Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Fà Á Tó Fi Ń Hu Irú Ìwà Yìí sí Mi?
“[Ọ̀rẹ́kùnrin ] mi sábà máa ń purọ́ nǹkan tí mi ò lè ṣe mọ́ mi. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ẹ̀ ti kó sí mi lórí.”—Kathrin.a
“Èèyàn ò lè rí [àpá kankan] o, àmọ́ nínú lọ́hùn-ún ó ń dùn mí gan-an ni.”—Andrea, tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ fọ́ létí.
KÌ Í ṣe nǹkan tójú ò rí rí: Pé ọ̀dọ́bìnrin kan ń fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó dà bíi pé ó rẹwà lọ́kùnrin, tó sì mọ̀wà hù. Àfi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Ó wá di pé kí èébú àti àbùkù rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́. Nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ọmọbìnrin náà rò pé ó ń bá òun fọ̀rọ̀ dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ ni. Àmọ́, nígbà tó yá ló di kí ọmọkùnrin náà máa nà án ní pàṣán ọ̀rọ̀, kó máa fara ya, tá sì wá máa kábàámọ̀ lẹ́yìn tó bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán. Ọmọbìnrin náà máa ń rò pé ẹjọ́ òun ni gbogbo bí ọmọkùnrin náà ṣe ń hùwà, á sì máa pa á mọ́ra nírètí pé nǹkan máa tó yí padà. Ṣùgbọ́n nǹkan ò mà yí padà o. Ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ti wá bá a débi kó máa jágbe mọ́ ọn kó sì máa ké lé e lórí. Nígbà kan tínú bí i, o tiẹ̀ taari ọmọbìnrin yìí dànù! Ẹ̀rù bà á pé bí irú ẹ̀ bá tún wáyé, ó máa lu òun ni.b
Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní olólùfẹ́ tó máa ń lù wọ́n tàbí tó ń bú wọn ni irú àwọn olólùfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń kàn lábùkù, wọ́n máa ń láálí wọn, wọ́n sì tún máa ń jágbe mọ́ wọn. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà? (Wo àpótí náà “Díẹ̀ Lára Àwọn Àmì Tó Lè Kì Ọ́ Nílọ̀.”) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìrònú lè dorí ẹ kodò kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ débi pé o ò tiẹ̀ ní mọ èyí tí wà á ṣe mọ́.
Ohun tá à ń sọ yìí kì í ṣe ohun tójú ò rí rí, bó o ṣe lè máa rò. Àwọn olùwádìí sọ pé tá a bá kó ẹni márùn-ún jọ, a óò rí ẹnì kan tí ẹni tó ń fẹ́ sọ́nà ti hùwà ipá sí lọ́nà kan ṣá. Bí wọ́n bá wá ka nínani lẹ́gba ọ̀rọ̀ kún ìwà ipá, á óò rí tó ẹni mẹ́rin nínú márùn-ún. Obìnrin nìkan làwọn èèyàn máa ń fọkàn sí pé wọ́n máa ń fìyà jẹ lọ́nà yìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ìwádìí kan tó dá lórí ìwà ipá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà, èyí tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ṣàwárí rẹ̀ pé “bákan náà ni iye àwọn obìnrin àti ọkùnrin” tí wọ́n sọ pé olólùfẹ́ àwọn ń fìyà jẹ àwọn ṣe pọ̀ tó.c
Kí ló dé tí irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé láàárín àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà? Kí ló yẹ kó o ṣe bó o bá bára ẹ nírú ipò yìí?
Mímọ Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Wo Ọ̀ràn Náà
Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ bọ́ràn náà ṣe lágbára tó lójú Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé àwọn ẹ̀dá aláìpé ò lè ṣe kí wọ́n má sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n hùwà tó lè dun ẹlòmíràn. (Jákọ́bù 3:2) Òótọ́ sì ni pẹ̀lú pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èdèkòyédè máa ń wà láàárín àwọn ẹni méjì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni tó dàgbà dénú ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Síbẹ̀ “ìbújáde ìbínú mímúná” wáyé láàárín wọn nígbà kan. (Ìṣe 15:39) Nítorí náà tó o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, gbún-gbùn-gbún lè máa ṣẹlẹ̀ látìgbàdégbà.
Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò bọ́gbọ́n mu láti máa rò pé àfẹ́sọ́nà rẹ ò ní sọ̀rọ̀ tó le koko. Ṣebí ẹ fẹ́ fẹ́ra yín sílé ni. Bó bá lohun kan tí ò tẹ́ ẹ lọ́rùn lára ìwà ẹ tàbí lára nǹkan tó ò ń ṣe, ṣé kì í ṣe àmì pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ ni tó bá bá ọ sọ ọ́? Lóòótọ́, ó máa ń dùn wá bí wọ́n bá ṣàríwísí nípa wa. (Hébérù 12:11) Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ló sún un débẹ̀ tó sì jẹ́ pé tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ṣe é, ìyẹn kì í ṣe èébú.—Òwe 27:6.
Àmọ́ ṣá o, eléyìí yàtọ̀ sí pípariwo léni lórí, gbígbáni létí, gbígbáni lẹ́ṣẹ̀ẹ́, tàbí yíyẹ̀yẹ́ ẹni. Bíbélì ò fọwọ́ sí “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú [àti] ọ̀rọ̀ èébú.” (Kólósè 3:8) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an bí ẹnì kan bá ń lo “agbára” rẹ̀ láti wọ́ ẹlòmíràn nílẹ̀, láti dẹ́rù bà á, tàbí kó fojú ẹ̀ gbolẹ̀. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Kódà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọkọ láti “máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn . . . , nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Éfésù 5:28, 29) Ẹni tó bá ń bú obìnrin tó ń fẹ́ sọ́nà tàbí tó ń fìyà jẹ ẹ́ ń fira ẹ̀ hàn bí ẹni tí ò ṣe é fi ṣọkọ. Bákan náà ló ń kọ̀wé sí ìbínú Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀!
Ìwọ Kọ́ Lo Fà Á!
Síbẹ̀, àwọn tó ń gboni mọ́lẹ̀ yìí máa ń di ẹ̀bi ìwà tí wọ́n ń hù ru àwọn tí wọ́n ń jẹ níyà. Nítorí náà, nígbà míì ìwọ náà ti lè máa rò pé ìwọ lo fà á tí àfẹ́sọ́nà ẹ fi máa ń bínú ṣáá. Ṣùgbọ́n, ó lè jẹ́ pé ohun tó ń bí i nínú ò fi bẹ́ẹ̀ kàn ọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti máa ń jà tàbí tí wọ́n ti máa ń búra wọn bí ẹní láyin ni wọ́n ti tọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó ń fìyà jẹni dàgbà.d Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àṣà pé ọmọkùnrin ò gbọ́dọ̀ gbàgbàkugbà tó gba ìgboro ti kó sáwọn ọ̀dọ́kùnrin lórí. Àwọn ojúgbà ọmọkùnrin kan tún lè tì í láti máa lo ògbójú bí ọkùnrin. Bó bá jẹ́ ẹni tí ò dára ẹ̀ lójú ni, gbogbo nǹkan tó o bá sọ tàbí ohun tó o bá ṣe lá máa bà á lẹ́rù.
Èyí ó wù kó jẹ́, ìwọ kọ́ lo fà á tó fi ń fara ya. Kò sídìí kankan tó fi yẹ kó máa bú ẹ, tàbí kó máa lù ẹ́.
Yíyí Èrò Rẹ Padà
Síbẹ̀, ó lè jẹ́ pé ìwọ gan-an lo máa yí èrò ẹ nípa ọ̀rọ̀ náà padà. Bíi báwo? Wò ó ná, tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti máa ń lura wọn tí wọ́n sì máa ń láálí ara wọn ni wọ́n ti tọ́ ọmọbìnrin kan dàgbà, ó lè máà rí nǹkan tó burú nínú fífìyàjẹni. Dípò kó fi hàn pé irú ìwà tí ò yẹ Kristẹni bẹ́ẹ̀ kò tẹ́ òun lọ́rùn, ó lè fara mọ́ ọn—irú ìwà bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè máa dá a lọ́rùn. Àní àwọn kan tí wọ́n máa ń fìyà jẹ gbà pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọkùnrin tó bá níwà pẹ̀lẹ́. Ohun tó máa ń jẹ àwọn ọ̀dọ́bìnrin míì níyà ni pé wọ́n máa ń tanra wọn jẹ pé àwọ́n lè yí ọ̀rẹ́kùnrin àwọn padà.
