Ṣọọṣi Latin-America Ninu Idaamu—Eeṣe ti Araadọta-Ọkẹ Fi Ń Kuro?
LATI iha ibode ariwa Mexico si otente iha guusu Chile, ṣàṣà ni ilu-nla tabi abule Latin-America kan ti kò fi ṣọọṣi Roman Katoliki kan ti o wà ni ibi ikorita pataki rẹ̀ yangàn. Bi o ti wu ki o ri, “iyipada manigbagbe kan ń ṣẹlẹ ni Latin America,” ni Joseph E. Davis, oludari itolẹsẹẹsẹ eto-idasilẹ kan ti ń ṣagbatẹru awọn igbokegbodo Katoliki jẹwọ. O tun gbà pe Latin America, agbegbe kan ti o ti wà labẹ idari Ṣọọṣi Roman Katoliki fun eyi ti o ju ọrundun mẹta lọ, nisinsinyi ti wà ni bèbè iyipada titobi.
Kìí ṣe aṣiri pe ijẹgaba Ṣọọṣi Katoliki ń yára kankan di ahẹrẹpẹ. Laipẹ yii, iye awọn Katoliki aláápọn ni a ṣiro si eyi ti o jẹ́ kìkì ipin 15 ninu ọgọrun-un apapọ iye awọn eniyan Latin America. Iwe naa 1991 Britannica Book of the Year rohin pe: “Awọn Biṣọọbu Roman Katoliki ati poopu fúnraarẹ̀ fi ìbẹ̀rù hàn pe niti ọrọ ìtàn, Latin America ti o jẹ́ ti Katoliki ń yipada kuro ninu igbagbọ atijọ lọna ti o léwu.” Eeṣe ti eyi fi ń ṣẹlẹ? Eeṣe ti ọpọ tobẹẹ ṣe ń fi agbo Katoliki silẹ? Ki ni ti ṣẹlẹ si awọn ti wọn ṣako lọ?
Iwakiri fun Àlàyé
Awọn aṣaaju Katoliki dá ẹ̀bi iṣoro wọn fun ìgbèrú “awọn ẹ̀ya ìsìn.” Alufaa ara Europe kan ti ń ṣiṣẹ ni Bolivia ṣaroye pe: “Ṣọọṣi naa dabi igi kan ti awọn ẹ̀ya ìsìn rẹ ti wọn dabi èpò ń jẹ agbara rẹ̀ run.”
Ni Argentina, 140 eto isin titun ni a ń rohin ni ọdọọdun, eyi ti o le ṣeranwọ lati ṣalaye idi fun ilọsilẹ ninu iye mẹmba Ṣọọṣi Katoliki lati ipin 90 ninu ọgọrun-un si ipin 60 tabi 70 ninu ọgọrun-un lati aarin awọn ọdun 1970 wá. Ni Tijuana, Mexico, ipin 10 ninu ọgọrun-un ninu awọn million meji olugbe ilẹ̀ naa ni wọn ti sọdá lọ sinu awọn ẹya isin 327 ti wọn kìí ṣe Katoliki nibẹ. Iwe-irohin Time sọ pe: “Lọna ti o yanilẹnu, o fẹrẹ daju pe awọn ará Brazil onisin Protẹstant ti o wà ni ṣọọṣi ni ọjọ Sunday pọ̀ ju awọn onisin Katoliki lọ.” Kò yanilẹnu pe, gẹgẹ bi iwe-irohin kan ti sọ, nigba ti “awọn alufaa agba Latin-America pade pẹlu poopu ni Ilu-nla Vatican lati jiroro awọn koko-ọrọ meji ti o ṣepataki gan-an fun ṣọọṣi naa lonii,” ọ̀kan ninu wọn ni “iṣoro awọn ẹ̀ya ìsìn.”
