Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè jáwọ́ nínú àṣà tí kò dáa tó ti mọ́ni lára, kéèyàn sì fi èyí tó dáa rọ́pò rẹ̀, àmọ́ ṣé ó lérè?
Bíbélì sọ pé:
“Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.”—Oníwàásù 7:8.
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti ní àwọn àṣà tó máa ṣe é láǹfààní.