Igbe Àtúntò Laráyé Ń ké
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ JÁMÁNÌ
Obìnrin ẹni ọgọ́rin ọdún kan tó ń jẹ́ Anna sọ ní Jámánì pé: “Ká ní mo tún lè padà di ọmọdé ni, ǹ bá dá ẹgbẹ́ alátùn-úntò sílẹ̀!” Robert bi í léèrè pé: “Kí ni wàá yí padà?” Anna fèsì pé: “Gbogbo nǹkan pátá!”
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló máa gbà pẹ̀lú Anna. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Jámánì lọ́dún 1993 fi hàn pé ẹni méjì nínú mẹ́ta tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn rò pé ó ṣe pàtàkì kí ‘àwọn àtúntò tó délé dóko dé bá gbogbo ọ̀ràn tó kan ọmọnìyàn.’ Bóyá bọ́ràn ṣe rí lórílẹ̀-èdè tíwọ náà ń gbé nìyẹn.
Nígbà táwọn aráàlú bá ń béèrè pé kí wọ́n tún nǹkan ṣe, ńṣe làwọn aláṣẹ máa ń ṣèlérí pé àwọn á tún ìlú tò. Frederick Hess tó jẹ́ igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìmọ̀ nípa ìṣèjọba sọ nípa àtúntò ètò ẹ̀kọ́ pé: “Ojú ayé lásán ni wọ́n ń fi àtúntò ṣe láti fàwọn aráàlú tó ń ṣèyọnu lọ́kàn balẹ̀.” À ń ka àwọn àkọlé ìwé ìròyìn tí wọ́n fi ń kéde àtúntò tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe lórí ètò ìṣúnná, ètò ìlera, iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ọ̀ràn òfin. A tún gbọ́ nípa àtúntò tí wọ́n ń gbèrò àtiṣe lórí ètò ẹ̀kọ́, ètò ìdẹ̀rùn aráàlú àti ètò ọgbà ẹ̀wọ̀n.a Ìròyìn tún gbé e pé àwọn mẹ́ńbà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ń béèrè pé kí wọ́n ṣe àtúntò tàbí ìyípadà sáwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́.
Ṣé Ká Ṣe Àtúntò Ni àbí Kí Ètò Ìlú Wà Bó Ṣe Wà?
Kí ló fà á táwọn èèyàn fi ń fẹ́ àyípadà gan-an? Ọmọ aráyé sábà máa ń wá bí ayé á ṣe dẹrùn fáwọn ni. Kí ìyẹn baà lè ṣeé ṣe, wọ́n ti fìbò yan àwọn tó máa ṣèjọba lé wọn lórí, wọ́n ti náwó ribiribi, wọ́n ti ṣòfin, wọ́n sì ti lo ipá. Ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn èèyàn ní ìfẹ́ alọ́májàá sí ohun tó bá máa mú kí ìgbésí ayé wọn dẹrùn sí i, kí ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ wọn dáa, kí àwùjọ rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí, níbi tí ìgbé ayé ìdẹ̀rùn yóò ti wà fún gbogbo èèyàn, táwọn èèyàn yóò máa hùwà ọmọlúàbí tí ìdájọ́ òdodo á sì rídìí jókòó. Níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì ń rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń tiraka láti bọ́ aṣọ tí àìmọ̀kan-mọ̀kàn, àrùn, òṣì àti ebi dá wọ̀ wọ́n, kò sí ìgbà tá ò ní máa gbọ́ ariwo àtúntò.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn mìíràn dùn sí àtúntò, ọ̀tọ̀ ni nǹkan táwọn mìíràn ń rò nípa àwọn alátùn-úntò àti èròǹgbà wọn. Àwọn kan gbà pé ṣe ló yẹ ká fi àwùjọ sílẹ̀ bó ṣe wà, ká má tọwọ́ bọ ètò ìlú lójú. Wọ́n ń wo àwọn alátùn-úntò bí àwọn tó kàn ń gbéra wọn gẹṣin aáyán, tí wọ́n láwọn fẹ́ yí ayé padà. Ìwé Handbuch der deutschen Reformbewegungen 1880-1933 (Ìwé Ìléwọ́ Àwọn Ẹgbẹ́ Alátùn-úntò Tó Wà Nílẹ̀ Jámánì 1880 sí 1933) sọ pé: “Orí àwọn alátùn-úntò ni oríṣiríṣi àtakò, àwòrán tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn olóṣèlú, èébú, àti ìfiniṣẹlẹ́yà máa ń dá lé.” Òǹkọ̀wé eré onítàn náà Molière sọ nígbà kan rí pé: “Kò sẹ́ni tó ń tanra ẹ̀ jẹ bí ẹni tó lóun fẹ́ tún ayé ṣe.”
Kí lèrò tìẹ? Ṣé àtúntò lè jẹ́ káyé dára sí i? Àbí àwọn alátùn-úntò wulẹ̀ ń gbéra wọn gẹṣin aáyán ni? Àwọn àtúntò táwọn èèyàn ti ṣe sẹ́yìn ńkọ́? Ṣé àwọn nǹkan táwọn tó wà nídìí ẹ̀ fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ pàpà ṣẹlẹ̀? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò àwọn ọ̀ràn yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé ìròyìn Jí! ò kúrò lórí ìdí tá a fi ń tẹ̀ ẹ́ jáde, ó “dá dúró gedegbe láìdá sí ọ̀ràn ìṣèlú.” Ìdí tá a fi ń jíròrò ọ̀rọ̀ tó dá lórí àtúntò yìí ni láti la àwọn òǹkàwé wa lọ́yẹ̀ nípa ojútùú tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìṣòro tó ń bá aráyé fínra.