Nibi ipade kan pẹlu awọn biṣọọbu Mexico, poopu sọ pe aṣeyọrisirere pupọ awọn isin titun naa “jẹ́ nitori kò-gbóná-kò-tutù ati idagunla awọn ọmọkunrin ṣọọṣi ti wọn kò kaju ìwọ̀n iṣẹ ajihinrere wọn.” Eeṣe ti “awọn ọmọkunrin ṣọọṣi” fi dagunla si pipese fun aini tẹmi awọn ara Latin America nigba ti o jẹ pe ọpọ ninu awọn wọnyi ni wọn bọwọ fun Bibeli? Irohin kan ninu Última Hora, ti ilẹ La Paz, Bolivia, ṣalaye pe: “Ṣọọṣi naa ti wọnu ayé de iru iwọn kan debi pe ni ọjọ kọọkan o dabi ẹni pe o ń tẹsiwaju ni kíkọ sakaani tirẹ̀ silẹ. Kò nilati jẹ́ ohun iyalẹnu fun wa lati ri, gẹgẹ bi o ti ń ṣẹlẹ niti gidi, pe awọn alufaa tubọ dabi awọn onimọ nipa ajọṣepọ ẹgbẹ-oun-ọgba, ti onimọ iṣunna-owo, oniṣẹ akọrohin, tabi oṣelu ju bi wọn ti jẹ́ alufaa lọ.
Wọn Ha Tubọ Jẹ́ Oṣelu Ju Oniwaasu Lọ Bi?
Ilọwọ ṣọọṣi naa ninu oṣelu ni awọn ọdun 1970 ati 1980 laiṣe àníàní dakun irira ti pupọ awọn eniyan Latin America nimọlara rẹ̀ fun isin Katoliki nisinsinyi. Iwadii kan ti a tẹjade ni 1985 ṣe awọn akiyesi ti o tẹlee yii nipa Maryknoll, Ẹgbẹ Ihin-iṣẹ Ilẹ Okeere ti Katoliki ní America, pẹlu ọpọ awọn ihin-iṣẹ Latin-America rẹ̀: “Maryknoll ti mu ihin-iṣẹ iṣọtẹ onika ti ẹkọ Max-oun-Lenin wọnu itẹwọgba itagbangba pẹlu aṣeyọrisirere ni pato nitori pe a ti gba a laaye lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi apakan Sọọṣi Katoliki. Awọn ihin-iṣẹ rẹ̀ ti dé kìí ṣe kiki ọ̀dọ̀ awọn gbáàtúù olùreṣọ́ọ̀ṣì nikan ni, ṣugbọn awọn ti wọn mu ipo iwaju ninu ṣiṣe ilana eto America, bakan naa.”
Ṣagbeyẹwo ogun eléèríí ti a fi ẹnu lasan pè bẹẹ pẹlu ninu eyi ti, lọna yiyanilẹnu, a ti gbé 10,000 si 30,000 awọn eniyan ilẹ Argentina salọ ti a si pa wọn laisi ìgbẹ́jọ́ ni apa ipari awọn ọdun 1970. Irohin kan ninu National Catholic Reporter, labẹ akọle naa “Ẹ̀jẹ̀ Kó Àbààwọ́n Bá Ṣọọṣi ni Argentina,” sọ pe: “Iriri awọn eniyan Argentina ni ọ̀nà ti o sunmọra farajọ iṣesi ṣọọṣi Katoliki ni Nazi Germany, o tun gbe ibeere dide nipa boya agbara ṣe pataki fun ṣọọṣi naa ju Ihinrere ti kò ṣeefi falẹ lati jẹ́ ẹ̀rí kan si otitọ.”
Ìfẹ́-ọkàn ṣọọṣi naa fun agbara ninu awọn ijọba ayé sami si i kedere gẹgẹ bi eyi ti kìí ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Bibeli sọ pe: “Iwọ kò ha mọ̀ pe fifi ayé ṣe ọ̀rẹ́ rẹ jẹ́ fifi Ọlọrun ṣe ọ̀tá rẹ bi? Ẹnikẹni ti o bá yan ayé ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọrun.” (Jakọbu 4:4, Jerusalem Bible ti Katoliki) Kò yanilẹnu, nigba naa, pe ọpọlọpọ kò gbẹkẹle Ṣọọṣi Katoliki fun itọsọna tẹmi mọ́. Ṣugbọn ki ni o ti ṣẹlẹ si awọn eniyan ti wọn ti fi agbo isin Katoliki silẹ?