Bí èyíkéyìí nínú ohun tá a sọ lókè yìí bá ń ṣe ẹ́, ó yẹ kó o “para dà nípa yíyí èrò inú [rẹ] padà” lápá ibí yìí. (Róòmù 12:2) Máa gbàdúrà, máà kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò kó o lè fi bí Jèhófà ṣe ń wo fífìyàjẹni sọ́kàn, kó o sì máa wò ó bí ohun tí ò sunwọ̀n. Ó yẹ kó yé ẹ pé o kì í ṣe ẹran ìyà, kò yẹ kí ẹnì kankan máa fìyà jẹ ẹ́. Bó o bá mọ̀wọ̀n ara ẹ, ìyẹn ni pé tó o bá mọbi tágbára ẹ mọ, wà á rí i dájú pé o ò lè yí onínúfùfù ọ̀rẹ́kùnrin padà. Ẹ̀tọ́ tiẹ̀ ni pé kó yí padà!—Gálátíà 6:5.
Nígbà míì, àwọn ọmọbìnrin mìíràn ti ro ara wọn pin ló jẹ́ kí wọ́n máa forí rọ́ ìyà tí ọ̀rẹ́kùnrin wọn fi ń jẹ wọ́n. Kathrin, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ lè sọ bí ìgbésí ayé mi a ṣe rí tí ò bá sí i, àti pé mi ò rò pé mo lè rí ẹlòmíì tó dáa jù ú lọ fẹ́.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Helga sọ nípa àfẹ́sọ́nà ẹ̀ pé: “Mo máa ń jẹ́ kó nà mí nítorí pé ìyẹn dáa ju pé kí n má tiẹ̀ rẹ́ni wojú mi rárá.”
Ṣé o rò pé béèyàn bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ó ń fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìgbéyàwó aláyọ̀? Ṣé o lè nífẹ̀ẹ́ ẹlòmíì dénú bó ò bá nífẹ̀ẹ́ ara rẹ ? (Mátíù 19:19) Ṣiṣẹ́ lórí bó o ṣe máa fi ara ẹ sípò ọ̀wọ̀ tó tọ́ sí ẹ.e Fífarada ìfìyàjẹni ò ní ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìrírí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Irena kọ́ ọ pé fífara da ìfìyàjẹni yóò “já iyì rẹ gbà mọ́ ọ lọ́wọ́.”
Má Ṣe Tan Ara Rẹ Jẹ
Ó lè ṣòro fáwọn kan láti gbà pé ohun táwọn kà sí ìfẹ́sọ́nà yìí léwu fáwọn, pàápàá jù lọ bí ìfẹ́ bá ti kó sí wọn lórí. Ṣùgbọ́n, má ṣe tan ara rẹ jẹ. Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Hanna rántí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Tí ìfẹ́ bọ̀bọ́ yẹn bá ti kó sí ẹ lórí tán, bí afọ́jú ni wà á ṣe máa ṣe, gbogbo ohun tó bá ti ṣe náà lá máa dáa lójú ẹ.” Àmọ́ ṣá o, tó bá ń fìyà jẹ ẹ́, ó ṣe pàtàkì pé kó o kíyè sí irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Bí ọ̀rẹ́kùnrin ẹ bá ń ṣe nǹkan tó ń jẹ́ kẹ́rù máa bà ọ́, tàbí tí ò kà ẹ́ sí, a jẹ́ pé ewu ń bẹ. Má ṣe tanra ẹ jẹ, tàbí kó o máa wá bí wà á ṣe dá a láre, tí wà á sì máa dá ara ẹ lẹ́bi. Ìrírí ti fi hàn pé bí ò bá kọwọ́ ọmọ ẹ̀ bọṣọ, ìwà ìfìyàjẹni tó ń hù á máa gogò sí i ni. Ẹ̀mí ẹ sì lè má dè mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀!
