbẹ́ tí ó tọ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni lónírúurú ọjọ́ orí àti ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tí wọ́n lè fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé ní onírúurú ẹ̀bùn àti òye bí a ti ń ṣe àwọn nǹkan. Gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, a fi í ṣe góńgó wa láti pèsè àwọn nǹkan wọ̀nyí fún ìdílé wa.
Bí a bá wo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí a ti fi ń sin Jèhófà, èmi àti aya mi lè sọ láìṣiyèméjì pé, ó ti fún wa ní ohun tó dára jù lọ ní ìgbésí ayé, ó sì ti pèsè ọ̀pọ̀ ìgbádùn àti ìbùkún fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lọ ṣe eré Òlíńpíìkì, mo ṣì ń gbádùn lílúwẹ̀ẹ́ fún ọ̀pọ̀ kìlómítà lọ́sẹ̀. Ní tòótọ́, jíjẹ́ dókítà àti jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú kí ọwọ́ mi máa dí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n èrè ńláǹlà ló jẹ́ fún mi láti máa ran àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run nìṣó lójú àdánwò.
Wọ́n sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ mi bóyá mo ń ṣàníyàn nípa pé mo máa pàdánù iṣẹ́ mi nígbà tí ètò tuntun Ọlọ́run bá dé, tí kò sì sí àìsàn mọ́. Mo máa ń dáhùn pé, inú mi yóò dùn débi pé èmi ni yóò kọ́kọ́ fò sókè nígbà tí ‘ẹni tí ó yarọ bá gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, tí ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde,’ àti tí ‘kò sí olùgbé kankan tó sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’—Aísáyà 33:24; 35:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àgbàlagbà tí ara rẹ̀ le máa ń ní ìwọ̀n àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ tó jẹ́ nǹkan bíi gíráàmù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ìdá mẹ́wàá lítà kan ẹ̀jẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ abẹ fún aláìsàn kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Èmi àti Vera Lúcia, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa