ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 23-27
  • Ṣé Àwọn Alátùn-úntò Ló Máa Tún Ayé Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwọn Alátùn-úntò Ló Máa Tún Ayé Ṣe?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtàn Nípa Àwọn Alátùn-úntò
  • Ẹ̀ka Àtúntò
  • Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Rí I Bẹ́ẹ̀
  • Àwọn Àtúntò Tí Ò Lẹ́sẹ̀ Ńlẹ̀
  • Ṣé Alátùn-úntò Ni Jésù Kristi?
  • Igbe Àtúntò Laráyé Ń ké
    Jí!—2004
  • Ohun Tó Sàn Ju Àtúntò Lọ
    Jí!—2004
  • Èéṣe Tí Ó Fi Tó Àkókò Láti Ṣe Ìpinnu?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 23-27

Ṣé Àwọn Alátùn-úntò Ló Máa Tún Ayé Ṣe?

JÌBÌTÌ nínú ìṣòwò, àwọn agbófinró tó ń ṣègbè, ká fọwọ́ ọlá gbáni lójú, ètò ìlera tó mẹ́hẹ, ètò ẹ̀kọ́ tí ò múná dóko, fífi ẹ̀sìn bojú láti rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, àti bíba àyíká jẹ́ torí owó—gbogbo àwọn nǹkan báwọ̀nyí ló ń ba ọ̀pọ̀ nínú wa lọ́kàn jẹ́. Àwọn nǹkan tó ń sún àwọn alátùn-úntò dédìí à ń wá àtúntò náà rèé.

Gbogbo ibi làwọn alátùn-úntò wà, wọ́n á máa sọ fáwọn èèyàn pé ó yẹ kí àyípadà dé bá bí nǹkan ṣe ń lọ, ẹsẹ̀ òfin ló sì yẹ kí wọ́n fi tọ̀ ọ́ létòlétò. A ò lè pè wọ́n ní adàlúrú tàbí ajàjàgbara, ìdí ni pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn kì í ṣe kọjá nǹkan tófin là kalẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fàjàngbọ̀n. Àwọn alátùn-úntò díẹ̀ di ipò jàǹkàn-jàǹkàn mú láwùjọ, wọ́n sì máa ń lo àǹfààní ipò yẹn láti mú àyípadà wá. Àwọn mìíràn ń lo ẹsẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ kí wọ́n lè rọ̀ wọ́n láti wá nǹkan ṣe.

Àwọn alátùn-úntò máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí àwọn èèyàn térò wọn pa lórí ọ̀nà tí wọ́n á gbé ìṣètò àwùjọ gbà. Wọn kì í ṣàdédé yarí; wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n á gbé nǹkan gbà tí yóò fi gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Láti jẹ́ kí aráyé mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́, wọ́n máa ń ké gbàjarè sáwọn èèyàn, wọ́n máa ń wọ́de, wọ́n sì máa ń polongo ara wọn kiri àwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde. Lára àwọn ohun tó máa ń dun àwọn alátùn-úntò jù lọ ni pé káwọn èèyàn má kọbi ara sí nǹkan tí wọ́n ń sọ.

Ìtàn Nípa Àwọn Alátùn-úntò

A ti gbọ́ ìtàn nípa ọ̀pọ̀ àtúntò tó ti wáyé. Bíbélì sọ fún wa pé ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, ẹnì kan tó jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba gbóṣùbà fún Fẹ́líìsì tó jẹ́ gómìnà ajẹ́lẹ̀ Róòmù tó ń ṣàkóso ẹkùn ìpínlẹ̀ Jùdíà, ó sọ pé: “Àwọn àtúnṣe ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yìí nípasẹ̀ ìròtẹ́lẹ̀ rẹ.” (Ìṣe 24:2) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ṣáájú àkókò Fẹ́líìsì, Solon tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní orílẹ̀-èdè Gíríìkì ṣe kòkáárí ọ̀pọ̀ àyípadà láti mú ayé dẹrùn fáwọn tálákà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé Solon “mú òpin dé bá gbogbo láabi tó ń fi òṣì ta àwọn èèyàn” ní Áténì ìgbàanì.

