ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 7/8 ojú ìwé 24-26
  • Má Máa Pẹ́ Lẹ́yìn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Máa Pẹ́ Lẹ́yìn!
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Dídé Lásìkò
    Jí!—2016
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 7/8 ojú ìwé 24-26

Má Máa Pẹ́ Lẹ́yìn!

ÌWÉ ìròyìn USA Today ròyìn àbọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ṣíṣàyẹ̀wò ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] àwọn ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́, pé: “Pípẹ́ lẹ́yìn ti di mọ́ọ́lí sára ọ̀pọ̀ ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́. Bí wọ́n bá lọ sí ìpàdé mẹ́wàá, wọ́n á pẹ́ kí wọ́n tó dé mẹ́fà nínú wọn.”

Pípẹ́ lẹ́yìn burú ju nǹkan tá a kàn lè pè ní àṣà burúkú kan tó ti mọ́ àwọn oníṣòwò lára. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa ṣíṣàyẹ̀wò ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́rin [81,000] àwọn tó ń wáṣẹ́ fi hàn pé: “Bí ọ̀pọ̀ wákàtí ṣe ń ṣòfò nítorí pípẹ́ táwọn èèyàn ń pẹ́ dé àti bí wọ́n ṣe ń pa ibi iṣẹ́ jẹ láìtọrọ àyè wà lára àwọn nǹkan pàtàkì tó ń ṣokùnfà bí wọ́n ṣe máa ń pàdánù owó gọbọi.” Àárín àwọn oníṣòwò nìkan kọ́ ni pípẹ́ dé ti máa ń dá ìṣòro sílẹ̀ o. Ìwádìí tí wọ́n ṣe lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ àgbà láwọn ilé ìwé girama fi hàn pé “olórí ìwà ìbàjẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń hù ni pípẹ́ lẹ́yìn, ìwà yìí sì ni ìwà ìbàjẹ́ tó gogò jù lọ láàárín wọn.”

Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká máa fọwọ́ pàtàkì mú àkókò. Ó sọ “àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ńlá méjì,” ìyẹn oòrùn àti òṣùpá, lọ́jọ̀ sáyè wọn kí wọ́n lè máa ràn wá lọ́wọ́ láti díwọ̀n àkókò. (Jẹ́nẹ́sísì. 1:14-16) Lóde òní, àwọn aago ìgbàlódé ń jẹ́ ká díwọ̀n àkókò wa níṣẹ̀ẹ́jú-ìṣẹ́jú àti níṣẹ̀ẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, pẹ̀lú ibi tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ dé dúró yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa ń pẹ́ dé síbi iṣẹ́, sílé ìwé, àti sáwọn ibòmíràn tó bá yẹ kí wọ́n lọ.

Ṣé àìsí àkókò nìkan ló ń fa ìṣòro yìí ni? Òótọ́ ni pé àkókò díẹ̀ kọ́ ló ń náni ká tó ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ká tó bójú tó ìdílé. Síbẹ̀, abiyamọ kan tó tún ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, Wanda Rosseland, sọ pé: “Nígbà tí mo wò ó pé wákàtí mẹ́rìnlélógún náà ni gbogbo wa ní lójúmọ́ ni mo tó yéé ráhùn pé àkókò ò tó mi í lò. Mo ti rò ó dáadáa mo sì ti rí i pé láyé tó dóde yìí, kì í ṣe pé àkókò tá a ní kéré jù ni, ṣùgbọ́n nǹkan tó ń gbà wá lákòókò ló pọ̀ jura lọ.”

Tún wo àpẹẹrẹ ti Renee,a ìyà ọlọ́mọ mẹ́fà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọ mi ṣì kéré, ó máa ń ṣòro fún mi láti múra ilé ìwé àti ìpàdé Kristẹni fún wọn. Síbẹ̀, n kì í pẹ́ lẹ́yìn. Nígbà tí wọ́n dàgbà tán báyìí, mo ti wá dẹni tí pípẹ́ lẹ́yìn ti wọ̀ lẹ́wù.” Ṣé ìwọ náà ní àṣà tí ò dáa yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe láti yí padà! Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé.

