Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Jáwọ́ Nínú Àṣà Burúkú?
ÒǸKỌ̀WÉ Mark Twain sọ nígbà kan rí pé: “Láyé yìí o, kò sóhun tó rọrùn láti ṣe tó kéèyàn fi sìgá mímu sílẹ̀. Ohun tó jẹ́ kí n mọ̀ ni pé mo ti ṣe bẹ́ẹ̀ láìmọye ìgbà.” Láìsí àníàní, ńṣe lọ̀rọ̀ tí Twain sọ á ró kì lọ́kàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Bí wọ́n tiẹ̀ mọ̀ pé àwọn àṣà kan ò yẹ ọmọlúwàbí tí wọ́n tiẹ̀ léwu pàápàá, wọn ò tún ṣaláì mọ̀ pé jíjáwọ́ nínú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ àti bíborí wọn gan-an lohun tó ṣòro jù. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àwọn àṣà kan lè mọ́ni lára débi pé ó máa ṣòro gan-an láti yí wọn padà. Gbígbìyànjú láti mú kí ọkàn ẹni má ṣe fà sí irú àṣà bẹ́ẹ̀ mọ́ máa ń tánni lókun, ìsapá tó sì ń gbà ò kéré rárá.
Dókítà Anthony Daniels, tó ń ṣiṣẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ṣàlàyé pé àwọn ọ̀daràn sábà máa ń ṣàwáwí pé ìwà burúkú táwọn ń hù ti di mọ́ọ́lí sáwọn lára, kò sì ṣeé ṣe fáwọn láti jáwọ́ nínú ẹ̀ rárá. Wọ́n sọ pé gbàrà tí àṣà kan bá ti di bárakú sẹ́nì kan lára, a jẹ́ pé “ọwọ́ ṣìnkún ìwà tí ò lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ nìyẹn.” Bí ohun tí wọ́n sọ yìí bá wá jóòótọ́, a jẹ́ pé àṣegbé ni ohunkóhun yòówù tá a bá hù níwà nítorí pé a ò kúkú lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé itú tó bá ṣáà ti wu èrò inú àti ìfẹ́ ọkàn wa ni wọ́n lè fi wá pa? Àbí, ó ṣeé ṣe láti jáwọ́ nínú àṣà burúkú? Láti rí ìdáhùn tó ṣeé gbára lé, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ.
Ohun Tó Wuni Làgbà Ohun Tá A Ṣe
Bíbélì mú kó ṣe kedere pé a óò jíhìn ohun tá a bá ṣe fún Ọlọ́run. (Róòmù 14:12) Bákan náà, ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé ká dójú ìlà àwọn ìlànà òdodo òun. (1 Pétérù 1:15) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ ohun tó dára jù lọ fún wa, àwọn ìlànà rẹ̀ sì dẹ́bi fún ọ̀pọ̀ lára àwọn àṣà tó wọ́pọ̀ nínú ayé yìí. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Gálátíà 5:19-21) Àmọ́ ṣá o, aláàánú ni, kò sì retí pé kí àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé ṣe ohun tí agbára wọn ò gbé.—Sáàmù 78:38; 103:13, 14.
Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí onísáàmù náà fi kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà mọ̀ dáadáa pé “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Àbùdá wa, àìlera ẹ̀dá àti ohun tójú ti rí láyé kì í jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn búburú pátá. Ìyẹn ló fi yẹ ká máa ṣọpẹ́ pé Jèhófà ò fagbára mú wa láti máa ṣe nǹkan lọ́nà pípé pérépéré.—Diutarónómì 10:12; 1 Jòhánù 5:3.
Àmọ́ ṣá o, gbígbà tí Ọlọ́run ń gba tiwa rò lọ́nà yìí ò wá fi hàn pé kò sí ọlọ́pàá tó máa mú wa bá a bá ń gba èròkerò láyè o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun alára máa ń bá ìfẹ́ ọkàn búburú jagun, kò fìgbà kan juwọ́ sílẹ̀. (Róòmù 7:21-24) Ó sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” Nítorí kí ni? “Kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.” (1 Kọ́ríńtì 9:27) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì bá a bá fẹ́ gbógun ti èròkerò àti àwọn àṣà burúkú ká sì borí wọn.
Ó Ṣeé Ṣe Láti Yí Padà
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìwà híhù sọ pé bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ lèèyàn ń kọ́ láti hùwà rere bẹ́ẹ̀ náà lèèyàn lè kọ́ láti hùwà burúkú. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú nígbà náà pé èèyàn lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó kọ́! Lọ́nà wo nìyẹn ná? Àwọn méjì kan tí wọ́n ṣèwé nípa béèyàn ṣe lè kojú másùnmáwo sọ pé: “Máa ronú nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú pé kó o jáwọ́ nínú ìwà tó ò ń hù tẹ́lẹ̀.” Lẹ́yìn náà, “ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí yíyí ìwà rẹ padà fi lè mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ríronú nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú yíyí ìwà tí ò dáa padà lè sún wa láti yí i padà.