Awọn Agutan Laisi Oluṣọ
Wọn rí gan-an bii awọn eniyan tí awọn aṣaaju tẹmi ti isin Ju ní ọrundun kin-in-ni kuna lati bojuto. Bibeli sọ pe Jesu “kun fun aanu fun wọn nitori pe a dá wọn lagara a sì kó irẹwẹsi bá wọn, gẹgẹ bi awọn agutan ti kò ni oluṣọ.” (Matteu 9:36, JB) Pupọ ni o ti sá kuro ni Ṣọọṣi Katoliki lọ si awọn ti a wulẹ pe ni isin ajihinrere. Ǹjẹ́ awọn wọnyi ha ti ṣetọju awọn agutan ti o ṣako lọ naa lọna ti o dara ju bi? Ǹjẹ́ awọn Protẹstanti ha ní itẹsi lati ri bí Jesu ti sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ: “Wọn kìí ṣe ti ayé, gẹgẹ bi emi kìí tií ṣe ti ayé” bi?—Johannu 17:14.
Pupọ isin ti kìí ṣe ti Katoliki gbiyanju lati tan imọlẹ sori aworan jíjẹ́ onigbọran si Bibeli dipo awọn ẹkọ atọwọdọwọ ti isin. Bojúbojú lasan ni eyi saba maa ń jẹ́. Awọn ẹkọ ipilẹṣẹ awọn eto-ajọ Protẹstanti ti jọra pẹlu awọn Ṣọọṣi Katoliki debi pe ọpọ awọn onworan lè fi tirọruntirọrun lo ọ̀rọ̀ ilẹ Andes naa: “Es la misma cholita con otra pollera” (Ọdọmọbinrin ibilẹ kan-naa ni, sikẹẹti rẹ̀ ni o yàtọ̀).
Fun apẹẹrẹ, o fẹrẹ jẹ pe gbogbo awọn ẹgbẹ́ Protẹstanti ni wọn kọni pe Ọlọrun jẹ́ Mẹtalọkan, sibẹ eyi kìí sìí ṣe ẹkọ Bibeli. Iwe gbédègbéyọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pe: “Awọn aláwìíyé ati awọn ẹlẹkọọ isin lonii fohunṣọkan pe Bibeli Heberu kò ni ẹkọ kankan nipa Mẹtalọkan . . . Majẹmu Titun pẹlu kò ní ẹkọ kan ti o daju nipa Mẹtalọkan ninu.”a
Awọn Protẹstanti ni a sopọ ni kedere mọ́ ayé yii ati eto oṣelu rẹ̀ gan-an bii ti awọn Katoliki. Iwe gbédègbéyọ̀ Encyclopedia of Latin America sọ pe: “Isin Protẹstanti ni Latin America pẹlu ti mu araarẹ̀ bá . . . eto oṣelu ìbò aṣoju fun awọn mẹ̀kúnnù mu. Awọn alufaa ọmọ onilẹ sábà maa ń di oníbàárà fun awọn babaàsàlẹ̀ oṣelu ti wọn a si pese awọn ìbò ni ìdápadà fun ojurere ijọba si awọn ṣọọṣi wọn.” Iwe Latin American Research Review sọ pe: “A ti jó isin Protẹstanti pọ̀ mọ́ iṣelu ni Guatemala tipẹtipẹ lati ìgbà ti o ti kọkọ dé orilẹ-ede naa,” ni fifikun un pe o “ti jẹ́ ọ̀nà gan-an fun tita àtagbà ihuwa niti oṣelu ati ti ẹgbẹ-oun-ọgba gẹgẹ bi irú isin kan.”
Ikopa Protẹstanti ninu iṣelu ti sábà maa ń yọri si ikopa Protẹstanti ninu ogun. Oloogbe Harry Emerson Fosdick, ti a mọ̀ si ọ̀kan lara awọn alufaa Protẹstanti ti o ni agbara idari giga julọ ninu ìtàn America, gba pe: “Ìtàn iha Iwọ-oorun wa ti jẹ́ ogun kan tẹle omiran. A ti tọ́ awọn eniyan fun ogun, dá awọn eniyan lẹkọọ fun ogun; a ti fogo fun ogun; a ti fi awọn jagunjagun ṣe akikanju wa ani ninu awọn ṣọọṣi wa paapaa ni a ti gbé awọn asia ogun si . . . A ti fi kọ̀rọ̀ ẹrẹkẹ wa kan yin Ọmọ-Alade Alaafia ti a sì fi kọ̀rọ̀ ẹrẹkẹ keji fi ògo fun ogun.”
Ki Ni Iwọ Nilati Ṣe?
