Ìlera fún Gbogbo Èèyàn—Ṣé Góńgó Tó Ṣeé Lé Bá Ni?
ǸJẸ́ O fẹ́ kí ìwọ àti ìdílé rẹ gbádùn ìlera tó jí pépé? Ó dájú pé ò ń fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ máa ń bá ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa fínra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó ń roni lára ń bá fínra.
Síbẹ̀síbẹ̀, akitiyan ńláǹlà ń lọ lọ́wọ́ láti kápá àrùn. Tiẹ̀ wo Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO), tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ná. Níbi ìpàdé àpérò kan tí WHO ṣagbátẹrù rẹ̀ lọ́dún 1978, àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnléláàádóje àti àjọ mẹ́tàdínláàádọ́rin ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fohùn ṣọ̀kan pé ìlera kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ òmìnira kúrò lọ́wọ́ àrùn. Wọ́n polongo pé ìlera jẹ́ “ipò àlàáfíà pátápátá ní ti ara, ní ti èrò orí àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.” Lẹ́yìn náà làwọn tó pésẹ̀ wá gbé ìgbésẹ̀ akọni ti pípolongo pé ìlera jẹ́ “ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó ṣe kókó”! Àjọ WHO tipa báyìí gbé góńgó “fífún gbogbo èèyàn lágbàáyé ní ìlera tó jọjú” kalẹ̀.
Irú góńgó yẹn máa ń tuni lára, ó tiẹ̀ ń wúni lórí pàápàá. Àmọ́ báwo lọwọ́ á ṣe tẹ̀ ẹ́ láyé ńbí? Nínú gbogbo nǹkan tọ́mọ ẹ̀dá tíì gbé ṣe, ti ìṣègùn ti di èyí táa fọkàn tán jù lọ táa sì ń ṣe sàdáńkátà fún. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà The European ṣe sọ, àwọn èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ti gbọ́njú mọ “èrò ìṣègùn àbáláyé ti ìtọ́jú ‘ajẹ́bíidán’: tó jẹ́ pé hóró oògùn kan péré ló ń wo àìsàn kan sàn.” Lédè mìíràn, fún gbogbo àìsàn, a retí pé kí ìmọ̀ ìṣègùn pèsè ìtọ́jú lọ́wọ́ kan. Ṣé lóòótọ́ ni iṣẹ́ ìṣègùn lè sọ ìfojúsọ́nà tó ga yìí di òótọ́?