ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 101
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Tí Mo Bá Ń Kàwé Látilé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Tí Mo Bá Ń Kàwé Látilé?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn àbá márùn-ún tó máa jẹ́ kó o lè ṣàṣeyọrí
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ǹjẹ́ Mo Lè Túbọ̀ Ṣe Dáradára Nílé Ẹ̀kọ́?
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?
    Jí!—2009
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 101
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń kẹ́kọ̀ọ́ nídìí tábìlì kan nítòsí wíńdò inú ilé rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Tí Mo Bá Ń Kàwé Látilé?

Ọ̀pọ̀ ọmọ ilé ìwé ló ti ń kẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi “kíláàsì” báyìí, ìyẹn nínú ilé wọn. Tó bá jẹ́ pé ohun tíwọ náà ń ṣe nìyẹn, báwo lo ṣe lè jàǹfààní tó pọ̀ níbẹ̀? Àwọn àbá díẹ̀ rèé.a

  • Àwọn àbá márùn-ún tó máa jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Àwọn àbá márùn-ún tó máa jẹ́ kó o lè ṣàṣeyọrí

  • Ṣètò ohun tí wà á máa ṣe. Rí i pé o ní ìṣètò tí ò ń tẹ̀ lé déédéé bó o ṣe máa ṣe nílé ìwé. Ṣètò àkókò pàtó tó máa fi ṣe iṣẹ́ ilé ìwé, iṣẹ́ ilé àtàwọn ohun míì tó ṣe pàtàkì. O lè tún ètò rẹ ṣe tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ . . . nípa ètò.”​—⁠1 Kọ́ríńtì 14:​40, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

    “Ṣètò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ilé ìwé lo wà. Ó yẹ kó o ní àkókò pàtó tí wàá máa ṣe àwọn ohun kan.”​—⁠Katie.

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tó fi dáa kó o kọ àwọn ètò tó o ṣe, kó o sì fi í síbi tí wàá ti tètè rí i?

  • Máa kó ara rẹ níjàánu. Kó o lè fi hàn pé ò ń hùwà àgbà, ó yẹ kó o ṣe ohun tó bá yẹ kó o ṣe, kódà nígbà tí kò wù ẹ́ láti ṣe é. Má fòní dónìí, fọ̀la dọ́la!

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára, ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín.”​—⁠Róòmù 12:​11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

    “Olórí ìṣòro ni kéèyàn kó ara ẹ̀ níjàánu. Ó rọrùn láti sọ pé, ‘Màá ṣe iṣẹ́ ilé ìwé mi tó bá yá.’ Oò sì ní lè ṣe é nígbà yẹn, iṣẹ́ tó pọ̀ á wá wà fún ẹ láti ṣe.”​—⁠Alexandra.

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ ilé ìwé ẹ níbi kan náà àti lákòókò kan náà, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó o túbọ̀ kó ara ẹ níjàánu?

  • Ṣètò ibi tó o ti lè kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kí gbogbo ohun tó o nílò wà nítòsí ẹ. Jẹ́ kí ibi tó o ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ tù ẹ́ lára, àmọ́ ibẹ̀ ò gbọdọ̀ tù ẹ́ lára débi táá fi mú kórun kùn ẹ́. Iṣẹ́ ló fẹ́ ṣe níbẹ̀, kìí ṣe oorun lo wá sùn! Tí kò bá sí ibi tíwọ nìkan ti lè ṣe iṣẹ́ ilé ìwé ẹ, o lè lo ilé ìdáná tàbí yàrá ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ọ̀sán.

    Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”​—⁠Òwe 21:⁠5.

    “Mú bọ́ọ̀lù, géèmù, àwọn ohun èlò ìkọrin kúrò nítòsí ẹ, kó o sì yí fóònù rẹ wálẹ̀. Kó o tó lè kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kó o mú àwọn ohun tó lè pín ọkàn ẹ níyà kúrò nítòsí ẹ.”​—⁠Elizabeth.

