ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 82
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣọ́ àkókò lò?
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?
    Jí!—2009
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?
    Jí!—2004
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Tí Mo Bá Ń Kàwé Látilé?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 82
Inú ọ̀dọ́kùnrin kan ò dùn torí bó ṣe lo àkókò ẹ̀​—ó kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù, ó sì wo tẹlifíṣọ̀n kó tó ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣọ́ àkókò lò?

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣọ́ àkókò lò?

  • Bí owó ni àkókò rí. Tó o bá ti fi ṣòfò, o ò ní rí i nígbà tó o bá nílò ẹ̀. Àmọ́ tó o bá ṣètò bó o ṣe fẹ́ lo àkókò ẹ, wàá rí i lò bó o ṣe fẹ́, kódà, á tún ṣẹ́ kù láti fi ṣe àwọn nǹkan míì tó o fẹ́ràn!

    Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.”​—Òwe 13:4.

    Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá ń ṣọ́ àkókò ẹ lò, kò ní jẹ́ kí òmìnira ẹ dín kù, ṣe ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira.

  • Ó ṣe pàtàkì kó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ àkókò lò, torí ó máa wúlò fún ẹ tó o bá dàgbà. Kódà, bó o bá ṣe ń lo àkókò ẹ máa pinnu bóyá iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ àbí ó máa pẹ́ lọ́wọ́ ẹ. Ìwọ náà rò ó, tó o bá jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ kan, ṣé o ò ní wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń pẹ́ débi iṣẹ́?

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.”​—Lúùkù 16:10.

    Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Bó o bá ṣe ń lo àkókò sí máa fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn.

Àmọ́ ká sòótọ́, kì í rọrùn láti ṣọ́ àkókò lò. Wo àwọn ohun kan tó lè jẹ́ kó ṣòro.

Ìṣòro #1: Àwọn ọ̀rẹ́

“Táwọn ọ̀rẹ́ mi bá ní ká jọ jáde, kódà kí n má fi bẹ́ẹ̀ ráyè, mo máa ń fẹ́ rí i pé mo tẹ̀ lé wọn. Mo máa ń rò ó pé, ‘Tí n bá pa dà dé, màá sáré ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe jàre.’ Àmọ́ gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rí bí mo ṣe rò, ó sì ti ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́.”​—Cynthia.

Ìṣòro #2: Àwọn ohun tó ń pín ọkàn níyà

“Baba ńlá ìdẹwò ni tẹlifíṣọ̀n. Àwọn eré àtàwọn fíìmù kan wà tó jẹ́ pé ṣe ló máa ń múùyàn mọ́lẹ̀, kì í rọrùn láti jára ẹni gbà.”​—Ivy.

“Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo máa ń fi ṣòfò tí mo bá ti ń tẹ fóònù. Ó máa ń dùn mí pé ó dìgbà tí fóònù ọ̀hún bá kú kí n tó fi sílẹ̀.”​—Marie.

Ìṣòro #3: Fífòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la

“Tó bá di pé kí n ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún wa níléèwé tàbí tí mo fẹ́ ṣe ohunkóhun míì tó yẹ kí n ṣe, ṣe ni mo máa ń fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la. Màá wá máa fi àkókò mi ṣòfò lórí ohun tí ò ní láárí títí á fi wá bọ́ sórí fún mi láti parí iṣẹ́ àṣetiléwá mi. Ẹ ò rí i pé ìyẹn kù díẹ̀ káàtó.”​—Beth.

Inú ọ̀dọ́kùnrin kan ń dùn torí ó ṣọ́ àkókò ẹ̀ lò​—ó kọ́kọ́ kàwé, ó wá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, àkókò tún wá ṣẹ́ kù láti gbá bọ́ọ̀lù

Tó o bá ń ṣọ́ àkókò ẹ lò, kò ní jẹ́ kí òmìnira ẹ dín kù, ṣe ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira

Ohun tó o lè ṣe

  1. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe. Lára ẹ̀ ni àwọn iṣẹ́ ilé àti iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún ẹ níléèwé. Kọ iye àkókò tí ìkọ̀ọ̀kan wọn máa gbà ẹ́ lọ́sẹ̀ kan.

    Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

  2. Kọ àwọn ohun tó máa wù ẹ́ kó o ṣe tọ́wọ́ ẹ bá dilẹ̀. Ó lè jẹ́ lílo ìkànnì àjọlò àti wíwo tẹlifíṣọ̀n. Tún kọ iye wákàtí tó o máa ń lò lórí ìkọ̀ọ̀kan wọn láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n . . . , ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.”​—Kólósè 4:5.

  3. Ṣètò bó o ṣe fẹ́ lo àkókò ẹ. Wo àwọn àkọsílẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó o ti ṣe ṣáájú. Ṣé àkókò tó o pín fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì máa tó? Àbí wàá dín àkókò tó o fẹ́ fi gbafẹ́ kù?

    Àbá: Ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó o máa ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o máa sàmì sí ìkọ̀ọ̀kan tó o bá ṣe ń parí ẹ̀.

    Ìlànà Bíbélì: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”​—Òwe 21:5.

  4. Gbé ìgbésẹ̀. Ká sòótọ́, ó lè gba pé kó o má ráyè bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ jáde tàbí gbafẹ́ lásìkò kan torí kó o lè ráyè ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wàá rí i pé o túbọ̀ rí àyè ìgbafẹ́, wàá sì túbọ̀ gbádùn ẹ̀.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín.”​​—Róòmù 12:11.

  5. Fúnra ẹ ní kóríyá lákòókò tó tọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tara sọ pé, “Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé tí mo bá ti parí méjì nínú àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kan, màá rò ó pé, ‘Jẹ́ n wo tẹlifíṣọ̀n ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kí n tó máa báṣẹ́ lọ.’ Ni ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún á bá di ọgbọ̀n ìṣẹ́jú mọ́ mi lọ́wọ́, ká tó wí ká tó fọ̀, ó ti di wákàtí kan, kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, mo ti fi wákàtí méjì ṣòfò nídìí tẹlifíṣọ̀n!”

    Ohun tó o lè ṣe ni pé ìgbà tó o bá parí iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kan ni kó o tó gbafẹ́ láti ṣe kóríyá fúnra ẹ. Má wò ó pé o parí iṣẹ́ o, o ò parí iṣẹ́ o, o lè gbafẹ́ tó bá wù ẹ́.

    Ìlànà Bíbélì: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó . . . jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”​—Oníwàásù 2:​24.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Cheyenne

“Ṣe ni mo máa ń kọ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe sílẹ̀ kí n lè rí iṣẹ́ tó wà níwájú mi. Kódà, mo máa ń ṣètò àkókò tó pa rọ́rọ́ tí mo máa fi dá wà kí n lè lókun pa dà. Tí mo bá ti ṣètò àkókò mi, ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ tí mo bá ti ń kọjá àyè mi, ó sì máa ń jẹ́ kí n ríbi tí àtúnṣe ti lè wọlé.”​—Cheyenne.

Samuel

“Mo ti kọ́ ọ pé tí ohun kan bá wà tí mi ò ní lè ṣe, kí n kúkú lahùn pé mi ò lè ṣe é. Àtisọ bẹ́ẹ̀ lè má rọrùn, àmọ́ mi ò tíì rí i kẹ́nì kan fara ya fún mi torí pé mo ṣàlàyé fún un pé ìdí tí mi ò fi ní lè ṣe nǹkan tó fẹ́ kí n ṣe ni pé mi ò ní lè pọkàn pọ̀ ṣe é.”​—Samuel.

Brooklyn

“Nígbà míì tí ọwọ́ mi bá dí dójú àmì, ó máa ń ṣe mí bíi kí n má sùn tàbí kí n má ṣe eré ìmárale. Àmọ́ ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé oorun tí mo bá rọ́jú sùn tàbí eré ìmárale tí mo ṣe yẹn láá jẹ́ kí n túbọ̀ lókun, kí n sì láyọ̀ lọ́jọ́ kejì. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn mójú tó ìlera ẹ̀.”​​—Brooklyn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́