ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 33
  • Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Igbe Àtúntò Laráyé Ń ké
    Jí!—2004
  • Ṣọọṣi Latin-America Ninu Idaamu—Eeṣe ti Araadọta-Ọkẹ Fi Ń Kuro?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Ogun Ìsìn Ní Ilẹ̀ Faransé
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 33
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún aládùúgbò rẹ̀

Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Rárá. Kristẹni ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ a kì í ṣe ara àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Kí nìdí?

Àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni “àjọ àwọn ẹlẹ́sìn kan tí wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Kátólíìkì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fara mọ́ ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì fi ń kọ́ni, síbẹ̀ a kì í ṣe ara àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì torí àwọn ìdí yìí:

  1. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ló ta ko ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kọ́ wa pé “Ọlọ́run kan ni ó wà” kì í ṣe Mẹ́talọ́kan. (1 Tímótì 2:5; Jòhánù 14:28) Bákan náà, Bíbélì fi hàn kedere pé ìparun títí láé ló wà fún àwọn aṣebi kì í ṣe inú iná ọ̀run àpáàdì ni wọ́n ń lọ.​—Sáàmù 37:9; 2 Tẹsalóníkà 1:9.

  2. A kì í ṣe ìwọ́de lòdì sí ẹ̀sìn Kátólíìkì tàbí àwọn ẹlẹ́sìn míì, a kì í sì fẹ́ ṣàtúnṣe sí wọn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ńṣe la máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ohun tí a fẹ́ ni pé kí a kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì, kì í ṣe láti ṣàtúnṣe sí ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn míì fi ń kọ́ni.​—Kólósè 1:​9, 10; 2 Tímótì 2:​24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́