ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 8/8 ojú ìwé 3
  • Ìkórìíra Gbòde Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkórìíra Gbòde Kan
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkórìíra Gbòde Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tí A Lè Gbà Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìkórìíra
    Jí!—2001
  • Kristi Koriira Iwa-Ailofin—Iwọ Ha Koriira Rẹ̀ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 8/8 ojú ìwé 3

Ìkórìíra Gbòde Kan

ÈÈMỌ̀ kan ti wọ̀lú o, ìkórìíra ni wọ́n ń pè é. Ó sì ti ń jà kárí ayé.

Ẹkùn ìpínlẹ̀ kan wà lágbègbè Balkan tí kò tíì bọ́ lọ́wọ́ ràbọ̀ràbọ̀ pípa ẹ̀yà run tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Kèéta tó ti wà nílẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́ ti fa pípa èèyàn lọ bẹẹrẹ, ìfipábáni-lòpọ̀, líléni-kúrò-nílùú, jíjólé àti kíkẹ́rù ẹlẹ́rù, bíba irè oko jẹ́ àti pípa ohun ọ̀sìn nípakúpa, àti ebi. Àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ ṣì pọ̀ lọ jaburata.

Ní East Timor, Gúúsù Ìlà Oòrùn Asia, ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000] èèyàn bá ẹsẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ nítorí ìpayà ìpànìyàn, ìluni, fífi ìbọn pani láìbìkítà, àti fífipá léni kúrò nílùú. Àwọn ohun tó ṣẹ́ kù sílẹ̀ jẹ́ kìkì ilẹ̀ táwọn jagunjagun tó jẹ́ ọ̀dàlúrú ti sọ dahoro. Ọ̀kan lára àwọn tó kàgbákò náà sọ pé: “Ńṣe ni mo dà bí ẹran tí wọ́n ń dọdẹ kiri.”

Ní Moscow, àwọn apániláyà ju bọ́ǹbù ńlá kan sínú ilé kan tó sì fọ́ ọ túútúú. Ńṣe ni bọ́ǹbù náà fọ́n òkú àwọn èèyàn mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún tó kàgbákò ọ̀hún káàkiri, àwọn ọmọdé sì wà lára wọn. Àwọn tó fara gbọgbẹ́ lé ní àádọ́jọ. Lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ amúnigbọ̀nrìrì bí irú èyí bá ṣẹlẹ̀ tán, àwọn èèyàn á wá bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé, ‘Ta ni ọpọ́n máa sún kàn báyìí o?’

Ní Los Angeles, California, ọ̀gbẹ́ni kan tí kì í fẹ́ rí ẹ̀yà mìíràn dàbọn bo àwọn ọmọ Júù kan tí wọ́n ń lọ sílé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi ó sì pa ọ̀gbẹ́ni akólẹ́tà kan tó jẹ́ ará Philippines lẹ́yìn náà.

Kì í ṣe àsọdùn báa bá sọ pé àrùn kárí ayé ni ìkórìíra jẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojoojúmọ́ làwọn ìròyìn ń sọ ohun tó ń jáde láti inú kèéta ẹ̀yà, ìran, tàbí ti ìsìn, pẹ̀lú ìwà ta-ló-máa-mú-mi. A ń rí àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn àwùjọ, àtàwọn ìdílé tí wọ́n ń tú ká. A ń rí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kíra bọ pípa ẹ̀yà run. A kò ṣàìrí ìwà tí kò yẹ ọmọnìyàn tí wọ́n ń hù sáwọn kan kìkì nítorí pé wọ́n “yàtọ̀.”

Bí a bá máa mú èèmọ̀ tí wọ́n ń pè ní ìkórìíra yìí kúrò, a gbọ́dọ̀ mọ ibi ti irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ wá. Ṣé inú ẹ̀jẹ̀ ọmọ ènìyàn tiẹ̀ ni ìkórìíra wà ni? Ṣé ohun téèyàn ń kọ́ ni? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti fòpin sí ìwà ìkórìíra?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Kemal Jufri/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́