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí làwọn ohun tó yẹ kó o ṣàtúnṣe sí níbi tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ kó lè túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti pọkàn pọ̀?

  • Kọ́ bí wà á ṣe máa pọkàn pọ̀. Pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń ṣe, má sì ṣe ohun míì lákòókò kan náà. Tó o bá ń ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, o lè ṣàṣìṣe, o sì máa lo ọ̀pọ̀ àkókò kó o tó lè parí iṣẹ́ rẹ.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ [lo] àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—⁠Éfésù 5:⁠16.

    “Mi ò lè pọkàn pọ̀ tí fóònù mi bá wà nítòsí mi. Ọ̀pọ̀ àkókò ni mo fi ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò nítumọ̀.”​—⁠Olivia.

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣó o lè máa fi kún àkókò tó o lè fi pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ kan díẹ̀díẹ̀?

  • Máa sinmi. Rìn jáde, gun kẹ̀kẹ́, tàbí kó o ṣeré ìmárale. Eré ìdárayá tún lè jẹ́ kó o lókun sí i. Ìwé náà School Power sọ pé “Kọ́kọ́ parí iṣẹ́ ẹ ná, ìgbà tó o bá parí gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe lo máa túbọ̀ gbádùn àkókò ìsinmi ẹ.”

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”​—⁠Oníwàásù 4:⁠6.

    “Ní ilé ìwé, o lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan tàbí kó o lọ sí kíláàsì tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ọnà. Ìgbà tí mi ò láǹfààní láti kọ́ àwọn nǹkan yẹn mọ́ ni mo tó mọ̀ pé ó yẹ kí n ti kọ́ ọ. Láfikún sí ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́, ó dáa kó o mọ̀ nípa ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ọnà.”​—⁠Taylor.

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Báwo ló ṣe yẹ kó o sinmi tó tí wàá fi lókun láti ṣe iṣẹ́ ilé ìwé rẹ?

a Oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè gbà kàwé látilé. Lo àbá èyíkéyìí tó bá ipò rẹ mú lára èyí tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Jacob.

“Máa sinmi léraléra àmọ́ má jẹ́ kó pẹ́. Ó lè má rọrùn láti jókòó fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àmọ́ á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti pọkàn pọ̀ tó o bá ń dìde léraléra, kò sì ní jẹ́ kí nǹkan sú ẹ.”—Jacob.

Juliana.

“Tó o bá ń dúró dìgbà tẹ́nì kan máa sọ ohun tó yẹ kó o ṣe, kò sóhun tí wà á lè ṣe. Ní àfojúsùn ohun tó yẹ kó ṣe lójoojúmọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún ẹ láti parí iṣẹ́ rẹ.”—Juliana.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo ni mo ṣe lè ṣàṣeyọrí tí mo bá ń kàwé látilé?

  • Ṣètò ohun tí wà á máa ṣe. Tí o ò bá ní ètò tí ò ń tẹ̀ lé fún iṣẹ́ ilé ìwé rẹ, ṣètò rẹ̀ kó o sì máa tẹ̀ lé e.

  • Máa kó ara rẹ níjàánu. Kọ́ bó o ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó yẹ kó o ṣe, kódà tí kò bá wù ẹ́ láti ṣe.

  • Ṣètò ibi tó o ti lè kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kí ibi tó o ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ tù ẹ́ lára, àmọ́ kò gbọdọ̀ tù ẹ́ lára débi táá fi mú kórun kùn ẹ́. Mú ohunkóhun tó lè pín ọkàn ẹ níyà kúrò.

  • Kọ́ bí wà á ṣe máa pọkàn pọ̀. Pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń ṣe, má sì ṣe ohun míì lákòókò kan náà.

  • Máa sinmi. Eré ìmárale tàbí eré ìdárayá lè jẹ́ kó o lókun sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́