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn alátùn-úntò pọ̀ nínú ìtàn ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, Martin Luther gbìyànjú láti ṣàtúntò Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, ohun tó bẹ̀rẹ̀ yẹn ló wá ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìdásílẹ̀ ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì.

Ẹ̀ka Àtúntò

Àwọn alátùn-úntò tún lè máa gbìyànjú láti yí nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì padà. Àwọn alátùn-úntò kan máa ń gbé ọ̀nà ìgbésí ayé tó yàtọ̀ pátápátá lárugẹ. Irú ìyẹn ni tàwọn ẹgbẹ́ alátùn-úntò Lebensreform (àtúntò ìgbésí ayé) tó wà nílẹ̀ Jámánì níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Bí ayé ṣe ń dayé táwọn èèyàn ti ń fi ẹ̀rọ ṣe gbogbo nǹkan nítorí bí wọ́n ṣe ń dá oríṣiríṣi ilé iṣẹ́ sílẹ̀, àwọn èèyàn kò ka ọmọnìkejì wọn sí mọ́ nítorí pé wọ́n gbà pé kò sí àǹfààní kankan táwọn lè ṣe fúnra àwọn. Àwọn alátùn-úntò náà polongo pé ó yẹ káwọn èèyàn padà sí ẹsẹ àárọ̀. Wọ́n ṣagbátẹrù eré ìmárale, nínajú káàkiri, kéèyàn máa lo àwọn oògùn tí wọ́n fi àwọn nǹkan adánidá ṣe dípò egbòogi tí wọ́n ṣe nílé ìwòsàn àti pé kéèyàn máa jẹ ewébẹ̀ dípò ẹran.

Àwọn alátùn-úntò mìíràn túdìí àṣírí ìwà ìrẹ́jẹ, wọ́n sì ń yọ ìjọba lẹ́nu pé àfi kí wọ́n wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà. Láti àwọn ọdún 1970 wá, ẹgbẹ́ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ti fẹ̀hónú hàn lórí báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́ àti báwọn nǹkan tó wà láyìíká ṣe ń dẹnu kọlẹ̀. Àwọn kan lára àwọn ẹgbẹ́ yìí ti wá gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ débi tí wọ́n ti di ẹgbẹ́ kárí ayé. Nǹkan táwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn náà ń ṣe kọjá kí wọ́n kàn máa wọ́de tàbí kí wọ́n kàn máa fẹ̀hónú hàn nítorí àwọn ewu tó wà láyìíká. Wọ́n tún máa ń dábàá àwọn nǹkan tó yẹ ní ṣíṣe láti lè mú àtúnṣe dé bá ipò náà. Akitiyan wọn ló mú kí wọ́n ṣe àtúnṣe àwọn òfin tó de dída àwọn kẹ́míkà olóró sínú òkun àti pípa ẹja àbùùbùtán ní ìpakúpa àtàwọn òfin mìíràn.

Láwọn ọdún 1960 Ìgbìmọ̀ Ìjọba Póòpù Ẹlẹ́ẹ̀kejì bẹ̀rẹ̀ àtúntò Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì. Nígbà tó sì tún di àwọn ọdún 1990, a tún rí àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n di alátùn-úntò láàárín àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n dábàá pé ó yẹ kí àyípadà dé bá ọ̀rọ̀ málọ̀ọ́kọ málàáya. Àwọn alátùn-úntò tó wà nínú Ìjọ Áńgílíkà ń fẹ́ kí àyípadà ṣẹlẹ̀ lórí yíyan àwọn àlùfáà kí ipò náà lè máa kan àwọn obìnrin.

Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Rí I Bẹ́ẹ̀

Àwọn àtúntò kan ti mú àǹfààní tó pọ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì a rí àpẹẹrẹ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè àtàwọn míì tí wọ́n léwájú nínú mímú àyípadà tínú àwọn èèyàn dùn sí wá. Irú ìsapá bẹ́ẹ̀ mú káwọn èèyàn sọjí nípa tẹ̀mí, ó tún mú kí ìgbà ọ̀tun dé bá ìgbé ayé wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (2 Àwọn Ọba 22:3-20; 2 Kíróníkà 33:14-17; Nehemáyà orí 8 àti 9) Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, táwọn èèyàn túbọ̀ ń tẹnu mọ́ òmìnira fún gbogbo ènìyàn, ẹ̀tọ́ aráàlú àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ààbò ti wá wà fáwọn èèyàn kéréje tí ò gbajúmọ̀ àtàwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí.

Àmọ́ ṣá o, bí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ àtúntò báyìí kò sẹ́ni tó mọ ibi tó lè já sí. John W. Gardner, ọ̀gá kan lẹ́nu iṣẹ́ ọba ní ọ̀rúndún ogún, sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tí ò yé àwọn èèyàn ni pé láti ìgbà ìwásẹ̀ làwọn alátùn-úntò kì í ti í ro ohun tó máa tẹ̀yìn àtúntò tí wọ́n dáwọ́ lé yọ.” Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé.

Kété lẹ́yìn ọdún 1980, Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Yúróòpù gùn lé àtúntò iṣẹ́ àgbẹ̀ láti ṣe àwọn tó ń gbé ibi tí koríko àti ilẹ̀ tí wọn ò tíì lò pọ̀ sí láǹfààní. Òfin tuntun tí wọ́n gbé kalẹ̀ lórí iṣẹ́ ọ̀gbìn ya ilẹ̀ tó ṣeé dáko tó fẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] hẹ́kítà lọ níbùú lóòró sọ́tọ̀ fún gbígbin koríko nílẹ̀ Jámánì àti Ítálì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò rere ni wọ́n ní lọ́kàn, ṣùgbọ́n àwọn ewu kan fara sin. Ètò Àbójútó Àyíká ti Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn èèyàn kọ́kọ́ dùn sí i nítorí pé wọ́n kà á sí àǹfààní láti jẹ́ kí ilẹ̀ yẹn túbọ̀ ṣeé gbé fáwọn ohun abẹ̀mí, dídá ibi kan sí gẹ́gẹ́ bí ‘ilẹ̀ àìlò’ lè yọrí sí nǹkan tí ò dáa, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn pa iṣẹ́ àgbẹ̀ àdáyébá tì kí wọ́n sì máa dágbó sí lọ́nà tí kò yẹ.”

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìsapá tí wọ́n ti ṣe láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́, Àjọ Ìdàgbàsókè Iṣẹ́ Àgbẹ̀ Lágbàáyé sọ pé: “Gbogbo akitiyan láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ nípasẹ̀ àtúntò ló ń kojú ìṣòro tó le koko. Àwọn alágbára ló sábà máa ń dá gbogbo lẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti lájọlájọ sílẹ̀, bó sì ṣe tẹ́ àwọn wọ̀nyí lọ́rùn ni wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àjọ náà. . . . Ọ̀nà tó fi máa pé ‘àwọn baba alayé’ ni wọ́n máa ń fẹ́ láti gbà bójú tó àwọn àjọ tó wà ládùúgbò wọn.”