● RO ÀTẸ̀YÌNBỌ̀ RẸ̀. Pé kó mọ́ èèyàn lára láti máa pẹ́ lẹ́yìn lè dà bí ohun tí ò tó nǹkan. Àmọ́ kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ: “Àwọn òkú eṣinṣin ní ń mú kí òróró olùṣe òróró ìkunra ṣíyàn-án, kí ó máa hó kùṣọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ṣe sí ẹni tí ó ṣe iyebíye nítorí ọgbọ́n àti ògo.” (Oníwàásù 10:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, “ìwà òmùgọ̀ díẹ̀” tó o hù nípa ṣíṣàì gba tàwọn ẹlòmíì rò lè bà ọ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ olùkọ́ rẹ tàbí ẹni tó gbà ọ́ ṣíṣẹ́.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Marie ṣàkíyèsí pé nígbà tóun ń kẹ́kọ̀ọ́ àgbà nílé ẹ̀kọ́ gíga kan, púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì “ni kì í sábà ka àkókò sí,” wọ́n sábà máa ń pẹ́ dé kíláàsì. Ó ní “kò sí ẹni tó kọ́ wọn tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. Àwọn méjì lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ wa ni kì í fọ̀rọ̀ àkókò bá èèyàn ṣeré. Nítorí náà, bí akẹ́kọ̀ọ́ bá fi ìṣẹ́jú mélòó kan pẹ́ dé, wọ́n á kọ orúkọ wọn pé wọn ò wá nìyẹn. Ẹni tó bá sì ti pa kíláàsì jẹ jù, ipò ẹ̀yìn ló máa mú nínú ìdánwò.”

Tí pípẹ́ lẹ́yìn bá ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù, ó tún lè sọ ọ́ lórúkọ burúkú láàárín àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúgbà rẹ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Joseph tọ́jọ́ orí rẹ̀ á tó bí àádọ́ta ọdún rántí Kristẹni ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan tó mọ̀ lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò kóyán ẹ̀ kéré tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ kinní kan wà tó bà á jẹ́. Joseph sọ pé: “Ó sábà máa ń pẹ́ lẹ́yìn. Àní ṣẹ́, gbogbo ibi ló máa ń pẹ́ dé! Kò sì dà bíi pé ó ka ọ̀rọ̀ náà sí. Àwọn èèyàn máa ń fi pípẹ́ tó ń pẹ́ lẹ́yìn ṣàwàdà.” Ṣé àwọn èèyàn ti ń fojú ẹni tó máa ń pẹ́ lẹ́yìn wò ọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wọn ò ní pẹ́ gbójú fo àwọn ànímọ́ rere tó o ní dá.

● MÁA RO TÀWỌN ẸLÒMÍRÀN MỌ́ TÌẸ. Ìwà àìlọ́wọ̀ ni pípẹ́ lẹ́yìn, ó sì máa ń fa ìpínyà ọkàn fáwọn ẹlòmíràn. Ó sì tún lè jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé o jọra ẹ lójú. Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tó fi dà bíi pé àwọn ọ̀gá àgbá ilé iṣẹ́ sábà máa ń pẹ́ dé sípàdé, ọkùnrin oníṣòwò kan sọ pé: “Ìgbéraga ló ń da èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa láàmú.” Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ńṣe làwọn Kristẹni máa ń ka àwọn ẹlòmíràn sí ẹni tó lọ́lá ju àwọn fúnra wọn lọ. (Fílípì 2:3) Wọ́n tún máa ń tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì náà nípa bíbá àwọn ẹlòmíràn lò bí wọ́n ṣe fẹ́ kí wọ́n máa bá àwọn pẹ̀lú lò. (Mátíù 7:12) Àbí wàá ní kì í dun ìwọ náà bó o bá ní láti máa dúró de ẹlòmíràn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa dúró dè ọ́.

