Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
December 8, 2003
Ṣé Owó Orí Tí Ò Ń San Ti Pọ̀ Jù?
Níbi gbogbo lágbàáyé làwọn èèyàn ti sábà máa ń ṣàròyé nípa owó orí. Kí ló mú kí àwọn òfin owó orí díjú gan-an, tí owó orí tí àwọn èèyàn ń san sì tún máa ń pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ṣé ó pọn dandan fún ọ láti san án?
3 Ṣé Ìkórìíra fún Sísan Owó Orí—Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I Ni?
5 Owó Orí Ṣé Òun Ló Mú Kí “Àwùjọ Ọ̀làjú” Ṣeé Ṣe?
10 Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa San Owó Orí?
16 Ǹjẹ́ O Mọ̀?
22 Ọṣẹ—“Abẹ́rẹ́ Àjẹsára” Tó O Lè Gún Fúnra Rẹ
28 Wíwo Ayé
30 Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ǹjẹ́ Kò Ti Ń di Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Kárí Ayé Báyìí?
31 Atọ́ka Ìdìpọ̀ Kẹrìnlélọ́gọ́rin Ti jí!
32 Wọ́n Rí I Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wọn
Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀ 12
Kà nípa bí ipa tí Bíbélì ní lórí oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Japan kan ṣe mú kó yí èrò rẹ̀ nípa ìfàjẹ̀sínilára padà.
Bí Àìsàn Ibà Bá Ń Ṣe Ọmọ Rẹ 25
Báwo ló ṣe yẹ kó ká ọ lára tó gan-an bí àìsàn ibà bá ń ṣe ọmọ rẹ? Kí lohun tó o lè ṣe fún ọmọ rẹ kí ara rẹ̀ lè wálẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwọn tí kò fara mọ́ owó orí ń fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá
[Credit Line]
AFP/Getty Images