Àpẹẹrẹ mìíràn ni tàwọn ẹgbẹ́ kò-sóhun-tóbìnrin-ò-lè-ṣe, tó yí nǹkan padà fáwọn obìnrin nílẹ̀ ọlọ́làjú nípa bó ṣe jà fún wọn láti lẹ́tọ̀ọ́ àtidìbò àti àǹfààní láti relé ìwé gíga títí kan àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ tó yááyì láwùjọ. Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn alátìlẹyìn òmìnira fáwọn obìnrin pàápàá gbà pé ńṣe ni bí wọ́n ṣe fáwọn obìnrin lẹ́tọ̀ọ́ kan náà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin yìí yanjú àwọn ìṣòro pàtó kan àmọ́, ó tún pa kún àwọn mìíràn. Obìnrin òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Susan Van Scoyoc béèrè pé: “Bá a ṣe gbà pé káwọn obìnrin bá ọkùnrin dọ́gba lẹ́nu iṣẹ́, tá ò sì wá ọ̀nà báwọn ọkọ wọn á ṣe máa bá wọn pín iṣẹ́ ilé ṣe, ṣe kì í ṣe pé a kàn ń dì kún ẹrù wọn ni?”

Àwọn Àtúntò Tí Ò Lẹ́sẹ̀ Ńlẹ̀

Wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn alátùn-úntò kan pé wọ́n kàn máa ń gùn lé àtúntò ká ṣáà lè ní wọ́n yí nǹkan kan padà ni. Nígbà tó ń ṣàpèjúwe ohun tó pè ní àtúntò tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, Frederick Hess, tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àtúntò ilé ẹ̀kọ́ sọ pé: “Ohun tó ń fà á tí àbárèbábọ̀ àwọn àtúntò gbígbòòrò táwọn èèyàn rawọ́ lé ò fi dáa kò ṣẹ̀yìn ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà. Dípò káwọn àtúntò wọ̀nyí yanjú ìṣòro ńṣe ni wọ́n ń yà bàrá kúrò lórí nǹkan tó yẹ kí wọ́n gbájú mọ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pa kún” ìṣòro tó yẹ kí wọ́n yanjú. Ó sọ síwájú sí i pé: “Nítorí pé gbogbo ìjọba tó bá dóde ló máa ń fẹ́ ṣe àtúntò tiẹ̀, láàárín ọdún díẹ̀ síra láwọn àtúntò mìíràn máa ń wáyé.”

Àtúntò tún lè di nǹkan tí wọ́n á fi máa jà fún nǹkan tó yàtọ̀, tàbí tó léwu nígbà mìíràn. Ẹgbẹ́ alátùn-úntò Lebensreform tó wà nílẹ̀ Jámánì, gbé èrò kan kalẹ̀ nípa bí ìran ènìyàn yóò ṣe dára sí i nípa wíwá àwọn òbí méjì tí wọ́n lè mú irú ọmọ tí yóò dá múṣémúṣé jáde. Àmọ́, àwọn térò wọn ò bá tayé mu ṣi àǹfààní ìmọ̀ tí wọ́n ní yìí lò láti ti Ìjọba Násì lẹ́yìn nínú èròǹgbà rẹ̀ láti jẹ́ kí ìran wọn dára ju ti gbogbo ayé lọ.

Kódà àwọn tí wọ́n ń fojoojúmọ́ wá àtúntò gan-an máa ń bá àbájáde tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀ pàdé. Kofi Annan, ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ tẹ̀dùntẹ̀dùn pé: “Mo rò pé ohun tó ń báni lọ́kàn jẹ́ jù níbẹ̀ ni pé gbogbo wa la mọ ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe àti ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n a kì í sábà lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Nígbà mìíràn wọ́n á sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì tó wà lábẹ́ ọ̀gá àgbà pé kí wọ́n wá bátiṣé sí ọ̀ràn ọ̀hún, ṣùgbọ́n owó tí wọ́n nílò láti mú ìpinnu wọn ṣẹ kò sí nítòsí. Nígbà míì táwọn nǹkan tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ tá a sì fẹ́ ta àwọn èèyàn jí lórí ẹ̀, kò sí ẹni tó máa ṣe nǹkan kan nítorí àwọn ìrírí búburú tí wọ́n ti ní látẹ̀yìnwá.”

