Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 8, 2002
Pàǹtírí—Èyí Ò Wa Pọ̀ Jù?
Pàǹtírí tọ́mọ aráyé ń kó jọ gègèrè ti wá pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ o. Èyí ti mú àwọn ìṣòro tá ò rírú ẹ̀ rí bá àyíká. Àwọn ìṣarasíhùwà wo ló ń dá kún àṣà fífi nǹkan ṣòfò yìí, báwo la sì ṣe lè borí wọn?
5 Ǹjẹ́ a Lè Rí Ọgbọ́n Dá Sí I?
9 Bó o Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ayé Alálòsọnù
22 Ògbógi Nínú Pípalẹ̀ Pàǹtírí Mọ́
23 Ṣé o Máa Ń dààmú Nípa Bí Irun Rẹ Ṣe Rí?
28 Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Máa Ń sùn Ṣáá—Ṣé Ọ̀ràn Wọn Ò Ń Fẹ́ Àmójútó Báyìí?
30 Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́
31 Ohun Ọ̀sìn Àtàtà Ni àbí Panipani Ẹhànnà?
Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ sí Ọ? 12
Kà nípa bí o ṣe lè yẹra fún àwọn nǹkan méjì tó wọ́pọ̀ jù lọ tó ń fa àgbákò lójú pópó.
Irú Àdúrà Tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ 26
Kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àwọn àdúrà wa, ó ń béèrè pé ká ṣe àwọn ohun kan. Kí làwọn ohun náà?