ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 29
  • Ohun Tó Sàn Ju Àtúntò Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Sàn Ju Àtúntò Lọ
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igbe Àtúntò Laráyé Ń ké
    Jí!—2004
  • Jésù La Ojú Àwọn Afọ́jú, Ó sì Ran Sákéù Lọ́wọ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ṣé Àwọn Alátùn-úntò Ló Máa Tún Ayé Ṣe?
    Jí!—2004
  • Jesu Kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní Jẹriko
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 29

Ohun Tó Sàn Ju Àtúntò Lọ

BÍ IGI kan bá ń so èso tí kò ní láárí, ìṣòro yẹn ò lè yanjú bá a bá kàn gé ẹ̀ka mélòó kan dà nù lára igi yẹn. A gbọ́dọ̀ gé igi yẹn lulẹ̀ ká sì wú u tegbòtegbò. A ó sì wá gbin igi mìíràn tí yóò máa so èso àtàtà.—Mátíù 7:16-20.

Fún ìdí kan náà, àní àwọn alátùn-úntò tí wọ́n ní àfojúsùn tó dára jù lọ gan-an wulẹ̀ ń bójú tó àwọn àmì tó fi hàn pé àwùjọ ò fara rọ fún ẹ̀dá ènìyàn ni, ìyẹn àwọn àmì bí ìwà ìbàjẹ́, àìsídàájọ́ òdodo, ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti jíjanilólè. Ohun tó ń fa àwọn ìṣòro yìí gan-an jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò nǹkan yìí gan-an lódindi ló yẹ kí àyípadà dé bá. Ohun tí Bíbélì sì ṣèlérí nìyí.

Ìjọba tó ń ṣàkóso láti ọ̀run wá ni Ìjọba Ọlọ́run, yóò ṣe kọjá wíwulẹ̀ ṣe ìyípadà ṣákálá kan, tàbí àtúnrọ tàbí àtúntò sí ọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀nà tuntun tó yàtọ̀ pátápátá ni ìjọba yẹn yóò gbà máa ṣàkóso àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn, yóò sì sọ aráyé dọ̀kan. Ìjọba náà yóò bójú tó gbogbo ọ̀ràn bí ètò ẹ̀kọ́, iṣẹ́, ilé gbígbé, oúnjẹ, ìlera àti àyíká.

Sáàmù 72:12-14 fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe àwọn nǹkan tí Mèsáyà Ọba náà yóò ṣe fún aráyé, ó ní: “Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”

Ṣùgbọ́n bí ayé bá máa bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́, àìsídàájọ́ òdodo àti ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ìjọba nìkan kọ́ ló yẹ kó yí padà, ó yẹ káwọn èèyàn pẹ̀lú yí padà. Ìdí rèé tí Ìjọba náà yóò fi fún olúkúlùkù ní ìtọ́ni lórí bí wọ́n ṣe máa gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ tó nítumọ̀ tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn. Bíbélì ṣèlérí pé Ìjọba Ọlọ́run yóò ran àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ láti yí padà fúnra wọn. Lọ́nà wo?

Ìjọba náà yóò kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ní àwọn ọnà Jèhófà Ọlọ́run, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. (Aísáyà 11:9) Ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà lọ́kàn ẹni ló máa ń súnni ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní Jésù pàdé Sákéù, olórí agbowó òde kan, tó ń fowó àwọn ara ìlú ṣara rindin nípa fífikún owó orí tí ìjọba ní kí wọ́n máa san. Jésù ò fagídí mú ọ̀gá jẹgúdújẹrá yìí láti yí ìwà rẹ̀ padà nípa dídójú tì í. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ran Sákéù lọ́wọ́ láti rí àṣìṣe ara rẹ̀ kó sì ronú pìwà dà. Ìmọ̀ pípéye nípa ìlànà Ọlọ́run àti ìfẹ́ tó ní sí i ló gún Sákéù ní kẹ́ṣẹ́. Ó ṣe ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Lúùkù 19:1-10.

Ǹjẹ́ ìyẹn kọ́ ni àtúnṣe tó ga jù sí gbogbo nǹkan tí kò lọ déédéé láwùjọ? Kí ìjọba òdodo pípé máa bójú tó àlámọ̀rí aráyé, pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá tí olúkúlùkù ní láti yí ọ̀nà rẹ̀ padà. Ṣé a óò tún wá nílò àtúntò nígbà yẹn? Kò ní wúlò mọ́, nítorí pé Ọlọ́run á ti sọ ohun gbogbo di ọ̀tun. Àwọn ohun àtijọ́ yóò ti kọjá lọ.—Ìṣípayá 21:4, 5.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àtúntò kọ́ ni Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá, bí kò ṣe ìyípadà pátápátá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Nígbà tí Jésù wà láyé ó ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn padà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́