Látilẹ̀wá gan-an ni ò tiẹ̀ ti yẹ kó o gbà láti fẹ́ ẹni tí ò ní ìkóra-ẹni-níjàánu. (Òwe 22:24) Nítorí náà bí ẹnì kan tó ò mọ̀ dáadáa bá kọnu sí ọ, á dáa kó o lọ wádìí àwọn nǹkan kan nípa ẹ̀ ná. O ò ṣe kọ́kọ́ sọ fún un pé kó jẹ́ kẹ́ ẹ ṣì máa wo ara yín níbi térò bá pọ̀ sí ná? Èyí á jẹ́ kó o lè mọ̀ ọ́n láìsí pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ń tètè wọ̀ ọ́. Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè tó nítumọ̀ bí: Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀? Irú orin wo, irú fíìmù wo, irú ayò orí kọ̀ǹpútà àti irú eré ìdárayá wo ló fẹ́ràn? Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí? Bá àwọn tó mọ̀ ọ́n sọ̀rọ̀, irú bí àwọn alàgbà ìjọ ẹ̀. Wọ́n á jẹ́ kó o mọ̀ báwọn ẹlòmíì bá ń “ròyìn rẹ̀ dáadáa” nítorí ìwà àgbà àti ìwà tínú Ọlọ́run dùn sí tó ń hù.—Ìṣe 16:2.
Ṣùgbọ́n kí lo lè ṣe ká ní o ti wá ń fẹ́ ẹnì kan tó ń fìyà jẹ ọ́? Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà yóò dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Àpilẹ̀kọ yìí dá lórí àwọn tí wọ́n ń nà lẹ́gba ọ̀rọ̀ àti àwọn tí wọ́n ń lù. Ìmọ̀ràn tó sì lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣe é sí ẹlòmíràn wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí, “Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára” àti “Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?” tó jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa ti October 22, 1996, àti March 22, 1997.
c Kí ohun tá à ń jíròrò lè ṣe kedere, a ó máa sọ̀rọ̀ bí ẹni pé obìnrin lẹ́ni tí wọ́n ń fìyà jẹ. Àwọn ìlànà tí a óò jíròrò níbí yìí kan tọkùnrin, tobìnrin.
d Wo àpilẹ̀kọ náà “Títúdìí Gbòǹgbò Èébú,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti October 22, 1996.
e Wo orí kejìlá ìwé náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Díẹ̀ Lára Àwọn Àmì Tó Lè Kì Ọ́ Nílọ̀
◼ Ó máa ń fọ̀rọ̀ tàbùkù ẹ, ìdílé ẹ, àtàwọn ọ̀rẹ́ yálà nígbà tó bá ku ìwọ àti ẹ̀ nìkan tàbí nígbà tẹ́ ẹ bá wà láàárín àwọn ẹlòmíì
◼ Kì í sábà ṣe bí ẹni tó wojú ẹ láti mọ nǹkan tó o fẹ́ àti bó ṣe ń ṣe ẹ́
◼ Ó máa ń fẹ́ dárí ẹ síbi tó bá wù ú, gbogbo ibi tó o bá yà sí ló máa ń fẹ́ mọ̀ tá sì fẹ́ máa pinnu gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe fún ẹ
◼ Ó máa ń jágbe mọ́ ẹ, ó máa ń gbún ẹ tàbí kó tì ẹ́ dànù, ó sì máa ń halẹ̀ mọ́ ẹ
◼ Ó máa ń gbìyànjú láti tàn ẹ́ ṣe erékéré kí ẹ lè fi ìfẹ́ hàn lọ́nà tí ò dáa
◼ Kò sí nǹkan tó o lè ṣe tó ò ní máa bẹ̀rù bóyá á bí i nínú lọ́nà kan ṣá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bó bá ń tako ẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, ó lè jẹ́ pé ìfẹ́sọ́nà yín yẹn léwu nìyẹn