Ohun táwọn alátùn-úntò kò fi lè retí pé káwọn èèyàn gba tiwọn ni pé bí wọ́n ṣe ń pariwo ohun tí wọ́n ń fẹ́ yẹn, ńṣe ni wọ́n ń fayé ni àwọn ẹlòmíràn lára. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn tó tún jẹ́ ògbógi lórí ọ̀ràn àwọn alátùn-úntò, Jürgen Reulecke tí ìwé ìròyìn Die Zeit fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, sọ pé: “Ẹ̀gún nínú ẹran ara làwọn alátùn-úntò.” Síwájú sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn alátùn-úntò kì í tẹ òfin lójú tí wọn kì í sì í fàjàngbọ̀n, wọ́n lè yarí tí nǹkan tí wọ́n ń fẹ́ ò bá tètè ṣẹlẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló máa ń jẹ́ káwọn ẹgbẹ́ alátùn-úntò di oníjàgídíjàgan tí wọ́n á máa dàgboro rú.

Ǹjẹ́ àwọn àtúntò tó gbalé gbòde lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí ti mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò tẹ́ wọn lọ́rùn sí i? Ó dà bíi pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ìwádìí tí wọ́n ṣe láti mọ èrò àwọn èèyàn fi hàn pé láti bí ọdún márùndínlógójì sẹ́yìn, kò sí ìyípadà gbòógì kan nínú bí ìgbésí ayé ṣe tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn sí. Nínú ìsìn ńkọ́? Ṣé àwọn àtúntò ìsìn ti mú káwọn olùjọ́sìn pọ̀ sí i? Ṣé ìsìn túbọ̀ ń tẹ́ àwọn olùjọ́sìn lọ́rùn sí i? Rárá o, nítorí pé ńṣe làwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ilẹ̀ ọlọ́làjú túbọ̀ ń kọ̀yìn sí ìsìn, tí ẹ̀sìn àjogúnbá wọn kò sì já mọ́ nǹkan lójú wọn mọ́.

Ṣé Alátùn-úntò Ni Jésù Kristi?

Àwọn kan ń sọ pé alátùn-úntò ni Jésù Kristi. Ṣé òótọ́ ni wọ́n sọ? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, nítorí pé láti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ń béèrè pé kéèyàn máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi tímọ́tímọ́.—1 Pétérù 2:21.

Kò sí iyèméjì pé Jésù lágbára láti mú àtúntò wá. Gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, ó lágbára láti káwọn èèyàn sòdí kó sì ṣe ohun tẹ́nìkan ò ṣe rí, kó sí yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan padà. Síbẹ̀, Kristi ò dágbá lé e láti ṣe ìpolongo tí yóò fi rẹ́yìn àwọn jẹgúdújẹrá òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláìṣòótọ́ oníṣòwò. Kò léwájú àwọn èèyàn láti máa wọ́de nítorí àìsí ìdájọ́ òdodo, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa tó jẹ òun náà níyà láìṣẹ̀ láìrò. Àwọn ìgbà mìíràn tiẹ̀ wà tí Jésù “kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” Kò tìtorí bẹ́ẹ̀ dá ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sílẹ̀ láti máa bá ìjọba fà á kí ìjọba lè bójú tó ìṣòro àwọn tí kò nílé lórí. Nígbà táwọn kan ń ṣàníyàn nípa ìṣúnná owó, ó ṣàlàyé pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.” Jésù ta kété sí gbogbo gbọ́nmi-si omi-ò-to tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà náà.—Mátíù 8:20; 20:28; 26:11; Lúùkù 12:13, 14; Jòhánù 6:14, 15; 18:36.