Ṣáà ronú nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣí wa létí pé ká “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú [wa] ṣiṣẹ́.” (Éfésù 4:22, 23) Ipá yẹn ni agbára tó ń darí èrò orí wa. Ọ̀nà táa lè gbà yí ipá yẹn padà ni pé ká sún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí, ká mọ àwọn ìlànà rẹ̀, ká sì lò wọ́n lọ́nà tó fi hàn pé a mọrírì wọn. Mímọ̀ pé ò ń ṣe ohun tó dùn mọ́ Jèhófà nínú á túbọ̀ fún ọ níṣìírí láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.—Sáàmù 69:30-33; Òwe 27:11; Kólósè 1:9, 10.
Àmọ́ ṣá o, jíjáwọ́ nínú àṣà burúkú tó ti ń darí ìgbésí ayé wa tipẹ́tipẹ́ máa ṣòro o. Ká má ṣe gbàgbé pé ojú bọ̀rọ̀ kọ́ la fi í gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́. O lè ní ìjákulẹ̀, o sì tún lè kùnà. Ṣùgbọ́n, mọ̀ dájú pé bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn nǹkan á túbọ̀ rọrùn sí i. Bó o bá ṣe ń sapá tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ á máa mọ́ ọ lára.
Ó dájú ṣáká pé béèyàn bá fẹ́ràn Ọlọ́run á rí ìrànlọ́wọ́ àti ìbùkún rẹ̀ gbà. Pọ́ọ̀lù ṣèlérí pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n . . . òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jèhófà Ọlọ́run á pa ètò àwọn nǹkan búburú yìí run yóò sì kásẹ̀ gbogbo ìdẹwò, ìfẹ́ búburú àtàwọn nǹkan jágbajàgba míì tọ́kàn èèyàn máa ń fà sí nílẹ̀. (2 Pétérù 3:9-13; 1 Jòhánù 2:16, 17) Bí àkókò ti ń lọ, gbogbo ẹ̀dá aláìpé tó bá la ìṣẹ̀lẹ̀ yìí já lè bọ́ lọ́wọ́ ìpọ́njú, ì báà jẹ́ ìpọ́njú nípa tara, ìdààmú ọpọlọ tàbí àárẹ̀ ọkàn. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Kò sí iyèméjì pé gbogbo ìyánhànhàn àti ìfẹ́ ọkàn tí ń dani láàmú á wà lára “àwọn ohun àtijọ́” wọ̀nyí. Ǹjẹ́ ìdí yìí ò lágbára tó láti sún wa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti yẹra fún àṣà burúkú ká sì gbéjà kò ó?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
JÍJÁWỌ́ NÍNÚ ÀṢÀ BURÚKÚ
1. Mọ ohun tí ìwà burúkú jẹ́, kó o sì gbà bó o bá ní in. Bí ara rẹ pé, ‘Kí ni mò ń rí gbà nínú àṣà yìí ná? Ṣó máa ń bí àwọn mìíràn nínú? Ṣó ń ṣàkóbá fún ìléra mi, ṣó ń gbọ́n mi lówó lọ, ṣó ń ba ayọ̀ mi jẹ́, ṣó ń ṣàkóbá fún ìdílé mi, àbí kò jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀? Báwo ni nǹkan ì bá ṣe sunwọ̀n fún mi tó bí mo bá jáwọ́ nínú ẹ̀?’
2. Fi ohun tó dára rọ́pò àṣà burúkú náà. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ò ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá tó o tiẹ̀ ń wo ìwòkuwò pàápàá? Kúkú lo àkókò yẹn fún ohun tó ṣàǹfààní, bíi kíkàwé, kíkẹ́kọ̀ọ́, tàbí ṣíṣeré ìdárayá.
3. Máa kíyèsí bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Lójoojúmọ́, fi ìṣẹ́jú díẹ̀ ronú lórí bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Bó o bá tún hùwà burúkú náà, rí i pé o mọ ohun tó sún ọ tó o fi kó sínú ìṣòro náà.
4. Wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Jẹ́ kí tẹbí tará mọ̀ pé ò ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú àṣà náà, kó o sì sọ pé kí wọ́n rán ọ létí tó bá dà bí ẹni pé o tún fẹ́ hùwà náà. Fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ti jáwọ́ nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀.—Òwe 11:14.
5. Wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsí má sì ṣe jura ẹ lọ. Má ṣe retí pé wéré bí ọgán ni nǹkan á padà bọ̀ sípò. Àwọn àṣà tó pẹ́ kó tó mọ́ni lára, ò lè lọ lọ́sàn-án kan òru kan.
6. Gbàdúrà sí Ọlọ́run. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, o lè jáwọ́ nínú àṣà burúkú èyíkéyìí.—Sáàmù 55:22; Lúùkù 18:27.