Lẹhin ṣiṣapejuwe isin èké gẹgẹ bi aṣẹwo iṣapẹẹrẹ kan ti ń dẹṣẹ agbere pẹlu awọn ijọba ayé, Bibeli ninu iwe Ìfihàn sọ pe: “Ẹ jade, ẹyin eniyan mi, kuro ninu rẹ̀, ki ẹ ma baa ṣalabaapin ninu awọn iwa ọdaran rẹ̀ ki ẹ sì ni iru ìyọnu kan-naa lati koju.”—Ìfihàn 18:4, JB.
Ọpọ eniyan ni wọn mọ̀ pe iwa ibajẹ pupọ wà ni ṣọọṣi, sibẹ wọn lọra lati jade nitori pe Ṣọọṣi Romu ní iru ìtàn àtayébáyé bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, ranti pe, ọ̀nà igbajọsin awọn Ju jẹ eyi ti o lọjọ lori gan-an; sibẹ Ọlọrun kọ awọn Ju silẹ gẹgẹ bi awọn eniyan ayanfẹ rẹ̀ nigba ti wọn pẹhinda kuro ninu awọn ẹkọ otitọ rẹ̀. Awọn olódodo iranṣẹ Ọlọrun fi isin awọn Ju silẹ nigba ti o hàn si wọn pe Ọlọrun ti ń lo ijọ Kristian dipo rẹ̀. Bawo ni iwọ ṣe le mọ ijọ Kristian tootọ naa lonii?
Eyi ti o fẹrẹẹ tó million kan awọn eniyan Latin America ni wọn ti di Ẹlẹ́rìí Jehofa ni awọn ẹwadun meji ti o ti kọja. Eeṣe ti wọn fi ṣe awọn iyipada wọnyi? Iwe-irohin kan ni Martínez de la Torre, Veracruz, Mexico, gbe ibeere yii yẹwo. O wi pe: “Ó fẹrẹ jẹ́ pe gbogbo awọn akẹkọọ Bibeli wọnyi ni wọn ti jẹ́ olukopa pataki tẹlẹri ninu oriṣiriṣi awọn isin, ti eyi ti o pọ julọ jẹ ti Katoliki, ti wọn ti ṣakiyesi bi isin ti ń fà siha iṣelu ati bi ó ti tẹwọgba ti ó sì fọwọsi awọn àṣà ti kò ba Bibeli mu bi àmúlùmálà igbagbọ, iwa palapala, ati iwa-ipa. O ti jẹ́ orisun itẹlọrun fun wọn lati ṣegbọran si awọn ilana iwahihu ti Iwe Mimọ laiyiju si ibọriṣa tabi awọn ẹkọ atọwọdọwọ ti o ni ipilẹ ti o farasin. Eyi ti fun wọn ni iṣọkan igbagbọ ti o yẹ fun igboriyin ti o dabi eyi ti o ń yà wọn sọtọ nibikibi ti a bá ti ri wọn.”
Iwe-irohin Latin-America miiran sọ ọ bayii pe: “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ oṣiṣẹ kára, alailabosi, olubẹru Ọlọrun. Wọn jẹ́ oniṣọọra ati olufẹ ẹkọ ti a ti fi kọ́ wọn a sì gbe isin wọn kari awọn ẹkọ Bibeli.” A kesi ọ lati kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibikibi ti o bá ń gbé. Iwọ yoo kẹkọọ pe awọn ireti wọn ati ọ̀nà igbesi-aye wọn lodindi ni a gbekari Bibeli. Bẹẹni, iwọ yoo kọ́ bi o ṣe lè jọsin Ọlọrun “ni ẹmi ati ni otitọ.”—Johannu 4:23, 24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo iwe pẹlẹbẹ naa Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 21]
AWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA NI AWỌN ORILẸ-EDE LATIN-AMERICA DIẸ 1971 1992
Orilẹ-Ede Awọn Akede Awọn Akede
Argentina 20,750 96,780
Bolivia 1,27 68,868
Brazil 72,269 335,039
Chile 8,231 44,067
Colombia 8,275 55,215
Costa Rica 3,271 14,018
Dominican Republic 4,106 15,418
Ecuador 3,323 22,763
El Salvador 2,181 20,374
Guadeloupe 1,705 6,830
Guatemala 2,604 13,479
Honduras 1,432 6,583
Mexico 54,384 354,023
Panama 2,013 7,732
Paraguay 901 4,115
Peru 5,384 43,429
Puerto Rico 8,511 25,315
Uruguay 3,370 8,683
Venezuela 8,170 60,444
AROPỌ 212,156 1,143,175