Kì í ṣe pé Kristi ṣe bí ẹni pé àwọn ìṣòro bí òṣì, ìwà ìbàjẹ́ àti àìṣèdájọ́ òdodo kò kan òun. Kódà, Bíbélì fi hàn pé àánú àwọn èèyàn ṣe é nígbà tó rí ìṣòro tó ń bá wọn fínra. (Máàkù 1:40, 41; 6:33, 34; 8:1, 2; Lúùkù 7:13) Ṣùgbọ́n ó fẹ́ láti bá wọn yanjú ìṣòro wọ̀nyẹn pátápátá ni. Kì í ṣe àtúntò kan lásán làsàn ni Kristi ní lọ́kàn láti ṣe, ńṣe ló fẹ́ láti mú àyípadà pátápátá bá ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bójú tó àlámọ̀rí aráyé. Ìjọba ọ̀run tí Ẹlẹ́dàá ìran ènìyàn, Jèhófà Ọlọ́run dá sílẹ̀, èyí tí Jésù Kristi yòó máa ṣàkóso bí Ọba rẹ̀ ni yóò mú àyípadà yìí wá. Èyí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Ọ̀kan lára ohun tí ò yé àwọn èèyàn ni pé láti ìgbà ìwásẹ̀ làwọn alátùn-úntò kì í ti í ro ohun tó máa tẹ̀yìn àtúntò tí wọ́n dáwọ́ lé yọ.”—John W. Gardner

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Mo rò pé ohun tó ń bani lọ́kàn jẹ́ jù níbẹ̀ ni pé gbogbo wa la mọ ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe àti ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n a kì í sábà lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀.”—Kofi Annan, Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

“Mo Fẹ̀mí Ara Mi Wewu Torí Àtidáàbò Bo Àyíká”

Ọdún méjìdínláàádọ́ta ni Hans fi ṣiṣẹ́ awakọ̀ ojú omi, èyí tó ju ọdún márùndínlógójì nínú ọdún wọ̀nyí ló sì fi jẹ́ ọ̀gákọ̀. Nígbà tó kù díẹ̀ kó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó di ọ̀gákọ̀ ọkọ ojú omi kan tí àjọ kan tó ń bójú tó àyíká ń lò. Ó ṣàlàyé pé:

“Ìgbàgbọ́ tèmi ni pé ó yẹ káwọn èèyàn máa fọwọ́ pàtàkì mú àyíká àtàwọn ìṣẹ̀dá inú rẹ̀. Nítorí náà nígbà tí wọ́n fi àǹfààní láti di ọ̀gákọ̀ ojú omi àwọn ẹgbẹ́ kan tó ń dáàbò bo àyíká lọ̀ mí, ńṣe ni mo bẹ́ mọ́ ọn lójú ẹsẹ̀. Iṣẹ́ wa ni láti jẹ́ káyé mọ àwọn ohun tó lè ba àyíká jẹ́. Gbàrà tá a ti ń múra àtidáwọ́ lé ìgbòkègbodò tá a fẹ́ ṣe lójú òkun báyìí la ti ké sáwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde láti lè pariwo wa fáyé gbọ́. A lọ sójú agbami òkun a sì gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí báwọn èèyàn ṣe ń da pàǹtírí ìtànṣán olóró àtàwọn nǹkan onímájèlé sínú òkun. Nínú ìgbòkègbodò mìíràn, a gbìyànjú láti fòpin sí bí wọ́n ṣe ń dọdẹ àwọn kìnnìún òkun àtàwọn ọmọ wọn.

“Ojo ò lè ṣe irú iṣẹ́ yìí o. Mo fẹ̀mí ara mi wewu láti dáàbò bo àyíká. Lákòókò kan tí a fẹ̀hónú hàn, mo fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọwọ́ ara mi mọ́ ìdákọ̀ró ọkọ̀ ojú omi kan tó fi di pé ọkọ̀ ojú omi yẹn wọ́ mi dé ìsàlẹ̀ odò. Lákòókò mìíràn, mo wà nínú ọkọ̀ ojú omi onírọ́bà kan tí mo sì ń lọ lójú omi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ ojú omi ńlá. Ẹnì kan ju àgbá onírin ńlá kan sínú ọkọ̀ wa, bó ṣe dojú dé nìyẹn. Mo fara pa yánnayànna.”