● KỌ́ BÉÈYÀN ṢEÉ ṢỌ́ ÀKÓKÒ LÒ. Ṣé ńṣe lo máa ń sún àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe síwájú dìgbà tó bá kù díẹ̀ kó bọ́ sórí kó o tó máa kánjú ṣe wọ́n? Ṣé o ti máa ń kó nǹkan tó pọ̀ jù síwájú ara ẹ láti ṣe, tí wà á máa gbìyànjú láti ṣe nǹkan púpọ̀ láàárín àkókò kúkúrú? Ìlànà tó wà ní Oníwàásù 3:1 lè ràn ọ́ lọ́wọ́, ó sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” Tó o bá ní ‘àkókò tí o yàn kalẹ̀’ fún àwọn nǹkan tó ò ń ṣe, wà á lè máa ṣe wọ́n létòlétò.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kọ gbogbo nǹkan tó yẹ kó o ṣe sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Fílípì 1:10, tó sọ pe: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Àní sẹ́, fi ohun àkọ́kọ́ sípò àkọ́kọ́. Èwo lo ò gbọ́dọ̀ má ṣe? Kí lo lè fi sílẹ̀ nísinsìnyí tí ò ní fa wàhálà tó o bá ṣe é nígbà míì? Paríparì rẹ̀, ṣírò iye àkókò tá á gbà ọ́ láti ṣe àwọn nǹkan kan àti ìgbà tó o lè ṣe wọ́n. Má ṣe jura ẹ lọ, máà dáwọ́ lé ohun tó pọ̀ jù láàárín àkókò kúkúrú.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Dorothy kan sáárá sáwọn òbí ẹ̀ fún kíkọ́ tí wọ́n kọ́ ọ láti máa ṣe nǹkan lákòókò. Ó ṣàlàyé pé: “Tó bá jẹ́ pé aago méje àbọ̀ alẹ́ ló yẹ ká dé ìpàdé Kristẹni, màmá mi á ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ fún wa látìgbà tó bá ti ku wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta ṣáájú àkókò ìpàdé. A ní láti fàkókò sílẹ̀ fún jíjẹ oúnjẹ alẹ́, fífọ abọ́ tá a fi jẹun, wíwọṣọ, àti wíwakọ̀ dé ìpàdé. Ó ti wá mọ́ wa lára láti máa tètè dé síbi tá a bá ń lọ.” Nígbà míì ó máa ń ṣàǹfààní tá a bá ro tàwọn nǹkan tó lè fa ìdádúró òjijì mọ́ ọn nígbà tá a bá ń ṣírò àkókò tá a fẹ́ fi ṣe nǹkan. Dorothy níran ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó wá sọ pé: “Láìpẹ́ yìí, ó yẹ kí n gbé àwọn èèyàn díẹ̀ dání lọ sí ìpàdé kan. Táyà mọ́tò mi bá jò lójú ọ̀nà. Mo pààrọ̀ táyà náà, mi ò sì pẹ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó yẹ kí n gbé. Ṣé ẹ rí i, mo máa ń ro ti ìgbà tí ọkọ̀ bá máa bà jẹ́ tàbí ìgbà tí ọkọ̀ bá máa pọ̀ jù lójú pópó.”

● MÁA GBÀMỌ̀RÀN ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN. Nínú ìwé Òwe 27:17 Bíbélì sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” Níbàámu pẹ̀lú ìlànà yìí, bá àwọn míì tí ipò yín nínú ìgbésí ayé jọra ṣùgbọ́n tí wọ́n kì í pẹ́ lẹ́yìn sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé wọ́n á ní àwọn ìmọ̀ràn bíi mélòó kan tá á ràn ọ́ lọ́wọ́.

Renee tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú pinnu láti dẹ́kun pípẹ́ lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mo ti pinnu pé láti ìsinsìnyí lọ mi ò ní máa pẹ́ lẹ́yìn mọ́. Lóòótọ́ kò rọrùn fún mi o, àmọ́ mo ti ń rí ìyàtọ̀ nínú bí mo ṣe ń ṣe sí.” Ìwọ pẹ̀lú lè yí padà. Tó o bá ti fi sọ́kàn pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, tó o sì sakun láti yí padà, o ò ní pẹ́ lẹ́yìn mọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Tó bá ti mọ́ ẹnì kan lára láti máa pẹ́ dé, ó lè sọ onítọ̀hún lórúkọ burúkú lójú àwọn agbaniṣíṣẹ́ ó sì lè fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kì í gba tàwọn ẹlòmíràn rò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Tó o bá ṣètò ara ẹ lọ́nà tó dáa, á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má máa fàkókò ṣòfò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́