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni Hans wá mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé èròǹgbà ẹgbẹ́ náà dára, ńṣe lòun kàn ń fẹ̀mí ara òun wewu lórí nǹkan tó jẹ́ pé bóyá ni àǹfààní tá ṣe fún àyíká lè tọ́jọ́. (Oníwàásù 1:9) Kò pẹ́ sígbà yẹn tó fi pa ẹgbẹ́ tó ń jà fún àyíká yẹn tì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi. Lónìí, ó ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. “Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún bíbójútó àyíká lọ́nà tó dára ni ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Mèsáyà.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ó Jà fún Àtúntò

Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn 1960 ni wọ́n bí Sara (orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyẹn) nílẹ̀ Éṣíà. Kò tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tí ìyípadà tegbòtigaga kan tó wáyé lórílẹ̀-èdè tó ń gbé mú kí ìjọba tuntun gorí àlééfà tí ìjọba ọ̀hún sì lérí léka pé òun á mú àtúntò òṣèlú àti àwùjọ wá. Inú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kọ́kọ́ dùn sí ìyípadà tó dé bá wọn, àmọ́ láàárín ọdún kan, ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣenúnibíni sáwọn alátakò rẹ̀, ohun tí ìjọba tó kógbá sílé náà ṣe nìyẹn. Ojú ọ̀pọ̀ èèyàn ti là kọjá kí wọ́n tàn wọ́n jẹ, Sara sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń tako ìjọba tuntun náà. Ó ṣàlàyé pé:

“Ẹgbẹ́ alátakò wa máa ń ṣèpàdé a sì máa ń wọ́de. Níbi tí mo ti ń lẹ ìwé ìpolongo wa káàkiri ìgboro tí mo sì ń pín ìwé pélébé fáwọn èèyàn làwọn sọ́jà ti rá mi kó. Níkẹyìn wọ́n fi mí sílẹ̀ kí n máa lọ. Nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fáwọn tó kù nínú ẹgbẹ́ wa. Ọwọ́ tẹ àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì, wọ́n sì pa wọ́n. Ẹ̀mí mi wà nínú ewu, nítorí náà bàbá mi rọ̀ mí láti kúrò lórílẹ̀-èdè náà.”

Nígbà tí Sara dé ilẹ̀ Yúróòpù, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní báyìí, ó ti di ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà tí Sara wo ìgbésí ayé rẹ̀ látẹ̀yìnwá, ó sọ pé:

“Ìdájọ́ òdodo àti ojútùú sáwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra láàárín ìlú ni mò ń wá. Mo rí i pé ohun tí ìjọba tuntun ní orílẹ̀-èdè wa fi bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn kó tó di pé wọ́n ki àṣejù bọ̀ ọ́ débi tí wọn kò fi lépa ohun tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ mọ́ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fìyà jẹ àwọn ará ìlú. Mo tún rí i pé àwọn ẹgbẹ́ tá a jọ ń fẹ̀hónú hàn kò lè yanjú àwọn ìṣòro orílẹ̀-èdè wa. (Sáàmù 146:3, 4) Mo ti wá rí i báyìí pé ojútùú sí gbogbo ìṣòro aráyé di inú Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Mèsáyà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ògiri Berlin wó lọ́dún 1989

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ṣé àwọn àtúntò ìsìn ti mú kí àwọn olùjọ́sìn pọ̀ sí i?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Lókè, lápá ọ̀tún: Fọ́tò U.S. Information Agency

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Kofi Annan: Fọ́tò UN/DPI tí Evan Schneider yà (Feb97); àwòrán apá ẹ̀yìn: WHO/OXFAM

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́